Surah Al-Ankabut with Yoruba

  1. Surah mp3
  2. More
  3. Yoruba
The Holy Quran | Quran translation | Language Yoruba | Surah Ankabut | العنكبوت - Ayat Count 69 - The number of the surah in moshaf: 29 - The meaning of the surah in English: The Spider.

الم(1)

 ’Alif lam mim

أَحَسِبَ النَّاسُ أَن يُتْرَكُوا أَن يَقُولُوا آمَنَّا وَهُمْ لَا يُفْتَنُونَ(2)

 Nje awon eniyan lero pe A oo fi won sile ki won maa so pe: “A gbagbo”, ti A o si nii dan won wo

وَلَقَدْ فَتَنَّا الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۖ فَلَيَعْلَمَنَّ اللَّهُ الَّذِينَ صَدَقُوا وَلَيَعْلَمَنَّ الْكَاذِبِينَ(3)

 A kuku ti dan awon t’o siwaju won wo. Nitori naa, dajudaju Allahu maa safi han awon t’o so ododo. Dajudaju O si maa safi han awon opuro

أَمْ حَسِبَ الَّذِينَ يَعْمَلُونَ السَّيِّئَاتِ أَن يَسْبِقُونَا ۚ سَاءَ مَا يَحْكُمُونَ(4)

 Abi awon t’o n se ise aburu lero pe awon maa mori bo mo Wa lowo ni? Ohun ti won n da lejo buru

مَن كَانَ يَرْجُو لِقَاءَ اللَّهِ فَإِنَّ أَجَلَ اللَّهِ لَآتٍ ۚ وَهُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ(5)

 Enikeni ti o ba n reti ipade Allahu, dajudaju akoko Allahu kuku n bo. Oun si ni Olugbo, Onimo

وَمَن جَاهَدَ فَإِنَّمَا يُجَاهِدُ لِنَفْسِهِ ۚ إِنَّ اللَّهَ لَغَنِيٌّ عَنِ الْعَالَمِينَ(6)

 Enikeni ti o ba gbiyanju, o n gbiyanju fun emi ara re ni. Dajudaju Allahu ni Oloro ti ko bukata si gbogbo eda

وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَنُكَفِّرَنَّ عَنْهُمْ سَيِّئَاتِهِمْ وَلَنَجْزِيَنَّهُمْ أَحْسَنَ الَّذِي كَانُوا يَعْمَلُونَ(7)

 Awon t’o ba gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, dajudaju A maa ha awon ise aburu won danu fun won. Dajudaju A o si san won lesan pelu eyi t’o dara ju ohun ti won n se

وَوَصَّيْنَا الْإِنسَانَ بِوَالِدَيْهِ حُسْنًا ۖ وَإِن جَاهَدَاكَ لِتُشْرِكَ بِي مَا لَيْسَ لَكَ بِهِ عِلْمٌ فَلَا تُطِعْهُمَا ۚ إِلَيَّ مَرْجِعُكُمْ فَأُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ(8)

 A pa a ni ase fun eniyan lati se daadaa si awon obi re mejeeji. Ti awon mejeeji ba si ja o logun pe ki o fi ohun ti iwo ko ni imo nipa re sebo si Mi, ma se tele awon mejeeji. Odo Mi ni ibupadasi yin. Nitori naa, Mo maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise

وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَنُدْخِلَنَّهُمْ فِي الصَّالِحِينَ(9)

 Awon t’o ba gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, dajudaju A maa fi won sinu awon eni rere

وَمِنَ النَّاسِ مَن يَقُولُ آمَنَّا بِاللَّهِ فَإِذَا أُوذِيَ فِي اللَّهِ جَعَلَ فِتْنَةَ النَّاسِ كَعَذَابِ اللَّهِ وَلَئِن جَاءَ نَصْرٌ مِّن رَّبِّكَ لَيَقُولُنَّ إِنَّا كُنَّا مَعَكُمْ ۚ أَوَلَيْسَ اللَّهُ بِأَعْلَمَ بِمَا فِي صُدُورِ الْعَالَمِينَ(10)

 O n be ninu awon eniyan, eni t’o n wi pe: “A gba Allahu gbo.” Nigba ti won ba si fi inira kan won ninu esin Allahu, o maa so inira eniyan da bi iya ti Allahu. Ti aranse kan lati odo Oluwa re ba si de, dajudaju won yoo wi pe: “Dajudaju awa wa pelu yin.” Se Allahu ko l’O nimo julo nipa ohun ti n be ninu igba-aya gbogbo eda ni

وَلَيَعْلَمَنَّ اللَّهُ الَّذِينَ آمَنُوا وَلَيَعْلَمَنَّ الْمُنَافِقِينَ(11)

 Dajudaju Allahu maa safi han awon t’o gbagbo ni ododo. O si maa safi han awon sobe-selu musulumi

وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لِلَّذِينَ آمَنُوا اتَّبِعُوا سَبِيلَنَا وَلْنَحْمِلْ خَطَايَاكُمْ وَمَا هُم بِحَامِلِينَ مِنْ خَطَايَاهُم مِّن شَيْءٍ ۖ إِنَّهُمْ لَكَاذِبُونَ(12)

 Awon t’o sai gbagbo wi fun awon t’o gbagbo ni ododo pe: “E tele oju ona tiwa nitori ki a le ru awon ese yin.” Won ko si le ru kini kan ninu ese won. Dajudaju opuro ma ni won

وَلَيَحْمِلُنَّ أَثْقَالَهُمْ وَأَثْقَالًا مَّعَ أَثْقَالِهِمْ ۖ وَلَيُسْأَلُنَّ يَوْمَ الْقِيَامَةِ عَمَّا كَانُوا يَفْتَرُونَ(13)

 Dajudaju won yoo ru eru ese tiwon ati awon eru ese kan mo eru ese tiwon. Ati pe dajudaju A oo bi won leere ni Ojo Ajinde nipa ohun ti won n da ni adapa iro

وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا نُوحًا إِلَىٰ قَوْمِهِ فَلَبِثَ فِيهِمْ أَلْفَ سَنَةٍ إِلَّا خَمْسِينَ عَامًا فَأَخَذَهُمُ الطُّوفَانُ وَهُمْ ظَالِمُونَ(14)

 Dajudaju A ran (Anabi) Nuh nise si ijo re. O gbe laaarin won fun egberun odun afi aadota odun. Ekun-omi si gba won mu nigba ti won je alabosi

فَأَنجَيْنَاهُ وَأَصْحَابَ السَّفِينَةِ وَجَعَلْنَاهَا آيَةً لِّلْعَالَمِينَ(15)

 A si la oun ati awon ero inu oko oju-omi. A si se won ni ami fun gbogbo eda

وَإِبْرَاهِيمَ إِذْ قَالَ لِقَوْمِهِ اعْبُدُوا اللَّهَ وَاتَّقُوهُ ۖ ذَٰلِكُمْ خَيْرٌ لَّكُمْ إِن كُنتُمْ تَعْلَمُونَ(16)

 (Ranti Anabi) ’Ibrohim. Nigba ti o so fun ijo re pe: “E josin fun Allahu. Ki e si paya Re. Iyen loore julo fun yin ti e ba mo.”

إِنَّمَا تَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللَّهِ أَوْثَانًا وَتَخْلُقُونَ إِفْكًا ۚ إِنَّ الَّذِينَ تَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللَّهِ لَا يَمْلِكُونَ لَكُمْ رِزْقًا فَابْتَغُوا عِندَ اللَّهِ الرِّزْقَ وَاعْبُدُوهُ وَاشْكُرُوا لَهُ ۖ إِلَيْهِ تُرْجَعُونَ(17)

 E kan n josin fun awon orisa leyin Allahu. E si n da adapa iro. Dajudaju awon ti e n josin fun leyin Allahu, won ko ni ikapa arisiki kan fun yin. E wa arisiki si odo Allahu. Ki e josin fun Un. Ki e si dupe fun Un. Odo Re ni won yoo da yin pada si

وَإِن تُكَذِّبُوا فَقَدْ كَذَّبَ أُمَمٌ مِّن قَبْلِكُمْ ۖ وَمَا عَلَى الرَّسُولِ إِلَّا الْبَلَاغُ الْمُبِينُ(18)

 Ti e ba si pe (ododo) niro, awon ijo kan t’o siwaju yin kuku ti pe (ododo) niro. Ko si si ojuse kan fun Ojise bi ko se ise-jije ponnbele

أَوَلَمْ يَرَوْا كَيْفَ يُبْدِئُ اللَّهُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ ۚ إِنَّ ذَٰلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرٌ(19)

 Tabi won ko ri bi Allahu ti se bere eda ni? Leyin naa, O maa da a pada (si odo Re). Dajudaju iyen rorun fun Allahu

قُلْ سِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَانظُرُوا كَيْفَ بَدَأَ الْخَلْقَ ۚ ثُمَّ اللَّهُ يُنشِئُ النَّشْأَةَ الْآخِرَةَ ۚ إِنَّ اللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ(20)

 So pe: “E rin kiri lori ile, ki e wo bi O se bere eda (ni ipile). Leyin naa, Allahu l’O maa mu iseda ikeyin wa (fun ajinde). Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan.”

يُعَذِّبُ مَن يَشَاءُ وَيَرْحَمُ مَن يَشَاءُ ۖ وَإِلَيْهِ تُقْلَبُونَ(21)

 O n je eni ti O ba fe niya. O si n ke eni ti O ba fe. Odo Re si ni won yoo da yin pada si. o je ohun ti Allahu fe bee fun eda naa ninu kadara re nitori pe tibi-tire ni kadara eda. Fifebee yii ni a n pe ni ""mosi’atu-llahi al-kaoniyyah"" “fifebee Allahu taye”. Bi apeere lagbaja fe di olowo lona eto o je ohun ti Allahu fe bee fun eda ninu ofin ati ilana Re. Allahu ko si nii fe ofin ati ilana kan bee ninu Tira Re t’o sokale fun wa afi ki o je rere ponnbele tabi ki rere re tewon ju aburu re lo. Fifebee yii ni a n pe ni ""mosi’atu-llahi as-ser‘iyyah"" “fifebee Allahu tofin”. Bi apeere lagbaja fe di musulumi mejeeji l’o duro sori “ ‘adl” ati “ fodl” – deede ati ola. Alaye eyi ni pe ti iya ba je lagbaja nile aye tabi ni orun lai je onigbagbo ododo enu eni keni ko gba a lati fi esun kan Allahu lori fifebee Re lori eda re. Sebi nile aye yii gan-an

وَمَا أَنتُم بِمُعْجِزِينَ فِي الْأَرْضِ وَلَا فِي السَّمَاءِ ۖ وَمَا لَكُم مِّن دُونِ اللَّهِ مِن وَلِيٍّ وَلَا نَصِيرٍ(22)

 Ati pe eyin ko nii mori bo mo Allahu lowo lori ile ati ninu sanmo. Ko si si alaabo ati alaranse kan fun yin leyin Allahu

وَالَّذِينَ كَفَرُوا بِآيَاتِ اللَّهِ وَلِقَائِهِ أُولَٰئِكَ يَئِسُوا مِن رَّحْمَتِي وَأُولَٰئِكَ لَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ(23)

 Awon t’o sai gbagbo ninu awon ayah Allahu ati ipade Re (lorun), awon wonyen ti soreti nu ninu ike Mi. Awon wonyen ni iya eleta-elero n be fun

فَمَا كَانَ جَوَابَ قَوْمِهِ إِلَّا أَن قَالُوا اقْتُلُوهُ أَوْ حَرِّقُوهُ فَأَنجَاهُ اللَّهُ مِنَ النَّارِ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ(24)

 Esi ijo re ko je kini kan tayo pe won wi pe: “E pa a tabi ki e sun un nina.” Allahu si la a ninu ina. Dajudaju awon ami kuku wa ninu iyen fun ijo t’o gbagbo lododo

وَقَالَ إِنَّمَا اتَّخَذْتُم مِّن دُونِ اللَّهِ أَوْثَانًا مَّوَدَّةَ بَيْنِكُمْ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ ثُمَّ يَوْمَ الْقِيَامَةِ يَكْفُرُ بَعْضُكُم بِبَعْضٍ وَيَلْعَنُ بَعْضُكُم بَعْضًا وَمَأْوَاكُمُ النَّارُ وَمَا لَكُم مِّن نَّاصِرِينَ(25)

 O si so pe: “E kan mu awon orisa leyin Allahu, ni ohun ti e nifee si (lati josin fun) laaarin ara yin ninu isemi aye (yii). Leyin naa, ni Ojo Ajinde apa kan yin yoo tako apa kan. Apa kan yin yo si sebi le apa kan. Ina si ni ibugbe yin. Ko si nii si awon alaranse kan fun yin.”

۞ فَآمَنَ لَهُ لُوطٌ ۘ وَقَالَ إِنِّي مُهَاجِرٌ إِلَىٰ رَبِّي ۖ إِنَّهُ هُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ(26)

 (Anabi) Lut si gba a gbo. (Anabi ’Ibrohim) so pe: “Dajudaju emi yoo fi ilu yii sile nitori ti Oluwa mi. Dajudaju Oun ni Alagbara, Ologbon

وَوَهَبْنَا لَهُ إِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ وَجَعَلْنَا فِي ذُرِّيَّتِهِ النُّبُوَّةَ وَالْكِتَابَ وَآتَيْنَاهُ أَجْرَهُ فِي الدُّنْيَا ۖ وَإِنَّهُ فِي الْآخِرَةِ لَمِنَ الصَّالِحِينَ(27)

 A fi ’Ishaƙ ati Ya‘ƙub (omoomo re) ta a lore. A si se jije Anabi ati fifunni ni tira sinu aromodomo re. A fun un ni esan re ni aye yii. Dajudaju ni orun, o tun wa ninu awon eni rere

وَلُوطًا إِذْ قَالَ لِقَوْمِهِ إِنَّكُمْ لَتَأْتُونَ الْفَاحِشَةَ مَا سَبَقَكُم بِهَا مِنْ أَحَدٍ مِّنَ الْعَالَمِينَ(28)

 (Ranti Anabi) Lut. Nigba ti o so fun ijo re pe: “Dajudaju eyin n se ibaje ti ko si eni kan ninu eda ti o se e ri siwaju yin

أَئِنَّكُمْ لَتَأْتُونَ الرِّجَالَ وَتَقْطَعُونَ السَّبِيلَ وَتَأْتُونَ فِي نَادِيكُمُ الْمُنكَرَ ۖ فَمَا كَانَ جَوَابَ قَوْمِهِ إِلَّا أَن قَالُوا ائْتِنَا بِعَذَابِ اللَّهِ إِن كُنتَ مِنَ الصَّادِقِينَ(29)

 Se dajudaju eyin (okunrin) yoo maa to awon okunrin (egbe yin) lo (fun adun ibalopo), e tun n dana, e tun n se ohun buruku ninu akojo yin? Esi ijo re ko je kini kan afi ki won wi pe : “Mu iya Allahu wa fun wa ti o ba wa ninu awon olododo.”

قَالَ رَبِّ انصُرْنِي عَلَى الْقَوْمِ الْمُفْسِدِينَ(30)

 O so pe: “Oluwa mi, saranse fun mi lori ijo obileje.”

وَلَمَّا جَاءَتْ رُسُلُنَا إِبْرَاهِيمَ بِالْبُشْرَىٰ قَالُوا إِنَّا مُهْلِكُو أَهْلِ هَٰذِهِ الْقَرْيَةِ ۖ إِنَّ أَهْلَهَا كَانُوا ظَالِمِينَ(31)

 Nigba ti awon Ojise Wa si mu iro idunnu de ba (Anabi) ’Ibrohim, won so pe: “Dajudaju awa maa pa awon ara ilu yii run. Dajudaju awon ara ilu naa je alabosi.”

قَالَ إِنَّ فِيهَا لُوطًا ۚ قَالُوا نَحْنُ أَعْلَمُ بِمَن فِيهَا ۖ لَنُنَجِّيَنَّهُ وَأَهْلَهُ إِلَّا امْرَأَتَهُ كَانَتْ مِنَ الْغَابِرِينَ(32)

 O so pe: “Dajudaju (Anabi) Lut wa nibe! Won so pe: “Awa nimo julo nipa awon t’o wa nibe. Dajudaju awa yoo la oun ati awon ara ile re afi iyawo re ti o maa wa ninu awon t’o maa seku leyin sinu iparun.”

وَلَمَّا أَن جَاءَتْ رُسُلُنَا لُوطًا سِيءَ بِهِمْ وَضَاقَ بِهِمْ ذَرْعًا وَقَالُوا لَا تَخَفْ وَلَا تَحْزَنْ ۖ إِنَّا مُنَجُّوكَ وَأَهْلَكَ إِلَّا امْرَأَتَكَ كَانَتْ مِنَ الْغَابِرِينَ(33)

 Nigba ti awon Ojise Wa de odo (Anabi) Lut, o banuje nitori won. Agbara re ko si ka oro won mo. Won si so fun un pe: “Ma beru, ma si se banuje. Dajudaju a maa la iwo ati awon ara ile re afi iyawo re ti o maa wa ninu awon oluseku-leyin sinu iparun.”

إِنَّا مُنزِلُونَ عَلَىٰ أَهْلِ هَٰذِهِ الْقَرْيَةِ رِجْزًا مِّنَ السَّمَاءِ بِمَا كَانُوا يَفْسُقُونَ(34)

 Dajudaju a maa so iya kan kale le awon ara ilu yii lori lati inu sanmo nitori pe won je obileje

وَلَقَد تَّرَكْنَا مِنْهَا آيَةً بَيِّنَةً لِّقَوْمٍ يَعْقِلُونَ(35)

 Dajudaju A ti fi ami kan t’o foju han lele ninu re fun ijo t’o ni laakaye

وَإِلَىٰ مَدْيَنَ أَخَاهُمْ شُعَيْبًا فَقَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُوا اللَّهَ وَارْجُوا الْيَوْمَ الْآخِرَ وَلَا تَعْثَوْا فِي الْأَرْضِ مُفْسِدِينَ(36)

 A tun ranse si ara ilu Modyan. (A ran) arakunrin won, (Anabi) Su‘aeb (nise si won). O si so pe: “Eyin ijo mi, e josin fun Allahu. E reti Ojo Ikeyin, ki e si ma sebaje lori ile ni ti obileje.”

فَكَذَّبُوهُ فَأَخَذَتْهُمُ الرَّجْفَةُ فَأَصْبَحُوا فِي دَارِهِمْ جَاثِمِينَ(37)

 Won pe e ni opuro. Nitori naa, ohun igbe lile t’o mi ile titi gba won mu. Won si di eni t’o da lule, ti won ti doku sinu ilu won

وَعَادًا وَثَمُودَ وَقَد تَّبَيَّنَ لَكُم مِّن مَّسَاكِنِهِمْ ۖ وَزَيَّنَ لَهُمُ الشَّيْطَانُ أَعْمَالَهُمْ فَصَدَّهُمْ عَنِ السَّبِيلِ وَكَانُوا مُسْتَبْصِرِينَ(38)

 (A tun ranse si awon) ara ‘Ad ati ara Thamud. (Iparun won) si kuku ti foju han kedere si yin ninu awon ibugbe won. Esu se awon ise won ni oso fun won. O si seri won kuro ninu esin (Allahu). Won si je oluriran (nipa oro aye)

وَقَارُونَ وَفِرْعَوْنَ وَهَامَانَ ۖ وَلَقَدْ جَاءَهُم مُّوسَىٰ بِالْبَيِّنَاتِ فَاسْتَكْبَرُوا فِي الْأَرْضِ وَمَا كَانُوا سَابِقِينَ(39)

 (A tun ranse si awon) Ƙorun, Fir‘aon ati Hamon. Dajudaju (Anabi) Musa mu awon eri t’o yanju wa ba won. Won si segberaga lori ile. Won ko si le mori bo ninu iya

فَكُلًّا أَخَذْنَا بِذَنبِهِ ۖ فَمِنْهُم مَّنْ أَرْسَلْنَا عَلَيْهِ حَاصِبًا وَمِنْهُم مَّنْ أَخَذَتْهُ الصَّيْحَةُ وَمِنْهُم مَّنْ خَسَفْنَا بِهِ الْأَرْضَ وَمِنْهُم مَّنْ أَغْرَقْنَا ۚ وَمَا كَانَ اللَّهُ لِيَظْلِمَهُمْ وَلَٰكِن كَانُوا أَنفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ(40)

 A si mu ikookan won nipa ese re. O wa ninu won, eni ti A fi okuta ina ranse si. O wa ninu won eni ti igbe lile gba mu. O wa ninu won eni ti A je ki ile gbemi. O si wa ninu won eni ti A teri sinu omi. Allahu ko si nii sabosi si won, sugbon emi ara won ni won n sabosi si

مَثَلُ الَّذِينَ اتَّخَذُوا مِن دُونِ اللَّهِ أَوْلِيَاءَ كَمَثَلِ الْعَنكَبُوتِ اتَّخَذَتْ بَيْتًا ۖ وَإِنَّ أَوْهَنَ الْبُيُوتِ لَبَيْتُ الْعَنكَبُوتِ ۖ لَوْ كَانُوا يَعْلَمُونَ(41)

 Apejuwe awon t’o mu awon (orisa) ni alatileyin leyin Allahu, o da bi apejuwe alantaakun ti o ko ile kan. Dajudaju ile ti o yepere julo ni ile alantaakun, ti won ba mo

إِنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ مَا يَدْعُونَ مِن دُونِهِ مِن شَيْءٍ ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ(42)

 Dajudaju Allahu mo ohunkohun ti won n pe leyin Re. Oun si ni Alagbara, Ologbon

وَتِلْكَ الْأَمْثَالُ نَضْرِبُهَا لِلنَّاسِ ۖ وَمَا يَعْقِلُهَا إِلَّا الْعَالِمُونَ(43)

 Awon akawe wonyi, ti A n fun awon eniyan, ko si si eni ti o maa se laakaye nipa re afi awon onimo

خَلَقَ اللَّهُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بِالْحَقِّ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً لِّلْمُؤْمِنِينَ(44)

 Allahu seda awon sanmo ati ile pelu ododo. Dajudaju ami kan wa ninu iyen fun awon onigbagbo ododo

اتْلُ مَا أُوحِيَ إِلَيْكَ مِنَ الْكِتَابِ وَأَقِمِ الصَّلَاةَ ۖ إِنَّ الصَّلَاةَ تَنْهَىٰ عَنِ الْفَحْشَاءِ وَالْمُنكَرِ ۗ وَلَذِكْرُ اللَّهِ أَكْبَرُ ۗ وَاللَّهُ يَعْلَمُ مَا تَصْنَعُونَ(45)

