سورة سبأ باليوربا
Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile n je tiRe. Ati pe tiRe ni gbogbo ope ni orun. Oun si ni Ologbon, Alamotan |
O mo ohunkohun t’o n wonu ile ati ohunkohun t’o n jade latinu re. (O mo) ohunkohun t’o n sokale latinu sanmo ati ohunkohun t’o n gunke lo sinu re. Oun si ni Asake-orun, Alaforijin |
Awon alaigbagbo wi pe: “Akoko naa ko nii de ba wa.” So pe: “Bee ko. Emi fi Oluwa mi bura. Dajudaju o maa de ba yin (lati odo) Onimo-ikoko (Eni ti) odiwon omo ina-igun ko pamo fun ninu sanmo ati ninu ile. (Ko si nnkan ti o) kere si iyen tabi ti o tobi (ju u lo) afi ki o wa ninu akosile t’o yanju.” |
(O maa sele) nitori ki Allahu le san esan fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won tun se ise rere. Awon wonyen ni aforijin ati ese alapon-onle n be fun |
وَالَّذِينَ سَعَوْا فِي آيَاتِنَا مُعَاجِزِينَ أُولَٰئِكَ لَهُمْ عَذَابٌ مِّن رِّجْزٍ أَلِيمٌ(5) Ati pe awon t’o se ise buruku nipa awon ayah Wa, (ti won lero pe) awon mori bo ninu iya; awon wonyen ni iya eleta-elero t’o buru n be fun |
Awon ti A fun ni imo ri i pe eyi ti won sokale fun o lati odo Oluwa re, ohun ni ododo, ati pe o n se itosona si ona Alagbara, Eleyin |
Awon t’o sai gbagbo wi pe: “Se ki a toka yin si okunrin kan ti o maa fun yin ni iro pe nigba ti won ba fon yin ka tan patapata (sinu erupe), pe dajudaju e maa pada wa ni eda titun |
Se o da adapa iro mo Allahu ni tabi alujannu n be lara re ni?” Rara o! Awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo ti wa ninu iya ati isina t’o jinna |
Se won ko ri ohun t’o n be niwaju won ati ohun t’o n be leyin won ni sanmo ati ile? Ti A ba fe, Awa iba je ki ile ri mo won lese, tabi ki A ja apa kan sanmo lule le won lori mole. Dajudaju ami kan wa ninu iyen fun gbogbo erusin, oluronupiwada |
Dajudaju A ti fun (Anabi) Dawud ni oore ajulo lati odo Wa; Eyin apata, e se afomo pelu re. (A pe) awon eye naa (pe ki won se bee.) A si ro irin fun un |
(A so fun un) pe se awon ewu irin t’o maa bo ara, se oruka-orun fun ewu irin naa niwon-niwon. Ki e si se rere. Dajudaju Emi ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise |
Ati pe (A te) ategun lori ba fun (Anabi) Sulaemon, irin osu kan ni irin owuro re, irin osu kan si ni irin irole re . A si mu ki odo ide maa san ninu ile fun un. O si wa ninu awon alujannu, eyi t’o n sise (fun un) niwaju re pelu iyonda Oluwa re. Ati pe eni ti o ba gbunri kuro nibi ase Wa ninu won, A maa fun un ni iya ina t’o n jo fofo to wo |
Won n se ise ti o ba fe fun un nipa mimo awon ile t’o dara, awon ere, awo koto fife bi abata ati awon ikoko t’o ridii mule. Eyin eniyan (Anabi) Dawud, e sise idupe (fun Allahu). Die ninu awon erusin Mi si ni oludupe |
Nigba ti A pase pe ki iku pa (Anabi) Sulaemon, ko si ohun ti o mu awon alujannu mo pe o ti ku bi ko se kokoro inu ile kan ti o je opa re. Nigba ti o wo lule, o han kedere si awon alujannu pe ti o ba je pe awon ni imo ikoko ni, awon iba ti wa ninu (ise) iya t’o n yepere eda |
Dajudaju ami kan wa fun awon Saba’ ninu ibugbe won; (ohun ni) ogba oko meji t’o wa ni otun ati ni osi. “E je ninu arisiki Oluwa yin. Ki e si dupe fun Un.” Ilu t’o dara ni (ile Saba’. Allahu si ni) Oluwa Alaforijin |
Won gbunri (nibi esin). Nitori naa, A ran adagun odo ti won mo odi yika si won. A si paaro oko won mejeeji fun won pelu oko meji miiran ti o je oko eleso kikoro, oko igi elegun-un ati kini kan die ninu igi sidir |
ذَٰلِكَ جَزَيْنَاهُم بِمَا كَفَرُوا ۖ وَهَلْ نُجَازِي إِلَّا الْكَفُورَ(17) Iyen ni A fi san won ni esan nitori pe won sai moore. Nje A maa san eni kan lesan iya bi ko se alaimoore |
A si fi awon ilu kan t’o han si aarin ilu ti A ran adagun odo si ati awon ilu ti A fi ibukun si. A si seto ibuso niwon-niwon fun irin-ajo sise sinu awon ilu naa. E rin lo sinu won ni oru ati ni oju ojo pelu ifayabale |
(Awon ara ilu Saba’) wi pe: “Oluwa wa, mu awon irin-ajo wa lati ilu kan si ilu miiran jinna sira won.” Won se abosi si emi ara won. A si so won di itan. A si fon won ka patapata. Dajudaju awon ami kan wa ninu iyen fun gbogbo onisuuru, oludupe |
وَلَقَدْ صَدَّقَ عَلَيْهِمْ إِبْلِيسُ ظَنَّهُ فَاتَّبَعُوهُ إِلَّا فَرِيقًا مِّنَ الْمُؤْمِنِينَ(20) Dajudaju ’Iblis ti so aba re di ododo le won lori. Won si tele e afi igun kan ninu awon onigbagbo ododo |
(’Iblis) ko si ni agbara kan lori won bi ko se pe ki A le safi han eni t’o gba Ojo Ikeyin gbo kuro lara eni t’o wa ninu iyemeji nipa re. Oluso si ni Oluwa re lori gbogbo nnkan |
So pe: “E pe awon ti e so pe (won je oluwa) leyin Allahu.” Won ko ni ikapa odiwon omo-ina igun ninu sanmo tabi ninu ile. Won ko si ni ipin kan ninu mejeeji. Ati pe ko si oluranlowo kan fun Allahu laaarin won |
Isipe ko si nii sanfaani lodo Allahu afi fun eni ti O ba yonda fun. (Inufu-ayafu ni awon olusipe ati awon olusipe-fun maa wa) titi A oo fi yo ijaya kuro ninu okan won. Won si maa so (fun awon molaika) pe: “Ki ni Oluwa yin so (ni esi isipe)?” Won maa so pe: “Ododo l’O so (isipe yin ti wole. Allahu) Oun l’O ga, O tobi |
So pe: “Ta ni O n pese fun yin lati inu awon sanmo ati ile?” So pe: “Allahu ni.” Dajudaju awa tabi eyin wa ninu imona tabi ninu isina ponnbele |
قُل لَّا تُسْأَلُونَ عَمَّا أَجْرَمْنَا وَلَا نُسْأَلُ عَمَّا تَعْمَلُونَ(25) So pe: “Won ko nii bi yin leere nipa ese ti a da; won ko si nii bi awa naa nipa ohun ti e n se nise.” |
قُلْ يَجْمَعُ بَيْنَنَا رَبُّنَا ثُمَّ يَفْتَحُ بَيْنَنَا بِالْحَقِّ وَهُوَ الْفَتَّاحُ الْعَلِيمُ(26) So pe: “Oluwa wa yoo ko wa jo papo. Leyin naa, O maa fi ododo sedajo laaarin wa. Oun si ni Onidaajo, Onimo.” |
So pe: “E fi han mi na awon orisa ti e dapo mo Allahu.” Rara (ko ni akegbe). Rara se, Oun ni Alagbara, Ologbon |
A o ran o nise afi si gbogbo eniyan patapata; (o je) oniroo-idunnu ati olukilo sugbon opolopo awon eniyan ko mo |
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا الْوَعْدُ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ(29) Won si n wi pe: “Igba wo ni adehun yii yoo se ti e ba je olododo?” |
قُل لَّكُم مِّيعَادُ يَوْمٍ لَّا تَسْتَأْخِرُونَ عَنْهُ سَاعَةً وَلَا تَسْتَقْدِمُونَ(30) So pe: “Adehun ojo kan n be fun yin, ti eyin ko le sun siwaju di igba kan, e o si le fa a seyin.” |
Awon t’o sai gbagbo wi pe: “A o nii ni igbagbo ninu al-Ƙur’an yii ati eyi t’o wa siwaju re.” Ti o ba je pe o ba ri won ni nigba ti won ba da awon alabosi duro niwaju Oluwa won, (o maa ri won ti) apa kan won yoo da oro naa pada si apa kan; awon ti won so di ole (ninu won) yoo wi fun awon t’o segberaga (ninu won) pe: “Ti ki i ba se eyin ni, awa iba je onigbagbo ododo.” |
Awon t’o segberaga yo si wi fun awon ti won so di ole pe: “Se awa l’a se yin lori kuro ninu imona leyin ti o de ba yin? Rara o! Odaran ni yin ni.” |
Awon ti won so di ole yo si wi fun awon t’o segberaga pe: “Rara! Ete oru ati osan (lati odo yin loko ba wa) nigba ti e n pa wa ni ase pe ki a sai gbagbo ninu Allahu, ki a si so (awon kan) di egbe Re.” Won fi abamo won pamo nigba ti won ri iya. A si ko ewon si orun awon t’o sai gbagbo. Se A oo san won ni esan kan bi ko se ohun ti won n se nise |
Ati pe A o ran olukilo kan si ilu kan ayafi ki awon onigbedemuke ilu naa wi pe: “Dajudaju awa sai gbagbo ninu ohun ti Won fi ran yin nise.” |
وَقَالُوا نَحْنُ أَكْثَرُ أَمْوَالًا وَأَوْلَادًا وَمَا نَحْنُ بِمُعَذَّبِينَ(35) Won tun wi pe: “Awa ni dukia ati omo ju (yin lo); won ko si nii je wa niya.” |
So pe: “Dajudaju Oluwa mi, O n te arisiki sile fun eni ti O ba fe. O si n diwon re (fun elomiiran), sugbon opolopo awon eniyan ko mo |
Ki i se awon dukia yin, ki i si se awon omo yin ni nnkan ti o maa mu yin sunmo Wa pekipeki afi eni ti o ba gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere. Awon wonyen ni esan ilopo wa fun nipa ohun ti won se nise. Won yo si wa ninu awon ipo giga (ninu Ogba Idera) pelu ifayabale |
وَالَّذِينَ يَسْعَوْنَ فِي آيَاتِنَا مُعَاجِزِينَ أُولَٰئِكَ فِي الْعَذَابِ مُحْضَرُونَ(38) Awon t’o n se ise aburu nipa awon ayah Wa, (ti won lero pe) awon mori bo ninu iya; awon wonyen ni won maa mu wa sinu Ina.” |
So pe: “Dajudaju Oluwa mi, O n te arisiki sile fun eni ti O ba fe. O si n diwon re fun elomiiran. Ati pe ohunkohun ti e ba na, Oun l’O maa fi (omiran) ropo re. O si l’oore julo ninu awon olupese.” |
Ni ojo ti Allahu yoo ko gbogbo won jo patapata, leyin naa O maa so fun awon molaika pe: “Se eyin ni won n josin fun?” |
Won a so pe: “Mimo fun O! Iwo ni Alaabo wa, ki i se awon. Rara (won ko josin fun wa). Awon alujannu ni won n josin fun; opolopo won ni won gba alujannu gbo |
Nitori naa, ni oni apa kan yin ko ni ikapa anfaani, ko si ni ikapa inira fun apa kan. A si maa so fun awon t’o sabosi pe: “E to iya Ina ti e n pe niro wo.” |
Ati pe nigba ti won ba n ke awon ayah Wa t’o yanju fun won, won a wi pe: “Ki ni eyi bi ko se okunrin kan ti o fe se yin lori kuro nibi nnkan ti awon baba yin n josin fun.” Won tun wi pe: “Ki ni eyi bi ko se adapa iro.” Ati pe awon t’o sai gbagbo wi nipa ododo nigba ti o de ba won pe: “Ki ni eyi bi ko se idan ponnbele.” |
وَمَا آتَيْنَاهُم مِّن كُتُبٍ يَدْرُسُونَهَا ۖ وَمَا أَرْسَلْنَا إِلَيْهِمْ قَبْلَكَ مِن نَّذِيرٍ(44) A o fun won ni awon tira kan kan ti won n ko eko ninu re, A o si ran olukilo kan kan si won siwaju re |
Awon t’o siwaju won naa pe ododo niro. (Owo awon wonyi) ko si ti i te ida kan ida mewaa ninu ohun ti A fun (awon t’o siwaju). Sibesibe won pe awon Ojise Mi ni opuro. Bawo si ni bi Mo se (fi iya) ko (aburu fun won) ti ri |
So pe: “Ohun kan soso ni mo n se waasi re fun yin pe, e duro nitori ti Allahu ni meji ati ni eyo kookan. Leyin naa, ki e ronu jinle. Ko si alujannu kan lara eni yin. Ko si je kini kan bi ko se olukilo fun yin siwaju iya lile kan.” |
So pe: “Emi ko bi yin leere owo-oya kan, eyin le kuku lowo yin. Ko si owo oya mi (lodo eni kan) afi lodo Allahu. Oun si ni Arinu-rode gbogbo nnkan.” |
قُلْ إِنَّ رَبِّي يَقْذِفُ بِالْحَقِّ عَلَّامُ الْغُيُوبِ(48) So pe: “Dajudaju Oluwa mi, Onimo-ikoko l’O n mu ododo wa.” |
قُلْ جَاءَ الْحَقُّ وَمَا يُبْدِئُ الْبَاطِلُ وَمَا يُعِيدُ(49) So pe: “Ododo ti de. Iro (esu) ko le mu nnkan be, ko si le da nnkan pada (leyin to ti ku).” |
So pe: “Ti mo ba sina, mo sina fun emi ara mi ni. Ti mo ba si mona, nipa ohun ti Oluwa mi fi ranse si mi ni imisi ni. Dajudaju Oun ni Olugbo, Alasun-unmo eda.” |
وَلَوْ تَرَىٰ إِذْ فَزِعُوا فَلَا فَوْتَ وَأُخِذُوا مِن مَّكَانٍ قَرِيبٍ(51) Ti o ba je pe o le ri (esin won ni) nigba ti eru ba de ba won (ni Ojo Ajinde, o maa ri i pe), ko nii si imoribo kan (fun won). A si maa gba won mu lati aye t’o sunmo |
وَقَالُوا آمَنَّا بِهِ وَأَنَّىٰ لَهُمُ التَّنَاوُشُ مِن مَّكَانٍ بَعِيدٍ(52) Won yoo wi pe: “A gbagbo ninu (al-Ƙur’an bayii).” Bawo ni owo won se le te igbagbo ododo lati aye t’o jinna (iyen, orun).” |
وَقَدْ كَفَرُوا بِهِ مِن قَبْلُ ۖ وَيَقْذِفُونَ بِالْغَيْبِ مِن مَّكَانٍ بَعِيدٍ(53) Won kuku ti sai gbagbo ninu re siwaju (nile aye). Won si n soro nipa ikoko lati aye t’o jinna (iyen, ile aye) |
A si fi gaga si aarin awon ati ohun ti won n soju kokoro re gege bi A ti se fun awon egbe won ni isaaju. Dajudaju won wa ninu iyemeji t’o gbopon (nipa Ojo Ajinde) |
المزيد من السور باللغة اليوربا:
تحميل سورة سبأ بصوت أشهر القراء :
قم باختيار القارئ للاستماع و تحميل سورة سبأ كاملة بجودة عالية
أحمد العجمي
خالد الجليل
سعد الغامدي
سعود الشريم
عبد الباسط
عبد الله الجهني
علي الحذيفي
فارس عباد
ماهر المعيقلي
محمد جبريل
المنشاوي
الحصري
مشاري العفاسي
ناصر القطامي
ياسر الدوسري
Sunday, December 22, 2024
لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب