La sourate At-Taghabun en Yoruba
Ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile n se afomo fun Allahu. TiRe ni ijoba. TiRe si ni ope. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
هُوَ الَّذِي خَلَقَكُمْ فَمِنكُمْ كَافِرٌ وَمِنكُم مُّؤْمِنٌ ۚ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ(2) Oun ni Eni ti O seda yin. Alaigbagbo wa ninu yin. Onigbagbo ododo si wa ninu yin. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se |
O seda awon sanmo ati ile pelu ododo. O ya aworan yin. O si se awon aworan yin daradara. Odo Re si ni abo eda |
O mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. O si mo ohun ti e n fi pamo ati ohun ti e n safi han re. Allahu si ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu igba-aya eda |
Se iro awon t’o sai gbagbo ni isaaju ko ti i de ba yin ni? Nitori naa, won to iya oran won wo. Iya eleta-elero si wa fun won |
Iyen nitori pe dajudaju awon Ojise won n wa ba won pelu awon eri t’o yanju. Won si wi pe: "Se abara l’o maa fi ona mo wa?" Nitori naa, won sai gbagbo. Won si peyin da (si ododo). Allahu si roro lai si awon. Ati pe Allahu ni Oloro, Olope |
Awon t’o sai gbagbo lero pe A o nii gbe won dide. So pe: "Bee ko, mo fi Oluwa mi bura, dajudaju Won yoo gbe yin dide. Leyin naa, Won yoo fun yin ni iro ohun ti e se nise. Iyen si je irorun fun Allahu |
فَآمِنُوا بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ وَالنُّورِ الَّذِي أَنزَلْنَا ۚ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ(8) Nitori naa, e gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re ati imole ti A sokale. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se |
Ni ojo ti (Allahu) yoo ko yin jo fun ojo akojo. Iyen ni ojo ere ati adanu. Enikeni ti o ba gba Allahu gbo ni ododo, ti o si se ise rere, (Allahu) yoo pa awon asise re re fun un. O si maa mu un wo inu Ogba Idera, ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Iyen si ni erenje nla |
Awon t’o si sai gbagbo, ti won tun pe awon ayah Wa niro, awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re. Ikangun naa si buru |
Adanwo kan ko le sele ayafi pelu iyonda Allahu. Enikeni ti o ba gba Allahu gbo, Allahu maa fi okan re mona. Allahu si ni Onimo nipa gbogbo nnkan |
Ki e tele ti Allahu. Ki e si tele ti Ojise. Ti e ba gbunri, ise-jije ponnbele lojuse Ojise Wa |
اللَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۚ وَعَلَى اللَّهِ فَلْيَتَوَكَّلِ الْمُؤْمِنُونَ(13) Allahu, ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Allahu si ni ki awon onigbagbo ododo gbarale |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, dajudaju ota wa fun yin ninu awon iyawo yin ati awon omo yin. Nitori naa, e sora fun won. Ti e ba samojukuro, ti e safojufo, ti e si saforijin (fun won), dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun |
إِنَّمَا أَمْوَالُكُمْ وَأَوْلَادُكُمْ فِتْنَةٌ ۚ وَاللَّهُ عِندَهُ أَجْرٌ عَظِيمٌ(15) Ifooro ni awon dukia yin ati awon omo yin. Allahu si ni esan nla wa ni odo Re |
Nitori naa, e beru Allahu bi e ba se lagbara mo. E gbo oro (Allahu), e tele e, ki e si nawo (fun esin Re) loore julo fun emi yin. Enikeni ti A ba so nibi ahun ati okanjua inu emi re, awon wonyen, awon ni olujere |
Ti e ba ya Allahu ni dukia t’o dara, O maa sadipele re fun yin. O si maa forijin yin. Allahu si ni Olumoore, Alafarada |
Onimo-ikoko ati gbangba, Alagbara, Ologbon |
Plus de sourates en Yoruba :
Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :
Téléchargez le fichier mp3 de la sourate At-Taghabun : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate At-Taghabun complète en haute qualité.















Donnez-nous une invitation valide