Surah Al-Mujadilah with Yoruba
Dajudaju Allahu ti gbo oro (obinrin) t’o n ba o se ariyanjiyan nipa oko re, ti o si n saroye fun Allahu. Allahu si n gbo isorogbesi eyin mejeeji. Dajudaju Allahu ni Olugbo, Oluriran |
Awon t’o n fi eyin iyawo won we ti iya won ninu yin, awon iyawo ki i se iya won. Ko si eni ti o je iya won bi ko se iya ti o bi won lomo. Dajudaju won n so aburu ninu oro ati oro iro. Dajudaju Allahu ni Alamoojukuro, Alaforijin |
Awon t’o n fi eyin iyawo won we ti iya won, leyin naa ti won n seri kuro nibi ohun ti won so, won maa tu eru kan sile loko eru siwaju ki awon mejeeji to le sunmo ara won. Iyen ni A n fi se waasi fun yin. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise |
Eni ti ko ba ri (eru), o maa gba aawe osu meji ni telentele siwaju ki awon mejeeji t’o le sunmo ara won. Eni ti ko ba ni agbara (aawe), o maa bo ogota talika. Iyen nitori ki e le ni igbagbo ododo ninu Allahu ati Ojise Re. Iwonyi si ni awon enu-ala (ofin) ti Allahu gbe kale fun eda. Iya eleta-elero si wa fun awon alaigbagbo |
Dajudaju awon t’o n yapa Allahu ati Ojise Re, A oo yepere won gege bi A se yepere awon t’o siwaju won. A kuku ti so awon ayah t’o yanju kale. Iya ti i yepere eda si wa fun awon alaigbagbo |
Ni ojo ti Allahu yoo gbe gbogbo won dide, O si maa fun won ni iro ohun ti won se nise. Allahu se akosile re, awon si gbagbe re. Allahu si ni Arinu-rode gbogbo nnkan |
Se o o ri i pe dajudaju Allahu mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile ni? Ko si oro ikoko kan laaarin eni meta afi ki Allahu se ikerin won ati eni marun-un afi ki O se ikefa won. Won kere si iyen, won tun po (ju iyen) afi ki O wa pelu won ni ibikibi ti won ba wa. Leyin naa, O maa fun won ni iro ohun ti won se nise ni Ojo Ajinde. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan. ayah yii ko tumo si pe Paapaa Bibe Allahu wa lori ile aye tabi pe Paapaa Bibe Allahu wa pelu eni kookan. Ti Allahu ba se ikeji eni kan tabi O se iketa eni meji bi ko se pe wiwa Allahu pelu eda Re ni pe “Allahu n gbo ohun eda” ninu surah al-Waƙi‘ah; 56:85 isunmo ti Allahu sunmo eda ju bi a se sunmo ara wa lo duro fun bi awon molaika olugbemi-eda se maa sunmo eni kookan ni akoko ti emi ba fe jade lara eda. Eyi rinle bee ninu ayah 83 ati 84 ninu surah naa. Nitori naa isunmo ti Allahu n toka si ninu awon ayah wonyen ati iru won miiran ko tumo si isokale Allahu wa si inu isan orun eda |
Se o o ri awon ti A ko oro ikoko fun, leyin naa ti won tun pada sibi ohun ti A ko fun won. Won n bara won so oro ikoko lori ese, abosi ati iyapa Ojise. Nigba ti won ba si de odo re, won yoo ki o ni kiki ti Allahu ko fi ki o. Won si n wi sinu emi won pe: "Ki ni ko je ki Allahu je wa niya lori ohun ti a n wi (ni ikoko)!" Ina Jahnamo maa to won. Won maa wo inu re. Ikangun naa si buru |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba n bara yin so oro ikoko, e ma se so oro ikoko lori ese, abosi ati iyapa Ojise. E bara yin so oro ikoko lori ise rere ati iberu Allahu. E beru Allahu, Eni ti won yoo ko yin jo si odo Re |
Dajudaju oro ikoko (buruku) n wa lati odo Esu nitori ki o le ko ibanuje ba awon t’o gbagbo ni ododo. Ko si le fi kini kan ko inira ba won afi pelu iyonda Allahu. Allahu si ni ki awon onigbagbo ododo gbarale |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti won ba so fun yin pe ki e gbara yin laye ninu awon ibujokoo, e gbara yin laye. Allahu yoo f’aye gba yin. Nigba ti won ba so pe: "E dide (sibi ise rere)." E dide (si i). Allahu yoo sagbega awon ipo fun awon t’o gbagbo ni ododo ati awon ti A fun ni imo ninu yin. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba ba Ojise soro ateso, e fi ore tita siwaju oro ateso yin. Iyen loore julo fun yin. O si fo yin mo julo. Ti e o ba si ri (ore), dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun |
Se e n paya (osi) nibi ki e maa ti ore siwaju awon oro ateso yin ni? Nigba ti e o se e, Allahu si gba ironupiwada yin. Nitori naa, e kirun, e yo Zakah. E tele ti Allahu ati Ojise Re. Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise |
Se o o ri awon t’o mu ijo kan ti Allahu binu si ni ore? Won ki i se ara yin, won ko si je ara won. Won yo si maa bura lori iro, won si mo |
أَعَدَّ اللَّهُ لَهُمْ عَذَابًا شَدِيدًا ۖ إِنَّهُمْ سَاءَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ(15) Allahu ti pese iya lile de won. Dajudaju ohun ti won n se nise buru |
اتَّخَذُوا أَيْمَانَهُمْ جُنَّةً فَصَدُّوا عَن سَبِيلِ اللَّهِ فَلَهُمْ عَذَابٌ مُّهِينٌ(16) Won fi ibura won se aabo; won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu. Nitori naa, iya ti i yepere eda wa fun won |
Awon dukia won ati awon omo won ko nii fi kini kan ro won loro ni odo Allahu. Awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere si ni won ninu re |
Ni ojo ti Allahu yoo gbe gbogbo won dide patapata, won yo si maa bura fun Un gege bi won se n bura fun yin. Won n lero pe dajudaju awon ti ri nnkan se. Gbo! Dajudaju awon, awon ni opuro |
Esu je gaba le won lori. O si mu won gbagbe iranti Allahu. Awon wonyen ni ijo Esu. Gbo! Dajudaju ijo esu, awon ni eni ofo |
إِنَّ الَّذِينَ يُحَادُّونَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ أُولَٰئِكَ فِي الْأَذَلِّينَ(20) Dajudaju awon t’o n yapa Allahu ati Ojise Re, awon wonyen wa ninu awon oluyepere julo |
كَتَبَ اللَّهُ لَأَغْلِبَنَّ أَنَا وَرُسُلِي ۚ إِنَّ اللَّهَ قَوِيٌّ عَزِيزٌ(21) Allahu ko o pe: "Dajudaju Mo maa bori; Emi ati awon Ojise Mi." Dajudaju Allahu ni Alagbara, Olubori |
O o nii ri ijo kan t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, ki won maa nifee awon t’o ba yapa Allahu ati Ojise Re koda ki won je awon baba won, tabi awon omo won tabi awon arakunrin won tabi awon ibatan won. Awon wonyen ni Allahu ti ko igbagbo ododo sinu okan won. Allahu si kun won lowo pelu imole (al-Ƙur’an ati isegun) lati odo Re. O si maa mu won wo inu awon Ogba Idera, eyi ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Allahu yonu si won. Won si yonu si (ohun ti Allahu fun won). Awon wonyen ni ijo Allahu. Gbo! Dajudaju ijo Allahu, awon ni olujere |
More surahs in Yoruba:
Download surah Al-Mujadilah with the voice of the most famous Quran reciters :
surah Al-Mujadilah mp3 : choose the reciter to listen and download the chapter Al-Mujadilah Complete with high quality
Ahmed Al Ajmy
Bandar Balila
Khalid Al Jalil
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdul Rashid Sufi
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Yasser Al Dosari
لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب