La sourate At-Takwir en Yoruba
Nigba ti Won ba ka oorun korobojo danu |
ati nigba ti awon irawo ba ja bo kaakiri |
ati nigba ti Won ba mu awon apata rin (kuro ni aye won, ti won ku won danu) |
ati nigba ti won ba pa awon rakunmi aboyun ti |
ati nigba ti Won ba ko awon eranko jo |
ati nigba ti Won ba mu awon agbami odo gbina |
ati nigba ti Won ba so awon emi po mora won, (eni rere pelu eni rere, eni ibi pelu eni ibi) |
ati nigba ti omobinrin ti won bo mole laaye ba beere pe |
ese wo ni won pa oun fun |
ati nigba ti Won ba si awon takada (ise eda) sile |
ati nigba ti Won ba ka sanmo kuro loke |
ati nigba ti won ba mu ina Jehim jo fofo |
ati nigba ti Won ba sun Ogba Idera mo (awon onigbagbo ododo) |
(nigba naa ni) emi (kookan) yoo mo ohun ti o mu wa (ninu ise ire ati ise ibi) |
Nitori naa, Emi (Allahu) n bura pelu awon irawo t’o n yo ni ale, t’o n wookun ni osan |
(iyen) awon irawo t’o n rin lo rin bo, t’o n wookun si ibuwo won |
Mo tun bura pelu ale nigba ti o ba lo |
Mo tun bura pelu owuro nigba ti o ba mole |
Dajudaju (al-Ƙur’an) ni oro (ti A fi ran Jibril) Ojise, alapon-onle |
alagbara, eni pataki ni odo Eni t’O ni Ite-ola |
eni ti won n tele ase re nibe yen (ninu sanmo), olufokantan |
Ati pe eni yin (Anabi Muhammad s.a.w.) ki i se were |
O kuku ri i ninu ofurufu kedere |
Ati pe ki i se ahun (tabi eni-afurasi) lori iro ikoko (ti A fi ranse si i) |
Al-Ƙur’an ki i si se oro (ti A fi ran) Esu, eni eko |
Nitori naa, ibo l’e n lo |
Ki si ni al-Ƙur’an bi ko se iranti fun gbogbo eda |
(O wa) fun eni ti o ba fe ninu yin lati duro deede |
وَمَا تَشَاءُونَ إِلَّا أَن يَشَاءَ اللَّهُ رَبُّ الْعَالَمِينَ(29) Eyin ko si nii fe (lati duro deede) ayafi ti Allahu ba fe, Oluwa gbogbo eda |
Plus de sourates en Yoruba :
Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :
Téléchargez le fichier mp3 de la sourate At-Takwir : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate At-Takwir complète en haute qualité.















Donnez-nous une invitation valide