Surah Fussilat with Yoruba
حم(1) Ha mim |
Isokale imisi kan (niyi) lati odo Ajoke-aye, Asake-orun |
كِتَابٌ فُصِّلَتْ آيَاتُهُ قُرْآنًا عَرَبِيًّا لِّقَوْمٍ يَعْلَمُونَ(3) (Eyi ni) Tira kan ti Won salaye awon ayah inu re; al-Ƙur’an ni ede Larubawa ni fun ijo t’o nimo |
بَشِيرًا وَنَذِيرًا فَأَعْرَضَ أَكْثَرُهُمْ فَهُمْ لَا يَسْمَعُونَ(4) (O je) iro-idunnu ati ikilo, sugbon opolopo won gbunri kuro nibe. Won ko si teti si i |
Won si wi pe: "Okan wa wa ni titi pa si ohun ti e n pe wa si. Edidi si wa ninu eti wa. Ati pe gaga wa laaarin awa ati iwo. Nitori naa, maa se tire. Dajudaju awa naa n se tiwa |
So pe: "Abara bi iru yin kuku ni emi naa. Won n fi imisi ranse si mi ni, pe Olohun yin, Olohun Okan soso ni. Nitori naa, e duro sinsin ti I, ki e si toro aforijin ni odo Re. Egbe si ni fun awon osebo |
الَّذِينَ لَا يُؤْتُونَ الزَّكَاةَ وَهُم بِالْآخِرَةِ هُمْ كَافِرُونَ(7) awon ti ko yo Zakah. Awon si ni alaigbagbo ninu Ojo Ikeyin |
إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَهُمْ أَجْرٌ غَيْرُ مَمْنُونٍ(8) Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, esan ti ko nii pedin n be fun won |
So pe: "Se dajudaju eyin maa sai gbagbo ninu Eni ti O seda ile fun ojo meji, e si n so (eda Re) di akegbe fun Un?" Iyen si ni Oluwa gbogbo eda |
O si fi awon apata sinu ile lati oke re. O fi ibukun sinu re. O si pebubu awon arisiki (ati ohun amusoro) sinu re laaarin ojo merin. (Awon ojo naa) dogba (sira won) fun awon olubeere (nipa re). o jeyo ninu won pe “Allahu seda awon sanmo ati ile fun ojo mefa.” O wa bee ninu surah al-’A‘rof; 7:54 nnkan naa ko nii dohun afi pelu gbolohun “kunfayakun”. Awon eda ti ko ba si jemo eroja iseda tabi awon eda ti Allahu (subhanahu wa ta’ala) ko so nipa eroja iseda won fun wa Allahu l’O kuku nimo nipa iseda awon eda Re awon eda kan di eda pelu gbolohun “kunfayakun” nikan. Awon eda kan si di eda nipase eroja iseda ati gbolohun “kunfayakun”. Allahu n seda ohun ti O ba fe ni ona ti O ba fe. Nitori naa gbolohun “kunfayakun” t’o je ti Allahu nikan soso ko le so Allahu di olukanju. Ikanju ki i se iroyin rere fun Allahu. Bi Allahu se gbaroyin pelu gbolohun “kunfayakun” |
Leyin naa, Allahu wa ni oke sanmo, nigba ti sanmo wa ni eefin. O si so fun ohun ati ile pe: "E wa bi e fe tabi e ko." Awon mejeeji so pe: "A wa pelu ifinnu-findo |
O si pari (iseda) re si sanmo meje fun ojo meji. O si fi ise sanmo kookan ranse sinu re. A si fi awon atupa (irawo) se sanmo ile aye ni oso ati aabo (fun un). Iyen ni eto Alagbara, Onimo |
فَإِنْ أَعْرَضُوا فَقُلْ أَنذَرْتُكُمْ صَاعِقَةً مِّثْلَ صَاعِقَةِ عَادٍ وَثَمُودَ(13) Ti won ba gbunri, so pe: "Emi n sekilo iparun iru iparun ijo ‘Ad ati Thamud fun yin ni |
Nigba ti awon Ojise won wa ba won niwaju won ati leyin won, (won so) pe: "Eyin ko gbodo josin fun eni kan afi Allahu." Won wi pe: "Ti o ba je pe Oluwa wa ba fe ni, iba so molaika kale (fun ipepe yii). Dajudaju awa je alaigbagbo ninu ohun ti Won fi ran yin nise |
Ni ti ijo ‘Ad, won segberaga ni ori ile lai letoo. Won si wi pe: "Ta ni o lagbara ju wa lo na?" Se won ko ri i pe dajudaju Allahu ti O seda won, O ni agbara ju won lo ni. Won si n se atako si awon ayah Wa |
Nitori naa, A ran ategun lile si won ni awon ojo buruku kan nitori ki A le je ki won to iya yepere wo ninu isemi aye yii. Iya ojo Ikeyin si maa yepere won julo; Won ko si nii ran won lowo. “ojo kan” di “awon ojo kan” ninu ayah ti surah Fussilat. Amo apapo onka ojo iparun won l’o jeyo ninu ayah ti surah al-Haƙƙoh. Se e ti ri i bayii pe ainimo nipa eto laaarin awon ayah le sokunfa itakora ayah loju alaimokan |
Ni ti ijo Thamud, A salaye imona fun won, sugbon won nifee si airiran dipo imona. Nitori naa, igbe iya ti i yepere eda gba won mu nitori ohun ti won n se nise |
A si gba awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si n beru (Allahu) la |
وَيَوْمَ يُحْشَرُ أَعْدَاءُ اللَّهِ إِلَى النَّارِ فَهُمْ يُوزَعُونَ(19) Ni ojo ti won maa ko awon ota Allahu jo sibi Ina, won yo si ko awon eni akoko won papo mo awon eni ikeyin won |
titi di igba ti won ba de ibe tan, igboro won, iriran won ati awo ara won yo si maa jerii le won lori nipa ohun ti won n se nise |
Won yoo wi fun awo ara won pe: "Nitori ki ni e se jerii le wa lori na?" Won yoo so pe: "Allahu, Eni ti O fun gbogbo nnkan ni oro so, Oun l’O fun wa ni oro so. Oun si l’O seda yin nigba akoko. Odo Re si ni won yoo da yin pada si |
Eyin ko le para yin mo (kuro nibi ese, nitori) ki igboro yin, iriran yin ati awo ara yin ma fi le jerii le yin lori. Sugbon e lero pe dajudaju Allahu ko mo opolopo ninu ohun ti e n se nise |
وَذَٰلِكُمْ ظَنُّكُمُ الَّذِي ظَنَنتُم بِرَبِّكُمْ أَرْدَاكُمْ فَأَصْبَحْتُم مِّنَ الْخَاسِرِينَ(23) Iyen, ero yin ti e lero si Oluwa yin lo ko iparun ba yin. E si di eni ofo |
فَإِن يَصْبِرُوا فَالنَّارُ مَثْوًى لَّهُمْ ۖ وَإِن يَسْتَعْتِبُوا فَمَا هُم مِّنَ الْمُعْتَبِينَ(24) Ti won ba se suuru (fun iya), Ina kuku ni ibugbe fun won. Ti won ba si fe seri pada si sise ohun ti Allahu yonu si (ni asiko yii), A o nii gba won laye lati seri pada |
Awa ti yan awon alabaarin kan fun won, ti won se ohun ti n be niwaju won ati ohun ti n be ni eyin won ni oso fun won. Oro naa si ko le won lori (bi o se sele) si awon ijo t’o siwaju won ninu awon alujannu ati eniyan pe dajudaju won je eni ofo |
Awon t’o sai gbagbo wi pe: "E ma se teti si al-Ƙur’an yii. Ki e si so isokuso nipa re ki e le bori |
Nitori naa, dajudaju A oo fun awon t’o sai gbagbo niya lile to wo. Ati pe dajudaju A oo fi eyi t’o buru ju eyi ti won n se nise san won ni esan |
Ina, iyen ni esan awon ota Allahu. Ile gbere wa ninu re fun won. O je esan nitori pe won n tako awon ayah Wa |
Awon t’o sai gbagbo wi pe: "Oluwa wa, fi awon mejeeji ti won si wa lona ninu awon alujannu ati eniyan han wa nitori ki a le fi awon mejeeji si abe gigise wa, nitori ki won le wa ni isale patapata |
Dajudaju awon t’o so pe: "Allahu ni Oluwa wa." leyin naa, ti won duro sinsin, awon molaika yoo maa sokale wa ba won (ni ojo iku won, won si maa so pe: “E ma se paya, e ma se banuje. Ki e si dunnu si Ogba Idera eyi ti Won n se ni adehun fun yin) |
Awa ni ore yin ninu isemi aye ati ni orun. Ohun ti emi yin n fe ti wa fun yin ninu Ogba Idera. Ohun ti e n beere fun si ti wa ninu re |
Nnkan igbalejo ni lati odo Alaforijin, Asake-orun.” |
Ta ni o dara julo ni oro siso t’o tayo eni ti o pepe si odo Allahu, ti o se ise rere, ti o si so pe: "Dajudaju emi wa ninu awon musulumi |
Rere ati aburu ko dogba. Fi eyi ti o dara julo dena (aburu). Nigba naa ni eni ti ota wa laaarin iwo ati oun maa da bi ore alasun-unmo pekipeki |
وَمَا يُلَقَّاهَا إِلَّا الَّذِينَ صَبَرُوا وَمَا يُلَقَّاهَا إِلَّا ذُو حَظٍّ عَظِيمٍ(35) A o nii fun eni kan ni (iwa rere yii) afi awon t’o se suuru. A o nii fun eni kan se afi olori-ire nla |
Ati pe ti erokero kan lati odo Esu ba fe se o lori (kuro nibi iwa rere yii), sa di Allahu. Dajudaju Oun ni Olugbo, Onimo |
Ninu awon ami Re ni oru, osan, oorun ati osupa. E o gbodo fori kanle fun oorun ati osupa. E fori kanle fun Allahu, Eni ti O da won, ti eyin ba je eni t’o n josin fun Oun nikan soso |
Ti won ba si segberaga, awon t’o wa ni odo Oluwa re, won n safomo fun Un ni ale ati ni osan; won ko si kagara |
Ninu awon ami Re tun ni pe dajudaju iwo yoo ri ile ni asale. Nigba ti A ba si so omi kale le e lori, o maa rura wa, o si maa ga (fun hihu irugbin jade). Dajudaju Eni ti O ji i, Oun ma ni Eni ti O maa so awon oku di alaaye. Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
Dajudaju awon t’o n ye awon ayah Wa (sibi omiran), won ko pamo fun Wa. Se eni ti won maa ju sinu Ina l’o loore julo ni tabi eni ti o maa wa ni olufayabale ni Ojo Ajinde? E maa se ohun ti e ba fe. Dajudaju Allahu ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise |
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا بِالذِّكْرِ لَمَّا جَاءَهُمْ ۖ وَإِنَّهُ لَكِتَابٌ عَزِيزٌ(41) Dajudaju awon t’o sai gbagbo ninu Tira Iranti naa (iyen, al-Ƙur’an) nigba ti o de ba won (eni iparun ni won.) Dajudaju ohun ma ni Tira t’o lagbara |
لَّا يَأْتِيهِ الْبَاطِلُ مِن بَيْنِ يَدَيْهِ وَلَا مِنْ خَلْفِهِ ۖ تَنزِيلٌ مِّنْ حَكِيمٍ حَمِيدٍ(42) Ibaje ko nii kan an lati iwaju re ati lati eyin re. Imisi ti won sokale ni lati odo Ologbon, Eleyin |
Won ko so oro kan si o bi ko se ohun ti won ti so si awon Ojise t’o siwaju re. Dajudaju Oluwa re ma ni Alaforijin, O si ni iya eleta-elero (lodo) |
Ti o ba je pe A se al-Ƙur’an ni nnkan kike ni ede miiran yato si ede Larubawa ni, won iba wi pe: "Ki ni ko je ki Won se alaye awon ayah re?" Bawo ni al-Ƙur’an se le je ede miiran (yato si ede Larubawa), nigba ti Anabi (Muhammad s.a.w.) je Larubawa? So pe: "O je imona ati iwosan fun awon t’o gbagbo ni ododo. Awon ti ko si gbagbo, edidi wa ninu eti won. Fojunfoju si wa ninu oju won si (ododo al-Ƙur’an). Awon wonyen ni won si n pe (sibi ododo al-Ƙur’an) lati aye t’o jinna |
A kuku fun (Anabi) Musa ni Tira. Won si yapa enu si i. Ti ko ba je pe oro kan ti o ti siwaju ni odo Oluwa re ni, A iba se idajo laaarin won. Dajudaju won tun wa ninu iyemeji t’o gbopon nipa al-Ƙur’an |
Enikeni ti o ba se ise rere, o se e fun emi ara re. Enikeni ti o ba si se aburu, o se e fun emi ara re. Oluwa re ko si nii se abosi si awon erusin |
Odo Re ni won yoo maa da imo Akoko naa pada si. Ko si eso kan ti o maa jade ninu apo re, obinrin kan ko si nii loyun, ko si nii bimo afi pelu imo Re. (Ranti) ojo ti O si maa pe won pe: "Ibo ni awon akegbe Mi (ti e josin fun) wa?" Won a wi pe: "Awa n je ki O mo pe ko si olujerii kan ninu wa (ti o maa jerii pe O ni akegbe) |
وَضَلَّ عَنْهُم مَّا كَانُوا يَدْعُونَ مِن قَبْلُ ۖ وَظَنُّوا مَا لَهُم مِّن مَّحِيصٍ(48) Ohun ti won n pe teletele si dofo mo won lowo. Won si mo ni amodaju pe ko si ibusasi kan fun awon |
لَّا يَسْأَمُ الْإِنسَانُ مِن دُعَاءِ الْخَيْرِ وَإِن مَّسَّهُ الشَّرُّ فَيَئُوسٌ قَنُوطٌ(49) Eniyan ko ko susu nibi adua (lati toro) oore. Ti aburu ba si fowo ba a, o maa di olusoretinu, olujakanmuna |
Dajudaju ti A ba se idera fun un lati odo Wa leyin aburu ti o fowo ba a, dajudaju o maa wi pe: "Eyi ni temi. Emi ko si ni amodaju pe Akoko naa maa sele. Ati pe dajudaju ti Won ba da mi pada si odo Oluwa mi, dajudaju rere tun wa fun mi ni odo Re." Dajudaju Awa yoo fun awon t’o sai gbagbo ni iro ohun ti won se nise. Dajudaju A si maa fun won ni iya t’o nipon to wo |
Ati pe nigba ti A ba se idera fun eniyan, o maa gbunri (kuro ni odo Wa). O si maa segberaga. Nigba ti aburu ba si fowo ba a, nigba naa l’o maa di aladuaa regede |
So pe: " E so fun mi, ti o ba je pe al-Ƙur’an wa lati odo Allahu, leyin naa ti e sai gbagbo ninu re (se eyin ko ti wa ninu iyapa bi?)" Ta l’o sina ju eni ti o wa ninu iyapa t’o jinna (si ododo) |
A oo maa fi awon ami Wa han won ninu ofurufu ati ninu emi ara won titi o maa fi han kedere si won pe dajudaju al-Ƙur’an ni ododo. Nje Oluwa re ko to ki o je pe dajudaju Oun ni Arinu-rode lori gbogbo nnkan |
أَلَا إِنَّهُمْ فِي مِرْيَةٍ مِّن لِّقَاءِ رَبِّهِمْ ۗ أَلَا إِنَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ مُّحِيطٌ(54) Gbo, dajudaju won wa ninu iyemeji nipa ipade Oluwa won. Gbo, dajudaju Allahu yi gbogbo nnkan ka |
More surahs in Yoruba:
Download surah Fussilat with the voice of the most famous Quran reciters :
surah Fussilat mp3 : choose the reciter to listen and download the chapter Fussilat Complete with high quality
Ahmed Al Ajmy
Bandar Balila
Khalid Al Jalil
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdul Rashid Sufi
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Yasser Al Dosari
لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب