سورة الأحقاف باليوربا
حم(1) Ha mim |
Tira naa sokale lati odo Allahu, Alagbara, Ologbon |
A o seda awon sanmo ati ile, ati ohunkohun t’o wa laaarin mejeeji bi ko se pelu ododo ati fun gbedeke akoko kan. Awon t’o sai gbagbo yo si maa gbunri kuro nibi ohun ti A fi sekilo fun won |
So pe: "E so fun mi nipa nnkan ti e n pe leyin Allahu; e fi won han mi na, ki ni won seda ninu (ohun t’o wa lori) ile. Tabi won ni ipin kan (pelu Allahu) ninu (iseda) awon sanmo? E mu Tira kan wa fun mi t’o siwaju (al-Ƙur’an) yii tabi oripa kan ninu imo ti e ba je olododo |
Ta l’o si sina ju eni ti o n pe leyin Allahu, eni ti ko le je ipe re titi di Ojo Ajinde! Ati pe won ko ni oye si pipe ti won n pe won |
وَإِذَا حُشِرَ النَّاسُ كَانُوا لَهُمْ أَعْدَاءً وَكَانُوا بِعِبَادَتِهِمْ كَافِرِينَ(6) Nigba ti A ba si ko awon eniyan jo (fun Ajinde), awon orisa yoo di ota fun awon aborisa. Won si maa tako ijosin ti won se fun won |
Nigba ti won ba n ke awon ayah Wa t’o yanju fun won, awon t’o sai gbagbo yo si maa so isokuso si ododo nigba ti o de ba won pe: "Eyi ni idan ponnbele |
Tabi won n wi pe: "O da (al-Ƙur’an) hun funra re ni." So pe: "Ti mo ba hun un funra mi, e o ni ikapa kini kan fun mi ni odo Allahu (nibi iya Re). Oun ni Onimo-julo nipa isokuso ti e n so nipa re. O (si) to ni Elerii laaarin emi ati eyin. Oun ni Alaforijin, Asake-orun |
So pe: "Emi ki i se akoko ninu awon Ojise. Emi ko si mo nnkan ti won maa se fun emi ati eyin. Emi ko tele kini kan ayafi ohun ti Won fi ranse si mi ni imisi. Emi ko si je kini kan bi ko se olukilo ponnbele." won wa labe ijoba awon osebo ninu ilu Mokkah alapon-onle. Won si bere si nii yowo kowo si awon omoleyin Anabi (sollalahu alayhi wa sallam). Lasiko naa ipo ole ni awon musulumi wa ninu ilu naa. Ko si ohun t’o wa le fi won lokan bale sinu ’Islam tayo ki Anabi (sollalahu alayhi wa sallam) je ki o di mimo fun eni kookan awon omoleyin re pe ijiya ati pipa han awon musulumi ni eemo ifoju-egbo-rin. Mo daju pe ko si Anabi kan ninu awon Anabi Olohun (ahm.s.w.) ti ko mo pe ti o ba je pe itumo ti awon kristieni fun ayah naa l’o ba je ododo “emi ko si mo nnkan ti Allahu maa se fun emi ati eyin” ni iba je agbekale re. Bakan naa ise ti Anabi (sollalahu alayhi wa sallam) je faye ko yato si ti awon t’o siwaju re ninu awon Ojise Allahu (ahm.s.w). Bakan naa ayah naa n pe wa sibi iduro sinsin ati atemora lasiko inira awon alaigbagbo |
So pe: " E so fun mi, ti o ba je pe lati odo Allahu ni (al-Ƙur’an) ti wa, ti e si sai gbagbo ninu re, ti elerii kan ninu awon omo ’Isro’il si jerii lori iru re, ti o si gba a gbo, (amo) ti eyin segberaga si i, (se e o ti sabosi bayen bi?). Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi |
Awon t’o sai gbagbo wi fun awon t’o gbagbo pe: "Ti o ba je pe al-Ƙur’an je oore ni, won ko nii siwaju wa debe." Nigba ti awon osebo ko ti tele imona re, ni won n wi pe: "Iro ijoun ni eyi |
Tira (Anabi) Musa si ti wa siwaju re, ti o je tira ti won n tele, o si je ike (fun won. Al-Ƙur’an) yii tun ni Tira kan t’o n jerii si ododo ni ede Larubawa nitori ki o le sekilo fun awon t’o sabosi, (o si je) iro idunnu fun awon oluse-rere |
Dajudaju awon t’o so pe: "Allahu ni Oluwa wa", leyin naa, ti won duro sinsin, ko nii si ipaya fun won. Won ko si nii banuje |
أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَنَّةِ خَالِدِينَ فِيهَا جَزَاءً بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ(14) Awon wonyen ni ero inu Ogba Idera. Olusegbere ni won ninu re. (O je) esan nitori ohun ti won n se nise |
A pa a ni ase fun eniyan pe ki o maa se daadaa si awon obi re mejeeji. Iya re ni oyun re pelu wahala. O si bi i pelu wahala. Oyun re ati gbigba omu lenu re je ogbon osu. (O si n to o) titi o fi dagba, ti o fi di omo ogoji odun, o si so pe: "Oluwa mi, fi mo mi ki ng maa dupe idera Re, eyi ti O fi se idera fun mi ati fun awon obi mi mejeeji, ki ng si maa se ise rere, eyi ti O yonu si. Ki O si se rere fun mi lori awon aromodomo mi. Dajudaju emi ti ronu piwada si odo Re. Dajudaju emi si wa ninu awon musulumi |
Awon wonyen ni awon ti A maa gba ise rere ti won se nise, A si maa se amojukuro nibi awon aburu ise won; won maa wa ninu awon ero inu Ogba Idera. (O je) adehun ododo ti A n se ni adehun fun won |
Eni ti o so fun awon obi re mejeeji pe: "Sio eyin mejeeji! Se eyin yoo maa seleri fun mi pe Won yoo mu mi jade (laaye lati inu saree), sebi awon iran kan ti re koja lo siwaju mi (ti Won ko ti i mu won jade lati inu saree won)." Awon (obi re) mejeeji si n toro igbala ni odo Allahu (fun omo yii. Won si so pe): "Egbe ni fun o! (O je) gbagbo ni ododo. Dajudaju adehun Allahu ni ododo." (Omo naa si) wi pe: "Eyi ko je kini kan bi ko se akosile alo awon eni akoko |
Awon (alaigbagbo) wonyen ni awon ti oro naa ti ko le lori ninu awon ijo kan ti o ti re koja siwaju won ninu awon alujannu ati eniyan. Dajudaju won je eni ofo |
وَلِكُلٍّ دَرَجَاتٌ مِّمَّا عَمِلُوا ۖ وَلِيُوَفِّيَهُمْ أَعْمَالَهُمْ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ(19) Awon ipo yoo wa fun eni kookan nipa ise ti won se nise. Ati pe (eyi ri bee) nitori ki (Allahu) le san won ni esan ise won. Awa ko si nii sabosi si won |
Ni ojo ti won maa dari awon t’o sai gbagbo ko Ina, (won maa so fun won pe:) "E ti lo igbadun yin tan ninu isemi aye? E si ti je igbadun aye? Nitori naa, ni oni, won maa san yin ni esan abuku iya nitori pe e n segberaga ni ori ile lai letoo ati nitori pe e n sebaje |
Seranti arakunrin (ijo) ‘Ad. Nigba ti o sekilo fun awon eniyan re t’o n gbe ninu yanrin ti ategun kojo bi oke. Awon olukilo si ti re koja siwaju re ati leyin re. (O si so pe:) "Eyin ko gbodo josin fun kini kan ayafi Allahu. Dajudaju emi n paya iya ojo nla kan fun yin |
Won wi pe: "Se iwo wa ba wa lati se wa lori kuro nibi awon orisa wa ni? Mu ohun ti o n se ileri re fun wa wa ti iwo ba wa ninu awon olododo |
O so pe: "Imo (nipa re) wa ni odo Allahu nikan soso. Emi yo si je ise ti Won fi ran mi de opin fun yin, sugbon emi n ri eyin ni ijo alaimokan |
Nigba ti won ri iya naa ni esujo regede, t’o n wo bo wa sinu awon koto ilu won, won wi pe: "Eyi ni esujo regede, ti o maa rojo fun wa." Ko si ri bee, ohun ti e n wa pelu ikanju ni. Ategun ti iya eleta-elero wa ninu re ni |
O n pa gbogbo nnkan re pelu ase Oluwa re. Nigba naa, won di eni ti won ko ri mo afi awon ibugbe won. Bayen ni A se n san ijo elese ni esan |
A kuku fun won ni ipo ti A o fun eyin. A si fun won ni igboro, awon iriran ati awon okan. Amo igboro won ati awon iriran won pelu awon okan won ko ro won loro kan kan nibi iya nitori pe won n se atako si awon ayah Allahu. Ati pe ohun ti won n fi se yeye si diya t’o yi won po |
وَلَقَدْ أَهْلَكْنَا مَا حَوْلَكُم مِّنَ الْقُرَىٰ وَصَرَّفْنَا الْآيَاتِ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ(27) Awa kuku ti pa re ninu awon ilu ti o wa ni ayika yin. Awa si ti salaye awon ayah naa ni orisirisi ona nitori ki won le seri pada (sibi ododo) |
Awon olohun ti won so di ohun ti o maa mu won sunmo (igbala) leyin Allahu ko se ran won lowo mo? Rara (ko le si aranse fun won)! Won ti dofo mo won lowo. Iyen si ni (olohun) iro won ati ohun ti won n da ni adapa iro |
(Ranti) nigba ti A dari ijo kan ninu awon alujannu si o, ti won n teti gbo al-Ƙur’an. Nigba ti won de sibe, won so pe: "E dake (fun al-Ƙur’an)." Nigba ti won si pari (kike re tan), won pada si odo ijo won, ti won n sekilo (fun won) |
Won so pe: "Eyin ijo wa, dajudaju awa gbo (nipa) Tira kan ti won sokale leyin (Anabi) Musa, ti o n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o wa siwaju re, ti o si n toni si ona ododo ati ona taara |
Eyin ijo wa, e je ipe olupepe Allahu. Ki e si gba a gbo ni ododo. (Allahu) yo si fori awon ese yin jin yin. O si maa yo yin kuro ninu iya eleta-elero |
Enikeni ti ko ba si jepe olupepe Allahu, ko le mori bo mo (Allahu) lowo lori ile. Ko si si alaabo kan fun un leyin Allahu. Awon wonyen si wa ninu isina ponnbele |
Se won ko ri i pe dajudaju Allahu, Eni ti O da awon sanmo ati ile, ti ko si kaaare nipa iseda won, (se ko) ni agbara lati so awon oku di alaaye ni? Rara, (O lagbara lati se bee). Dajudaju O n je Alagbara lori gbogbo nnkan |
(Ranti) ojo ti won maa dari awon t’o sai gbagbo lo sori Ina, (won si maa so fun won pe:) "Se eyi ki i se ododo bi?" Won yoo wi pe: "Rara, (ododo ni) Oluwa wa." (Allahu maa) so pe: "Nitori naa, e to iya wo nitori pe eyin je alaigbagbo |
Nitori naa, se suuru gege bi awon onipinnu okan ninu awon Ojise ti se suuru. Ma se ba won wa iya pelu ikanju. Ni ojo ti won ba ri ohun ti A n se ni adehun fun won, won yoo da bi eni pe won ko gbe ile aye (yii) tayo akoko kan ninu osan. Al-Ƙur’an yii si ni ijise dopin. Ta ni o si maa parun bi ko se ijo obileje |
المزيد من السور باللغة اليوربا:
تحميل سورة الأحقاف بصوت أشهر القراء :
قم باختيار القارئ للاستماع و تحميل سورة الأحقاف كاملة بجودة عالية
أحمد العجمي
خالد الجليل
سعد الغامدي
سعود الشريم
عبد الباسط
عبد الله الجهني
علي الحذيفي
فارس عباد
ماهر المعيقلي
محمد جبريل
المنشاوي
الحصري
مشاري العفاسي
ناصر القطامي
ياسر الدوسري
Sunday, December 22, 2024
لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب