سورة المجادلة باليوربا

  1. استمع للسورة
  2. سور أخرى
  3. ترجمة السورة
القرآن الكريم | ترجمة معاني القرآن | اللغة اليوربا | سورة المجادلة | Mujadilah - عدد آياتها 22 - رقم السورة في المصحف: 58 - معنى السورة بالإنجليزية: The Pleading.

قَدْ سَمِعَ اللَّهُ قَوْلَ الَّتِي تُجَادِلُكَ فِي زَوْجِهَا وَتَشْتَكِي إِلَى اللَّهِ وَاللَّهُ يَسْمَعُ تَحَاوُرَكُمَا ۚ إِنَّ اللَّهَ سَمِيعٌ بَصِيرٌ(1)

Dajudaju Allahu ti gbo oro (obinrin) t’o n ba o se ariyanjiyan nipa oko re, ti o si n saroye fun Allahu. Allahu si n gbo isorogbesi eyin mejeeji. Dajudaju Allahu ni Olugbo, Oluriran

الَّذِينَ يُظَاهِرُونَ مِنكُم مِّن نِّسَائِهِم مَّا هُنَّ أُمَّهَاتِهِمْ ۖ إِنْ أُمَّهَاتُهُمْ إِلَّا اللَّائِي وَلَدْنَهُمْ ۚ وَإِنَّهُمْ لَيَقُولُونَ مُنكَرًا مِّنَ الْقَوْلِ وَزُورًا ۚ وَإِنَّ اللَّهَ لَعَفُوٌّ غَفُورٌ(2)

Awon t’o n fi eyin iyawo won we ti iya won ninu yin, awon iyawo ki i se iya won. Ko si eni ti o je iya won bi ko se iya ti o bi won lomo. Dajudaju won n so aburu ninu oro ati oro iro. Dajudaju Allahu ni Alamoojukuro, Alaforijin

وَالَّذِينَ يُظَاهِرُونَ مِن نِّسَائِهِمْ ثُمَّ يَعُودُونَ لِمَا قَالُوا فَتَحْرِيرُ رَقَبَةٍ مِّن قَبْلِ أَن يَتَمَاسَّا ۚ ذَٰلِكُمْ تُوعَظُونَ بِهِ ۚ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ(3)

Awon t’o n fi eyin iyawo won we ti iya won, leyin naa ti won n seri kuro nibi ohun ti won so, won maa tu eru kan sile loko eru siwaju ki awon mejeeji to le sunmo ara won. Iyen ni A n fi se waasi fun yin. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

فَمَن لَّمْ يَجِدْ فَصِيَامُ شَهْرَيْنِ مُتَتَابِعَيْنِ مِن قَبْلِ أَن يَتَمَاسَّا ۖ فَمَن لَّمْ يَسْتَطِعْ فَإِطْعَامُ سِتِّينَ مِسْكِينًا ۚ ذَٰلِكَ لِتُؤْمِنُوا بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ ۚ وَتِلْكَ حُدُودُ اللَّهِ ۗ وَلِلْكَافِرِينَ عَذَابٌ أَلِيمٌ(4)

Eni ti ko ba ri (eru), o maa gba aawe osu meji ni telentele siwaju ki awon mejeeji t’o le sunmo ara won. Eni ti ko ba ni agbara (aawe), o maa bo ogota talika. Iyen nitori ki e le ni igbagbo ododo ninu Allahu ati Ojise Re. Iwonyi si ni awon enu-ala (ofin) ti Allahu gbe kale fun eda. Iya eleta-elero si wa fun awon alaigbagbo

إِنَّ الَّذِينَ يُحَادُّونَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ كُبِتُوا كَمَا كُبِتَ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۚ وَقَدْ أَنزَلْنَا آيَاتٍ بَيِّنَاتٍ ۚ وَلِلْكَافِرِينَ عَذَابٌ مُّهِينٌ(5)

Dajudaju awon t’o n yapa Allahu ati Ojise Re, A oo yepere won gege bi A se yepere awon t’o siwaju won. A kuku ti so awon ayah t’o yanju kale. Iya ti i yepere eda si wa fun awon alaigbagbo

يَوْمَ يَبْعَثُهُمُ اللَّهُ جَمِيعًا فَيُنَبِّئُهُم بِمَا عَمِلُوا ۚ أَحْصَاهُ اللَّهُ وَنَسُوهُ ۚ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدٌ(6)

Ni ojo ti Allahu yoo gbe gbogbo won dide, O si maa fun won ni iro ohun ti won se nise. Allahu se akosile re, awon si gbagbe re. Allahu si ni Arinu-rode gbogbo nnkan

أَلَمْ تَرَ أَنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۖ مَا يَكُونُ مِن نَّجْوَىٰ ثَلَاثَةٍ إِلَّا هُوَ رَابِعُهُمْ وَلَا خَمْسَةٍ إِلَّا هُوَ سَادِسُهُمْ وَلَا أَدْنَىٰ مِن ذَٰلِكَ وَلَا أَكْثَرَ إِلَّا هُوَ مَعَهُمْ أَيْنَ مَا كَانُوا ۖ ثُمَّ يُنَبِّئُهُم بِمَا عَمِلُوا يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۚ إِنَّ اللَّهَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ(7)

Se o o ri i pe dajudaju Allahu mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile ni? Ko si oro ikoko kan laaarin eni meta afi ki Allahu se ikerin won ati eni marun-un afi ki O se ikefa won. Won kere si iyen, won tun po (ju iyen) afi ki O wa pelu won ni ibikibi ti won ba wa. Leyin naa, O maa fun won ni iro ohun ti won se nise ni Ojo Ajinde. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan. ayah yii ko tumo si pe Paapaa Bibe Allahu wa lori ile aye tabi pe Paapaa Bibe Allahu wa pelu eni kookan. Ti Allahu ba se ikeji eni kan tabi O se iketa eni meji bi ko se pe wiwa Allahu pelu eda Re ni pe “Allahu n gbo ohun eda” ninu surah al-Waƙi‘ah; 56:85 isunmo ti Allahu sunmo eda ju bi a se sunmo ara wa lo duro fun bi awon molaika olugbemi-eda se maa sunmo eni kookan ni akoko ti emi ba fe jade lara eda. Eyi rinle bee ninu ayah 83 ati 84 ninu surah naa. Nitori naa isunmo ti Allahu n toka si ninu awon ayah wonyen ati iru won miiran ko tumo si isokale Allahu wa si inu isan orun eda

أَلَمْ تَرَ إِلَى الَّذِينَ نُهُوا عَنِ النَّجْوَىٰ ثُمَّ يَعُودُونَ لِمَا نُهُوا عَنْهُ وَيَتَنَاجَوْنَ بِالْإِثْمِ وَالْعُدْوَانِ وَمَعْصِيَتِ الرَّسُولِ وَإِذَا جَاءُوكَ حَيَّوْكَ بِمَا لَمْ يُحَيِّكَ بِهِ اللَّهُ وَيَقُولُونَ فِي أَنفُسِهِمْ لَوْلَا يُعَذِّبُنَا اللَّهُ بِمَا نَقُولُ ۚ حَسْبُهُمْ جَهَنَّمُ يَصْلَوْنَهَا ۖ فَبِئْسَ الْمَصِيرُ(8)

Se o o ri awon ti A ko oro ikoko fun, leyin naa ti won tun pada sibi ohun ti A ko fun won. Won n bara won so oro ikoko lori ese, abosi ati iyapa Ojise. Nigba ti won ba si de odo re, won yoo ki o ni kiki ti Allahu ko fi ki o. Won si n wi sinu emi won pe: "Ki ni ko je ki Allahu je wa niya lori ohun ti a n wi (ni ikoko)!" Ina Jahnamo maa to won. Won maa wo inu re. Ikangun naa si buru

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا تَنَاجَيْتُمْ فَلَا تَتَنَاجَوْا بِالْإِثْمِ وَالْعُدْوَانِ وَمَعْصِيَتِ الرَّسُولِ وَتَنَاجَوْا بِالْبِرِّ وَالتَّقْوَىٰ ۖ وَاتَّقُوا اللَّهَ الَّذِي إِلَيْهِ تُحْشَرُونَ(9)

Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba n bara yin so oro ikoko, e ma se so oro ikoko lori ese, abosi ati iyapa Ojise. E bara yin so oro ikoko lori ise rere ati iberu Allahu. E beru Allahu, Eni ti won yoo ko yin jo si odo Re

إِنَّمَا النَّجْوَىٰ مِنَ الشَّيْطَانِ لِيَحْزُنَ الَّذِينَ آمَنُوا وَلَيْسَ بِضَارِّهِمْ شَيْئًا إِلَّا بِإِذْنِ اللَّهِ ۚ وَعَلَى اللَّهِ فَلْيَتَوَكَّلِ الْمُؤْمِنُونَ(10)