 Ke ohun ti A fi ranse si o ninu Tira. Ki o si kirun. Dajudaju irun kiki n ko iwa ibaje ati aburu. Ati pe iranti Allahu tobi julo. Allahu si mo ohun ti e n se. bi irun kiki se ni esan bee naa lo tun je ohun t’o n mu olukirun jinna si iwa aburu aawe gbigba ati bee bee lo. Enikeni ti o ba pa irun kiki ati aawe gbigba ti nipase fifun gbolohun yii ni itumo odi o ti ko iparun ba emi ara re ni ibamu si surah al-Muddaththir; 74: 42-43. Ki Allahu (subhanahu wa ta’ala) la wa ninu eyi

۞ وَلَا تُجَادِلُوا أَهْلَ الْكِتَابِ إِلَّا بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ إِلَّا الَّذِينَ ظَلَمُوا مِنْهُمْ ۖ وَقُولُوا آمَنَّا بِالَّذِي أُنزِلَ إِلَيْنَا وَأُنزِلَ إِلَيْكُمْ وَإِلَٰهُنَا وَإِلَٰهُكُمْ وَاحِدٌ وَنَحْنُ لَهُ مُسْلِمُونَ(46)

 E ma se ba ahlul-kitab sariyan jiyan afi ni ona t’o dara julo (eyi ni lilo al-Ƙur’an ati hadith. E ma si se ja won logun) afi awon t’o ba sabosi ninu won. Ki e si so pe: “A gbagbo ninu ohun ti Won sokale fun awa ati ohun ti Won sokale fun eyin. Olohun wa ati Olohun yin, (Allahu) Okan soso ni. Awa si ni musulumi (olujuwo-juse-sile) fun Un.”

وَكَذَٰلِكَ أَنزَلْنَا إِلَيْكَ الْكِتَابَ ۚ فَالَّذِينَ آتَيْنَاهُمُ الْكِتَابَ يُؤْمِنُونَ بِهِ ۖ وَمِنْ هَٰؤُلَاءِ مَن يُؤْمِنُ بِهِ ۚ وَمَا يَجْحَدُ بِآيَاتِنَا إِلَّا الْكَافِرُونَ(47)

 Bayen ni A se so Tira kale fun o. Nitori naa, awon ti A fun ni Tira, won gba a gbo. O si wa ninu awon wonyi (iyen, awon ara Mokkah), eni t’o gba a gbo. Ko si si eni t’o n tako awon ayah Wa afi awon alaigbagbo

وَمَا كُنتَ تَتْلُو مِن قَبْلِهِ مِن كِتَابٍ وَلَا تَخُطُّهُ بِيَمِينِكَ ۖ إِذًا لَّارْتَابَ الْمُبْطِلُونَ(48)

 Iwo ko ke tira kan ri siwaju al-Ƙur’an, iwo ko si fi owo otun re ko nnkan ri. Bi bee ko nigba naa, ki awon opuro seyemeji (si al-Ƙur’an)

بَلْ هُوَ آيَاتٌ بَيِّنَاتٌ فِي صُدُورِ الَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ ۚ وَمَا يَجْحَدُ بِآيَاتِنَا إِلَّا الظَّالِمُونَ(49)

 Rara (ko ri bi won se ro o. al-Ƙur’an), ohun ni awon ayah t’o yanju ninu igba-aya awon ti A fun ni imo-esin. Ko si si eni t’o n tako awon ayah Wa afi awon alabosi

وَقَالُوا لَوْلَا أُنزِلَ عَلَيْهِ آيَاتٌ مِّن رَّبِّهِ ۖ قُلْ إِنَّمَا الْآيَاتُ عِندَ اللَّهِ وَإِنَّمَا أَنَا نَذِيرٌ مُّبِينٌ(50)

 Won si wi pe: “Nitori ki ni Won ko se so awon ami (iyanu) kan kale fun un lati odo Oluwa re?” So pe: “Allahu nikan ni awon ami (iyanu) wa lodo Re. Ati pe olukilo ponnbele ni emi.”

أَوَلَمْ يَكْفِهِمْ أَنَّا أَنزَلْنَا عَلَيْكَ الْكِتَابَ يُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَرَحْمَةً وَذِكْرَىٰ لِقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ(51)

 Se ko to fun won (ni ami iyanu) pe A so tira (al-Ƙur’an) kale fun o, ti won n ke e fun won? Dajudaju ike ati isiti wa ninu iyen fun ijo t’o gbagbo

قُلْ كَفَىٰ بِاللَّهِ بَيْنِي وَبَيْنَكُمْ شَهِيدًا ۖ يَعْلَمُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۗ وَالَّذِينَ آمَنُوا بِالْبَاطِلِ وَكَفَرُوا بِاللَّهِ أُولَٰئِكَ هُمُ الْخَاسِرُونَ(52)

 So pe: “Allahu to ni Elerii laaarin emi ati eyin. O mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Awon t’o gba iro gbo, ti won si sai gbagbo ninu Allahu; awon wonyen, awon ni eni ofo

وَيَسْتَعْجِلُونَكَ بِالْعَذَابِ ۚ وَلَوْلَا أَجَلٌ مُّسَمًّى لَّجَاءَهُمُ الْعَذَابُ وَلَيَأْتِيَنَّهُم بَغْتَةً وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ(53)

 Won si n kan o loju nipa iya! Ti ko ba je pe o ti ni gbedeke akoko kan ni, iya naa iba kuku de ba won. (Iya) iba de ba won ni ojiji se, won ko si nii fura

يَسْتَعْجِلُونَكَ بِالْعَذَابِ وَإِنَّ جَهَنَّمَ لَمُحِيطَةٌ بِالْكَافِرِينَ(54)

 Won n kan o loju nipa iya! Dajudaju ina Jahanamo kuku maa yi awon alaigbagbo po

يَوْمَ يَغْشَاهُمُ الْعَذَابُ مِن فَوْقِهِمْ وَمِن تَحْتِ أَرْجُلِهِمْ وَيَقُولُ ذُوقُوا مَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ(55)

 (Ranti) ojo ti iya yoo bo won mole lati oke won ati isale ese won, (Allahu) si maa so pe: “E to (iya) ohun ti e n se nise wo.”

يَا عِبَادِيَ الَّذِينَ آمَنُوا إِنَّ أَرْضِي وَاسِعَةٌ فَإِيَّايَ فَاعْبُدُونِ(56)

 Eyin erusin Mi, ti e gbagbo ni ododo, dajudaju ile Mi gbooro. Nitori naa, Emi nikan ni ki e josin fun

كُلُّ نَفْسٍ ذَائِقَةُ الْمَوْتِ ۖ ثُمَّ إِلَيْنَا تُرْجَعُونَ(57)

 Gbogbo emi l’o maa to iku wo. Leyin naa, odo Wa ni won yoo da yin pada si

وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَنُبَوِّئَنَّهُم مِّنَ الْجَنَّةِ غُرَفًا تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا ۚ نِعْمَ أَجْرُ الْعَامِلِينَ(58)

 Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, dajudaju A maa fi won sinu awon ile peteesi giga kan ninu Ogba Idera, ti odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Esan awon oluse-rere si dara

الَّذِينَ صَبَرُوا وَعَلَىٰ رَبِّهِمْ يَتَوَكَّلُونَ(59)

 (Awon ni) awon t’o se suuru. Oluwa won si ni won n gbarale

وَكَأَيِّن مِّن دَابَّةٍ لَّا تَحْمِلُ رِزْقَهَا اللَّهُ يَرْزُقُهَا وَإِيَّاكُمْ ۚ وَهُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ(60)

 Meloo meloo ninu awon eranko ti ko le da bukata ije-imu re gbe, ti Allahu si n se ije-imu fun awon ati eyin. Oun si ni Olugbo, Onimo

وَلَئِن سَأَلْتَهُم مَّنْ خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَسَخَّرَ الشَّمْسَ وَالْقَمَرَ لَيَقُولُنَّ اللَّهُ ۖ فَأَنَّىٰ يُؤْفَكُونَ(61)

 Ti o ba bi won leere pe: “Ta ni O da awon sanmo ati ile, ti O si ro oorun ati osupa?”, dajudaju won a wi pe: “Allahu ni.” Nitori naa, bawo ni won se n seri won kuro nibi ododo

اللَّهُ يَبْسُطُ الرِّزْقَ لِمَن يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ وَيَقْدِرُ لَهُ ۚ إِنَّ اللَّهَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ(62)

 Allahu l’O n te oro sile fun eni ti O ba fe ninu awon erusin Re. O si n diwon re fun elomiiran. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan

وَلَئِن سَأَلْتَهُم مَّن نَّزَّلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَحْيَا بِهِ الْأَرْضَ مِن بَعْدِ مَوْتِهَا لَيَقُولُنَّ اللَّهُ ۚ قُلِ الْحَمْدُ لِلَّهِ ۚ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْقِلُونَ(63)

 Ti o ba bi won leere pe: “Ta ni O so omi kale lati sanmo, ti O fi ta ile ji leyin ti o ti ku?”, dajudaju won a wi pe: “Allahu ni.” So pe: “Gbogbo ope n je ti Allahu, sugbon opolopo won ni ko se laakaye.”

وَمَا هَٰذِهِ الْحَيَاةُ الدُّنْيَا إِلَّا لَهْوٌ وَلَعِبٌ ۚ وَإِنَّ الدَّارَ الْآخِرَةَ لَهِيَ الْحَيَوَانُ ۚ لَوْ كَانُوا يَعْلَمُونَ(64)

 Ki ni isemi aye yii bi ko se iranu ati ere sise. Ati pe dajudaju Ile Ikeyin si ni isemi gbere ti won ba mo

فَإِذَا رَكِبُوا فِي الْفُلْكِ دَعَوُا اللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ فَلَمَّا نَجَّاهُمْ إِلَى الْبَرِّ إِذَا هُمْ يُشْرِكُونَ(65)

 Nigba ti won ba gun oko oju-omi, won yoo pe Allahu (gege bi) olusafomo-adua fun Un. Amo nigba ti O ba ko won yo si ori ile, nigba naa ni won yoo maa sebo

لِيَكْفُرُوا بِمَا آتَيْنَاهُمْ وَلِيَتَمَتَّعُوا ۖ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ(66)

 nitori ki won le sai moore si nnkan ti A fun won ati nitori ki won le jayekaye. Nitori naa, laipe won maa mo

أَوَلَمْ يَرَوْا أَنَّا جَعَلْنَا حَرَمًا آمِنًا وَيُتَخَطَّفُ النَّاسُ مِنْ حَوْلِهِمْ ۚ أَفَبِالْبَاطِلِ يُؤْمِنُونَ وَبِنِعْمَةِ اللَّهِ يَكْفُرُونَ(67)

 Se won ko ri i pe dajudaju Awa se Haram (Mokkah) ni aye ifayabale, ti won si n ji awon eniyan gbe lo ni ayika won? Se iro ni won yoo gbagbo, ti won yo si sai moore si idera Allahu

وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا أَوْ كَذَّبَ بِالْحَقِّ لَمَّا جَاءَهُ ۚ أَلَيْسَ فِي جَهَنَّمَ مَثْوًى لِّلْكَافِرِينَ(68)

 Ta l’o sabosi ju eni t’o da adapa iro mo Allahu, tabi t’o pe ododo ni iro nigba ti o de ba a? Se inu ina Jahanamo ko ni ibugbe fun awon alaigbagbo ni

وَالَّذِينَ جَاهَدُوا فِينَا لَنَهْدِيَنَّهُمْ سُبُلَنَا ۚ وَإِنَّ اللَّهَ لَمَعَ الْمُحْسِنِينَ(69)

 Awon t’o gbiyanju nipa Wa, dajudaju A maa fi won mo awon ona Wa. Ati pe dajudaju Allahu wa pelu awon oluse-rere


More surahs in Yoruba:


Al-Baqarah Al-'Imran An-Nisa'
Al-Ma'idah Yusuf Ibrahim
Al-Hijr Al-Kahf Maryam
Al-Hajj Al-Qasas Al-'Ankabut
As-Sajdah Ya Sin Ad-Dukhan
Al-Fath Al-Hujurat Qaf
An-Najm Ar-Rahman Al-Waqi'ah
Al-Hashr Al-Mulk Al-Haqqah
Al-Inshiqaq Al-A'la Al-Ghashiyah

Download surah Al-Ankabut with the voice of the most famous Quran reciters :

surah Al-Ankabut mp3 : choose the reciter to listen and download the chapter Al-Ankabut Complete with high quality
surah Al-Ankabut Ahmed El Agamy
Ahmed Al Ajmy
surah Al-Ankabut Bandar Balila
Bandar Balila
surah Al-Ankabut Khalid Al Jalil
Khalid Al Jalil
surah Al-Ankabut Saad Al Ghamdi
Saad Al Ghamdi
surah Al-Ankabut Saud Al Shuraim
Saud Al Shuraim
surah Al-Ankabut Abdul Basit Abdul Samad
Abdul Basit
surah Al-Ankabut Abdul Rashid Sufi
Abdul Rashid Sufi
surah Al-Ankabut Abdullah Basfar
Abdullah Basfar
surah Al-Ankabut Abdullah Awwad Al Juhani
Abdullah Al Juhani
surah Al-Ankabut Fares Abbad
Fares Abbad
surah Al-Ankabut Maher Al Muaiqly
Maher Al Muaiqly
surah Al-Ankabut Muhammad Siddiq Al Minshawi
Al Minshawi
surah Al-Ankabut Al Hosary
Al Hosary
surah Al-Ankabut Al-afasi
Mishari Al-afasi
surah Al-Ankabut Yasser Al Dosari
Yasser Al Dosari


Thursday, January 2, 2025

لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب