La sourate At-Talaq en Yoruba
Iwo Anabi, nigba ti e ba fe ko awon obinrin sile, e ko won sile pelu sise onka ojo opo fun ikosile won. Ki e si so onka ojo opo. Ki e beru Allahu, Oluwa yin. E ma se mu won jade kuro ninu ile won, awon naa ko si gbodo jade afi ti won ba lo se ibaje t’o foju han. Iwonyen si ni awon enu-ala ti Allahu gbekale. Enikeni ti o ba tayo awon enu-ala ti Allahu gbekale, o kuku ti sabosi si emi ara re. Iwo ko si mo boya Allahu maa mu oro titun sele leyin iyen |
Nigba ti won ba fe pari onka ojo opo won, e mu won modo ni ona t’o dara tabi ki e ko won sile ni ona t’o dara. E fi awon onideede meji ninu yin jerii si i. Ki e si gbe ijerii naa duro ni titori ti Allahu. Iyen ni A n fi se waasi fun enikeni ti o ba ni igbagbo ododo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Enikeni ti o ba n beru Allahu, O maa fun un ni ona abayo (ninu isoro) |
O si maa pese fun un ni aye ti ko ti rokan. Ati pe enikeni ti o ba gbekele Allahu, O maa to o. Dajudaju Allahu yoo mu oro Re de opin. Dajudaju Allahu ti ko odiwon akoko fun gbogbo nnkan |
Awon obinrin t’o ti soreti nu nipa nnkan osu sise ninu awon obinrin yin, ti e ba seyemeji, onka ojo ikosile won ni osu meta. (Bee naa ni fun) awon ti ko ti i maa se nnkan osu. Awon oloyun, ipari onka ojo opo ikosile tiwon ni pe ki won bi oyun inu won. Enikeni ti o ba n beru Allahu, O maa se oro re ni irorun |
Iyen ni ase Allahu, ti O sokale fun yin. Enikeni ti o ba n beru Allahu, O maa pa awon asise re re. O si maa je ki esan re tobi |
E fun won ni ibugbe ninu ibugbe yin bi aye se gba yin mo. E ma se ni won lara lati ko ifunpinpin ba won. Ti won ba je oloyun, e nawo le won lori titi won yoo fi bi oyun inu won. Ti won ba n fun omo yin ni oyan mu, e fun won ni owo-oya won. E damoran laaarin ara yin ni ona t’o dara. Ti oro ko ba si rogbo laaarin ara yin, ki elomiiran ba oko (fun omo) ni oyan mu |
Ki oloro na ninu oro re. Eni ti A si diwon arisiki re fun (niwonba), ki o na ninu ohun ti Allahu fun un. Allahu ko labo emi kan lorun ayafi nnkan ti O fun un. Allahu yo si mu irorun wa leyin inira |
Meloo meloo ninu awon ilu ti won yapa ase Oluwa Re ati awon Ojise Re. A si maa siro ise won ni isiro lile. Ati pe A maa je won niya t’o buru gan-an |
فَذَاقَتْ وَبَالَ أَمْرِهَا وَكَانَ عَاقِبَةُ أَمْرِهَا خُسْرًا(9) Nitori naa, won to iya oran won wo. Ikangun oro won si je ofo |
Allahu ti pese iya lile sile de won. Nitori naa, e beru Allahu, eyin onilaakaye ti e gbagbo ni ododo. Allahu kuku ti so iranti kale fun yin |
Ojise kan ti o maa ke awon ayah Allahu t’o yanju fun yin nitori ki o le mu awon t’o gbagbo ni ododo, ti won tun se awon ise rere, kuro ninu awon okunkun lo sinu imole. Enikeni ti o ba gba Allahu gbo ni ododo, ti o si n se ise rere, O maa mu un wo inu awon Ogba Idera, ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Dajudaju Allahu ti se arisiki t’o dara julo fun un |
Allahu ni Eni ti O seda awon sanmo meje ati ile ni (onka) iru re. Ase n sokale laaarin won nitori ki e le mo pe dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan. Ati pe dajudaju Allahu fi imo rogba yi gbogbo nnkan ka |
Plus de sourates en Yoruba :
Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :
Téléchargez le fichier mp3 de la sourate At-Talaq : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate At-Talaq complète en haute qualité.















Donnez-nous une invitation valide