Dajudaju oro ikoko (buruku) n wa lati odo Esu nitori ki o le ko ibanuje ba awon t’o gbagbo ni ododo. Ko si le fi kini kan ko inira ba won afi pelu iyonda Allahu. Allahu si ni ki awon onigbagbo ododo gbarale

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا قِيلَ لَكُمْ تَفَسَّحُوا فِي الْمَجَالِسِ فَافْسَحُوا يَفْسَحِ اللَّهُ لَكُمْ ۖ وَإِذَا قِيلَ انشُزُوا فَانشُزُوا يَرْفَعِ اللَّهُ الَّذِينَ آمَنُوا مِنكُمْ وَالَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ دَرَجَاتٍ ۚ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ(11)

Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti won ba so fun yin pe ki e gbara yin laye ninu awon ibujokoo, e gbara yin laye. Allahu yoo f’aye gba yin. Nigba ti won ba so pe: "E dide (sibi ise rere)." E dide (si i). Allahu yoo sagbega awon ipo fun awon t’o gbagbo ni ododo ati awon ti A fun ni imo ninu yin. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا نَاجَيْتُمُ الرَّسُولَ فَقَدِّمُوا بَيْنَ يَدَيْ نَجْوَاكُمْ صَدَقَةً ۚ ذَٰلِكَ خَيْرٌ لَّكُمْ وَأَطْهَرُ ۚ فَإِن لَّمْ تَجِدُوا فَإِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ(12)

Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba ba Ojise soro ateso, e fi ore tita siwaju oro ateso yin. Iyen loore julo fun yin. O si fo yin mo julo. Ti e o ba si ri (ore), dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

أَأَشْفَقْتُمْ أَن تُقَدِّمُوا بَيْنَ يَدَيْ نَجْوَاكُمْ صَدَقَاتٍ ۚ فَإِذْ لَمْ تَفْعَلُوا وَتَابَ اللَّهُ عَلَيْكُمْ فَأَقِيمُوا الصَّلَاةَ وَآتُوا الزَّكَاةَ وَأَطِيعُوا اللَّهَ وَرَسُولَهُ ۚ وَاللَّهُ خَبِيرٌ بِمَا تَعْمَلُونَ(13)

Se e n paya (osi) nibi ki e maa ti ore siwaju awon oro ateso yin ni? Nigba ti e o se e, Allahu si gba ironupiwada yin. Nitori naa, e kirun, e yo Zakah. E tele ti Allahu ati Ojise Re. Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

۞ أَلَمْ تَرَ إِلَى الَّذِينَ تَوَلَّوْا قَوْمًا غَضِبَ اللَّهُ عَلَيْهِم مَّا هُم مِّنكُمْ وَلَا مِنْهُمْ وَيَحْلِفُونَ عَلَى الْكَذِبِ وَهُمْ يَعْلَمُونَ(14)

Se o o ri awon t’o mu ijo kan ti Allahu binu si ni ore? Won ki i se ara yin, won ko si je ara won. Won yo si maa bura lori iro, won si mo

أَعَدَّ اللَّهُ لَهُمْ عَذَابًا شَدِيدًا ۖ إِنَّهُمْ سَاءَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ(15)

Allahu ti pese iya lile de won. Dajudaju ohun ti won n se nise buru

اتَّخَذُوا أَيْمَانَهُمْ جُنَّةً فَصَدُّوا عَن سَبِيلِ اللَّهِ فَلَهُمْ عَذَابٌ مُّهِينٌ(16)

Won fi ibura won se aabo; won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu. Nitori naa, iya ti i yepere eda wa fun won

لَّن تُغْنِيَ عَنْهُمْ أَمْوَالُهُمْ وَلَا أَوْلَادُهُم مِّنَ اللَّهِ شَيْئًا ۚ أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ(17)

Awon dukia won ati awon omo won ko nii fi kini kan ro won loro ni odo Allahu. Awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere si ni won ninu re

يَوْمَ يَبْعَثُهُمُ اللَّهُ جَمِيعًا فَيَحْلِفُونَ لَهُ كَمَا يَحْلِفُونَ لَكُمْ ۖ وَيَحْسَبُونَ أَنَّهُمْ عَلَىٰ شَيْءٍ ۚ أَلَا إِنَّهُمْ هُمُ الْكَاذِبُونَ(18)

