Surah Qaf with Yoruba

  1. Surah mp3
  2. More
  3. Yoruba
The Holy Quran | Quran translation | Language Yoruba | Surah Qaf | ق - Ayat Count 45 - The number of the surah in moshaf: 50 - The meaning of the surah in English: Qaf.

ق ۚ وَالْقُرْآنِ الْمَجِيدِ(1)

 Ƙof. (Allahu fi) al-Ƙur’an alapon-onle bura

بَلْ عَجِبُوا أَن جَاءَهُم مُّنذِرٌ مِّنْهُمْ فَقَالَ الْكَافِرُونَ هَٰذَا شَيْءٌ عَجِيبٌ(2)

 Sugbon won seemo nitori pe olukilo kan wa ba won lati aarin ara won. Awon alaigbagbo si wi pe: "Eyi ni ohun iyanu

أَإِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا ۖ ذَٰلِكَ رَجْعٌ بَعِيدٌ(3)

 Se nigba ti a ba ti ku, ti a ti di erupe (ni a oo tun ji dide pada). Iyen ni idapada to jinna (si nnkan ti o le sele)

قَدْ عَلِمْنَا مَا تَنقُصُ الْأَرْضُ مِنْهُمْ ۖ وَعِندَنَا كِتَابٌ حَفِيظٌ(4)

 Dajudaju A ti mo ohun ti ile n mu je ninu won. Tira (ise eda ) ti won n so si wa ni odo Wa

بَلْ كَذَّبُوا بِالْحَقِّ لَمَّا جَاءَهُمْ فَهُمْ فِي أَمْرٍ مَّرِيجٍ(5)

 Sibesibe won pe ododo (al-Ƙur’an) ni iro nigba ti o de ba won. Nitori naa, won ti wa ninu idaamu

أَفَلَمْ يَنظُرُوا إِلَى السَّمَاءِ فَوْقَهُمْ كَيْفَ بَنَيْنَاهَا وَزَيَّنَّاهَا وَمَا لَهَا مِن فُرُوجٍ(6)

 Se won ko wo sanmo oke won bi A ti se mo on pa ati (bi) A ti se e ni oso, ti ko si si alafo sisan kan lara re

وَالْأَرْضَ مَدَدْنَاهَا وَأَلْقَيْنَا فِيهَا رَوَاسِيَ وَأَنبَتْنَا فِيهَا مِن كُلِّ زَوْجٍ بَهِيجٍ(7)

 Ati pe ile, A te e perese. A si ju awon apata t’o duro gbagidi sinu re. A si mu orisirisi irugbin t’o dara hu jade lati inu re

تَبْصِرَةً وَذِكْرَىٰ لِكُلِّ عَبْدٍ مُّنِيبٍ(8)

 (O je) ariwoye ati iranti fun gbogbo erusin to n seri pada (sibi ododo)

وَنَزَّلْنَا مِنَ السَّمَاءِ مَاءً مُّبَارَكًا فَأَنبَتْنَا بِهِ جَنَّاتٍ وَحَبَّ الْحَصِيدِ(9)

 A n so omi ibukun kale lati sanmo. A si n fi mu awon ogba oko ati awon eso ti won maa kaje hu jade

وَالنَّخْلَ بَاسِقَاتٍ لَّهَا طَلْعٌ نَّضِيدٌ(10)

 (A tun mu) igi dabinu hu ga, ti awon eso ori re so jigbinni

رِّزْقًا لِّلْعِبَادِ ۖ وَأَحْيَيْنَا بِهِ بَلْدَةً مَّيْتًا ۚ كَذَٰلِكَ الْخُرُوجُ(11)

 Arisiki ni fun awon eru (Allahu). A si n fi so oku ile di aye. Bayen ni ijade eda (lati inu saree yo se ri)

كَذَّبَتْ قَبْلَهُمْ قَوْمُ نُوحٍ وَأَصْحَابُ الرَّسِّ وَثَمُودُ(12)

 Awon eniyan (Anabi) Nuh, awon eniyan Rass ati awon (eniyan) Thamud pe ododo niro siwaju won

