La sourate Al-Mursalat en Yoruba
Allahu bura pelu awon ategun t’o n sare ni telentele |
O bura pelu awon iji ategun t’o n ja |
O bura pelu awon ategun t’o n tu esujo ka |
O bura pelu awon t’o n sepinya laaarin ododo ati iro |
O tun bura pelu awon molaika t’o n mu iranti wa (ba awon Ojise) |
(Iranti naa je) awijare tabi ikilo |
Dajudaju ohun ti A se ni adehun fun yin kuku maa sele |
Nitori naa, nigba ti won ba pa (imole) irawo re |
ati nigba ti won ba si sanmo sile gbagada |
ati nigba ti won ba ku awon apata danu |
ati nigba ti won ba fun awon Ojise ni asiko lati kojo, (Akoko naa ti de niyen) |
Ojo wo ni won so (awon isele wonyi) ro fun na |
Fun ojo ipinya (laaarin awon eda) ni |
Ki si ni o mu o mo ohun t’o n je Ojo ipinya |
Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro |
Nje Awa ko ti pa awon eni akoko re bi |
Leyin naa, A si maa fi awon eni Ikeyin tele won (ninu iparun) |
Bayen ni A o ti se pelu awon elese |
Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro |
Se A o seda yin lati inu omi lile yepere bi |
Leyin naa, A fi sinu aye aabo (iyen, ile-omo) |
titi di gbedeke akoko kan ti A ti mo (iyen, ojo ibimo) |
A si ni ikapa ati ayanmo (lori re). (Awa si ni) Olukapa ati Olupebubu eda t’o dara |
Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro |
Nje Awa ko se ile ni ohun t’o n ko eda jo mora won |
(iyen) awon alaaye ati awon oku |
وَجَعَلْنَا فِيهَا رَوَاسِيَ شَامِخَاتٍ وَأَسْقَيْنَاكُم مَّاءً فُرَاتًا(27) A si fi awon apata gbagidi giga-giga sinu re. A si fun yin ni omi didun mu |
Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro |
E maa lo si ibi ti e n pe niro |
E maa lo si ibi eefin eleka meta |
Ki i se iboji tutu. Ko si nii ro won loro ninu ijofofo Ina |
Dajudaju (Ina naa) yoo maa ju etapara (re soke t’o maa da) bi peteesi |
(O maa da) bi awon rakunmi alawo omi osan |
Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro |
Eyi ni ojo ti won ko nii soro |
A o si nii yonda (oro siso) fun won, ambosibosi pe won yoo mu awawi wa |
Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro |
Eyi ni ojo ipinya. Awa yo si ko eyin ati awon eni akoko jo |
Ti e ba ni ete kan lowo, e dete si Mi wo |
Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro |
Dajudaju awon oluberu Allahu yoo wa nibi iboji ati awon omi iseleru |
ati awon eso eyi ti won ba n fe |
E je, ki e si mu pelu igbadun nitori ohun ti e n se nise |
Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere) |
Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro |
E je, ki e si gbadun fun igba die. Dajudaju elese ni yin |
Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro |
Nigba ti won ba so fun won pe ki won kirun, won ko nii kirun |
Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro |
Nigba naa, oro wo ni won yoo gbagbo leyin re |
Plus de sourates en Yoruba :
Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :
Téléchargez le fichier mp3 de la sourate Al-Mursalat : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate Al-Mursalat complète en haute qualité.















Donnez-nous une invitation valide