سوره جاثية به زبان یوروبا
حم(1) Ha mim |
Tira naa sokale lati odo Allahu, Alagbara, Ologbon |
إِنَّ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ لَآيَاتٍ لِّلْمُؤْمِنِينَ(3) Dajudaju ninu awon sanmo ati ile awon ami wa (ninu won) fun awon onigbagbo ododo |
وَفِي خَلْقِكُمْ وَمَا يَبُثُّ مِن دَابَّةٍ آيَاتٌ لِّقَوْمٍ يُوقِنُونَ(4) Awon ami wa ninu iseda yin ati ohun ti Allahu n fonka (sori ile) ninu awon nnkan abemi; (ami wa ninu won) fun ijo t’o ni amodaju |
(Ninu) itelentele ati iyato oru ati osan, ati ohun ti Allahu n sokale ni arisiki, ti O n fi so ile di aye leyin t’o ti ku ati iyipada ategun, awon ami tun wa (ninu won) fun ijo t’o ni laakaye |
Iwonyi ni awon ayah Allahu ti A n ke (ni keu) fun o pelu ododo. Nitori naa, oro wo leyin (oro) Allahu ati awon ami Re ni won yoo tun gbagbo |
Egbe ni fun aladaapaaro, elese |
t’o n gbo awon ayah Allahu, ti won n ke e fun un, leyin naa, ti o (tun) taku ni ti igberaga bi eni pe ko gbo o. Fun un ni iro iya eleta-elero |
وَإِذَا عَلِمَ مِنْ آيَاتِنَا شَيْئًا اتَّخَذَهَا هُزُوًا ۚ أُولَٰئِكَ لَهُمْ عَذَابٌ مُّهِينٌ(9) Nigba ti o ba nimo nipa kini kan ninu awon ayah Wa, o maa mu un ni nnkan yeye. Awon wonyen ni iya ti i yepere eda n be fun |
Ina Jahanamo wa niwaju won. Ohun ti won se nise ati ohun ti won mu ni alaabo leyin Allahu ko si nii ro won loro kan nibi iya. Iya nla si wa fun won |
هَٰذَا هُدًى ۖ وَالَّذِينَ كَفَرُوا بِآيَاتِ رَبِّهِمْ لَهُمْ عَذَابٌ مِّن رِّجْزٍ أَلِيمٌ(11) Eyi ni imona. Awon t’o si sai gbagbo ninu awon ayah Oluwa won, iya elegbin eleta-elero wa fun won |
Allahu ni Eni ti O ro agbami odo fun yin nitori ki awon oko oju-omi le rin ninu re pelu ase Re ati nitori ki e tun le wa ninu oore Re ati nitori ki e le dupe (fun Un) |
O tun ro ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile patapata fun yin lati odo ara Re. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni arojinle |
So fun awon t’o gbagbo ni ododo pe ki won samoju kuro fun awon ti ko reti awon ojo (ti) Allahu (yoo se aranse fun awon onigbagbo ododo) nitori ki O le san esan fun ijo kan nipa ohun ti won n se nise |
مَنْ عَمِلَ صَالِحًا فَلِنَفْسِهِ ۖ وَمَنْ أَسَاءَ فَعَلَيْهَا ۖ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُمْ تُرْجَعُونَ(15) Enikeni ti o ba se ise rere, fun emi ara re ni. Enikeni ti o ba si se ise aburu, fun emi ara re ni. Leyin naa, odo Oluwa yin ni won yoo da yin pada si |
Dajudaju A fun awon omo ’Isro’il ni Tira ati idajo sise pelu ipo Anabi. A si se arisiki fun won ninu awon nnkan daadaa. A si soore ajulo fun won lori awon eda (asiko won) |
A tun fun won ni awon eri t’o yanju nipa oro naa. Nitori naa, won ko pin si ijo otooto afi leyin ti imo (’Islam) de ba won. (Won se bee) nipase ote aarin won (si awon Anabi). Dajudaju Oluwa re l’O maa se idajo laaarin won ni Ojo Ajinde nipa nnkan ti won n yapa enu si |
Leyin naa, A fi o si oju ona kan ninu oro (esin ’Islam). Nitori naa, tele e. Ki o si ma se tele ife-inu awon ti ko nimo |
Dajudaju won ko le ro o loro kini kan nibi iya ni odo Allahu. Ati pe dajudaju awon alabosi, apa kan won lore apa kan. Allahu si ni Ore awon oluberu (Re) |
هَٰذَا بَصَائِرُ لِلنَّاسِ وَهُدًى وَرَحْمَةٌ لِّقَوْمٍ يُوقِنُونَ(20) Eyi ni itosona fun awon eniyan. Imona ati ike ni fun ijo t’o ni amodaju |
Tabi awon t’o n se ise aburu lero pe A maa se won gege bi (A ti se) awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, ki isemi aye won ati iku won ri bakan naa? Ohun ti won n da lejo buru |
Allahu seda awon sanmo ati ile pelu ododo ati nitori ki A le san emi kookan ni esan nnkan ti o se nise. A o si nii se abosi si won |
So fun mi nipa eni ti o so ife-inu re di olohun re, ti Allahu si si i lona pelu imo , ti O si fi edidi di igboro re ati okan re, ti O tun fi ebibo bo oju re! Ta ni o maa fi ona mo on leyin Allahu? Se e o nii lo iranti ni |
Won wi pe: "Ko si isemi kan mo bi ko se isemi aye wa yii; a n ku, a si n semi. Ati pe ko si nnkan t’o n pa wa bi ko se igba." Won ko si ni imo kan nipa iyen; won ko se kini kan bi ko se pe won n ro erokero |
Ati pe nigba ti won ba n ke awon ayah Wa t’o yanju fun won, awijare won ko je kini kan tayo ki won wi pe: "E mu awon baba wa wa ti e ba je olododo |
So pe: "Allahu l’O n so yin di alaaye. Leyin naa, O maa so yin di oku. Leyin naa, O maa ko yin jo ni Ojo Ajinde, ko si iyemeji ninu re, sugbon opolopo eniyan ni ko mo |
Ati pe ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile. (Ranti) ojo ti Akoko naa maa sele; ojo yen ni awon t’o n tele iro yoo sofo |
O si maa ri gbogbo ijo lori ikunle. Won yo si maa pe ijo kookan sibi iwe ise won. Ni oni ni A oo san yin ni esan ohun ti e n se nise |
هَٰذَا كِتَابُنَا يَنطِقُ عَلَيْكُم بِالْحَقِّ ۚ إِنَّا كُنَّا نَسْتَنسِخُ مَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ(29) Eyi ni iwe akosile Wa, ti o n so ododo nipa yin. Dajudaju Awa n se akosile ohun ti e n se nise |
Ni ti awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, Oluwa won yoo fi won sinu ike Re. Iyen ni erenje ponnbele |
Ni ti awon t’o si sai gbagbo, (A oo bi won leere pe:) "Nje won ki i ke awon ayah Mi fun yin bi?" Sugbon e segberaga. E si je ijo elese |
Nigba ti won ba so pe: "Dajudaju adehun Allahu ni ododo. Ati pe Akoko naa, ko si iyemeji ninu re." Eyin n wi pe: "Awa ko mo ohun ti Akoko naa je. Awa ko si ro o si kini kan bi ko se erokero; awa ko si ni amodaju (nipa re) |
وَبَدَا لَهُمْ سَيِّئَاتُ مَا عَمِلُوا وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ(33) Awon aburu ohun ti won se nise si han si won. Ati pe ohun ti won n fi se yeye si diya t’o yi won po |
Won si maa so pe: "Ni oni, Awa yoo gbagbe yin (sinu Ina) gege bi eyin naa se gbagbe ipade ojo yin (oni) yii. Ina si ni ibugbe yin. Ati pe ko nii si awon oluranlowo fun yin |
Bayen ni nitori pe, e so awon ayah Allahu di nnkan yeye. Ati pe isemi aye tan yin je. Nitori naa, ni oni won ko nii mu won jade kuro ninu Ina. Won ko si nii fun won ni aye lati se ohun ti won yoo fi ri iyonu Allahu |
فَلِلَّهِ الْحَمْدُ رَبِّ السَّمَاوَاتِ وَرَبِّ الْأَرْضِ رَبِّ الْعَالَمِينَ(36) Nitori naa, gbogbo ope n je ti Allahu, Oluwa awon sanmo ati ile, Oluwa gbogbo eda |
وَلَهُ الْكِبْرِيَاءُ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ(37) TiRe ni titobi ninu awon sanmo ati ile. Oun si ni Alagbara, Ologbon |
سورهای بیشتر به زبان یوروبا:
دانلود سوره جاثية با صدای معروفترین قراء:
انتخاب خواننده برای گوش دادن و دانلود کامل سوره جاثية با کیفیت بالا.
أحمد العجمي
ابراهيم الاخضر
بندر بليلة
خالد الجليل
حاتم فريد الواعر
خليفة الطنيجي
سعد الغامدي
سعود الشريم
الشاطري
صلاح بوخاطر
عبد الباسط
عبدالرحمن العوسي
عبد الرشيد صوفي
عبدالعزيز الزهراني
عبد الله بصفر
عبد الله الجهني
علي الحذيفي
علي جابر
غسان الشوربجي
فارس عباد
ماهر المعيقلي
محمد أيوب
محمد المحيسني
محمد جبريل
المنشاوي
الحصري
مشاري العفاسي
ناصر القطامي
وديع اليمني
ياسر الدوسري
به قرآن کریم چنگ بزنید