سورة الحشر باليوربا
سَبَّحَ لِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۖ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ(1) Ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile n safomo fun Allahu. Oun si ni Alagbara, Ologbon |
Oun ni Eni ti O mu awon t’o sai gbagbo ninu awon ahlu-l-kitab jade kuro ninu ile won fun ikojo akoko. Eyin ko lero pe won yoo jade. Awon naa si lero pe dajudaju awon odi ile won yoo daabo bo awon lodo Allahu. Sugbon Allahu wa ba won ni ibi ti won ko lero; Allahu si ju iberu sinu okan won. Won n fi owo ara won ati owo awon onigbagbo ododo wo awon ile won. Nitori naa, e woye, eyin ti e ni oju iriran |
Ati pe ti ko ba je pe Allahu ti ko ijade kuro ninu ilu Modinah le awon ahlu-l-kitab lori ni, dajudaju (Allahu) iba je won niya nile aye. Iya Ina si tun wa fun won ni orun |
Iyen nitori pe dajudaju won yapa (ase) Allahu ati Ojise Re. Enikeni ti o ba yapa (ase) Allahu, dajudaju Allahu le nibi iya |
Eyin ko nii ge igi dabinu kan tabi ki e fi sile ki o duro sori gbongbo re, (afi) pelu iyonda Allahu. (O ri bee) nitori ki O le doju ti awon obileje ni |
Ohunkohun ti Allahu ba da pada lati odo won fun Ojise Re, ti e o gbe esin ati rakunmi sare fun (ti Ojise Re ni). Sugbon Allahu yoo maa fun awon Ojise Re ni agbara lori eni ti O ba fe. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
Ohunkohun ti Allahu ba da pada lati odo awon ara ilu fun Ojise Re, (o je) ti Allahu ati ti Ojise ati ti awon ibatan, awon omo orukan, awon talika ati onirin-ajo ti agara da nitori ki o ma baa je adapin laaarin awon oloro ninu yin. Ohunkohun ti Ojise ba fun yin, e gba a. Ohunkohun ti o ba si ko fun yin, e jawo ninu re. Ki e si beru Allahu. Dajudaju Allahu le nibi iya |
(Ikogun naa tun wa fun) awon alaini, (iyen,) al-Muhajirun, awon ti won le jade kuro ninu ile won ati nibi dukia won, ti won si n wa oore ajulo ati iyonu lati odo Allahu, ti won si n saranse fun (esin) Allahu ati Ojise Re. Awon wonyen ni awon olododo |
Awon t’o n gbe ninu ilu Modinah, ti won si ni igbagbo ododo siwaju won, won nifee awon t’o fi ilu Mokkah sile wa si odo won (ni ilu Modinah). Won ko si ni bukata kan ninu igba-aya won si nnkan ti won fun won. Won si n gbe ajulo fun won lori emi ara won, koda ki o je pe awon gan-an ni bukata (si ohun ti won fun won). Enikeni ti A ba so nibi ahun ati okanjua inu emi re, awon wonyen, awon ni olujere |
Awon t’o de leyin won n so pe: "Oluwa wa, forijin awa ati awon omo iya wa t’o siwaju wa ninu igbagbo ododo. Ma se je ki inunibini wa ninu okan wa si awon t’o gbagbo ni ododo. Oluwa wa, dajudaju Iwo ni Alaaanu, Asake-orun |
Se o o ri awon t’o sobe-selu ti won n wi fun awon omo iya won, awon t’o sai gbagbo ninu awon ahlul-kitab, pe "Dajudaju ti won ba le yin jade (kuro ninu ilu), awa naa gbodo jade pelu yin ni. Awa ko si nii tele ase eni kan lori yin laelae. Ti won ba si gbe ogun dide si yin, awa gbodo se iranlowo fun yin ni." Allahu si n jerii pe dajudaju opuro ni won |
Dajudaju ti won ba le won jade, won ko nii jade pelu won. Dajudaju ti won ba si gbogun ti won, won ko nii se iranlowo fun won. Ti won ba si wa iranlowo won, dajudaju won yoo peyin da (lati fese fee). Leyin naa, won ko si nii ran won lowo |
Dajudaju eyin ni erujeje t’o lagbara ju Allahu lo ninu igba-aya won. Iyen nitori pe dajudaju awon ni ijo ti ko gbo agboye |
Won ko le parapo doju ija ko yin afi (ki won) wa ninu odi ilu tabi (ki won wa) leyin awon ogiri. Ogun aarin ara won gan-an le. O n lero pe won wa ni irepo ni, otooto si ni okan won wa. Iyen nitori pe dajudaju awon ni ijo ti ko ni laakaye |
كَمَثَلِ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ قَرِيبًا ۖ ذَاقُوا وَبَالَ أَمْرِهِمْ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ(15) Apeere won da bi awon t’o siwaju won ti ko ti i pe lo titi. Won to aburu oro ara won wo. Iya eleta-elero si wa fun won |
Apeere won da bi Esu nigba ti o ba wi fun eniyan pe: "Sai gbagbo." Nigba ti o ba sai gbagbo (tan), o maa wi pe: "Dajudaju emi yowo-yose kuro ninu oro re. Dajudaju emi n paya Allahu, Oluwa gbogbo eda |
فَكَانَ عَاقِبَتَهُمَا أَنَّهُمَا فِي النَّارِ خَالِدَيْنِ فِيهَا ۚ وَذَٰلِكَ جَزَاءُ الظَّالِمِينَ(17) Nitori naa, ikangun awon mejeeji ni pe, dajudaju awon mejeeji yoo wa ninu Ina. Olusegbere ni awon mejeeji ninu re. Iyen si ni esan awon alabosi |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu. Ki emi kan si woye si ohun ti o ti siwaju fun ola (alukiyaamo). E beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise |
وَلَا تَكُونُوا كَالَّذِينَ نَسُوا اللَّهَ فَأَنسَاهُمْ أَنفُسَهُمْ ۚ أُولَٰئِكَ هُمُ الْفَاسِقُونَ(19) Ki e si ma se da bi awon t’o gbagbe Allahu. (Allahu) si mu won gbagbe emi ara won. Awon wonyen, awon ni obileje |
لَا يَسْتَوِي أَصْحَابُ النَّارِ وَأَصْحَابُ الْجَنَّةِ ۚ أَصْحَابُ الْجَنَّةِ هُمُ الْفَائِزُونَ(20) Awon ero inu Ina ati awon ero inu Ogba Idera ko dogba. Awon ero inu Ogba Idera, awon ni olujere |
Ti o ba je pe A so al-Ƙur’an yii kale sori apata ni, dajudaju o maa ri i ti o maa wale, ti o maa fo petepete fun ipaya Allahu. Iwonyi ni awon apeere ti A n fi lele fun awon eniyan nitori ki won le ronu jinle |
Oun ni Allahu, ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Onimo ikoko ati gbangba. Oun ni Ajoke-aye, Asake-orun |
Oun ni Allahu, ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Oba (eda), Eni-mimo julo, Alailabuku, Olujerii-Ojise-Re, Olujerii-eda Alagbara, Olujeni-nipa, Atobi. Mimo ni fun Allahu tayo ohun ti won fi n sebo si I |
Oun ni Allahu, Eledaa, Olupile-eda, Oluyaworan-eda. TiRe ni awon oruko t’o dara julo. Ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile n safomo fun Un. Oun si ni Alagbara, Ologbon |
المزيد من السور باللغة اليوربا:
تحميل سورة الحشر بصوت أشهر القراء :
قم باختيار القارئ للاستماع و تحميل سورة الحشر كاملة بجودة عالية
أحمد العجمي
خالد الجليل
سعد الغامدي
سعود الشريم
عبد الباسط
عبد الله الجهني
علي الحذيفي
فارس عباد
ماهر المعيقلي
محمد جبريل
المنشاوي
الحصري
مشاري العفاسي
ناصر القطامي
ياسر الدوسري
Wednesday, January 22, 2025
لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب