La sourate Al-Mutaffifin en Yoruba
Egbe ni fun awon oludin-osuwon-ku |
awon (ontaja) t’o je pe nigba ti won ba won nnkan lodo awon eniyan, won a gba a ni ekun |
nigba ti awon (ontaja naa) ba si lo iwon fun awon (onraja) tabi lo osuwon fun won, won yoo din in ku |
Se awon wonyen ko mo daju pe dajudaju A maa gbe won dide |
ni Ojo nla kan |
Ni ojo ti awon eniyan yoo dide naro fun Oluwa gbogbo eda |
Bee ni, dajudaju iwe ise awon eni ibi kuku wa ninu Sijjin |
Ki si l’o mu o mo ohun t’o n je Sijjin |
Iwe ti won ti ko ise aburu eda sinu re (ti won si fi pamo sinu ile keje ni Sijjin) |
Ni ojo yen, egbe ni fun awon olupe-ododo- niro |
awon t’o n pe Ojo esan niro |
Ko si si eni t’o n pe e niro afi gbogbo alakoyo, elese |
إِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِ آيَاتُنَا قَالَ أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ(13) Nigba ti won ba n ke awon ayah Wa fun un, o maa wi pe: "Awon akosile alo awon eni akoko (niwonyi) |
كَلَّا ۖ بَلْ ۜ رَانَ عَلَىٰ قُلُوبِهِم مَّا كَانُوا يَكْسِبُونَ(14) Rara ko ri bee, amo ohun ti won n se nise ibi l’o joba lori okan won |
كَلَّا إِنَّهُمْ عَن رَّبِّهِمْ يَوْمَئِذٍ لَّمَحْجُوبُونَ(15) Ni ti ododo, dajudaju won yoo wa ninu gaga, won ko si nii ri Oluwa won ni ojo yen |
Leyin naa, dajudaju won yoo wo inu ina Jehim |
Leyin naa, won maa so (fun won) pe: "Eyi ni ohun ti e n pe niro |
Bee ni. Dajudaju iwe ise awon eni rere wa ninu ‘illiyyun |
Ki si l’o mu o mo ohun t’o n je ‘illiyyun |
Iwe ti won ti ko ise rere eda sinu re (ti won si fi pamo si oke sanmo ni ‘illiyyun) |
Awon (molaika) ti won sunmo Allahu n jerii si i |
Dajudaju awon eni rere maa wa ninu igbadun |
Won yoo maa woran lori awon ibusun |
Iwo yoo da itutu oju igbadun mo ninu oju won |
Won yoo maa fun won mu ninu oti onideeri |
خِتَامُهُ مِسْكٌ ۚ وَفِي ذَٰلِكَ فَلْيَتَنَافَسِ الْمُتَنَافِسُونَ(26) Alumisiki ni (oorun) ipari re. Ki awon alapaantete sapantete ninu iyen |
Tesnim ni won yoo maa popo (mo oti naa) |
(Tesnim ni) omi iseleru kan, ti awon olusunmo (Allahu) yoo maa mu |
إِنَّ الَّذِينَ أَجْرَمُوا كَانُوا مِنَ الَّذِينَ آمَنُوا يَضْحَكُونَ(29) Dajudaju awon t’o dese, won maa n fi awon t’o gbagbo ni ododo rerin-in |
Nigba ti won ba gba egbe won koja, (awon adese) yoo maa seju sira won ni ti yeye |
وَإِذَا انقَلَبُوا إِلَىٰ أَهْلِهِمُ انقَلَبُوا فَكِهِينَ(31) Nigba ti won ba si pada si odo awon eniyan won, won a pada ti won yoo maa se faari |
Ati pe nigba ti won ba ri (awon onigbagbo ododo) won a wi pe: "Dajudaju awon wonyi ni olusina |
Awa ko si ran won nise oluso si won |
فَالْيَوْمَ الَّذِينَ آمَنُوا مِنَ الْكُفَّارِ يَضْحَكُونَ(34) Nitori naa, ni oni awon t’o gbagbo ni ododo yoo fi awon alaigbagbo rerin-in |
Won yoo maa woran lori awon ibusun |
Sebi won ti fi ohun ti awon alaigbagbo n se nise san won lesan (bayii) |
Plus de sourates en Yoruba :
Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :
Téléchargez le fichier mp3 de la sourate Al-Mutaffifin : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate Al-Mutaffifin complète en haute qualité.















Donnez-nous une invitation valide