سوره حجرات به زبان یوروبا
Eyin ti e gbagbo ni ododo, eyin ko gbodo gbawaju mo Allahu ati Ojise Re lowo. Ki e si beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Olugbo, Onimo |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se gbe ohun yin ga bori ohun Anabi (sollalahu alayhi wa sallam). Ki e si ma se fi ohun ariwo ba a soro gege bi apa kan yin se n fi ohun ariwo ba apa kan soro nitori ki awon ise yin ma baa baje, eyin ko si nii fura |
Dajudaju awon t’o n re ohun won nile lodo Ojise Allahu, awon wonyen ni awon ti Allahu ti gbidanwo okan won fun iberu (Re). Aforijin ati esan nla wa fun won |
إِنَّ الَّذِينَ يُنَادُونَكَ مِن وَرَاءِ الْحُجُرَاتِ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْقِلُونَ(4) Dajudaju awon t’o n pe o lati eyin awon yara, opolopo won ni ko se laakaye |
Ti o ba je pe dajudaju won se suuru titi o maa fi jade si won ni, iba dara julo fun won. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, ti obileje kan ba mu iro kan wa ba yin, e se pelepele lati mo ododo (nipa oro naa) nitori ki e ma baa se awon eniyan kan ni suta pelu aimo. Leyin naa, ki e ma baa di alabaamo lori ohun ti e se |
Ki e si mo pe dajudaju Ojise Allahu wa laarin yin. Ti o ba je pe o n tele yin nibi opolopo ninu oro (t’o n sele) ni, dajudaju eyin iba ti ko o sinu idaamu. Sugbon Allahu je ki e nifee si igbagbo ododo. O se e ni oso sinu okan yin. O si je ki e korira aigbagbo, iwa buruku ati iyapa ase. Awon wonyen ni awon olumona |
فَضْلًا مِّنَ اللَّهِ وَنِعْمَةً ۚ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ(8) (Eyi je) oore ajulo ati idera lati odo Allahu. Allahu si ni Onimo, Ologbon |
Ti igun meji ninu awon onigbagbo ododo ba n ba ara won ja, e se atunse laaarin awon mejeeji. Ti okan ninu awon mejeeji ba si koja enu-ala lori ikeji, e ba eyi ti o koja enu-ala ja titi o fi maa seri pada sibi ase Allahu. Ti o ba si seri pada, e se atunse laaarin awon mejeeji pelu deede. Ki e si se eto. Dajudaju Allahu feran awon oluse-eto |
Omo iya (esin) ni awon onigbagbo ododo. Nitori naa, e satunse laaarin awon omo iya yin mejeeji. Ki e si beru Allahu nitori ki A le ke yin |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, awon eniyan kan ko gbodo fi awon eniyan kan se yeye. O le je pe awon (ti won so di oniyeye) dara ju awon (t’o n se yeye). Awon obinrin kan (ko si gbodo fi) awon obinrin kan (se yeye). O le je pe awon (ti won so di oniyeye) dara ju awon (t’o n se yeye). E ma se bura yin. E ma pe’ra yin loriki buruku leyin igbagbo ododo. Enikeni ti ko ba ronu piwada, awon wonyen ni awon alabosi |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e jinna si opolopo aroso. Dajudaju apa kan aroso ni ese. E ma se topinpin ara yin. Ki apa kan yin ma se soro apa kan leyin. Se okan ninu yin nifee si lati je eran-ara omo iya re t’o ti ku ni? E si korira re. E beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun |
Eyin eniyan, dajudaju Awa seda yin lati ara okunrin ati obinrin. A si se yin ni orile-ede orile-ede ati iran-iran nitori ki e le dara yin mo. Dajudaju alapon-onle julo ninu yin lodo Allahu ni eni t’o beru (Re) julo. Dajudaju Allahu ni Onimo, Alamotan |
Awon Larubawa oko so pe: "A gbagbo ni ododo." So pe: "Eyin ko gbagbo ni ododo." Sugbon e so pe: "A gba ’Islam." niwon igba ti igbagbo ododo ko ti i wo’nu okan yin. Ti e ba tele (ase) Allahu ati Ojise Re, (Allahu) ko nii din kini kan ku fun yin ninu (esan) awon ise yin. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun |
Awon onigbagbo ododo ni awon t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re, leyin naa ti won ko seyemeji, ti won si fi dukia won ati emi won jagun fun esin Allahu. Awon wonyen, awon ni olododo |
So pe: "Se e maa ko Allahu ni esin yin ni?" Allahu si mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Allahu si ni Onimo nipa gbogbo nnkan |
Won n seregun lori re pe won gba ’Islam. So pe: "E ma fi ’Islam yin seregun lori mi.” Bee ni! Allahu l’O maa seregun lori yin pe O fi yin mona sibi igbagbo ododo ti e ba je olododo |
إِنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ غَيْبَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ وَاللَّهُ بَصِيرٌ بِمَا تَعْمَلُونَ(18) Dajudaju Allahu mo ikoko awon sanmo ati ile. Ati pe Allahu ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise |
سورهای بیشتر به زبان یوروبا:
دانلود سوره حجرات با صدای معروفترین قراء:
انتخاب خواننده برای گوش دادن و دانلود کامل سوره حجرات با کیفیت بالا.
أحمد العجمي
ابراهيم الاخضر
بندر بليلة
خالد الجليل
حاتم فريد الواعر
خليفة الطنيجي
سعد الغامدي
سعود الشريم
الشاطري
صلاح بوخاطر
عبد الباسط
عبدالرحمن العوسي
عبد الرشيد صوفي
عبدالعزيز الزهراني
عبد الله بصفر
عبد الله الجهني
علي الحذيفي
علي جابر
غسان الشوربجي
فارس عباد
ماهر المعيقلي
محمد أيوب
محمد المحيسني
محمد جبريل
المنشاوي
الحصري
مشاري العفاسي
ناصر القطامي
وديع اليمني
ياسر الدوسري
به قرآن کریم چنگ بزنید