سورة فصلت باليوربا

  1. استمع للسورة
  2. سور أخرى
  3. ترجمة السورة
القرآن الكريم | ترجمة معاني القرآن | اللغة اليوربا | سورة فصلت | Fussilat - عدد آياتها 54 - رقم السورة في المصحف: 41 - معنى السورة بالإنجليزية: Expounded.

حم(1)

Ha mim

تَنزِيلٌ مِّنَ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ(2)

Isokale imisi kan (niyi) lati odo Ajoke-aye, Asake-orun

كِتَابٌ فُصِّلَتْ آيَاتُهُ قُرْآنًا عَرَبِيًّا لِّقَوْمٍ يَعْلَمُونَ(3)

(Eyi ni) Tira kan ti Won salaye awon ayah inu re; al-Ƙur’an ni ede Larubawa ni fun ijo t’o nimo

بَشِيرًا وَنَذِيرًا فَأَعْرَضَ أَكْثَرُهُمْ فَهُمْ لَا يَسْمَعُونَ(4)

(O je) iro-idunnu ati ikilo, sugbon opolopo won gbunri kuro nibe. Won ko si teti si i

وَقَالُوا قُلُوبُنَا فِي أَكِنَّةٍ مِّمَّا تَدْعُونَا إِلَيْهِ وَفِي آذَانِنَا وَقْرٌ وَمِن بَيْنِنَا وَبَيْنِكَ حِجَابٌ فَاعْمَلْ إِنَّنَا عَامِلُونَ(5)

Won si wi pe: "Okan wa wa ni titi pa si ohun ti e n pe wa si. Edidi si wa ninu eti wa. Ati pe gaga wa laaarin awa ati iwo. Nitori naa, maa se tire. Dajudaju awa naa n se tiwa

قُلْ إِنَّمَا أَنَا بَشَرٌ مِّثْلُكُمْ يُوحَىٰ إِلَيَّ أَنَّمَا إِلَٰهُكُمْ إِلَٰهٌ وَاحِدٌ فَاسْتَقِيمُوا إِلَيْهِ وَاسْتَغْفِرُوهُ ۗ وَوَيْلٌ لِّلْمُشْرِكِينَ(6)

So pe: "Abara bi iru yin kuku ni emi naa. Won n fi imisi ranse si mi ni, pe Olohun yin, Olohun Okan soso ni. Nitori naa, e duro sinsin ti I, ki e si toro aforijin ni odo Re. Egbe si ni fun awon osebo

الَّذِينَ لَا يُؤْتُونَ الزَّكَاةَ وَهُم بِالْآخِرَةِ هُمْ كَافِرُونَ(7)

awon ti ko yo Zakah. Awon si ni alaigbagbo ninu Ojo Ikeyin

إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَهُمْ أَجْرٌ غَيْرُ مَمْنُونٍ(8)

Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, esan ti ko nii pedin n be fun won

۞ قُلْ أَئِنَّكُمْ لَتَكْفُرُونَ بِالَّذِي خَلَقَ الْأَرْضَ فِي يَوْمَيْنِ وَتَجْعَلُونَ لَهُ أَندَادًا ۚ ذَٰلِكَ رَبُّ الْعَالَمِينَ(9)

So pe: "Se dajudaju eyin maa sai gbagbo ninu Eni ti O seda ile fun ojo meji, e si n so (eda Re) di akegbe fun Un?" Iyen si ni Oluwa gbogbo eda

وَجَعَلَ فِيهَا رَوَاسِيَ مِن فَوْقِهَا وَبَارَكَ فِيهَا وَقَدَّرَ فِيهَا أَقْوَاتَهَا فِي أَرْبَعَةِ أَيَّامٍ سَوَاءً لِّلسَّائِلِينَ(10)

O si fi awon apata sinu ile lati oke re. O fi ibukun sinu re. O si pebubu awon arisiki (ati ohun amusoro) sinu re laaarin ojo merin. (Awon ojo naa) dogba (sira won) fun awon olubeere (nipa re). o jeyo ninu won pe “Allahu seda awon sanmo ati ile fun ojo mefa.” O wa bee ninu surah al-’A‘rof; 7:54 nnkan naa ko nii dohun afi pelu gbolohun “kunfayakun”. Awon eda ti ko ba si jemo eroja iseda tabi awon eda ti Allahu (subhanahu wa ta’ala) ko so nipa eroja iseda won fun wa Allahu l’O kuku nimo nipa iseda awon eda Re awon eda kan di eda pelu gbolohun “kunfayakun” nikan. Awon eda kan si di eda nipase eroja iseda ati gbolohun “kunfayakun”. Allahu n seda ohun ti O ba fe ni ona ti O ba fe. Nitori naa gbolohun “kunfayakun” t’o je ti Allahu nikan soso ko le so Allahu di olukanju. Ikanju ki i se iroyin rere fun Allahu. Bi Allahu se gbaroyin pelu gbolohun “kunfayakun”

ثُمَّ اسْتَوَىٰ إِلَى السَّمَاءِ وَهِيَ دُخَانٌ فَقَالَ لَهَا وَلِلْأَرْضِ ائْتِيَا طَوْعًا أَوْ كَرْهًا قَالَتَا أَتَيْنَا طَائِعِينَ(11)

Leyin naa, Allahu wa ni oke sanmo, nigba ti sanmo wa ni eefin. O si so fun ohun ati ile pe: "E wa bi e fe tabi e ko." Awon mejeeji so pe: "A wa pelu ifinnu-findo

فَقَضَاهُنَّ سَبْعَ سَمَاوَاتٍ فِي يَوْمَيْنِ وَأَوْحَىٰ فِي كُلِّ سَمَاءٍ أَمْرَهَا ۚ وَزَيَّنَّا السَّمَاءَ الدُّنْيَا بِمَصَابِيحَ وَحِفْظًا ۚ ذَٰلِكَ تَقْدِيرُ الْعَزِيزِ الْعَلِيمِ(12)

O si pari (iseda) re si sanmo meje fun ojo meji. O si fi ise sanmo kookan ranse sinu re. A si fi awon atupa (irawo) se sanmo ile aye ni oso ati aabo (fun un). Iyen ni eto Alagbara, Onimo

فَإِنْ أَعْرَضُوا فَقُلْ أَنذَرْتُكُمْ صَاعِقَةً مِّثْلَ صَاعِقَةِ عَادٍ وَثَمُودَ(13)

Ti won ba gbunri, so pe: "Emi n sekilo iparun iru iparun ijo ‘Ad ati Thamud fun yin ni

إِذْ جَاءَتْهُمُ الرُّسُلُ مِن بَيْنِ أَيْدِيهِمْ وَمِنْ خَلْفِهِمْ أَلَّا تَعْبُدُوا إِلَّا اللَّهَ ۖ قَالُوا لَوْ شَاءَ رَبُّنَا لَأَنزَلَ مَلَائِكَةً فَإِنَّا بِمَا أُرْسِلْتُم بِهِ كَافِرُونَ(14)

Nigba ti awon Ojise won wa ba won niwaju won ati leyin won, (won so) pe: "Eyin ko gbodo josin fun eni kan afi Allahu." Won wi pe: "Ti o ba je pe Oluwa wa ba fe ni, iba so molaika kale (fun ipepe yii). Dajudaju awa je alaigbagbo ninu ohun ti Won fi ran yin nise

فَأَمَّا عَادٌ فَاسْتَكْبَرُوا فِي الْأَرْضِ بِغَيْرِ الْحَقِّ وَقَالُوا مَنْ أَشَدُّ مِنَّا قُوَّةً ۖ أَوَلَمْ يَرَوْا أَنَّ اللَّهَ الَّذِي خَلَقَهُمْ هُوَ أَشَدُّ مِنْهُمْ قُوَّةً ۖ وَكَانُوا بِآيَاتِنَا يَجْحَدُونَ(15)

Ni ti ijo ‘Ad, won segberaga ni ori ile lai letoo. Won si wi pe: "Ta ni o lagbara ju wa lo na?" Se won ko ri i pe dajudaju Allahu ti O seda won, O ni agbara ju won lo ni. Won si n se atako si awon ayah Wa

فَأَرْسَلْنَا عَلَيْهِمْ رِيحًا صَرْصَرًا فِي أَيَّامٍ نَّحِسَاتٍ لِّنُذِيقَهُمْ عَذَابَ الْخِزْيِ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ وَلَعَذَابُ الْآخِرَةِ أَخْزَىٰ ۖ وَهُمْ لَا يُنصَرُونَ(16)

Nitori naa, A ran ategun lile si won ni awon ojo buruku kan nitori ki A le je ki won to iya yepere wo ninu isemi aye yii. Iya ojo Ikeyin si maa yepere won julo; Won ko si nii ran won lowo. “ojo kan” di “awon ojo kan” ninu ayah ti surah Fussilat. Amo apapo onka ojo iparun won l’o jeyo ninu ayah ti surah al-Haƙƙoh. Se e ti ri i bayii pe ainimo nipa eto laaarin awon ayah le sokunfa itakora ayah loju alaimokan

وَأَمَّا ثَمُودُ فَهَدَيْنَاهُمْ فَاسْتَحَبُّوا الْعَمَىٰ عَلَى الْهُدَىٰ فَأَخَذَتْهُمْ صَاعِقَةُ الْعَذَابِ الْهُونِ بِمَا كَانُوا يَكْسِبُونَ(17)

Ni ti ijo Thamud, A salaye imona fun won, sugbon won nifee si airiran dipo imona. Nitori naa, igbe iya ti i yepere eda gba won mu nitori ohun ti won n se nise

وَنَجَّيْنَا الَّذِينَ آمَنُوا وَكَانُوا يَتَّقُونَ(18)

A si gba awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si n beru (Allahu) la

وَيَوْمَ يُحْشَرُ أَعْدَاءُ اللَّهِ إِلَى النَّارِ فَهُمْ يُوزَعُونَ(19)

Ni ojo ti won maa ko awon ota Allahu jo sibi Ina, won yo si ko awon eni akoko won papo mo awon eni ikeyin won

حَتَّىٰ إِذَا مَا جَاءُوهَا شَهِدَ عَلَيْهِمْ سَمْعُهُمْ وَأَبْصَارُهُمْ وَجُلُودُهُم بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ(20)

titi di igba ti won ba de ibe tan, igboro won, iriran won ati awo ara won yo si maa jerii le won lori nipa ohun ti won n se nise

وَقَالُوا لِجُلُودِهِمْ لِمَ شَهِدتُّمْ عَلَيْنَا ۖ قَالُوا أَنطَقَنَا اللَّهُ الَّذِي أَنطَقَ كُلَّ شَيْءٍ وَهُوَ خَلَقَكُمْ أَوَّلَ مَرَّةٍ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ(21)

Won yoo wi fun awo ara won pe: "Nitori ki ni e se jerii le wa lori na?" Won yoo so pe: "Allahu, Eni ti O fun gbogbo nnkan ni oro so, Oun l’O fun wa ni oro so. Oun si l’O seda yin nigba akoko. Odo Re si ni won yoo da yin pada si

وَمَا كُنتُمْ تَسْتَتِرُونَ أَن يَشْهَدَ عَلَيْكُمْ سَمْعُكُمْ وَلَا أَبْصَارُكُمْ وَلَا جُلُودُكُمْ وَلَٰكِن ظَنَنتُمْ أَنَّ اللَّهَ لَا يَعْلَمُ كَثِيرًا مِّمَّا تَعْمَلُونَ(22)

Eyin ko le para yin mo (kuro nibi ese, nitori) ki igboro yin, iriran yin ati awo ara yin ma fi le jerii le yin lori. Sugbon e lero pe dajudaju Allahu ko mo opolopo ninu ohun ti e n se nise

وَذَٰلِكُمْ ظَنُّكُمُ الَّذِي ظَنَنتُم بِرَبِّكُمْ أَرْدَاكُمْ فَأَصْبَحْتُم مِّنَ الْخَاسِرِينَ(23)

Iyen, ero yin ti e lero si Oluwa yin lo ko iparun ba yin. E si di eni ofo

فَإِن يَصْبِرُوا فَالنَّارُ مَثْوًى لَّهُمْ ۖ وَإِن يَسْتَعْتِبُوا فَمَا هُم مِّنَ الْمُعْتَبِينَ(24)

Ti won ba se suuru (fun iya), Ina kuku ni ibugbe fun won. Ti won ba si fe seri pada si sise ohun ti Allahu yonu si (ni asiko yii), A o nii gba won laye lati seri pada

۞ وَقَيَّضْنَا لَهُمْ قُرَنَاءَ فَزَيَّنُوا لَهُم مَّا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ وَحَقَّ عَلَيْهِمُ الْقَوْلُ فِي أُمَمٍ قَدْ خَلَتْ مِن قَبْلِهِم مِّنَ الْجِنِّ وَالْإِنسِ ۖ إِنَّهُمْ كَانُوا خَاسِرِينَ(25)

Awa ti yan awon alabaarin kan fun won, ti won se ohun ti n be niwaju won ati ohun ti n be ni eyin won ni oso fun won. Oro naa si ko le won lori (bi o se sele) si awon ijo t’o siwaju won ninu awon alujannu ati eniyan pe dajudaju won je eni ofo

وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لَا تَسْمَعُوا لِهَٰذَا الْقُرْآنِ وَالْغَوْا فِيهِ لَعَلَّكُمْ تَغْلِبُونَ(26)

Awon t’o sai gbagbo wi pe: "E ma se teti si al-Ƙur’an yii. Ki e si so isokuso nipa re ki e le bori

فَلَنُذِيقَنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا عَذَابًا شَدِيدًا وَلَنَجْزِيَنَّهُمْ أَسْوَأَ الَّذِي كَانُوا يَعْمَلُونَ(27)

Nitori naa, dajudaju A oo fun awon t’o sai gbagbo niya lile to wo. Ati pe dajudaju A oo fi eyi t’o buru ju eyi ti won n se nise san won ni esan

ذَٰلِكَ جَزَاءُ أَعْدَاءِ اللَّهِ النَّارُ ۖ لَهُمْ فِيهَا دَارُ الْخُلْدِ ۖ جَزَاءً بِمَا كَانُوا بِآيَاتِنَا يَجْحَدُونَ(28)

Ina, iyen ni esan awon ota Allahu. Ile gbere wa ninu re fun won. O je esan nitori pe won n tako awon ayah Wa

وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا رَبَّنَا أَرِنَا اللَّذَيْنِ أَضَلَّانَا مِنَ الْجِنِّ وَالْإِنسِ نَجْعَلْهُمَا تَحْتَ أَقْدَامِنَا لِيَكُونَا مِنَ الْأَسْفَلِينَ(29)

Awon t’o sai gbagbo wi pe: "Oluwa wa, fi awon mejeeji ti won si wa lona ninu awon alujannu ati eniyan han wa nitori ki a le fi awon mejeeji si abe gigise wa, nitori ki won le wa ni isale patapata

إِنَّ الَّذِينَ قَالُوا رَبُّنَا اللَّهُ ثُمَّ اسْتَقَامُوا تَتَنَزَّلُ عَلَيْهِمُ الْمَلَائِكَةُ أَلَّا تَخَافُوا وَلَا تَحْزَنُوا وَأَبْشِرُوا بِالْجَنَّةِ الَّتِي كُنتُمْ تُوعَدُونَ(30)

Dajudaju awon t’o so pe: "Allahu ni Oluwa wa." leyin naa, ti won duro sinsin, awon molaika yoo maa sokale wa ba won (ni ojo iku won, won si maa so pe: “E ma se paya, e ma se banuje. Ki e si dunnu si Ogba Idera eyi ti Won n se ni adehun fun yin)

نَحْنُ أَوْلِيَاؤُكُمْ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَفِي الْآخِرَةِ ۖ وَلَكُمْ فِيهَا مَا تَشْتَهِي أَنفُسُكُمْ وَلَكُمْ فِيهَا مَا تَدَّعُونَ(31)

Awa ni ore yin ninu isemi aye ati ni orun. Ohun ti emi yin n fe ti wa fun yin ninu Ogba Idera. Ohun ti e n beere fun si ti wa ninu re

نُزُلًا مِّنْ غَفُورٍ رَّحِيمٍ(32)

Nnkan igbalejo ni lati odo Alaforijin, Asake-orun.”

وَمَنْ أَحْسَنُ قَوْلًا مِّمَّن دَعَا إِلَى اللَّهِ وَعَمِلَ صَالِحًا وَقَالَ إِنَّنِي مِنَ الْمُسْلِمِينَ(33)

Ta ni o dara julo ni oro siso t’o tayo eni ti o pepe si odo Allahu, ti o se ise rere, ti o si so pe: "Dajudaju emi wa ninu awon musulumi

وَلَا تَسْتَوِي الْحَسَنَةُ وَلَا السَّيِّئَةُ ۚ ادْفَعْ بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ فَإِذَا الَّذِي بَيْنَكَ وَبَيْنَهُ عَدَاوَةٌ كَأَنَّهُ وَلِيٌّ حَمِيمٌ(34)

Rere ati aburu ko dogba. Fi eyi ti o dara julo dena (aburu). Nigba naa ni eni ti ota wa laaarin iwo ati oun maa da bi ore alasun-unmo pekipeki

وَمَا يُلَقَّاهَا إِلَّا الَّذِينَ صَبَرُوا وَمَا يُلَقَّاهَا إِلَّا ذُو حَظٍّ عَظِيمٍ(35)

A o nii fun eni kan ni (iwa rere yii) afi awon t’o se suuru. A o nii fun eni kan se afi olori-ire nla

وَإِمَّا يَنزَغَنَّكَ مِنَ الشَّيْطَانِ نَزْغٌ فَاسْتَعِذْ بِاللَّهِ ۖ إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ(36)

Ati pe ti erokero kan lati odo Esu ba fe se o lori (kuro nibi iwa rere yii), sa di Allahu. Dajudaju Oun ni Olugbo, Onimo

وَمِنْ آيَاتِهِ اللَّيْلُ وَالنَّهَارُ وَالشَّمْسُ وَالْقَمَرُ ۚ لَا تَسْجُدُوا لِلشَّمْسِ وَلَا لِلْقَمَرِ وَاسْجُدُوا لِلَّهِ الَّذِي خَلَقَهُنَّ إِن كُنتُمْ إِيَّاهُ تَعْبُدُونَ(37)

Ninu awon ami Re ni oru, osan, oorun ati osupa. E o gbodo fori kanle fun oorun ati osupa. E fori kanle fun Allahu, Eni ti O da won, ti eyin ba je eni t’o n josin fun Oun nikan soso

فَإِنِ اسْتَكْبَرُوا فَالَّذِينَ عِندَ رَبِّكَ يُسَبِّحُونَ لَهُ بِاللَّيْلِ وَالنَّهَارِ وَهُمْ لَا يَسْأَمُونَ ۩(38)

Ti won ba si segberaga, awon t’o wa ni odo Oluwa re, won n safomo fun Un ni ale ati ni osan; won ko si kagara

وَمِنْ آيَاتِهِ أَنَّكَ تَرَى الْأَرْضَ خَاشِعَةً فَإِذَا أَنزَلْنَا عَلَيْهَا الْمَاءَ اهْتَزَّتْ وَرَبَتْ ۚ إِنَّ الَّذِي أَحْيَاهَا لَمُحْيِي الْمَوْتَىٰ ۚ إِنَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ(39)

Ninu awon ami Re tun ni pe dajudaju iwo yoo ri ile ni asale. Nigba ti A ba si so omi kale le e lori, o maa rura wa, o si maa ga (fun hihu irugbin jade). Dajudaju Eni ti O ji i, Oun ma ni Eni ti O maa so awon oku di alaaye. Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan

إِنَّ الَّذِينَ يُلْحِدُونَ فِي آيَاتِنَا لَا يَخْفَوْنَ عَلَيْنَا ۗ أَفَمَن يُلْقَىٰ فِي النَّارِ خَيْرٌ أَم مَّن يَأْتِي آمِنًا يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۚ اعْمَلُوا مَا شِئْتُمْ ۖ إِنَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ(40)

Dajudaju awon t’o n ye awon ayah Wa (sibi omiran), won ko pamo fun Wa. Se eni ti won maa ju sinu Ina l’o loore julo ni tabi eni ti o maa wa ni olufayabale ni Ojo Ajinde? E maa se ohun ti e ba fe. Dajudaju Allahu ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise

إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا بِالذِّكْرِ لَمَّا جَاءَهُمْ ۖ وَإِنَّهُ لَكِتَابٌ عَزِيزٌ(41)

Dajudaju awon t’o sai gbagbo ninu Tira Iranti naa (iyen, al-Ƙur’an) nigba ti o de ba won (eni iparun ni won.) Dajudaju ohun ma ni Tira t’o lagbara

لَّا يَأْتِيهِ الْبَاطِلُ مِن بَيْنِ يَدَيْهِ وَلَا مِنْ خَلْفِهِ ۖ تَنزِيلٌ مِّنْ حَكِيمٍ حَمِيدٍ(42)

Ibaje ko nii kan an lati iwaju re ati lati eyin re. Imisi ti won sokale ni lati odo Ologbon, Eleyin

مَّا يُقَالُ لَكَ إِلَّا مَا قَدْ قِيلَ لِلرُّسُلِ مِن قَبْلِكَ ۚ إِنَّ رَبَّكَ لَذُو مَغْفِرَةٍ وَذُو عِقَابٍ أَلِيمٍ(43)

Won ko so oro kan si o bi ko se ohun ti won ti so si awon Ojise t’o siwaju re. Dajudaju Oluwa re ma ni Alaforijin, O si ni iya eleta-elero (lodo)

وَلَوْ جَعَلْنَاهُ قُرْآنًا أَعْجَمِيًّا لَّقَالُوا لَوْلَا فُصِّلَتْ آيَاتُهُ ۖ أَأَعْجَمِيٌّ وَعَرَبِيٌّ ۗ قُلْ هُوَ لِلَّذِينَ آمَنُوا هُدًى وَشِفَاءٌ ۖ وَالَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ فِي آذَانِهِمْ وَقْرٌ وَهُوَ عَلَيْهِمْ عَمًى ۚ أُولَٰئِكَ يُنَادَوْنَ مِن مَّكَانٍ بَعِيدٍ(44)

Ti o ba je pe A se al-Ƙur’an ni nnkan kike ni ede miiran yato si ede Larubawa ni, won iba wi pe: "Ki ni ko je ki Won se alaye awon ayah re?" Bawo ni al-Ƙur’an se le je ede miiran (yato si ede Larubawa), nigba ti Anabi (Muhammad s.a.w.) je Larubawa? So pe: "O je imona ati iwosan fun awon t’o gbagbo ni ododo. Awon ti ko si gbagbo, edidi wa ninu eti won. Fojunfoju si wa ninu oju won si (ododo al-Ƙur’an). Awon wonyen ni won si n pe (sibi ododo al-Ƙur’an) lati aye t’o jinna

وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ فَاخْتُلِفَ فِيهِ ۗ وَلَوْلَا كَلِمَةٌ سَبَقَتْ مِن رَّبِّكَ لَقُضِيَ بَيْنَهُمْ ۚ وَإِنَّهُمْ لَفِي شَكٍّ مِّنْهُ مُرِيبٍ(45)

A kuku fun (Anabi) Musa ni Tira. Won si yapa enu si i. Ti ko ba je pe oro kan ti o ti siwaju ni odo Oluwa re ni, A iba se idajo laaarin won. Dajudaju won tun wa ninu iyemeji t’o gbopon nipa al-Ƙur’an

مَّنْ عَمِلَ صَالِحًا فَلِنَفْسِهِ ۖ وَمَنْ أَسَاءَ فَعَلَيْهَا ۗ وَمَا رَبُّكَ بِظَلَّامٍ لِّلْعَبِيدِ(46)

Enikeni ti o ba se ise rere, o se e fun emi ara re. Enikeni ti o ba si se aburu, o se e fun emi ara re. Oluwa re ko si nii se abosi si awon erusin

۞ إِلَيْهِ يُرَدُّ عِلْمُ السَّاعَةِ ۚ وَمَا تَخْرُجُ مِن ثَمَرَاتٍ مِّنْ أَكْمَامِهَا وَمَا تَحْمِلُ مِنْ أُنثَىٰ وَلَا تَضَعُ إِلَّا بِعِلْمِهِ ۚ وَيَوْمَ يُنَادِيهِمْ أَيْنَ شُرَكَائِي قَالُوا آذَنَّاكَ مَا مِنَّا مِن شَهِيدٍ(47)

Odo Re ni won yoo maa da imo Akoko naa pada si. Ko si eso kan ti o maa jade ninu apo re, obinrin kan ko si nii loyun, ko si nii bimo afi pelu imo Re. (Ranti) ojo ti O si maa pe won pe: "Ibo ni awon akegbe Mi (ti e josin fun) wa?" Won a wi pe: "Awa n je ki O mo pe ko si olujerii kan ninu wa (ti o maa jerii pe O ni akegbe)

وَضَلَّ عَنْهُم مَّا كَانُوا يَدْعُونَ مِن قَبْلُ ۖ وَظَنُّوا مَا لَهُم مِّن مَّحِيصٍ(48)

Ohun ti won n pe teletele si dofo mo won lowo. Won si mo ni amodaju pe ko si ibusasi kan fun awon

لَّا يَسْأَمُ الْإِنسَانُ مِن دُعَاءِ الْخَيْرِ وَإِن مَّسَّهُ الشَّرُّ فَيَئُوسٌ قَنُوطٌ(49)

Eniyan ko ko susu nibi adua (lati toro) oore. Ti aburu ba si fowo ba a, o maa di olusoretinu, olujakanmuna

وَلَئِنْ أَذَقْنَاهُ رَحْمَةً مِّنَّا مِن بَعْدِ ضَرَّاءَ مَسَّتْهُ لَيَقُولَنَّ هَٰذَا لِي وَمَا أَظُنُّ السَّاعَةَ قَائِمَةً وَلَئِن رُّجِعْتُ إِلَىٰ رَبِّي إِنَّ لِي عِندَهُ لَلْحُسْنَىٰ ۚ فَلَنُنَبِّئَنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا بِمَا عَمِلُوا وَلَنُذِيقَنَّهُم مِّنْ عَذَابٍ غَلِيظٍ(50)

Dajudaju ti A ba se idera fun un lati odo Wa leyin aburu ti o fowo ba a, dajudaju o maa wi pe: "Eyi ni temi. Emi ko si ni amodaju pe Akoko naa maa sele. Ati pe dajudaju ti Won ba da mi pada si odo Oluwa mi, dajudaju rere tun wa fun mi ni odo Re." Dajudaju Awa yoo fun awon t’o sai gbagbo ni iro ohun ti won se nise. Dajudaju A si maa fun won ni iya t’o nipon to wo

وَإِذَا أَنْعَمْنَا عَلَى الْإِنسَانِ أَعْرَضَ وَنَأَىٰ بِجَانِبِهِ وَإِذَا مَسَّهُ الشَّرُّ فَذُو دُعَاءٍ عَرِيضٍ(51)

Ati pe nigba ti A ba se idera fun eniyan, o maa gbunri (kuro ni odo Wa). O si maa segberaga. Nigba ti aburu ba si fowo ba a, nigba naa l’o maa di aladuaa regede

قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِن كَانَ مِنْ عِندِ اللَّهِ ثُمَّ كَفَرْتُم بِهِ مَنْ أَضَلُّ مِمَّنْ هُوَ فِي شِقَاقٍ بَعِيدٍ(52)

So pe: " E so fun mi, ti o ba je pe al-Ƙur’an wa lati odo Allahu, leyin naa ti e sai gbagbo ninu re (se eyin ko ti wa ninu iyapa bi?)" Ta l’o sina ju eni ti o wa ninu iyapa t’o jinna (si ododo)

سَنُرِيهِمْ آيَاتِنَا فِي الْآفَاقِ وَفِي أَنفُسِهِمْ حَتَّىٰ يَتَبَيَّنَ لَهُمْ أَنَّهُ الْحَقُّ ۗ أَوَلَمْ يَكْفِ بِرَبِّكَ أَنَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدٌ(53)

A oo maa fi awon ami Wa han won ninu ofurufu ati ninu emi ara won titi o maa fi han kedere si won pe dajudaju al-Ƙur’an ni ododo. Nje Oluwa re ko to ki o je pe dajudaju Oun ni Arinu-rode lori gbogbo nnkan

أَلَا إِنَّهُمْ فِي مِرْيَةٍ مِّن لِّقَاءِ رَبِّهِمْ ۗ أَلَا إِنَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ مُّحِيطٌ(54)

Gbo, dajudaju won wa ninu iyemeji nipa ipade Oluwa won. Gbo, dajudaju Allahu yi gbogbo nnkan ka


المزيد من السور باللغة اليوربا:

سورة البقرة آل عمران سورة النساء
سورة المائدة سورة يوسف سورة ابراهيم
سورة الحجر سورة الكهف سورة مريم
سورة السجدة سورة يس سورة الدخان
سورة النجم سورة الرحمن سورة الواقعة
سورة الحشر سورة الملك سورة الحاقة

تحميل سورة فصلت بصوت أشهر القراء :

قم باختيار القارئ للاستماع و تحميل سورة فصلت كاملة بجودة عالية
سورة فصلت أحمد العجمي
أحمد العجمي
سورة فصلت خالد الجليل
خالد الجليل
سورة فصلت سعد الغامدي
سعد الغامدي
سورة فصلت سعود الشريم
سعود الشريم
سورة فصلت عبد الباسط عبد الصمد
عبد الباسط
سورة فصلت عبد الله عواد الجهني
عبد الله الجهني
سورة فصلت علي الحذيفي
علي الحذيفي
سورة فصلت فارس عباد
فارس عباد
سورة فصلت ماهر المعيقلي
ماهر المعيقلي
سورة فصلت محمد جبريل
محمد جبريل
سورة فصلت محمد صديق المنشاوي
المنشاوي
سورة فصلت الحصري
الحصري
سورة فصلت العفاسي
مشاري العفاسي
سورة فصلت ناصر القطامي
ناصر القطامي
سورة فصلت ياسر الدوسري
ياسر الدوسري



Saturday, May 4, 2024

لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب