سورة غافر باليوربا

  1. استمع للسورة
  2. سور أخرى
  3. ترجمة السورة
القرآن الكريم | ترجمة معاني القرآن | اللغة اليوربا | سورة غافر | Ghafir - عدد آياتها 85 - رقم السورة في المصحف: 40 - معنى السورة بالإنجليزية: The Forgiver (God).

حم(1)

Ha mim

تَنزِيلُ الْكِتَابِ مِنَ اللَّهِ الْعَزِيزِ الْعَلِيمِ(2)

Tira naa sokale lati odo Allahu, Alagbara, Onimo

غَافِرِ الذَّنبِ وَقَابِلِ التَّوْبِ شَدِيدِ الْعِقَابِ ذِي الطَّوْلِ ۖ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ إِلَيْهِ الْمَصِيرُ(3)

Alaforijin-ese, Olugba-ironupiwada, Eni lile nibi iya, Olore, ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Odo Re ni abo eda

مَا يُجَادِلُ فِي آيَاتِ اللَّهِ إِلَّا الَّذِينَ كَفَرُوا فَلَا يَغْرُرْكَ تَقَلُّبُهُمْ فِي الْبِلَادِ(4)

Ko si eni ti o maa se atako si awon ayah Allahu afi awon t’o sai gbagbo. Nitori naa, ma se je ki igbokegbodo won ninu ilu ko etan ba o

كَذَّبَتْ قَبْلَهُمْ قَوْمُ نُوحٍ وَالْأَحْزَابُ مِن بَعْدِهِمْ ۖ وَهَمَّتْ كُلُّ أُمَّةٍ بِرَسُولِهِمْ لِيَأْخُذُوهُ ۖ وَجَادَلُوا بِالْبَاطِلِ لِيُدْحِضُوا بِهِ الْحَقَّ فَأَخَذْتُهُمْ ۖ فَكَيْفَ كَانَ عِقَابِ(5)

Ijo (Anabi) Nuh pe ododo niro siwaju won. Awon ijo (miiran) leyin won (naa se bee). Ijo kookan lo gbero lati ki Ojise won mole. Won fi iro ja ododo niyan nitori ki won le fi wo ododo lule. Mo si gba won mu. Nitori naa, bawo ni iya (ti mo fi je won) ti ri (lara won na)

وَكَذَٰلِكَ حَقَّتْ كَلِمَتُ رَبِّكَ عَلَى الَّذِينَ كَفَرُوا أَنَّهُمْ أَصْحَابُ النَّارِ(6)

Ati pe bayen ni oro Oluwa re se ko lori awon t’o sai gbagbo pe: "Dajudaju awon ni ero inu Ina

الَّذِينَ يَحْمِلُونَ الْعَرْشَ وَمَنْ حَوْلَهُ يُسَبِّحُونَ بِحَمْدِ رَبِّهِمْ وَيُؤْمِنُونَ بِهِ وَيَسْتَغْفِرُونَ لِلَّذِينَ آمَنُوا رَبَّنَا وَسِعْتَ كُلَّ شَيْءٍ رَّحْمَةً وَعِلْمًا فَاغْفِرْ لِلَّذِينَ تَابُوا وَاتَّبَعُوا سَبِيلَكَ وَقِهِمْ عَذَابَ الْجَحِيمِ(7)

Awon t’o gbe Ite-ola naa ru ati awon t’o wa ni ayika re, won n se afomo pelu idupe fun Oluwa won. Won gba Allahu gbo. Won si n toro aforijin fun awon t’o gbagbo ni ododo (bayii pe): "Oluwa wa, ike ati imo (Re) gbooro ju gbogbo nnkan lo, nitori naa, saforijin fun awon t’o ronu piwada, ti won si tele oju-ona Re. Ki O si so won ninu iya ina Jehim

رَبَّنَا وَأَدْخِلْهُمْ جَنَّاتِ عَدْنٍ الَّتِي وَعَدتَّهُمْ وَمَن صَلَحَ مِنْ آبَائِهِمْ وَأَزْوَاجِهِمْ وَذُرِّيَّاتِهِمْ ۚ إِنَّكَ أَنتَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ(8)

Oluwa wa, fi won sinu awon Ogba Idera ti O se ni adehun fun awon ati eni t’o se ise rere ninu awon baba won, awon aya won ati awon aromodomo won. Dajudaju Iwo ni Alagbara, Ologbon

وَقِهِمُ السَّيِّئَاتِ ۚ وَمَن تَقِ السَّيِّئَاتِ يَوْمَئِذٍ فَقَدْ رَحِمْتَهُ ۚ وَذَٰلِكَ هُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ(9)

So won ninu awon aburu. Enikeni ti O ba so nibi awon aburu (iya) ni ojo yen, dajudaju O ti ke e. Iyen si ni erenje nla

إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا يُنَادَوْنَ لَمَقْتُ اللَّهِ أَكْبَرُ مِن مَّقْتِكُمْ أَنفُسَكُمْ إِذْ تُدْعَوْنَ إِلَى الْإِيمَانِ فَتَكْفُرُونَ(10)

Dajudaju awon t’o sai gbagbo, won yoo pe won (lati so fun won ninu Ina pe): " Dajudaju ibinu ti Allahu tobi ju ibinu ti e n bi sira yin (ninu Ina, sebi) nigba ti won n pe yin sibi igbagbo ododo, nse ni e n sai gbagbo

قَالُوا رَبَّنَا أَمَتَّنَا اثْنَتَيْنِ وَأَحْيَيْتَنَا اثْنَتَيْنِ فَاعْتَرَفْنَا بِذُنُوبِنَا فَهَلْ إِلَىٰ خُرُوجٍ مِّن سَبِيلٍ(11)

Won wi pe: "Oluwa wa, O pa wa ni ee meji. O si ji wa ni ee meji. Nitori naa, a si jewo awon ese wa. Nje ona kan wa lati jade (pada si ile aye) bi

ذَٰلِكُم بِأَنَّهُ إِذَا دُعِيَ اللَّهُ وَحْدَهُ كَفَرْتُمْ ۖ وَإِن يُشْرَكْ بِهِ تُؤْمِنُوا ۚ فَالْحُكْمُ لِلَّهِ الْعَلِيِّ الْكَبِيرِ(12)

(E wa ninu Ina) yen nitori pe dajudaju nigba ti won ba pe Allahu nikan soso, eyin sai gbagbo. Nigba ti won ba sebo si I, e si maa gbagbo (ninu ebo). Nitori naa, idajo n je ti Allahu, O ga, O tobi

هُوَ الَّذِي يُرِيكُمْ آيَاتِهِ وَيُنَزِّلُ لَكُم مِّنَ السَّمَاءِ رِزْقًا ۚ وَمَا يَتَذَكَّرُ إِلَّا مَن يُنِيبُ(13)

Oun ni Eni t’O n fi awon ami Re han yin. O si n so arisiki kale fun yin lati sanmo. Ko si eni t’o n lo iranti afi eni t’o n seri pada si odo Allahu (nipase ironupiwada)

فَادْعُوا اللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ وَلَوْ كَرِهَ الْكَافِرُونَ(14)

Nitori naa, e pe Allahu ni ti olusafomo-esin fun Un, awon alaigbagbo ibaa korira Re

رَفِيعُ الدَّرَجَاتِ ذُو الْعَرْشِ يُلْقِي الرُّوحَ مِنْ أَمْرِهِ عَلَىٰ مَن يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ لِيُنذِرَ يَوْمَ التَّلَاقِ(15)

(Allahu) Eni t’O ni gbogbo ipo ajulo, Oluwa Ite-ola, O n fi imisi (al-Ƙur’an) ranse pelu ase Re si eni ti O fe ninu awon erusin Re nitori ki o le fi sekilo nipa Ojo ipade naa

يَوْمَ هُم بَارِزُونَ ۖ لَا يَخْفَىٰ عَلَى اللَّهِ مِنْهُمْ شَيْءٌ ۚ لِّمَنِ الْمُلْكُ الْيَوْمَ ۖ لِلَّهِ الْوَاحِدِ الْقَهَّارِ(16)

Ni ojo ti won yoo yo jade (lati inu saree), kini kan ko si nii pamo nipa won fun Allahu. (Allahu yo si so pe): "Ti ta ni ijoba ni ojo oni? Ti Allahu, Okan soso, Olubori ni

الْيَوْمَ تُجْزَىٰ كُلُّ نَفْسٍ بِمَا كَسَبَتْ ۚ لَا ظُلْمَ الْيَوْمَ ۚ إِنَّ اللَّهَ سَرِيعُ الْحِسَابِ(17)

Ni oni ni A oo san emi kookan ni esan ohun ti o se nise. Ko si si abosi kan ni oni. Dajudaju Allahu ni Oluyara nibi isiro-ise

وَأَنذِرْهُمْ يَوْمَ الْآزِفَةِ إِذِ الْقُلُوبُ لَدَى الْحَنَاجِرِ كَاظِمِينَ ۚ مَا لِلظَّالِمِينَ مِنْ حَمِيمٍ وَلَا شَفِيعٍ يُطَاعُ(18)

Ati pe sekilo ojo ti o sunmo fun won. Nigba ti awon okan ba ga de gogongo, ti o maa kun fun ibanuje, ko nii si ore imule ati olusipe kan ti won maa tele oro re lori (oro) awon alabosi

يَعْلَمُ خَائِنَةَ الْأَعْيُنِ وَمَا تُخْفِي الصُّدُورُ(19)

(Allahu) mo oju ijanba ati ohun ti awon okan fi pamo

وَاللَّهُ يَقْضِي بِالْحَقِّ ۖ وَالَّذِينَ يَدْعُونَ مِن دُونِهِ لَا يَقْضُونَ بِشَيْءٍ ۗ إِنَّ اللَّهَ هُوَ السَّمِيعُ الْبَصِيرُ(20)

Ati pe Allahu l’O maa fi ododo dajo. Awon ti won n pe leyin Re, won ko le se idajo kan kan. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugbo, Oluriran

۞ أَوَلَمْ يَسِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَيَنظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الَّذِينَ كَانُوا مِن قَبْلِهِمْ ۚ كَانُوا هُمْ أَشَدَّ مِنْهُمْ قُوَّةً وَآثَارًا فِي الْأَرْضِ فَأَخَذَهُمُ اللَّهُ بِذُنُوبِهِمْ وَمَا كَانَ لَهُم مِّنَ اللَّهِ مِن وَاقٍ(21)

Se won ko rin kiri lori ile ki won wo bi ikangun awon t’o siwaju won se ri? Won ni agbara ju won lo. Won si lo ile (fun oko dida ju won lo). Sibesibe Allahu mu won nitori ese won. Ko si si oluso kan fun won (nibi iya) Allahu

ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ كَانَت تَّأْتِيهِمْ رُسُلُهُم بِالْبَيِّنَاتِ فَكَفَرُوا فَأَخَذَهُمُ اللَّهُ ۚ إِنَّهُ قَوِيٌّ شَدِيدُ الْعِقَابِ(22)

Iyen nitori pe awon Ojise won n wa ba won pelu awon eri t’o yanju, sugbon won sai gbagbo. Nitori naa, Allahu mu won. Dajudaju Oun ni Alagbara, Eni lile nibi iya

وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مُوسَىٰ بِآيَاتِنَا وَسُلْطَانٍ مُّبِينٍ(23)

Dajudaju A fi awon ami Wa ati eri t’o yanju ran (Anabi) Musa nise

إِلَىٰ فِرْعَوْنَ وَهَامَانَ وَقَارُونَ فَقَالُوا سَاحِرٌ كَذَّابٌ(24)

si Fir‘aon, Hamon ati Ƙorun. Sugbon won wi pe: "Opidan, opuro ni (Anabi Musa)

فَلَمَّا جَاءَهُم بِالْحَقِّ مِنْ عِندِنَا قَالُوا اقْتُلُوا أَبْنَاءَ الَّذِينَ آمَنُوا مَعَهُ وَاسْتَحْيُوا نِسَاءَهُمْ ۚ وَمَا كَيْدُ الْكَافِرِينَ إِلَّا فِي ضَلَالٍ(25)

Nigba ti o mu ododo naa de odo won lati odo Wa, won wi pe: "E pa awon omokunrin awon t’o gbagbo pelu re, ki e si fi awon omobinrin won sile." Ete awon alaigbagbo ko si ninu kini kan bi ko se ninu ofo

وَقَالَ فِرْعَوْنُ ذَرُونِي أَقْتُلْ مُوسَىٰ وَلْيَدْعُ رَبَّهُ ۖ إِنِّي أَخَافُ أَن يُبَدِّلَ دِينَكُمْ أَوْ أَن يُظْهِرَ فِي الْأَرْضِ الْفَسَادَ(26)

Fir‘aon wi pe: "E fi mi sile ki ng pa Musa, ki o si pe Oluwa re (wo boya O maa gba a sile). Dajudaju emi n beru pe o maa yi esin yin pada tabi pe o maa safi han ibaje lori ile

وَقَالَ مُوسَىٰ إِنِّي عُذْتُ بِرَبِّي وَرَبِّكُم مِّن كُلِّ مُتَكَبِّرٍ لَّا يُؤْمِنُ بِيَوْمِ الْحِسَابِ(27)

(Anabi) Musa so pe: "Dajudaju emi sa di Oluwa mi ati Oluwa yin kuro lowo gbogbo onigbeeraga, ti ko gba Ojo isiro-ise gbo

وَقَالَ رَجُلٌ مُّؤْمِنٌ مِّنْ آلِ فِرْعَوْنَ يَكْتُمُ إِيمَانَهُ أَتَقْتُلُونَ رَجُلًا أَن يَقُولَ رَبِّيَ اللَّهُ وَقَدْ جَاءَكُم بِالْبَيِّنَاتِ مِن رَّبِّكُمْ ۖ وَإِن يَكُ كَاذِبًا فَعَلَيْهِ كَذِبُهُ ۖ وَإِن يَكُ صَادِقًا يُصِبْكُم بَعْضُ الَّذِي يَعِدُكُمْ ۖ إِنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي مَنْ هُوَ مُسْرِفٌ كَذَّابٌ(28)

Okunrin onigbagbo ododo kan t’o n fi igbagbo re pamo ninu awon eniyan Fir‘aon so pe: "Se e maa pa okunrin kan nitori pe o n so pe, ‘Allahu ni Oluwa mi.’ O si kuku ti mu awon eri t’o yanju wa ba yin lati odo Oluwa yin. Ti o ba je opuro, (iya) iro re wa lori re. Ti o ba si je olododo, apa kan eyi ti o se ni ileri fun yin yo si ko le yin lori. Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo eni ti o je alaseju, opuro

يَا قَوْمِ لَكُمُ الْمُلْكُ الْيَوْمَ ظَاهِرِينَ فِي الْأَرْضِ فَمَن يَنصُرُنَا مِن بَأْسِ اللَّهِ إِن جَاءَنَا ۚ قَالَ فِرْعَوْنُ مَا أُرِيكُمْ إِلَّا مَا أَرَىٰ وَمَا أَهْدِيكُمْ إِلَّا سَبِيلَ الرَّشَادِ(29)

Eyin eniyan mi, eyin l’e ni ijoba lonii, eyin si ni alase lori ile naa. Sugbon ta ni o maa ran wa lowo ti iya Allahu ba de ba wa?" Fir‘aon wi pe: "Emi ko fi nnkan kan han yin bi ko se ohun ti mo ri (ninu oye mi). Emi ko si to yin si ona kan bi ko se oju ona imona

وَقَالَ الَّذِي آمَنَ يَا قَوْمِ إِنِّي أَخَافُ عَلَيْكُم مِّثْلَ يَوْمِ الْأَحْزَابِ(30)

Eni t’o gbagbo ni ododo tun so pe: "Eyin eniyan mi, dajudaju iru ojo (esan iya t’o sele si) awon omo-ogun onijo ni emi n paya lori yin

مِثْلَ دَأْبِ قَوْمِ نُوحٍ وَعَادٍ وَثَمُودَ وَالَّذِينَ مِن بَعْدِهِمْ ۚ وَمَا اللَّهُ يُرِيدُ ظُلْمًا لِّلْعِبَادِ(31)

Iru ise (iparun t’o sele si awon) eniyan Nuh, ‘Ad, Thamud ati awon t’o tele won. Allahu ko si gbero abosi si awon erusin naa

وَيَا قَوْمِ إِنِّي أَخَافُ عَلَيْكُمْ يَوْمَ التَّنَادِ(32)

Eyin eniyan mi, dajudaju emi n paya Ojo ipe fun yin

يَوْمَ تُوَلُّونَ مُدْبِرِينَ مَا لَكُم مِّنَ اللَّهِ مِنْ عَاصِمٍ ۗ وَمَن يُضْلِلِ اللَّهُ فَمَا لَهُ مِنْ هَادٍ(33)

Ojo ti e maa peyinda lati sa lo; ko si nii si alaabo kan fun yin lodo Allahu. Ati pe eni ti Allahu ba si lona, ko le si afinimona kan fun un

وَلَقَدْ جَاءَكُمْ يُوسُفُ مِن قَبْلُ بِالْبَيِّنَاتِ فَمَا زِلْتُمْ فِي شَكٍّ مِّمَّا جَاءَكُم بِهِ ۖ حَتَّىٰ إِذَا هَلَكَ قُلْتُمْ لَن يَبْعَثَ اللَّهُ مِن بَعْدِهِ رَسُولًا ۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ اللَّهُ مَنْ هُوَ مُسْرِفٌ مُّرْتَابٌ(34)

Ati pe dajudaju (Anabi) Yusuf ti to yin wa siwaju pelu awon alaye oro t’o yanju, sugbon eyin ko ye wa ninu iyemeji nipa ohun ti o mu wa ba yin titi di igba ti o fi ku, ti e fi wi pe: "Allahu ko nii gbe Ojise kan dide mo leyin re." Bayen ni Allahu se n so eni ti o je alaseju, oniyemeji nu

الَّذِينَ يُجَادِلُونَ فِي آيَاتِ اللَّهِ بِغَيْرِ سُلْطَانٍ أَتَاهُمْ ۖ كَبُرَ مَقْتًا عِندَ اللَّهِ وَعِندَ الَّذِينَ آمَنُوا ۚ كَذَٰلِكَ يَطْبَعُ اللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ قَلْبِ مُتَكَبِّرٍ جَبَّارٍ(35)

Awon t’o n jiyan nipa awon ayah Allahu laisi eri kan ti o de ba won. Ese nla si ni ni odo Allahu ati ni odo awon t’o gbagbo ni ododo. Bayen ni Allahu se n fi edidi bo gbogbo okan onigbeeraga, ajeninipa.”

وَقَالَ فِرْعَوْنُ يَا هَامَانُ ابْنِ لِي صَرْحًا لَّعَلِّي أَبْلُغُ الْأَسْبَابَ(36)

Fir‘aon wi pe: "Hamon, mo ile giga fiofio kan fun mi nitori ki emi le de awon oju ona naa

أَسْبَابَ السَّمَاوَاتِ فَأَطَّلِعَ إِلَىٰ إِلَٰهِ مُوسَىٰ وَإِنِّي لَأَظُنُّهُ كَاذِبًا ۚ وَكَذَٰلِكَ زُيِّنَ لِفِرْعَوْنَ سُوءُ عَمَلِهِ وَصُدَّ عَنِ السَّبِيلِ ۚ وَمَا كَيْدُ فِرْعَوْنَ إِلَّا فِي تَبَابٍ(37)

Awon oju ona (inu) sanmo ni, nitori ki emi le yoju wo Olohun Musa nitori pe dajudaju emi n ro o si opuro." Bayen ni won se ise aburu (owo) Fir‘aon ni oso fun un. Won si seri re kuro loju ona (esin Allahu). Ete Fir‘aon ko si wa ninu kini kan bi ko se ninu ofo

وَقَالَ الَّذِي آمَنَ يَا قَوْمِ اتَّبِعُونِ أَهْدِكُمْ سَبِيلَ الرَّشَادِ(38)

Eni t’o gbagbo ni ododo tun so pe: "Eyin eniyan mi, e tele mi, mo maa juwe yin si oju ona imona

يَا قَوْمِ إِنَّمَا هَٰذِهِ الْحَيَاةُ الدُّنْيَا مَتَاعٌ وَإِنَّ الْآخِرَةَ هِيَ دَارُ الْقَرَارِ(39)

Eyin eniyan mi, isemi ile aye yii je igbadun lasan. Dajudaju orun si ni ile gbere

مَنْ عَمِلَ سَيِّئَةً فَلَا يُجْزَىٰ إِلَّا مِثْلَهَا ۖ وَمَنْ عَمِلَ صَالِحًا مِّن ذَكَرٍ أَوْ أُنثَىٰ وَهُوَ مُؤْمِنٌ فَأُولَٰئِكَ يَدْخُلُونَ الْجَنَّةَ يُرْزَقُونَ فِيهَا بِغَيْرِ حِسَابٍ(40)

Eni ti o ba se aburu kan, Won ko nii san an ni esan kan ayafi iru re. Eni ti o ba si se ise rere ni okunrin tabi ni obinrin, ti o si je onigbagbo ododo, awon wonyen ni won maa wo inu Ogba Idera. Won yoo maa pese arisiki fun won ninu re lai la isiro lo

۞ وَيَا قَوْمِ مَا لِي أَدْعُوكُمْ إِلَى النَّجَاةِ وَتَدْعُونَنِي إِلَى النَّارِ(41)

Eyin eniyan mi, ki lo mu yin ti mo n pe yin sibi igbala, ti eyin si n pe mi sibi Ina

تَدْعُونَنِي لِأَكْفُرَ بِاللَّهِ وَأُشْرِكَ بِهِ مَا لَيْسَ لِي بِهِ عِلْمٌ وَأَنَا أَدْعُوكُمْ إِلَى الْعَزِيزِ الْغَفَّارِ(42)

E n pe mi pe ki ng sai gbagbo ninu Allahu, ki ng si so nnkan ti emi ko nimo nipa re di akegbe fun Un. Emi si n pe yin si odo Alagbara, Alaforijin

لَا جَرَمَ أَنَّمَا تَدْعُونَنِي إِلَيْهِ لَيْسَ لَهُ دَعْوَةٌ فِي الدُّنْيَا وَلَا فِي الْآخِرَةِ وَأَنَّ مَرَدَّنَا إِلَى اللَّهِ وَأَنَّ الْمُسْرِفِينَ هُمْ أَصْحَابُ النَّارِ(43)

Laisi tabi-sugbon, dajudaju nnkan ti e n pe mi si, ko ni eto si ipe kan ni aye ati ni orun. Ati pe dajudaju odo Allahu ni abo wa. Dajudaju awon olutayo-enu-ala, awon ni ero inu Ina

فَسَتَذْكُرُونَ مَا أَقُولُ لَكُمْ ۚ وَأُفَوِّضُ أَمْرِي إِلَى اللَّهِ ۚ إِنَّ اللَّهَ بَصِيرٌ بِالْعِبَادِ(44)

Nitori naa, e maa ranti ohun ti mo n so fun yin. Mo si n fi oro mi ti si odo Allahu. Dajudaju Allahu ni Oluriran nipa awon erusin

فَوَقَاهُ اللَّهُ سَيِّئَاتِ مَا مَكَرُوا ۖ وَحَاقَ بِآلِ فِرْعَوْنَ سُوءُ الْعَذَابِ(45)

Allahu si so o nibi awon aburu ti won dete re. Iya buruku si yi awon eniyan Fir‘aon po

النَّارُ يُعْرَضُونَ عَلَيْهَا غُدُوًّا وَعَشِيًّا ۖ وَيَوْمَ تَقُومُ السَّاعَةُ أَدْخِلُوا آلَ فِرْعَوْنَ أَشَدَّ الْعَذَابِ(46)

Ina ni Won yoo maa seri won si ni owuro ati ni asale. Ati pe ni ojo ti Akoko naa ba de (A maa so pe): "E mu awon eniyan Fir‘aon wo inu iya Ina t’o le julo

وَإِذْ يَتَحَاجُّونَ فِي النَّارِ فَيَقُولُ الضُّعَفَاءُ لِلَّذِينَ اسْتَكْبَرُوا إِنَّا كُنَّا لَكُمْ تَبَعًا فَهَلْ أَنتُم مُّغْنُونَ عَنَّا نَصِيبًا مِّنَ النَّارِ(47)

(Ranti) nigba ti won ba n ba ara won se ariyanjiyan ninu Ina. Awon ole yoo wi fun awon ti won segberaga pe: “Dajudaju awa je omoleyin fun yin, nje eyin le gbe ipin kan kuro fun wa ninu iya Ina?”

قَالَ الَّذِينَ اسْتَكْبَرُوا إِنَّا كُلٌّ فِيهَا إِنَّ اللَّهَ قَدْ حَكَمَ بَيْنَ الْعِبَادِ(48)

Awon t’o segberaga wi pe: "Dajudaju gbogbo wa l’a wa ninu re.” Dajudaju Allahu kuku ti dajo laaarin awon eru naa

وَقَالَ الَّذِينَ فِي النَّارِ لِخَزَنَةِ جَهَنَّمَ ادْعُوا رَبَّكُمْ يُخَفِّفْ عَنَّا يَوْمًا مِّنَ الْعَذَابِ(49)

Awon t’o wa ninu Ina tun wi fun awon eso-Ina pe: "E ba wa pe Oluwa yin, ki O se iya ni fifuye fun wa fun ojo kan

قَالُوا أَوَلَمْ تَكُ تَأْتِيكُمْ رُسُلُكُم بِالْبَيِّنَاتِ ۖ قَالُوا بَلَىٰ ۚ قَالُوا فَادْعُوا ۗ وَمَا دُعَاءُ الْكَافِرِينَ إِلَّا فِي ضَلَالٍ(50)

Won yoo so pe: "Nje awon Ojise yin ki i mu awon eri t’o yanju wa ba yin bi?" Won wi pe: “Rara, (won n mu un wa).” Won so pe: “E sadua wo.” Adua awon alaigbagbo ko si je kini kan bi ko se sinu isina. ona wo ni awon alaigbagbo n gba ri oore laye? Ko si oore aye kan ti o le te alaigbagbo lowo bi ko se ipin re ninu kadara. Amo ni ti onigbagbo ododo oore inu kadara ati oore adua l’o wa fun un niwon igba ti adua re ba ti ba sunnah Anabi (sollalahu alayhi wa sallam) mu

إِنَّا لَنَنصُرُ رُسُلَنَا وَالَّذِينَ آمَنُوا فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَيَوْمَ يَقُومُ الْأَشْهَادُ(51)

Dajudaju Awa kuku maa saranse fun awon Ojise Wa ati awon t’o gbagbo ni ododo ninu igbesi aye yii ati ni ojo ti awon elerii yo dide (ni Ojo Ajinde)

يَوْمَ لَا يَنفَعُ الظَّالِمِينَ مَعْذِرَتُهُمْ ۖ وَلَهُمُ اللَّعْنَةُ وَلَهُمْ سُوءُ الدَّارِ(52)

Ni ojo ti awawi awon alabosi ko nii se won ni anfaani; egun n be fun won, ile (iya) buruku si wa fun won

وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَى الْهُدَىٰ وَأَوْرَثْنَا بَنِي إِسْرَائِيلَ الْكِتَابَ(53)

Dajudaju A fun (Anabi) Musa ni imona. A si jogun Tira fun awon omo ’Isro’il

هُدًى وَذِكْرَىٰ لِأُولِي الْأَلْبَابِ(54)

(O je) imona ati iranti fun awon onilaakaye

فَاصْبِرْ إِنَّ وَعْدَ اللَّهِ حَقٌّ وَاسْتَغْفِرْ لِذَنبِكَ وَسَبِّحْ بِحَمْدِ رَبِّكَ بِالْعَشِيِّ وَالْإِبْكَارِ(55)

Nitori naa, se suuru. Dajudaju adehun Allahu ni ododo. Toro aforijin fun ese re. Ki o si se afomo pelu idupe fun Oluwa re ni asale ati ni owuro kutukutu. awon ti Anabi Muhammad (sollalahu alayhi wa sallam) tu sile wonyi awon ni olori awon osebo ninu ilu Mokkah. Won si ti pa awon musulumi kan nipakupa siwaju ki owo to te awon naa loju ogun Badr. Amo ohun ti Anabi Muhammad (sollalahu alayhi wa sallam) ro t’o fi tu won sile ni pe ‘O gba iyawo lowo omo re o si fi saya!’. Oro ko si ri bee nitori pe a o gbodo foju bin-intin wo eyikeyii asise tabi ese. A gbodo kun fun titoro aforijin ni lodo Allahu Alaforijin. Ko si ohun t’o dara to riri aforijin gba lodo Allahu lori gbogbo asise wa siwaju ojo iku wa

إِنَّ الَّذِينَ يُجَادِلُونَ فِي آيَاتِ اللَّهِ بِغَيْرِ سُلْطَانٍ أَتَاهُمْ ۙ إِن فِي صُدُورِهِمْ إِلَّا كِبْرٌ مَّا هُم بِبَالِغِيهِ ۚ فَاسْتَعِذْ بِاللَّهِ ۖ إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْبَصِيرُ(56)

Dajudaju awon t’o n jiyan nipa awon ayah Allahu laini eri kan (lowo) ti o wa ba won (lati odo Allahu), ko si kini kan ninu igba-aya won ayafi okan-giga. Won ko si le de ibi giga (pelu okan giga). Nitori naa, sa di Allahu. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugbo, Oluriran

لَخَلْقُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ أَكْبَرُ مِنْ خَلْقِ النَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ(57)

Dajudaju iseda awon sanmo ati ile tobi ju iseda awon eniyan; sugbon opolopo awon eniyan ni ko mo

وَمَا يَسْتَوِي الْأَعْمَىٰ وَالْبَصِيرُ وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ وَلَا الْمُسِيءُ ۚ قَلِيلًا مَّا تَتَذَكَّرُونَ(58)

Afoju ati oluriran ko dogba. Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere ati onise-aburu (ko dogba). Die l’e n lo ninu iranti

إِنَّ السَّاعَةَ لَآتِيَةٌ لَّا رَيْبَ فِيهَا وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يُؤْمِنُونَ(59)

Dajudaju Akoko naa n bo, ko si si iyemeji ninu re. Sugbon opolopo awon eniyan ni ko gbagbo

وَقَالَ رَبُّكُمُ ادْعُونِي أَسْتَجِبْ لَكُمْ ۚ إِنَّ الَّذِينَ يَسْتَكْبِرُونَ عَنْ عِبَادَتِي سَيَدْخُلُونَ جَهَنَّمَ دَاخِرِينَ(60)

Oluwa yin so pe: "E pe Mi, ki Ng jepe yin. Dajudaju awon t’o n segberaga nipa jijosin fun Mi, won yoo wo inu ina Jahanamo ni eni yepere

اللَّهُ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ اللَّيْلَ لِتَسْكُنُوا فِيهِ وَالنَّهَارَ مُبْصِرًا ۚ إِنَّ اللَّهَ لَذُو فَضْلٍ عَلَى النَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَشْكُرُونَ(61)

Allahu ni Eni ti O se oru fun yin nitori ki e le sinmi ninu re. (O si se) osan (nitori ki e le fi) riran. Dajudaju Allahu ni Olola-julo lori awon eniyan, sugbon opolopo awon eniyan ki i dupe (fun Un)

ذَٰلِكُمُ اللَّهُ رَبُّكُمْ خَالِقُ كُلِّ شَيْءٍ لَّا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ فَأَنَّىٰ تُؤْفَكُونَ(62)

Iyen ni Allahu, Oluwa yin, Eledaa gbogbo nnkan. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, bawo ni won se n se yin lori kuro nibi ododo

كَذَٰلِكَ يُؤْفَكُ الَّذِينَ كَانُوا بِآيَاتِ اللَّهِ يَجْحَدُونَ(63)

Bayen naa ni won se n se awon t’o n tako awon ayah Allahu lori kuro nibi ododo (siwaju tiwon)

اللَّهُ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الْأَرْضَ قَرَارًا وَالسَّمَاءَ بِنَاءً وَصَوَّرَكُمْ فَأَحْسَنَ صُوَرَكُمْ وَرَزَقَكُم مِّنَ الطَّيِّبَاتِ ۚ ذَٰلِكُمُ اللَّهُ رَبُّكُمْ ۖ فَتَبَارَكَ اللَّهُ رَبُّ الْعَالَمِينَ(64)

Allahu ni Eni ti O se ile fun yin ni ibugbe. O mo sanmo (le yin lori). O ya aworan yin. O si ya aworan yin daradara. O pese arisiki fun yin ninu awon nnkan daadaa. Iyen ni Allahu, Oluwa yin. Nitori naa, mimo ni fun Allahu, Oluwa gbogbo eda

هُوَ الْحَيُّ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ فَادْعُوهُ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ ۗ الْحَمْدُ لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ(65)

Oun ni Alaaye. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, e pe E ni ti olusafomo-esin fun Un. Gbogbo ope n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda

۞ قُلْ إِنِّي نُهِيتُ أَنْ أَعْبُدَ الَّذِينَ تَدْعُونَ مِن دُونِ اللَّهِ لَمَّا جَاءَنِيَ الْبَيِّنَاتُ مِن رَّبِّي وَأُمِرْتُ أَنْ أُسْلِمَ لِرَبِّ الْعَالَمِينَ(66)

So pe: "Dajudaju Won ko fun mi pe ki ng josin fun awon ti e n pe leyin Allahu, nigba ti awon eri t’o yanju ti de ba mi lati odo Oluwa mi, ti won si pa mi ni ase pe ki ng juwo juse sile (ki ng je musulumi) fun Oluwa gbogbo eda

هُوَ الَّذِي خَلَقَكُم مِّن تُرَابٍ ثُمَّ مِن نُّطْفَةٍ ثُمَّ مِنْ عَلَقَةٍ ثُمَّ يُخْرِجُكُمْ طِفْلًا ثُمَّ لِتَبْلُغُوا أَشُدَّكُمْ ثُمَّ لِتَكُونُوا شُيُوخًا ۚ وَمِنكُم مَّن يُتَوَفَّىٰ مِن قَبْلُ ۖ وَلِتَبْلُغُوا أَجَلًا مُّسَمًّى وَلَعَلَّكُمْ تَعْقِلُونَ(67)

Oun ni Eni ti O seda yin lati inu erupe, leyin naa lati inu ato, leyin naa lati inu eje didi, leyin naa O mu yin jade ni oponlo. Leyin naa, (O da yin si) nitori ki e le sanngun dopin agbara yin. Leyin naa (O tun da yin si) nitori ki e le di agbalagba. O wa ninu yin eni ti A oo ti gba emi re siwaju (ipo agba). Ati pe (O da yin si) nitori ki e le dagba de gbedeke akoko kan ati nitori ki e le se laakaye

هُوَ الَّذِي يُحْيِي وَيُمِيتُ ۖ فَإِذَا قَضَىٰ أَمْرًا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُ كُن فَيَكُونُ(68)

Oun ni Eni ti n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Nigba ti O ba si pebubu kini kan, O kan maa so fun un pe: "Je bee." O si maa je bee

أَلَمْ تَرَ إِلَى الَّذِينَ يُجَادِلُونَ فِي آيَاتِ اللَّهِ أَنَّىٰ يُصْرَفُونَ(69)

Se o o ri awon ti n sariyanjiyan nipa awon ayah Allahu bi won se n seri won kuro nibi ododo

الَّذِينَ كَذَّبُوا بِالْكِتَابِ وَبِمَا أَرْسَلْنَا بِهِ رُسُلَنَا ۖ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ(70)

Awon t’o pe Tira naa ati ohun ti A fi ran awon Ojise Wa niro, laipe won maa mo

إِذِ الْأَغْلَالُ فِي أَعْنَاقِهِمْ وَالسَّلَاسِلُ يُسْحَبُونَ(71)

Nigba ti awon sekeseke ati ewon ba wa ni orun won, ti won yoo fi maa wo won

فِي الْحَمِيمِ ثُمَّ فِي النَّارِ يُسْجَرُونَ(72)

sinu omi gbigbona. Leyin naa, won yoo fi won ko Ina

ثُمَّ قِيلَ لَهُمْ أَيْنَ مَا كُنتُمْ تُشْرِكُونَ(73)

Leyin naa, Won maa so fun won pe: "Ibo ni ohun ti e so di orisa wa

مِن دُونِ اللَّهِ ۖ قَالُوا ضَلُّوا عَنَّا بَل لَّمْ نَكُن نَّدْعُو مِن قَبْلُ شَيْئًا ۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ اللَّهُ الْكَافِرِينَ(74)

(Ohun ti e josin fun) leyin Allahu (da)?" Won a wi pe: "Won ti di ofo mo wa lowo. Bee tie ko, awa ki i pe nnkan kan teletele." Bayen ni Allahu se n si awon alaigbagbo lona

ذَٰلِكُم بِمَا كُنتُمْ تَفْرَحُونَ فِي الْأَرْضِ بِغَيْرِ الْحَقِّ وَبِمَا كُنتُمْ تَمْرَحُونَ(75)

Iyen nitori pe e n yo lori ile lai letoo ati nitori pe e n se faari (lori aigbagbo)

ادْخُلُوا أَبْوَابَ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا ۖ فَبِئْسَ مَثْوَى الْمُتَكَبِّرِينَ(76)

E wo awon enu ona ina Jahanamo; olusegbere ni won ninu re. O si buru ni ibugbe fun awon onigbeeraga

فَاصْبِرْ إِنَّ وَعْدَ اللَّهِ حَقٌّ ۚ فَإِمَّا نُرِيَنَّكَ بَعْضَ الَّذِي نَعِدُهُمْ أَوْ نَتَوَفَّيَنَّكَ فَإِلَيْنَا يُرْجَعُونَ(77)

Nitori naa, se suuru. Dajudaju adehun Allahu ni ododo. O see se ki A fi apa kan eyi ti A se ni ileri fun won han o tabi ki A ti gba emi re (siwaju asiko naa). Odo Wa kuku ni won maa da won pada si

وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا رُسُلًا مِّن قَبْلِكَ مِنْهُم مَّن قَصَصْنَا عَلَيْكَ وَمِنْهُم مَّن لَّمْ نَقْصُصْ عَلَيْكَ ۗ وَمَا كَانَ لِرَسُولٍ أَن يَأْتِيَ بِآيَةٍ إِلَّا بِإِذْنِ اللَّهِ ۚ فَإِذَا جَاءَ أَمْرُ اللَّهِ قُضِيَ بِالْحَقِّ وَخَسِرَ هُنَالِكَ الْمُبْطِلُونَ(78)

Ati pe A kuku ti ran awon Ojise nise siwaju re. Awon ti A so itan won fun o wa ninu won. Awon ti A o si so itan won fun o wa ninu won. Ati pe ko to fun Ojise kan lati mu ami kan wa afi pelu iyonda Allahu. Nigba ti ase Allahu ba si de, A maa fi ododo dajo. Awon opuro si maa sofo danu nibe yen

اللَّهُ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الْأَنْعَامَ لِتَرْكَبُوا مِنْهَا وَمِنْهَا تَأْكُلُونَ(79)

Allahu ni Eni ti O da awon eran-osin fun yin nitori ki e le maa gun ninu won. E o si maa je ninu won

وَلَكُمْ فِيهَا مَنَافِعُ وَلِتَبْلُغُوا عَلَيْهَا حَاجَةً فِي صُدُورِكُمْ وَعَلَيْهَا وَعَلَى الْفُلْكِ تُحْمَلُونَ(80)

Awon anfaani (miiran) wa fun yin lara eran-osin. Ati nitori ki e le de ona jijin t’o wa lokan yin lori (gigun) won (kiri). E o si maa fi awon (eran-osin) ati oko oju-omi gbe awon eru

وَيُرِيكُمْ آيَاتِهِ فَأَيَّ آيَاتِ اللَّهِ تُنكِرُونَ(81)

(Allahu) n fi awon ami Re han yin. Nitori naa, ewo ninu awon ami Allahu l’e maa tako

أَفَلَمْ يَسِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَيَنظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۚ كَانُوا أَكْثَرَ مِنْهُمْ وَأَشَدَّ قُوَّةً وَآثَارًا فِي الْأَرْضِ فَمَا أَغْنَىٰ عَنْهُم مَّا كَانُوا يَكْسِبُونَ(82)

Se won ko rin kiri lori ile ki won wo bi ikangun awon t’o siwaju won se ri? Won po (ni onka) ju won lo. Won ni agbara ju won lo. Won si lo ile (fun oko dida ju won lo). Sibesibe ohun ti won n se nise ko ro won loro (nibi iya)

فَلَمَّا جَاءَتْهُمْ رُسُلُهُم بِالْبَيِّنَاتِ فَرِحُوا بِمَا عِندَهُم مِّنَ الْعِلْمِ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ(83)

Nigba ti awon Ojise mu awon eri t’o yanju wa ba won, won yo ayoporo nitori ohun t’o wa lodo won ninu imo (aye). Ohun ti won si n fi se yeye si diya t’o yi won po

فَلَمَّا رَأَوْا بَأْسَنَا قَالُوا آمَنَّا بِاللَّهِ وَحْدَهُ وَكَفَرْنَا بِمَا كُنَّا بِهِ مُشْرِكِينَ(84)

Nigba ti won ri iya Wa, won wi pe: "A gbagbo ninu Allahu, Oun nikan soso. A si lodi si nnkan ti a so di akegbe fun Un

فَلَمْ يَكُ يَنفَعُهُمْ إِيمَانُهُمْ لَمَّا رَأَوْا بَأْسَنَا ۖ سُنَّتَ اللَّهِ الَّتِي قَدْ خَلَتْ فِي عِبَادِهِ ۖ وَخَسِرَ هُنَالِكَ الْكَافِرُونَ(85)

Igbagbo won ko se won ni anfaani nigba ti won ri iya Wa. Ise Allahu, eyi ti o ti sele siwaju si awon eru Re (ni eyi). Awon alaigbagbo si sofo danu nibe yen


المزيد من السور باللغة اليوربا:

سورة البقرة آل عمران سورة النساء
سورة المائدة سورة يوسف سورة ابراهيم
سورة الحجر سورة الكهف سورة مريم
سورة السجدة سورة يس سورة الدخان
سورة النجم سورة الرحمن سورة الواقعة
سورة الحشر سورة الملك سورة الحاقة

تحميل سورة غافر بصوت أشهر القراء :

قم باختيار القارئ للاستماع و تحميل سورة غافر كاملة بجودة عالية
سورة غافر أحمد العجمي
أحمد العجمي
سورة غافر خالد الجليل
خالد الجليل
سورة غافر سعد الغامدي
سعد الغامدي
سورة غافر سعود الشريم
سعود الشريم
سورة غافر عبد الباسط عبد الصمد
عبد الباسط
سورة غافر عبد الله عواد الجهني
عبد الله الجهني
سورة غافر علي الحذيفي
علي الحذيفي
سورة غافر فارس عباد
فارس عباد
سورة غافر ماهر المعيقلي
ماهر المعيقلي
سورة غافر محمد جبريل
محمد جبريل
سورة غافر محمد صديق المنشاوي
المنشاوي
سورة غافر الحصري
الحصري
سورة غافر العفاسي
مشاري العفاسي
سورة غافر ناصر القطامي
ناصر القطامي
سورة غافر ياسر الدوسري
ياسر الدوسري



Saturday, May 4, 2024

لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب