La sourate Al-Qiyamah en Yoruba
Emi (Allahu) n bura pelu Ojo Ajinde |
Mo tun n bura pelu emi t’o maa dara re lebi |
Se eniyan lero pe A o nii ko awon eegun re jo ni |
Rara o. A lagbara lati to eegun omonika re dogba |
Sugbon eniyan gbero lati pe (Ojo Ajinde) t’o n be niwaju re niro |
O n beere pe: "Igba wo ni Ojo Ajinde |
Nigba ti oju ba ko mona |
ati (nigba) ti osupa ba wookun |
ati (nigba) ti A ba pa oorun ati osupa po mora won |
eniyan yoo wi ni ojo yen pe: "Nibo ni ibusasi wa |
Rara, ko si ibusasi |
Odo Oluwa re ni ibuduro ni ojo yen |
يُنَبَّأُ الْإِنسَانُ يَوْمَئِذٍ بِمَا قَدَّمَ وَأَخَّرَ(13) Won maa fun eniyan ni iro ni ojo yen nipa ohun t’o ti siwaju (ninu ise re) ati ohun t’o fi keyin (ninu oripa ise re) |
Sebi eniyan da ara re mo |
ibaa mu awon awawi re wa |
Ma se gbe ahon re si imisi lati kanju ke e |
Dajudaju Awa l’A maa se ikojo re (sinu okan re) ati kike re |
Nigba ti A ba n ke e (fun o), ki o si maa tele kike re |
Leyin naa, dajudaju Awa l’A maa se alaye re fun o |
E gbo! Nse l’e nifee aye |
E si n pa orun ti |
Awon oju kan ni ojo yen yoo tutu (fun idunnu) |
Oluwa won ni won yoo maa wo |
Awon oju kan ni ojo yen si maa baje |
(Oju naa) yoo mo daju pe Won maa fi aburu kan ohun |
E gbo! Nigba ti emi ba de gogongo |
A si maa so pe: "Nje olofo pipe kan wa bi (ti o maa gba a sile lowo iku) |
O si maa da a loju pe dajudaju ipinya aye ti de |
Ojugun yo si lomo ojugun |
Odo Oluwa re si ni wiwa eda lo ni ojo yen |
Ko kuku gba ododo gbo, ko si kirun |
Sugbon o pe ododo niro. O si keyin si i |
Leyin naa, o lo si odo awon eniyan re, o si n se faari |
Egbe ni fun o, egbe ni se |
Leyin naa, egbe ni fun o, egbe si se |
Se eniyan lero pe A maa fi oun sile lasan ni |
Se ko ti je ato moni ti won da jade sinu apoluke ni |
Leyin naa, o di eje didi. (Allahu) si seda (re). O si se e t’o dogba jale leeyan |
(Allahu) si se iran meji jade lati inu re, ako ati abo |
أَلَيْسَ ذَٰلِكَ بِقَادِرٍ عَلَىٰ أَن يُحْيِيَ الْمَوْتَىٰ(40) Nje Eni ti O se iyen ko nii ni agbara lati ji awon oku dide bi |
Plus de sourates en Yoruba :
Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :
Téléchargez le fichier mp3 de la sourate Al-Qiyamah : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate Al-Qiyamah complète en haute qualité.
Ahmed Al Ajmy Bandar Balila Khalid Al Jalil Saad Al Ghamdi Saud Al Shuraim Abdul Basit Abdul Rashid Sufi Abdullah Basfar Abdullah Al Juhani Fares Abbad Maher Al Muaiqly Al Minshawi Al Hosary Mishari Al-afasi Yasser Al Dosari
Donnez-nous une invitation valide