وَعَادٌ وَفِرْعَوْنُ وَإِخْوَانُ لُوطٍ(13)

 Ati awon ‘Ad, Fir‘aon ati awon omo iya (Anabi) Lut

وَأَصْحَابُ الْأَيْكَةِ وَقَوْمُ تُبَّعٍ ۚ كُلٌّ كَذَّبَ الرُّسُلَ فَحَقَّ وَعِيدِ(14)

 ati awon ara ’Aekah ati awon ijo Tubba‘u; gbogbo won pe awon Ojise ni opuro. Nitori naa, ileri Mi si di eto (lori won)

أَفَعَيِينَا بِالْخَلْقِ الْأَوَّلِ ۚ بَلْ هُمْ فِي لَبْسٍ مِّنْ خَلْقٍ جَدِيدٍ(15)

 Nje iseda akoko ko agara ba Wa bi? Rara, won wa ninu iyemeji nipa iseda (won) ni titun ni

وَلَقَدْ خَلَقْنَا الْإِنسَانَ وَنَعْلَمُ مَا تُوَسْوِسُ بِهِ نَفْسُهُ ۖ وَنَحْنُ أَقْرَبُ إِلَيْهِ مِنْ حَبْلِ الْوَرِيدِ(16)

 Dajudaju A seda eniyan. A si mo ohun ti emi re n so fun un. Awa si sunmo on ju isan orun re

إِذْ يَتَلَقَّى الْمُتَلَقِّيَانِ عَنِ الْيَمِينِ وَعَنِ الشِّمَالِ قَعِيدٌ(17)

 (Ranti) nigba ti (molaika) awon agboro-sile meji ba beresi gba oro (sile), ti okan jokoo si otun, ti okan jokoo si osi

مَّا يَلْفِظُ مِن قَوْلٍ إِلَّا لَدَيْهِ رَقِيبٌ عَتِيدٌ(18)

 (Eni kan) ko si nii so oro kan ayafi ki eso kan wa pelu re (fun akosile re)

وَجَاءَتْ سَكْرَةُ الْمَوْتِ بِالْحَقِّ ۖ ذَٰلِكَ مَا كُنتَ مِنْهُ تَحِيدُ(19)

 Ati pe ipokaka iku yoo de lati fi ododo orun rinle. Iyen ni ohun ti iwo n sa fun

وَنُفِخَ فِي الصُّورِ ۚ ذَٰلِكَ يَوْمُ الْوَعِيدِ(20)

 Won a fon fere oniwo fun ajinde. Iyen ni ojo ileri naa

وَجَاءَتْ كُلُّ نَفْسٍ مَّعَهَا سَائِقٌ وَشَهِيدٌ(21)

 Emi kookan yoo wa pelu oludari kan ati elerii kan (ninu awon molaika)

لَّقَدْ كُنتَ فِي غَفْلَةٍ مِّنْ هَٰذَا فَكَشَفْنَا عَنكَ غِطَاءَكَ فَبَصَرُكَ الْيَوْمَ حَدِيدٌ(22)

 Dajudaju iwo ti wa ninu igbagbera nibi eyi. A si ti si ebibo (oju) re kuro fun o bayii. Nitori naa, iriran re yoo riran kedere ni oni

وَقَالَ قَرِينُهُ هَٰذَا مَا لَدَيَّ عَتِيدٌ(23)

 (Molaika) alabaarin re yoo so pe: "Eyi ni ohun ti n be ni odo mi (gege bi akosile ise re)

أَلْقِيَا فِي جَهَنَّمَ كُلَّ كَفَّارٍ عَنِيدٍ(24)

 E ju u sinu ina Jahanamo, gbogbo alaigbagbo olorikunkun

مَّنَّاعٍ لِّلْخَيْرِ مُعْتَدٍ مُّرِيبٍ(25)

 oludena-ise rere, alakoyo, oniyemeji

الَّذِي جَعَلَ مَعَ اللَّهِ إِلَٰهًا آخَرَ فَأَلْقِيَاهُ فِي الْعَذَابِ الشَّدِيدِ(26)

 eni to mu olohun miiran mo Allahu. E ju u sinu iya lile

۞ قَالَ قَرِينُهُ رَبَّنَا مَا أَطْغَيْتُهُ وَلَٰكِن كَانَ فِي ضَلَالٍ بَعِيدٍ(27)

 (Esu) alabaarin re yoo wi pe: "Oluwa wa, emi ko ni mo si i lona, sugbon o ti wa ninu isina to jinna (si ododo) teletele

قَالَ لَا تَخْتَصِمُوا لَدَيَّ وَقَدْ قَدَّمْتُ إِلَيْكُم بِالْوَعِيدِ(28)

 (Allahu) yoo so pe: "E ma se sariyanjiyan lodo Mi. Mo kuku ti se ileri fun yin siwaju

مَا يُبَدَّلُ الْقَوْلُ لَدَيَّ وَمَا أَنَا بِظَلَّامٍ لِّلْعَبِيدِ(29)

 Won ko si le yi oro naa pada ni odo Mi. Emi ko si nii se abosi si awon eru Mi

يَوْمَ نَقُولُ لِجَهَنَّمَ هَلِ امْتَلَأْتِ وَتَقُولُ هَلْ مِن مَّزِيدٍ(30)

 (Ranti) ojo ti A oo so fun ina Jahnamo pe: Sebi o ti kun?" O si maa so pe: "Sebi afikun tun wa

وَأُزْلِفَتِ الْجَنَّةُ لِلْمُتَّقِينَ غَيْرَ بَعِيدٍ(31)

 Won maa sun Ogba Idera mo awon oluberu (Allahu). Ko si nii jinna (si won)

هَٰذَا مَا تُوعَدُونَ لِكُلِّ أَوَّابٍ حَفِيظٍ(32)

 Eyi ni ohun ti A n se ni adehun fun gbogbo oluronupiwada, oluso (ofin Allahu)

مَّنْ خَشِيَ الرَّحْمَٰنَ بِالْغَيْبِ وَجَاءَ بِقَلْبٍ مُّنِيبٍ(33)

 Enikeni ti o ba paya Allahu ni ikoko, ti o tun de pelu okan to seri pada si odo Allahu (nipa ironupiwada)

ادْخُلُوهَا بِسَلَامٍ ۖ ذَٰلِكَ يَوْمُ الْخُلُودِ(34)

 (A oo so fun won pe:) "E wo inu (Ogba Idera) pelu alaafia. Iyen ni ojo gbere

لَهُم مَّا يَشَاءُونَ فِيهَا وَلَدَيْنَا مَزِيدٌ(35)

 Ohun ti won n fe wa ninu re. Alekun si tun wa ni odo Wa

وَكَمْ أَهْلَكْنَا قَبْلَهُم مِّن قَرْنٍ هُمْ أَشَدُّ مِنْهُم بَطْشًا فَنَقَّبُوا فِي الْبِلَادِ هَلْ مِن مَّحِيصٍ(36)

 Meloo meloo ninu awon ijo ti A ti pare siwaju won. Won si ni agbara ju won lo. (Nigba ti iya de) won sa asala kiri ninu ilu. Nje ibusasi kan wa (fun won bi)

إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَذِكْرَىٰ لِمَن كَانَ لَهُ قَلْبٌ أَوْ أَلْقَى السَّمْعَ وَهُوَ شَهِيدٌ(37)

 Dajudaju iranti wa ninu iyen fun eni to ni okan tabi eni to fi eti sile, to wa nibe (pelu okan re)

وَلَقَدْ خَلَقْنَا السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ وَمَا مَسَّنَا مِن لُّغُوبٍ(38)

 Dajudaju A seda awon sanmo, ile ati nnkan to wa laaarin awon mejeeji fun ojo mefa. Ko si re Wa rara (ambosibosi pe A oo sinmi ni ojo keje)

فَاصْبِرْ عَلَىٰ مَا يَقُولُونَ وَسَبِّحْ بِحَمْدِ رَبِّكَ قَبْلَ طُلُوعِ الشَّمْسِ وَقَبْلَ الْغُرُوبِ(39)

 Nitori naa, se suuru lori ohun ti won n wi. Ki o si se afomo pelu idupe fun Oluwa Re siwaju yiyo oorun ati wiwo (re)

وَمِنَ اللَّيْلِ فَسَبِّحْهُ وَأَدْبَارَ السُّجُودِ(40)

 Ati pe ni oru ati ni eyin irun se afomo fun Un

وَاسْتَمِعْ يَوْمَ يُنَادِ الْمُنَادِ مِن مَّكَانٍ قَرِيبٍ(41)

 Ki o si teti si ojo ti olupepe yoo pepe lati aye kan t’o sunmo

يَوْمَ يَسْمَعُونَ الصَّيْحَةَ بِالْحَقِّ ۚ ذَٰلِكَ يَوْمُ الْخُرُوجِ(42)

 Ojo ti won yoo gbo igbe pelu ododo. Iyen ni ojo ijade eda (lati inu saree)

إِنَّا نَحْنُ نُحْيِي وَنُمِيتُ وَإِلَيْنَا الْمَصِيرُ(43)

 Dajudaju Awa, Awa l’A n so eda di alaaye. A si n so o di oku. Odo Wa si ni abo eda

يَوْمَ تَشَقَّقُ الْأَرْضُ عَنْهُمْ سِرَاعًا ۚ ذَٰلِكَ حَشْرٌ عَلَيْنَا يَسِيرٌ(44)

 (Ranti) ojo ti ile yoo faya perepere mo won lara, (ti won yoo maa) yara (jade lati inu ile). Iyen ni akojo t’o rorun fun Wa

نَّحْنُ أَعْلَمُ بِمَا يَقُولُونَ ۖ وَمَا أَنتَ عَلَيْهِم بِجَبَّارٍ ۖ فَذَكِّرْ بِالْقُرْآنِ مَن يَخَافُ وَعِيدِ(45)

 Awa nimo julo nipa ohun ti won n wi. Iwo ko si nii je won nipa (lati gbagbo). Nitori naa, fi al-Ƙur’an se iranti fun eni ti n paya ileri Mi


More surahs in Yoruba:


Al-Baqarah Al-'Imran An-Nisa'
Al-Ma'idah Yusuf Ibrahim
Al-Hijr Al-Kahf Maryam
Al-Hajj Al-Qasas Al-'Ankabut
As-Sajdah Ya Sin Ad-Dukhan
Al-Fath Al-Hujurat Qaf
An-Najm Ar-Rahman Al-Waqi'ah
Al-Hashr Al-Mulk Al-Haqqah
Al-Inshiqaq Al-A'la Al-Ghashiyah

Download surah Qaf with the voice of the most famous Quran reciters :

surah Qaf mp3 : choose the reciter to listen and download the chapter Qaf Complete with high quality
surah Qaf Ahmed El Agamy
Ahmed Al Ajmy
surah Qaf Bandar Balila
Bandar Balila
surah Qaf Khalid Al Jalil
Khalid Al Jalil
surah Qaf Saad Al Ghamdi
Saad Al Ghamdi
surah Qaf Saud Al Shuraim
Saud Al Shuraim
surah Qaf Abdul Basit Abdul Samad
Abdul Basit
surah Qaf Abdul Rashid Sufi
Abdul Rashid Sufi
surah Qaf Abdullah Basfar
Abdullah Basfar
surah Qaf Abdullah Awwad Al Juhani
Abdullah Al Juhani
surah Qaf Fares Abbad
Fares Abbad
surah Qaf Maher Al Muaiqly
Maher Al Muaiqly
surah Qaf Muhammad Siddiq Al Minshawi
Al Minshawi
surah Qaf Al Hosary
Al Hosary
surah Qaf Al-afasi
Mishari Al-afasi
surah Qaf Yasser Al Dosari
Yasser Al Dosari


Sunday, November 3, 2024

لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب