Surah At-Tahreem with Yoruba
Iwo Anabi, nitori ki ni o se maa so nnkan ti Allahu se ni eto fun o di eewo? Iwo n wa iyonu awon iyawo re. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun |
Dajudaju Allahu ti se alaye ofin itanran ibura yin fun yin. Allahu ni Oluranlowo yin. Oun si ni Onimo, Ologbon |
Ranti nigba ti Anabi ba okan ninu awon iyawo re s’oro asiri. Nigba ti (eni t’o ba soro, iyen Hafsoh) si soro naa fun (‘A’isah), Allahu si fi han Anabi (pe elomiiran ti gbo si i). Anabi si so apa kan re (fun Hafsoh pe: "O ti fi oro Moriyah to ‘A’isah leti."). O si fi apa kan sile (iyen, oro nipa ipo arole). Amo nigba ti (Anabi) fi iro naa to o leti, Hafsoh) so pe: "Ta ni o fun o ni iro eyi?" (Anabi) so pe: "Onimo, Alamotan l’O fun mi ni iro naa |
Ti eyin mejeeji ba ronu piwada si odo Allahu, (O maa gba ironupiwada yin). Sebi okan yin kuku ti te (sibi ki Anabi ma fee Moriyah). Ti e ba si ran ara yin lowo (lati ko ibanuje) ba a, dajudaju Allahu ni Oluranlowo re, ati (molaika) Jibril ati eni rere ninu awon onigbagbo ododo. Leyin iyen, awon molaika ti won je oluranlowo (tun wa fun un) |
O see se, ti o ba ko yin sile, ki Oluwa re fi awon obinrin kan, ti won loore ju yin lo ropo fun un, (ti won maa je) musulumi, onigbagbo ododo, awon olutele-ase, awon oluronupiwada, olujosin, olugbaawe ni adelebo ati wundia |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e so emi ara yin ati awon ara ile yin nibi Ina. Eniyan ati okuta ni nnkan ikona re. Awon molaika t’o roro, ti won le ni eso re. Won ko nii yapa ase Allahu nibi ohun ti O ba pa lase fun won. Won si n se ohun ti won ba pa lase fun won |
Eyin ti e sai gbagbo, e ma se saroye ni ojo oni. Ohun ti e n se nise ni A oo fi san yin ni esan |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ronu piwada si odo Allahu ni ironupiwada ododo. O see se pe Oluwa yin maa pa awon asise yin re fun yin. O si maa mu yin wo inu awon Ogba Idera ti awon odo n san ni isale re. Ni ojo ti Allahu ko nii doju ti Anabi ati awon t’o gbagbo ni ododo pelu re. Imole won yoo maa tan ni iwaju won ati ni owo otun won. Won yoo so pe: "Oluwa wa, pe imole wa fun wa, ki O si forijin wa. Dajudaju Iwo ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
Iwo Anabi, gbogun ti awon alaigbagbo ati awon sobe-selu musulumi. Ki o si le mo won. Ibugbe won si ni ina Jahanamo. Ikangun naa si buru |
Allahu fi iyawo (Anabi) Nuh ati iyawo (Anabi) Lut se apeere fun awon t’o sai gbagbo. Awon mejeeji wa labe erusin meji rere ninu awon erusin Wa. Awon (obinrin) mejeeji si janba awon oko won. Awon oko won ko si fi kini kan ro won loro lodo Allahu. A o si so fun awon obinrin mejeeji pe: "E wo inu Ina pelu awon oluwole (sinu Ina) |
Allahu tun fi iyawo Fir‘aon se apeere fun awon t’o gbagbo. Nigba ti o so pe: "Oluwa mi, ko ile kan fun mi lodo Re ninu Ogba Idera. La mi lowo Fir‘aon ati ise owo re. Ki O si la mi lowo ijo alabosi |
Ati Moryam omobinrin ‘Imron, eyi ti o so abe re. A si fe ategun si i lara ninu ategun emi ti A da. O gbagbo lododo ninu awon oro Oluwa re ati awon Tira Re. O si wa ninu awon olutele-ase Allahu |
More surahs in Yoruba:
Download surah At-Tahreem with the voice of the most famous Quran reciters :
surah At-Tahreem mp3 : choose the reciter to listen and download the chapter At-Tahreem Complete with high quality
Ahmed Al Ajmy
Bandar Balila
Khalid Al Jalil
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdul Rashid Sufi
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Yasser Al Dosari
لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب