Surah Ar-Rad with Yoruba
’Alif lam mim ro. Iwonyi ni awon ayah Tira naa. Ati pe ododo ni ohun ti won sokale fun o lati odo Oluwa re, sugbon opolopo awon eniyan ko gbagbo |
Allahu ni Eni ti O gbe awon sanmo ga soke lai si awon opo kan (fun un) ti e le foju ri. Leyin naa, O gunwa sori Ite-ola. O ro oorun ati osupa; ikookan won n rin fun gbedeke akoko kan. O n se eto oro (eda). O n se alaye awon ayah nitori ki e le mo amodaju nipa ipade Oluwa yin |
Oun ni Eni ti O te ile perese. O si fi awon apata t’o duro gbagidi sinu ile ati awon odo. Ati pe ninu gbogbo awon eso, O se e ni orisi meji-meji. O n fi oru bo osan loju. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni arojinle |
O tun wa ninu ile awon abala-abala ile (oniran-anran) t’o wa nitosi ara won ati awon ogba oko ajara, irugbin ati igi dabinu t’o peka ati eyi ti ko peka, ti won n fi omi eyo kan won. (Sibesibe) A se ajulo fun apa kan re lori apa kan nibi jije. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni laakaye |
Ti o ba seemo, eemo ma ni oro (enu) won (nipa bi won se so pe): “Se nigba ti a ba ti di erupe tan, se nigba naa ni awa yoo tun di eda titun?” Awon wonyen ni awon t’o sai gbagbo ninu Oluwa won. Awon wonyen ni ewon n be lorun won. Awon wonyen si ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re |
Won tun n kan o loju pe ki aburu sele siwaju rere. Awon apeere iya kuku ti sele siwaju won. Ati pe dajudaju Oluwa re ni Alaforijin fun awon eniyan lori abosi (owo) won. Dajudaju Oluwa re le nibi iya |
Awon t’o sai gbagbo n wi pe: “Ki ni ko je ki Won so ami kan kale fun un lati odo Oluwa re?” Olukilo ma ni iwo. Olutosona si wa fun ijo kookan |
Allahu mo ohun ti obinrin kookan ni loyun ati ohun ti ile omo yoo fi din ku (ninu ojo ibimo) ati ohun ti o maa fi lekun. Nnkan kookan l’o si ni odiwon lodo Re |
(Allahu ni) Onimo-ikoko-ati- gbangba. O tobi, O ga |
Bakan naa ni (lodo Allahu), eni ti o fi oro pamo sinu ninu yin ati eni ti o so o sita pelu eni ti o fi oru boju ati eni ti o n rin kiri ni osan |
O n be fun eniyan (kookan) awon molaika ti n gbase funra won; won wa niwaju (eniyan) ati leyin re; won n so (ise owo) re pelu ase Allahu. Dajudaju Allahu ko nii se iyipada nnkan t’o n be lodo ijo kan titi won yoo fi yi nnkan t’o n be ninu emi won pada. Nigba ti Allahu ba gbero aburu kan ro ijo kan, ko si eni t’o le da a pada. Ko si si alaabo kan fun won leyin Re |
هُوَ الَّذِي يُرِيكُمُ الْبَرْقَ خَوْفًا وَطَمَعًا وَيُنشِئُ السَّحَابَ الثِّقَالَ(12) Oun ni Eni t’o n fi monamona han yin ni iberu ati ni ireti (fun yin). O si n seda esujo t’o su dede |
Ara n se afomo ati idupe fun Un, awon molaika n se bee fun iberu Re. O n ran ina ara nise. O si n fi kolu eni ti O ba fe. Sibe won n jiyan nipa Allahu. O si le nibi gbigba-eda-mu |
TiRe ni ipe ododo. Awon ti won n pe leyin Re, won ko le fi kini kan je pe won afi bi eni ti o tewo re mejeeji (lasan) si omi nitori ki omi le de enu re. Omi ko si le de enu re. Adua awon alaigbagbo ko si je kini kan bi ko se sinu isina |
Allahu ni awon t’o wa ninu awon sanmo ati ile n fori kanle fun, won fe, won ko, - ooji won (naa n se bee) - ni owuro ati ni asale |
So pe: “Ta ni Oluwa awon sanmo ati ile?” So pe: “Allahu ni.” So pe: “Se leyin Re ni e tun mu awon alafeyinti kan, ti won ko ni ikapa oore ati inira fun emi ara won?” So pe: “Se afoju ati oluriran dogba bi? Tabi awon okunkun ati imole dogba? Tabi won yoo fun Allahu ni awon akegbe kan ti awon naa da eda bii ti eda Re, (to bee ge) ti eda fi jora won loju won?” So pe: “Allahu ni Eledaa gbogbo nnkan. Oun si ni Okan soso, Olubori |
O n so omi kale lati sanmo. Awon oju-odo si n san pelu odiwon re. Agbara si n gbe ifofo ori-omi lo. Bakan naa, ninu nnkan ti won n yo ninu ina lati fi se nnkan-oso tabi nnkan-elo, ohun naa ni ifofo bi iru re. Bayen ni Allahu se n mu apejuwe ododo ati iro wa. Ni ti ifofo, o maa ba panti lo. Ni ti eyi ti o si maa se eniyan ni anfaani, o maa duro si ori ile. Bayen ni Allahu se n mu apejuwe wa |
Ohun rere wa fun awon t’o jepe Oluwa won. Awon ti ko si jepe Re, ti o ba je pe tiwon ni gbogbo nnkan t’o n be lori ile patapata ati iru re pelu re, won iba fi serapada (fun emi ara won nibi Ina). Awon wonyen ni aburu isiro-ise wa fun. Ina Jahanamo ni ibugbe won; ibugbe naa si buru |
Nje eni ti o mo pe ododo kuku ni nnkan ti won sokale fun o lati odo Oluwa re da bi eni ti o foju (nipa re)? Awon onilaakaye l’o n lo iranti |
الَّذِينَ يُوفُونَ بِعَهْدِ اللَّهِ وَلَا يَنقُضُونَ الْمِيثَاقَ(20) (Awon ni) awon t’o n mu adehun Allahu se. Ati pe won ki i tu adehun |
(Awon ni) awon t’o n da ohun ti Allahu pa lase pe ki won dapo po. Won n paya Oluwa won. Won si n paya aburu isiro-ise |
(Awon ni) awon t’o se suuru lati fi wa Oju rere Oluwa won. Won n kirun. Won n na ninu ohun ti A pese fun won ni ikoko ati ni gbangba. Won si n fi rere ti aburu lo. Awon wonyen ni atubotan Ile rere n be fun |
Inu awon Ogba Idera gbere ni won yoo wo, (awon) ati eni t’o ba se rere ninu awon baba won, awon iyawo won ati awon aromodomo won. Awon molaika yo si maa wole to won lati enu ona kookan |
سَلَامٌ عَلَيْكُم بِمَا صَبَرْتُمْ ۚ فَنِعْمَ عُقْبَى الدَّارِ(24) (Won yoo so pe): “Alaafia fun yin nitori ifarada yin.” Atubotan Ile naa si dara |
Awon t’o n tu adehun Allahu leyin ti won ti gba adehun Re, ti won n ja ohun ti Allahu pa lase pe ki won dapo, ti won si n se ibaje lori ile; awon wonyen ni egun wa fun. Ati pe Ile (Ina) buruku wa fun won |
Allahu n te arisiki sile regede fun eni ti O ba fe. O si n diwon re (fun eni ti O ba fe). Won si dunnu si isemi ile aye! Ki si ni isemi aye ni egbe ti orun bi ko se igbadun bin-intin |
Awon t’o sai gbagbo n wi pe: “Ki ni ko je ki Won so ami kan kale fun un lati odo Oluwa re?” So pe: “Dajudaju Allahu n si eni ti O ba fe lona. O si n fi ona mo eni ti o ba seri sodo Re.” |
Awon t’o gbagbo ni ododo, ti okan won si bale pelu iranti Allahu; e gbo, pelu iranti Allahu ni awon okan maa fi bale |
الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ طُوبَىٰ لَهُمْ وَحُسْنُ مَآبٍ(29) Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, ori ire ati abo rere wa fun won |
Bayen ni A se ran o nise si ijo kan, (eyi ti) awon ijo kan kuku ti re koja lo siwaju won, nitori ki o le maa ka fun won nnkan ti A fi ranse si o ni imisi. Sibesibe won n sai gbagbo ninu Ajoke-aye. So pe: “Oun ni Oluwa mi. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Oun ni mo gbarale. Odo Re si ni abo mi.” |
Ti o ba je pe dajudaju Ƙur’an, won fi mu awon apata rin (bo si aye miiran), tabi won fi gele (lati yanu), tabi won fi ba awon oku soro (won si ji dide, won ko nii gbagbo). Amo sa, ti Allahu ni gbogbo ase patapata. Se awon t’o gbagbo ko mo pe ti o ba je pe Allahu ba fe, iba to gbogbo eniyan sona. Ajalu ko si nii ye sele si awon alaigbagbo nitori ohun ti won se nise tabi (ajalu naa ko nii ye) sokale si tosi ile won titi di igba ti adehun Allahu yoo fi de. Dajudaju Allahu ko nii yapa adehun |
Dajudaju won ti fi awon Ojise kan se yeye siwaju re. Mo si lo awon t’o sai gbagbo lara. Leyin naa, Mo gba won mu. Nitori naa, bawo ni iya (ti mo fi je won) ti ri (lara won na) |
Nje Eni ti O n mojuto emi kookan nipa ise ti o se (da bi eni ti ko le se bee bi? Sibe) e tun ba Allahu wa awon akegbe kan! So pe: “E daruko won na.” Tabi eyin yoo fun (Allahu) ni iro ohun ti ko mo lori ile tabi (eyin yoo pa) iro funfun balau ni? Won kuku ti se ete ni oso fun awon t’o sai gbagbo. Won si seri won kuro loju ona ododo. Enikeni ti Allahu ba si lona, ko si nii si olutosona kan fun un |
Iya wa fun won ninu isemi aye (yii). Iya ti Ojo Ikeyin kuku gbopon julo. Ko si nii si alaabo kan fun won lodo Allahu |
Apejuwe Ogba Idera ti Won se ni adehun fun awon oluberu Allahu (ni eyi ti) awon odo n san koja nisale re. Eso re ati iboji re yo si maa wa titi laelae. Iyen ni ikangun awon t’o beru (Allahu). Ina si ni ikangun awon alaigbagbo |
Awon ti A fun ni Tira n dunnu si ohun ti A sokale fun o. O si wa ninu awon ijo keferi-parapo t’o n se atako si apa kan re. So pe: “Nnkan ti Won pa mi lase re ni pe ki ng josin fun Allahu. Emi ko si gbodo wa akegbe fun Un. Odo Re ni mo n pepe si. Odo Re si ni abo mi.” |
Bayen ni A se so o kale ni idajo pelu ede Larubawa. Dajudaju ti o ba fi le tele ife-inu won, leyin nnkan ti o de ba o ninu imo, ko si alaabo ati oluso kan fun o mo lodo Allahu |
Dajudaju A ti ran awon Ojise kan nise siwaju re. A si fun won ni awon iyawo ati awon omoomo.1 Ko letoo fun Ojise kan lati mu ami kan wa ayafi pelu iyonda Allahu.2 Gbogbo isele l’o ni akosile |
يَمْحُو اللَّهُ مَا يَشَاءُ وَيُثْبِتُ ۖ وَعِندَهُ أُمُّ الْكِتَابِ(39) Allahu n pa ohun ti O ba fe re. O si n mu (ohun ti O ba fe) se. Odo Re si ni Tira Ipile wa. bere lati igba ti eda ko ti i maa je eda titi de ikangun eda ninu Ogba Idera tabi ninu Ina. Ninu akosile yii ni Allahu (subhanahu wa ta’ala) ti n yo akosile olodoodun fun awon molaika Re. Nitori naa ohun titun ninu kadara ti n be lowo awon molaika ni agboye “yamhu-llahu mo yasa’”. Bakan naa ki o pada sibi iyapa ase Allahu ki o si ku sinu isina aigbagbo. Onitoun ni eni ti Allahu pa oruko re re ninu imona. Irufe eni yii l’o wa ni abe “yamhu-llahu mo yasa’”. Ni ida keji ewe won yoo yo gbogbo oro ti ko la laada ati iya lo sile awon oro bii “Mo je; mo mu; mo sun; mo ji ati bee bee lo”. Eyi si ni itumo “yamhu-llahu mo yasa’” Won yo si fi awon oro ati ise yooku ti o la laada ati iya lo sile ninu akosile ise eda. Eyi si ni itumo “wa yuthbit”. ti Allahu yoo pa idajo inu won re. Irufe awon ayah bee si l’o wa ni abe “yamhu-llahu mo yasa’”. Ni ida keji ewe awon ayah kan si n be ti Allahu ko nii pa idajo inu won re. Irufe awon ayah bee l’o si wa ni abe “wa yuthbit”. mejeeji ti wa ninu kadara eda ti o wa ninu Tira Laohul-mahfuth. Ati pe ko si eda t’o nimo ewo ninu awon oore aye ati torun l’o maa te eda lowo nipase adua. Eyi je imo ikoko ni abala kan. O tun je ola fun adua sise labala kan nitori pe oore adua oto oore ebun Olohun oto. Nitori naa |
O see se ki A fi apa kan eyi ti A se ni ileri fun won han o tabi ki A ti gba emi re (siwaju asiko naa), ise-jije nikan ni ojuse tire, isiro-ise si ni tiWa |
Se won ko ri i pe dajudaju A n mu ile dinku (mo awon alaigbagbo lowo) lati awon eti ilu (wo inu ilu nipa fifun awon musulumi ni isegun lori won)? Allahu l’O n se idajo. Ko si eni kan ti o le da idajo Re pada (fun Un). Oun si ni Oluyara nibi isiro-ise |
Dajudaju awon t’o siwaju won dete. Ti Allahu si ni gbogbo ete patapata. O mo ohun ti emi kookan n se nise. Ati pe awon alaigbagbo n bo wa mo eni ti atubotan Ile (rere) wa fun |
Awon alaigbagbo n wi pe: “Iwo ki i se Ojise.” So pe: “Allahu to ni Elerii laaarin emi ati eyin ati eni ti imo Tira n be lodo re.” |
More surahs in Yoruba:
Download surah Ar-Rad with the voice of the most famous Quran reciters :
surah Ar-Rad mp3 : choose the reciter to listen and download the chapter Ar-Rad Complete with high quality
Ahmed Al Ajmy
Bandar Balila
Khalid Al Jalil
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdul Rashid Sufi
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Yasser Al Dosari
لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب