Перевод суры Аль-Калям на Йоруба язык
Nun. (Allahu bura pelu) gege ikowe ati ohun ti awon molaika n ko sile |
Iwo ki i se were nipa idera Oluwa re |
Ati pe dajudaju esan ti ko nii dawo duro ti wa fun o |
Dajudaju iwo si wa lori iwa aponle |
Laipe iwo yoo ri i, awon naa yo si ri i |
ewo ninu yin ni were |
إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِ وَهُوَ أَعْلَمُ بِالْمُهْتَدِينَ(7) Dajudaju Oluwa re, O nimo julo nipa eni t’o sina kuro loju ona Re. O si nimo julo nipa awon olumona |
Nitori naa, ma se tele awon olupe-ododo-niro |
Ati pe won fe ki o dewo, ki awon naa si dewo |
Ma se tele gbogbo eni ti ibura re po, eni yepere |
abuni, alarinka t’o n sofofo kiri |
oludena ise rere, alakoyo, elese |
odaju. Leyin iyen, asawo ni |
Nitori pe o ni dukia ati awon omokunrin |
إِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِ آيَاتُنَا قَالَ أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ(15) nigba ti won ba n ke awon ayah Wa fun un, o maa wi pe: “Akosile alo awon eni akoko (niwonyi)” |
A maa fi ami si i ni gongori imu |
Dajudaju Awa dan won wo gege bi A se dan awon ologba wo nigba ti won bura pe dajudaju awon yoo ka gbogbo eso ogba naa ni owuro kutukutu |
Won ko si se ayafi pe "ti Allahu ba fe |
فَطَافَ عَلَيْهَا طَائِفٌ مِّن رَّبِّكَ وَهُمْ نَائِمُونَ(19) Adanwo t’o n yi nnkan po lati odo Oluwa re si yi ogba naa po, nigba ti won sun lo |
O si da bi oko agedanu (ti won ti resun) |
Won n pera won ni owuro kutukutu |
pe e ji lo si oko yin ti e ba fe ka eso |
Won lo, won si n fi ohun jeeje bara won soro |
pe ni oni mekunnu kan ko gbodo wonu re wa ba yin |
Won ji lo lori ero-okan kan (pe) awon lagbara |
Nigba ti won ri i, won wi pe: "Dajudaju awa ti sina |
Rara o, won se ikore oko leewo fun wa ni |
قَالَ أَوْسَطُهُمْ أَلَمْ أَقُل لَّكُمْ لَوْلَا تُسَبِّحُونَ(28) Eni t’o duro deede julo ninu won so pe: "Se emi ko so fun yin pe eyin ko se safomo fun Allahu (pe "a maa kore oko wa, ’in sa ’Allahu) |
Won wi pe: "Mimo ni fun Oluwa wa, dajudaju awa je alabosi |
Apa kan won koju si apa kan; won si n dara won lebi |
Won wi pe: "Egbe wa o! Dajudaju awa je olutayo-enu ala |
عَسَىٰ رَبُّنَا أَن يُبْدِلَنَا خَيْرًا مِّنْهَا إِنَّا إِلَىٰ رَبِّنَا رَاغِبُونَ(32) O see se ki Oluwa wa fi eyi t’o dara ju eyi lo paaro re fun wa. Dajudaju odo Oluwa wa ni awa n rokan oore si |
كَذَٰلِكَ الْعَذَابُ ۖ وَلَعَذَابُ الْآخِرَةِ أَكْبَرُ ۚ لَوْ كَانُوا يَعْلَمُونَ(33) Bayen ni iya naa se ri (fun won). Iya orun si tobi julo, ti o ba je pe won mo |
إِنَّ لِلْمُتَّقِينَ عِندَ رَبِّهِمْ جَنَّاتِ النَّعِيمِ(34) Dajudaju awon Ogba Idera wa fun awon oluberu lodo Oluwa won |
Se A maa se awon musulumi bi (A se maa se) awon elese bi |
Ki l’o n se yin ti e fi n dajo bayii na |
Tabi tira kan wa fun yin ti e n kekoo ninu re |
pe dajudaju eyin le ni ohun ti e ba n sa lesa ninu idajo |
Nje e ni awon adehun kan lodo wa ti o maa wa titi di Ojo Ajinde pe: "Dajudaju tiyin ni idajo ti e ba ti mu wa |
Bi won leere wo pe ewo ninu won l’o le fowo iyen soya |
أَمْ لَهُمْ شُرَكَاءُ فَلْيَأْتُوا بِشُرَكَائِهِمْ إِن كَانُوا صَادِقِينَ(41) Tabi won ni awon orisa kan? Ki won mu awon orisa won wa nigba naa ti won ba je olododo |
يَوْمَ يُكْشَفُ عَن سَاقٍ وَيُدْعَوْنَ إِلَى السُّجُودِ فَلَا يَسْتَطِيعُونَ(42) Ni ojo ti A maa si ojugun sile, A si maa pe won sibi iforikanle, won ko si nii le se e |
Oju won yoo wale. Iyepere maa bo won mole. Won kuku ti pe won sibi iforikanle nigba ti won ni alaafia (won ko si kirun) |
فَذَرْنِي وَمَن يُكَذِّبُ بِهَٰذَا الْحَدِيثِ ۖ سَنَسْتَدْرِجُهُم مِّنْ حَيْثُ لَا يَعْلَمُونَ(44) Nitori naa, fi Emi ati eni t’o n pe oro yii niro sile. A oo maa de won leke lati je won niya ni aye ti won ko mo |
Mo n lora fun won ni. Dajudaju ete Mi lagbara |
أَمْ تَسْأَلُهُمْ أَجْرًا فَهُم مِّن مَّغْرَمٍ مُّثْقَلُونَ(46) Tabi o n beere owo-oya kan lodo won, ni gbese fi wo won lorun |
Tabi lodo won ni (walaa) ikoko wa ni won ba n ko o (sita) |
فَاصْبِرْ لِحُكْمِ رَبِّكَ وَلَا تَكُن كَصَاحِبِ الْحُوتِ إِذْ نَادَىٰ وَهُوَ مَكْظُومٌ(48) Nitori naa, se suuru fun idajo Oluwa re. Ki iwo ma si se da bi eleja (iyen, Anabi Yunus) nigba ti o pe (Allahu) pelu ibanuje |
لَّوْلَا أَن تَدَارَكَهُ نِعْمَةٌ مِّن رَّبِّهِ لَنُبِذَ بِالْعَرَاءِ وَهُوَ مَذْمُومٌ(49) Ti ko ba je pe ike kan lati odo Oluwa re le e ba, won iba ju u sori ile gbansasa (lati inu eja) ni eni-eebu |
Nitori naa, Oluwa re sa a lesa. O si se e ni ara awon eni rere |
Awon t’o sai gbagbo fee fi oju won gbe o subu nigba ti won gbo iranti naa. Won si n wi pe: "Dajudaju were ma ni |
Ki si ni al-Ƙur’an bi ko se iranti fun gbogbo eda |
Больше сур в Йоруба:
Скачать суру Al-Qalam с голосом самых известных рекитаторов Корана:
Сура Al-Qalam mp3: выберите рекитатора, чтобы прослушать и скачать главу Al-Qalam полностью в высоком качестве
Ahmed Al Ajmy
Bandar Balila
Khalid Al Jalil
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdul Rashid Sufi
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Yasser Al Dosari
Помолитесь за нас хорошей молитвой