سورة المنافقون باليوربا
Nigba ti awon sobe-selu musulumi ba wa si odo re, won a wi pe: “A n jerii pe dajudaju iwo, Ojise Allahu ni o.” Allahu si mo pe dajudaju iwo, Ojise Re ni o. Allahu si n jerii pe dajudaju awon sobe-selu musulumi, opuro ni won |
Won fi awon ibura won se aabo (fun emi ara won), won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu; dajudaju ohun ti won n se nise buru |
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ آمَنُوا ثُمَّ كَفَرُوا فَطُبِعَ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ فَهُمْ لَا يَفْقَهُونَ(3) (Won se) iyen nitori pe won gbagbo, leyin naa won sai gbagbo. Nitori naa, A ti fi edidi di okan won; won ko si nii gbo agboye |
Nigba ti o ba ri won, irisi won yoo jo o loju. Ti won ba n soro, iwo yoo teti gbo oro won. Won si da bi igi ti won gbe ti ogiri. Won si n lero pe gbogbo igbe (ibosi) n be lori won (nipa isobe-selu won). Ota ni won. Nitori naa, sora fun won. Allahu ti sebi le won. Bawo ni won se n seri won kuro nibi ododo |
Ati pe nigba ti won ba so fun won pe: “E wa ki Ojise ba yin toro aforijin.” Won a gbunri. O si maa ri won ti won yoo maa gbunri lo, ti won yoo maa segberaga |
Bakan naa ni fun won; yala o ba won toro aforijin tabi o o ba won toro aforijin. Allahu ko nii forijin won. Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo obileje |
Awon ni awon t’o n wi pe: “Eyin ko gbodo na owo fun awon t’o wa lodo Ojise Allahu titi won yoo fi fonka. Ti Allahu si ni awon apoti-oro sanmo ati ile, sugbon awon sobe-selu musulumi ko nii gbo agboye |
Won n wi pe: “Dajudaju ti a ba pada de sinu ilu Modinah, nse ni awon alagbara (ilu) yoo yo awon eni yepere jade kuro ninu ilu." Agbara si n je ti Allahu, ati ti Ojise Re ati awon onigbagbo ododo, sugbon awon sobe-selu musulumi ko mo |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se je ki awon dukia yin ati awon omo yin ko airoju ba yin nibi iranti Allahu. Enikeni ti o ba ko sinu (airoju) yen, awon wonyen, awon ni eni ofo |
E na ninu ohun ti A pese fun yin siwaju ki iku to de ba eni kan yin, ki o wa wi pe: "Oluwa mi, ki o si je pe O lo mi lara si i titi di igba kan to sunmo, emi iba si le maa tore, emi iba si wa lara awon eni rere |
وَلَن يُؤَخِّرَ اللَّهُ نَفْسًا إِذَا جَاءَ أَجَلُهَا ۚ وَاللَّهُ خَبِيرٌ بِمَا تَعْمَلُونَ(11) Allahu ko si nii lo emi kan lara nigba ti ojo iku re ba de. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise |
المزيد من السور باللغة اليوربا:
تحميل سورة المنافقون بصوت أشهر القراء :
قم باختيار القارئ للاستماع و تحميل سورة المنافقون كاملة بجودة عالية
أحمد العجمي
خالد الجليل
سعد الغامدي
سعود الشريم
عبد الباسط
عبد الله الجهني
علي الحذيفي
فارس عباد
ماهر المعيقلي
محمد جبريل
المنشاوي
الحصري
مشاري العفاسي
ناصر القطامي
ياسر الدوسري
Tuesday, December 3, 2024
لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب