La sourate Adh-Dhariyat en Yoruba
(Allahu bura pelu) ategun t’o n tu erupe jade nile taara |
(O bura pelu) awon esujo t’o wuwo rinrin |
(O bura pelu) awon oko oju-omi t’o n rin pelu irorun |
(O bura pelu) awon molaika t’o n pin nnkan (ti O ti pin fun eda) |
Ododo ma ni ohun ti A n se ni adehun fun yin |
Ati pe dajudaju Ojo Esan maa sele |
(Allahu tun bura pelu) sanmo olosoo |
Dajudaju eyin wa lori oro t’o n takora won (nipa al-Ƙur’an) |
Eni ti won n se lori kuro nibi al-Ƙur’an ni eni ti Won ti se lori kuro nibe (lati inu Laohul-Mahfuth) |
Egbe ni fun awon opuro |
awon ni won wa ninu aimokan, awon onigbagbe |
ti won n beere igba ti Ojo Esan maa sele |
Ni ojo naa si ni won yoo maa fi Ina je won niya |
ذُوقُوا فِتْنَتَكُمْ هَٰذَا الَّذِي كُنتُم بِهِ تَسْتَعْجِلُونَ(14) E to iya yin wo. Eyi ni nnkan ti e ti n wa pelu ikanju |
Dajudaju awon oluberu (Allahu) yoo wa ninu awon Ogba Idera pelu awon omi odo (ni isale re) |
آخِذِينَ مَا آتَاهُمْ رَبُّهُمْ ۚ إِنَّهُمْ كَانُوا قَبْلَ ذَٰلِكَ مُحْسِنِينَ(16) Won yoo maa gba nnkan ti Oluwa won ba fun won. Dajudaju won ti je oluse-rere siwaju iyen |
Won maa n sun oorun die ninu oru |
Won maa n toro aforijin ni afemojumo |
Ninu dukia won, won ni ojuse ti won n se fun alagbe ati eni ti A se arisiki ni eewo fun |
Awon ami wa ni ori ile fun awon alamodaju |
Ninu emi ara yin gan-an (ami iyanu wa ninu re). Se e o riran ni |
Arisiki yin ati ohun ti A n se ni adehun fun yin wa ninu sanmo |
فَوَرَبِّ السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ إِنَّهُ لَحَقٌّ مِّثْلَ مَا أَنَّكُمْ تَنطِقُونَ(23) Nitori naa, Mo fi Oluwa sanmo ati ile bura, dajudaju ododo ni (oro naa) gege bi o se je ododo pe e n fenu soro |
Nje oro awon alejo (Anabi) ’Ibrohim, awon alapon-onle, ti de odo re |
إِذْ دَخَلُوا عَلَيْهِ فَقَالُوا سَلَامًا ۖ قَالَ سَلَامٌ قَوْمٌ مُّنكَرُونَ(25) (Ranti) nigba ti won wole to o wa, won si so pe: "Alaafia (fun o)." Oun naa so pe: "Alaafia (fun yin), eyin ajoji eniyan |
O lo si odo awon ara ile re, o si de pelu omo maalu oloraa (ayangbe) |
O gbe e sunmo odo won. O si so pe: "Se e o nii jeun ni |
فَأَوْجَسَ مِنْهُمْ خِيفَةً ۖ قَالُوا لَا تَخَفْ ۖ وَبَشَّرُوهُ بِغُلَامٍ عَلِيمٍ(28) Nigba naa, o ni ipaya won ninu okan. Won so pe: "Ma se paya." Won si fun un ni iro idunnu nipa bibi omokunrin onimo kan |
فَأَقْبَلَتِ امْرَأَتُهُ فِي صَرَّةٍ فَصَكَّتْ وَجْهَهَا وَقَالَتْ عَجُوزٌ عَقِيمٌ(29) Nigba naa, iyawo re si bere igbe, o si gbara re loju, o so pe: "Arugbo, agan (ma ni mi) |
قَالُوا كَذَٰلِكِ قَالَ رَبُّكِ ۖ إِنَّهُ هُوَ الْحَكِيمُ الْعَلِيمُ(30) Won so pe: "Bayen ni Oluwa re so. Dajudaju Oun ni Ologbon, Onimo |
(Anabi ’Ibrohim) so pe: "Ki tun ni oro ti e ba wa, eyin Ojise |
Won so pe: "Dajudaju Won ran wa nise si ijo elese ni |
nitori ki a le fi okuta amo (sisun) ranse si won |
Won ti fami si i lara lodo Oluwa re fun awon alakoyo |
Nitori naa, A mu awon t’o je onigbagbo ododo jade kuro ninu (ilu naa) |
فَمَا وَجَدْنَا فِيهَا غَيْرَ بَيْتٍ مِّنَ الْمُسْلِمِينَ(36) A o si ri ninu (ilu naa) tayo ile kan t’o je ti awon musulumi |
وَتَرَكْنَا فِيهَا آيَةً لِّلَّذِينَ يَخَافُونَ الْعَذَابَ الْأَلِيمَ(37) A si fi ami kan sile ninu (ilu naa) fun awon t’o n paya iya eleta-elero |
وَفِي مُوسَىٰ إِذْ أَرْسَلْنَاهُ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ بِسُلْطَانٍ مُّبِينٍ(38) (Ami tun wa) lara (Anabi) Musa. Nigba ti A fi eri ponnbele ran an nise si Fir‘aon |
Sugbon (Fir‘aon) gbunri pelu awon omo ogun re. O si wi pe: "Opidan tabi were kan (niyi) |
فَأَخَذْنَاهُ وَجُنُودَهُ فَنَبَذْنَاهُمْ فِي الْيَمِّ وَهُوَ مُلِيمٌ(40) Nitori naa, A mu oun ati awon omo ogun re. A si ju won sinu agbami odo nigba ti o je alabuku |
وَفِي عَادٍ إِذْ أَرْسَلْنَا عَلَيْهِمُ الرِّيحَ الْعَقِيمَ(41) (Ami tun wa) lara ijo ‘Ad. (Ranti) nigba ti A ran ategun iparun si won |
مَا تَذَرُ مِن شَيْءٍ أَتَتْ عَلَيْهِ إِلَّا جَعَلَتْهُ كَالرَّمِيمِ(42) ko fi kini kan to fe si lara sile bee afi ko so o di bi eso rirun tuutu |
وَفِي ثَمُودَ إِذْ قِيلَ لَهُمْ تَمَتَّعُوا حَتَّىٰ حِينٍ(43) (Ami tun wa) lara ijo Thamud. (Ranti) nigba ti A so fun won pe: "E jaye fun igba die na |
فَعَتَوْا عَنْ أَمْرِ رَبِّهِمْ فَأَخَذَتْهُمُ الصَّاعِقَةُ وَهُمْ يَنظُرُونَ(44) Won segberaga si ase Oluwa won. Nitori naa, igbe iparun mu won; won si n wo boo |
فَمَا اسْتَطَاعُوا مِن قِيَامٍ وَمَا كَانُوا مُنتَصِرِينَ(45) Won ko le dide naro. Won ko si le ran ara won lowo |
وَقَوْمَ نُوحٍ مِّن قَبْلُ ۖ إِنَّهُمْ كَانُوا قَوْمًا فَاسِقِينَ(46) Ati ijo Nuh ti o siwaju (won), dajudaju Awa si ni olugbooro |
وَالسَّمَاءَ بَنَيْنَاهَا بِأَيْدٍ وَإِنَّا لَمُوسِعُونَ(47) Ati pe sanmo, A mo on (si oke yin) pelu agbara. Dajudaju Awa si ni olugbooro |
Ati ile, A se e ni ite. Awon olutele-sile si dara |
وَمِن كُلِّ شَيْءٍ خَلَقْنَا زَوْجَيْنِ لَعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ(49) Ati pe gbogbo nnkan ni A seda ni orisi meji-meji nitori ki e le lo iranti |
فَفِرُّوا إِلَى اللَّهِ ۖ إِنِّي لَكُم مِّنْهُ نَذِيرٌ مُّبِينٌ(50) Nitori naa, e sa lo si odo Allahu (nipa ironupiwada). Dajudaju emi ni olukilo ponnbele fun yin lati odo Re |
وَلَا تَجْعَلُوا مَعَ اللَّهِ إِلَٰهًا آخَرَ ۖ إِنِّي لَكُم مِّنْهُ نَذِيرٌ مُّبِينٌ(51) E ma se mu olohun miiran mo Allahu. Dajudaju emi ni olukilo ponnbele fun yin lati odo Re |
كَذَٰلِكَ مَا أَتَى الَّذِينَ مِن قَبْلِهِم مِّن رَّسُولٍ إِلَّا قَالُوا سَاحِرٌ أَوْ مَجْنُونٌ(52) Bayen ni (oro se ri)! Ojise kan ko wa ba awon t’o siwaju won afi ki won wi pe: "Opidan tabi were ni |
Se won so asoole nipa re laaarin ara won ni? Rara o! Ijo olutayo-enu-ala ni won ni |
Nitori naa, seri kuro lodo won na. Iwo ki i se alabuku |
Seranti nitori pe, dajudaju iranti maa wulo fun awon onigbagbo ododo |
Ati pe Emi ko seda alujannu ati eniyan bi ko se pe ki won le josin fun Mi |
مَا أُرِيدُ مِنْهُم مِّن رِّزْقٍ وَمَا أُرِيدُ أَن يُطْعِمُونِ(57) Emi ko gbero arisiki kan lati odo won. Emi ko si gbero pe ki won maa bo Mi |
إِنَّ اللَّهَ هُوَ الرَّزَّاقُ ذُو الْقُوَّةِ الْمَتِينُ(58) Dajudaju Allahu, Oun ni Olupese, Alagbara lile |
فَإِنَّ لِلَّذِينَ ظَلَمُوا ذَنُوبًا مِّثْلَ ذَنُوبِ أَصْحَابِهِمْ فَلَا يَسْتَعْجِلُونِ(59) Dajudaju ipin iya ti o maa je awon t’o sabosi (wonyi) ni iru ipin iya ti o je ijo elese (iru) won. Nitori naa, ki won ma se kan Mi loju (nipa iya won) |
فَوَيْلٌ لِّلَّذِينَ كَفَرُوا مِن يَوْمِهِمُ الَّذِي يُوعَدُونَ(60) Nitori naa, egbe ni fun awon t’o sai gbagbo ni ojo won ti A n se ni adehun fun won |
Plus de sourates en Yoruba :
Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :
Téléchargez le fichier mp3 de la sourate Adh-Dhariyat : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate Adh-Dhariyat complète en haute qualité.















Donnez-nous une invitation valide