Ni ojo ti Allahu yoo gbe gbogbo won dide patapata, won yo si maa bura fun Un gege bi won se n bura fun yin. Won n lero pe dajudaju awon ti ri nnkan se. Gbo! Dajudaju awon, awon ni opuro

اسْتَحْوَذَ عَلَيْهِمُ الشَّيْطَانُ فَأَنسَاهُمْ ذِكْرَ اللَّهِ ۚ أُولَٰئِكَ حِزْبُ الشَّيْطَانِ ۚ أَلَا إِنَّ حِزْبَ الشَّيْطَانِ هُمُ الْخَاسِرُونَ(19)

Esu je gaba le won lori. O si mu won gbagbe iranti Allahu. Awon wonyen ni ijo Esu. Gbo! Dajudaju ijo esu, awon ni eni ofo

إِنَّ الَّذِينَ يُحَادُّونَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ أُولَٰئِكَ فِي الْأَذَلِّينَ(20)

Dajudaju awon t’o n yapa Allahu ati Ojise Re, awon wonyen wa ninu awon oluyepere julo

كَتَبَ اللَّهُ لَأَغْلِبَنَّ أَنَا وَرُسُلِي ۚ إِنَّ اللَّهَ قَوِيٌّ عَزِيزٌ(21)

Allahu ko o pe: "Dajudaju Mo maa bori; Emi ati awon Ojise Mi." Dajudaju Allahu ni Alagbara, Olubori

لَّا تَجِدُ قَوْمًا يُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ يُوَادُّونَ مَنْ حَادَّ اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَلَوْ كَانُوا آبَاءَهُمْ أَوْ أَبْنَاءَهُمْ أَوْ إِخْوَانَهُمْ أَوْ عَشِيرَتَهُمْ ۚ أُولَٰئِكَ كَتَبَ فِي قُلُوبِهِمُ الْإِيمَانَ وَأَيَّدَهُم بِرُوحٍ مِّنْهُ ۖ وَيُدْخِلُهُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا ۚ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُمْ وَرَضُوا عَنْهُ ۚ أُولَٰئِكَ حِزْبُ اللَّهِ ۚ أَلَا إِنَّ حِزْبَ اللَّهِ هُمُ الْمُفْلِحُونَ(22)

O o nii ri ijo kan t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, ki won maa nifee awon t’o ba yapa Allahu ati Ojise Re koda ki won je awon baba won, tabi awon omo won tabi awon arakunrin won tabi awon ibatan won. Awon wonyen ni Allahu ti ko igbagbo ododo sinu okan won. Allahu si kun won lowo pelu imole (al-Ƙur’an ati isegun) lati odo Re. O si maa mu won wo inu awon Ogba Idera, eyi ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Allahu yonu si won. Won si yonu si (ohun ti Allahu fun won). Awon wonyen ni ijo Allahu. Gbo! Dajudaju ijo Allahu, awon ni olujere


المزيد من السور باللغة اليوربا:

سورة البقرة آل عمران سورة النساء
سورة المائدة سورة يوسف سورة ابراهيم
سورة الحجر سورة الكهف سورة مريم
سورة السجدة سورة يس سورة الدخان
سورة النجم سورة الرحمن سورة الواقعة
سورة الحشر سورة الملك سورة الحاقة

تحميل سورة المجادلة بصوت أشهر القراء :

قم باختيار القارئ للاستماع و تحميل سورة المجادلة كاملة بجودة عالية
سورة المجادلة أحمد العجمي
أحمد العجمي
سورة المجادلة خالد الجليل
خالد الجليل
سورة المجادلة سعد الغامدي
سعد الغامدي
سورة المجادلة سعود الشريم
سعود الشريم
سورة المجادلة عبد الباسط عبد الصمد
عبد الباسط
سورة المجادلة عبد الله عواد الجهني
عبد الله الجهني
سورة المجادلة علي الحذيفي
علي الحذيفي
سورة المجادلة فارس عباد
فارس عباد
سورة المجادلة ماهر المعيقلي
ماهر المعيقلي
سورة المجادلة محمد جبريل
محمد جبريل
سورة المجادلة محمد صديق المنشاوي
المنشاوي
سورة المجادلة الحصري
الحصري
سورة المجادلة العفاسي
مشاري العفاسي
سورة المجادلة ناصر القطامي
ناصر القطامي
سورة المجادلة ياسر الدوسري
ياسر الدوسري



Saturday, May 4, 2024

لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب