Surah Ghafir with Yoruba
حم(1) Ha mim |
Tira naa sokale lati odo Allahu, Alagbara, Onimo |
Alaforijin-ese, Olugba-ironupiwada, Eni lile nibi iya, Olore, ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Odo Re ni abo eda |
Ko si eni ti o maa se atako si awon ayah Allahu afi awon t’o sai gbagbo. Nitori naa, ma se je ki igbokegbodo won ninu ilu ko etan ba o |
Ijo (Anabi) Nuh pe ododo niro siwaju won. Awon ijo (miiran) leyin won (naa se bee). Ijo kookan lo gbero lati ki Ojise won mole. Won fi iro ja ododo niyan nitori ki won le fi wo ododo lule. Mo si gba won mu. Nitori naa, bawo ni iya (ti mo fi je won) ti ri (lara won na) |
وَكَذَٰلِكَ حَقَّتْ كَلِمَتُ رَبِّكَ عَلَى الَّذِينَ كَفَرُوا أَنَّهُمْ أَصْحَابُ النَّارِ(6) Ati pe bayen ni oro Oluwa re se ko lori awon t’o sai gbagbo pe: "Dajudaju awon ni ero inu Ina |
Awon t’o gbe Ite-ola naa ru ati awon t’o wa ni ayika re, won n se afomo pelu idupe fun Oluwa won. Won gba Allahu gbo. Won si n toro aforijin fun awon t’o gbagbo ni ododo (bayii pe): "Oluwa wa, ike ati imo (Re) gbooro ju gbogbo nnkan lo, nitori naa, saforijin fun awon t’o ronu piwada, ti won si tele oju-ona Re. Ki O si so won ninu iya ina Jehim |
Oluwa wa, fi won sinu awon Ogba Idera ti O se ni adehun fun awon ati eni t’o se ise rere ninu awon baba won, awon aya won ati awon aromodomo won. Dajudaju Iwo ni Alagbara, Ologbon |
So won ninu awon aburu. Enikeni ti O ba so nibi awon aburu (iya) ni ojo yen, dajudaju O ti ke e. Iyen si ni erenje nla |
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, won yoo pe won (lati so fun won ninu Ina pe): " Dajudaju ibinu ti Allahu tobi ju ibinu ti e n bi sira yin (ninu Ina, sebi) nigba ti won n pe yin sibi igbagbo ododo, nse ni e n sai gbagbo |
Won wi pe: "Oluwa wa, O pa wa ni ee meji. O si ji wa ni ee meji. Nitori naa, a si jewo awon ese wa. Nje ona kan wa lati jade (pada si ile aye) bi |
(E wa ninu Ina) yen nitori pe dajudaju nigba ti won ba pe Allahu nikan soso, eyin sai gbagbo. Nigba ti won ba sebo si I, e si maa gbagbo (ninu ebo). Nitori naa, idajo n je ti Allahu, O ga, O tobi |
Oun ni Eni t’O n fi awon ami Re han yin. O si n so arisiki kale fun yin lati sanmo. Ko si eni t’o n lo iranti afi eni t’o n seri pada si odo Allahu (nipase ironupiwada) |
فَادْعُوا اللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ وَلَوْ كَرِهَ الْكَافِرُونَ(14) Nitori naa, e pe Allahu ni ti olusafomo-esin fun Un, awon alaigbagbo ibaa korira Re |
(Allahu) Eni t’O ni gbogbo ipo ajulo, Oluwa Ite-ola, O n fi imisi (al-Ƙur’an) ranse pelu ase Re si eni ti O fe ninu awon erusin Re nitori ki o le fi sekilo nipa Ojo ipade naa |
Ni ojo ti won yoo yo jade (lati inu saree), kini kan ko si nii pamo nipa won fun Allahu. (Allahu yo si so pe): "Ti ta ni ijoba ni ojo oni? Ti Allahu, Okan soso, Olubori ni |
Ni oni ni A oo san emi kookan ni esan ohun ti o se nise. Ko si si abosi kan ni oni. Dajudaju Allahu ni Oluyara nibi isiro-ise |
Ati pe sekilo ojo ti o sunmo fun won. Nigba ti awon okan ba ga de gogongo, ti o maa kun fun ibanuje, ko nii si ore imule ati olusipe kan ti won maa tele oro re lori (oro) awon alabosi |
(Allahu) mo oju ijanba ati ohun ti awon okan fi pamo |
Ati pe Allahu l’O maa fi ododo dajo. Awon ti won n pe leyin Re, won ko le se idajo kan kan. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugbo, Oluriran |
Se won ko rin kiri lori ile ki won wo bi ikangun awon t’o siwaju won se ri? Won ni agbara ju won lo. Won si lo ile (fun oko dida ju won lo). Sibesibe Allahu mu won nitori ese won. Ko si si oluso kan fun won (nibi iya) Allahu |
Iyen nitori pe awon Ojise won n wa ba won pelu awon eri t’o yanju, sugbon won sai gbagbo. Nitori naa, Allahu mu won. Dajudaju Oun ni Alagbara, Eni lile nibi iya |
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مُوسَىٰ بِآيَاتِنَا وَسُلْطَانٍ مُّبِينٍ(23) Dajudaju A fi awon ami Wa ati eri t’o yanju ran (Anabi) Musa nise |
إِلَىٰ فِرْعَوْنَ وَهَامَانَ وَقَارُونَ فَقَالُوا سَاحِرٌ كَذَّابٌ(24) si Fir‘aon, Hamon ati Ƙorun. Sugbon won wi pe: "Opidan, opuro ni (Anabi Musa) |
Nigba ti o mu ododo naa de odo won lati odo Wa, won wi pe: "E pa awon omokunrin awon t’o gbagbo pelu re, ki e si fi awon omobinrin won sile." Ete awon alaigbagbo ko si ninu kini kan bi ko se ninu ofo |
Fir‘aon wi pe: "E fi mi sile ki ng pa Musa, ki o si pe Oluwa re (wo boya O maa gba a sile). Dajudaju emi n beru pe o maa yi esin yin pada tabi pe o maa safi han ibaje lori ile |
(Anabi) Musa so pe: "Dajudaju emi sa di Oluwa mi ati Oluwa yin kuro lowo gbogbo onigbeeraga, ti ko gba Ojo isiro-ise gbo |
Okunrin onigbagbo ododo kan t’o n fi igbagbo re pamo ninu awon eniyan Fir‘aon so pe: "Se e maa pa okunrin kan nitori pe o n so pe, ‘Allahu ni Oluwa mi.’ O si kuku ti mu awon eri t’o yanju wa ba yin lati odo Oluwa yin. Ti o ba je opuro, (iya) iro re wa lori re. Ti o ba si je olododo, apa kan eyi ti o se ni ileri fun yin yo si ko le yin lori. Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo eni ti o je alaseju, opuro |
Eyin eniyan mi, eyin l’e ni ijoba lonii, eyin si ni alase lori ile naa. Sugbon ta ni o maa ran wa lowo ti iya Allahu ba de ba wa?" Fir‘aon wi pe: "Emi ko fi nnkan kan han yin bi ko se ohun ti mo ri (ninu oye mi). Emi ko si to yin si ona kan bi ko se oju ona imona |
وَقَالَ الَّذِي آمَنَ يَا قَوْمِ إِنِّي أَخَافُ عَلَيْكُم مِّثْلَ يَوْمِ الْأَحْزَابِ(30) Eni t’o gbagbo ni ododo tun so pe: "Eyin eniyan mi, dajudaju iru ojo (esan iya t’o sele si) awon omo-ogun onijo ni emi n paya lori yin |
Iru ise (iparun t’o sele si awon) eniyan Nuh, ‘Ad, Thamud ati awon t’o tele won. Allahu ko si gbero abosi si awon erusin naa |
وَيَا قَوْمِ إِنِّي أَخَافُ عَلَيْكُمْ يَوْمَ التَّنَادِ(32) Eyin eniyan mi, dajudaju emi n paya Ojo ipe fun yin |
Ojo ti e maa peyinda lati sa lo; ko si nii si alaabo kan fun yin lodo Allahu. Ati pe eni ti Allahu ba si lona, ko le si afinimona kan fun un |
Ati pe dajudaju (Anabi) Yusuf ti to yin wa siwaju pelu awon alaye oro t’o yanju, sugbon eyin ko ye wa ninu iyemeji nipa ohun ti o mu wa ba yin titi di igba ti o fi ku, ti e fi wi pe: "Allahu ko nii gbe Ojise kan dide mo leyin re." Bayen ni Allahu se n so eni ti o je alaseju, oniyemeji nu |
Awon t’o n jiyan nipa awon ayah Allahu laisi eri kan ti o de ba won. Ese nla si ni ni odo Allahu ati ni odo awon t’o gbagbo ni ododo. Bayen ni Allahu se n fi edidi bo gbogbo okan onigbeeraga, ajeninipa.” |
وَقَالَ فِرْعَوْنُ يَا هَامَانُ ابْنِ لِي صَرْحًا لَّعَلِّي أَبْلُغُ الْأَسْبَابَ(36) Fir‘aon wi pe: "Hamon, mo ile giga fiofio kan fun mi nitori ki emi le de awon oju ona naa |
Awon oju ona (inu) sanmo ni, nitori ki emi le yoju wo Olohun Musa nitori pe dajudaju emi n ro o si opuro." Bayen ni won se ise aburu (owo) Fir‘aon ni oso fun un. Won si seri re kuro loju ona (esin Allahu). Ete Fir‘aon ko si wa ninu kini kan bi ko se ninu ofo |
وَقَالَ الَّذِي آمَنَ يَا قَوْمِ اتَّبِعُونِ أَهْدِكُمْ سَبِيلَ الرَّشَادِ(38) Eni t’o gbagbo ni ododo tun so pe: "Eyin eniyan mi, e tele mi, mo maa juwe yin si oju ona imona |
يَا قَوْمِ إِنَّمَا هَٰذِهِ الْحَيَاةُ الدُّنْيَا مَتَاعٌ وَإِنَّ الْآخِرَةَ هِيَ دَارُ الْقَرَارِ(39) Eyin eniyan mi, isemi ile aye yii je igbadun lasan. Dajudaju orun si ni ile gbere |
Eni ti o ba se aburu kan, Won ko nii san an ni esan kan ayafi iru re. Eni ti o ba si se ise rere ni okunrin tabi ni obinrin, ti o si je onigbagbo ododo, awon wonyen ni won maa wo inu Ogba Idera. Won yoo maa pese arisiki fun won ninu re lai la isiro lo |
۞ وَيَا قَوْمِ مَا لِي أَدْعُوكُمْ إِلَى النَّجَاةِ وَتَدْعُونَنِي إِلَى النَّارِ(41) Eyin eniyan mi, ki lo mu yin ti mo n pe yin sibi igbala, ti eyin si n pe mi sibi Ina |
E n pe mi pe ki ng sai gbagbo ninu Allahu, ki ng si so nnkan ti emi ko nimo nipa re di akegbe fun Un. Emi si n pe yin si odo Alagbara, Alaforijin |
Laisi tabi-sugbon, dajudaju nnkan ti e n pe mi si, ko ni eto si ipe kan ni aye ati ni orun. Ati pe dajudaju odo Allahu ni abo wa. Dajudaju awon olutayo-enu-ala, awon ni ero inu Ina |
Nitori naa, e maa ranti ohun ti mo n so fun yin. Mo si n fi oro mi ti si odo Allahu. Dajudaju Allahu ni Oluriran nipa awon erusin |
فَوَقَاهُ اللَّهُ سَيِّئَاتِ مَا مَكَرُوا ۖ وَحَاقَ بِآلِ فِرْعَوْنَ سُوءُ الْعَذَابِ(45) Allahu si so o nibi awon aburu ti won dete re. Iya buruku si yi awon eniyan Fir‘aon po |
Ina ni Won yoo maa seri won si ni owuro ati ni asale. Ati pe ni ojo ti Akoko naa ba de (A maa so pe): "E mu awon eniyan Fir‘aon wo inu iya Ina t’o le julo |
(Ranti) nigba ti won ba n ba ara won se ariyanjiyan ninu Ina. Awon ole yoo wi fun awon ti won segberaga pe: “Dajudaju awa je omoleyin fun yin, nje eyin le gbe ipin kan kuro fun wa ninu iya Ina?” |
قَالَ الَّذِينَ اسْتَكْبَرُوا إِنَّا كُلٌّ فِيهَا إِنَّ اللَّهَ قَدْ حَكَمَ بَيْنَ الْعِبَادِ(48) Awon t’o segberaga wi pe: "Dajudaju gbogbo wa l’a wa ninu re.” Dajudaju Allahu kuku ti dajo laaarin awon eru naa |
Awon t’o wa ninu Ina tun wi fun awon eso-Ina pe: "E ba wa pe Oluwa yin, ki O se iya ni fifuye fun wa fun ojo kan |
Won yoo so pe: "Nje awon Ojise yin ki i mu awon eri t’o yanju wa ba yin bi?" Won wi pe: “Rara, (won n mu un wa).” Won so pe: “E sadua wo.” Adua awon alaigbagbo ko si je kini kan bi ko se sinu isina. ona wo ni awon alaigbagbo n gba ri oore laye? Ko si oore aye kan ti o le te alaigbagbo lowo bi ko se ipin re ninu kadara. Amo ni ti onigbagbo ododo oore inu kadara ati oore adua l’o wa fun un niwon igba ti adua re ba ti ba sunnah Anabi (sollalahu alayhi wa sallam) mu |
Dajudaju Awa kuku maa saranse fun awon Ojise Wa ati awon t’o gbagbo ni ododo ninu igbesi aye yii ati ni ojo ti awon elerii yo dide (ni Ojo Ajinde) |
يَوْمَ لَا يَنفَعُ الظَّالِمِينَ مَعْذِرَتُهُمْ ۖ وَلَهُمُ اللَّعْنَةُ وَلَهُمْ سُوءُ الدَّارِ(52) Ni ojo ti awawi awon alabosi ko nii se won ni anfaani; egun n be fun won, ile (iya) buruku si wa fun won |
وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَى الْهُدَىٰ وَأَوْرَثْنَا بَنِي إِسْرَائِيلَ الْكِتَابَ(53) Dajudaju A fun (Anabi) Musa ni imona. A si jogun Tira fun awon omo ’Isro’il |
(O je) imona ati iranti fun awon onilaakaye |
Nitori naa, se suuru. Dajudaju adehun Allahu ni ododo. Toro aforijin fun ese re. Ki o si se afomo pelu idupe fun Oluwa re ni asale ati ni owuro kutukutu. awon ti Anabi Muhammad (sollalahu alayhi wa sallam) tu sile wonyi awon ni olori awon osebo ninu ilu Mokkah. Won si ti pa awon musulumi kan nipakupa siwaju ki owo to te awon naa loju ogun Badr. Amo ohun ti Anabi Muhammad (sollalahu alayhi wa sallam) ro t’o fi tu won sile ni pe ‘O gba iyawo lowo omo re o si fi saya!’. Oro ko si ri bee nitori pe a o gbodo foju bin-intin wo eyikeyii asise tabi ese. A gbodo kun fun titoro aforijin ni lodo Allahu Alaforijin. Ko si ohun t’o dara to riri aforijin gba lodo Allahu lori gbogbo asise wa siwaju ojo iku wa |
Dajudaju awon t’o n jiyan nipa awon ayah Allahu laini eri kan (lowo) ti o wa ba won (lati odo Allahu), ko si kini kan ninu igba-aya won ayafi okan-giga. Won ko si le de ibi giga (pelu okan giga). Nitori naa, sa di Allahu. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugbo, Oluriran |
Dajudaju iseda awon sanmo ati ile tobi ju iseda awon eniyan; sugbon opolopo awon eniyan ni ko mo |
Afoju ati oluriran ko dogba. Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere ati onise-aburu (ko dogba). Die l’e n lo ninu iranti |
إِنَّ السَّاعَةَ لَآتِيَةٌ لَّا رَيْبَ فِيهَا وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يُؤْمِنُونَ(59) Dajudaju Akoko naa n bo, ko si si iyemeji ninu re. Sugbon opolopo awon eniyan ni ko gbagbo |
Oluwa yin so pe: "E pe Mi, ki Ng jepe yin. Dajudaju awon t’o n segberaga nipa jijosin fun Mi, won yoo wo inu ina Jahanamo ni eni yepere |
Allahu ni Eni ti O se oru fun yin nitori ki e le sinmi ninu re. (O si se) osan (nitori ki e le fi) riran. Dajudaju Allahu ni Olola-julo lori awon eniyan, sugbon opolopo awon eniyan ki i dupe (fun Un) |
ذَٰلِكُمُ اللَّهُ رَبُّكُمْ خَالِقُ كُلِّ شَيْءٍ لَّا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ فَأَنَّىٰ تُؤْفَكُونَ(62) Iyen ni Allahu, Oluwa yin, Eledaa gbogbo nnkan. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, bawo ni won se n se yin lori kuro nibi ododo |
كَذَٰلِكَ يُؤْفَكُ الَّذِينَ كَانُوا بِآيَاتِ اللَّهِ يَجْحَدُونَ(63) Bayen naa ni won se n se awon t’o n tako awon ayah Allahu lori kuro nibi ododo (siwaju tiwon) |
Allahu ni Eni ti O se ile fun yin ni ibugbe. O mo sanmo (le yin lori). O ya aworan yin. O si ya aworan yin daradara. O pese arisiki fun yin ninu awon nnkan daadaa. Iyen ni Allahu, Oluwa yin. Nitori naa, mimo ni fun Allahu, Oluwa gbogbo eda |
Oun ni Alaaye. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, e pe E ni ti olusafomo-esin fun Un. Gbogbo ope n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda |
So pe: "Dajudaju Won ko fun mi pe ki ng josin fun awon ti e n pe leyin Allahu, nigba ti awon eri t’o yanju ti de ba mi lati odo Oluwa mi, ti won si pa mi ni ase pe ki ng juwo juse sile (ki ng je musulumi) fun Oluwa gbogbo eda |
Oun ni Eni ti O seda yin lati inu erupe, leyin naa lati inu ato, leyin naa lati inu eje didi, leyin naa O mu yin jade ni oponlo. Leyin naa, (O da yin si) nitori ki e le sanngun dopin agbara yin. Leyin naa (O tun da yin si) nitori ki e le di agbalagba. O wa ninu yin eni ti A oo ti gba emi re siwaju (ipo agba). Ati pe (O da yin si) nitori ki e le dagba de gbedeke akoko kan ati nitori ki e le se laakaye |
هُوَ الَّذِي يُحْيِي وَيُمِيتُ ۖ فَإِذَا قَضَىٰ أَمْرًا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُ كُن فَيَكُونُ(68) Oun ni Eni ti n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Nigba ti O ba si pebubu kini kan, O kan maa so fun un pe: "Je bee." O si maa je bee |
أَلَمْ تَرَ إِلَى الَّذِينَ يُجَادِلُونَ فِي آيَاتِ اللَّهِ أَنَّىٰ يُصْرَفُونَ(69) Se o o ri awon ti n sariyanjiyan nipa awon ayah Allahu bi won se n seri won kuro nibi ododo |
الَّذِينَ كَذَّبُوا بِالْكِتَابِ وَبِمَا أَرْسَلْنَا بِهِ رُسُلَنَا ۖ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ(70) Awon t’o pe Tira naa ati ohun ti A fi ran awon Ojise Wa niro, laipe won maa mo |
إِذِ الْأَغْلَالُ فِي أَعْنَاقِهِمْ وَالسَّلَاسِلُ يُسْحَبُونَ(71) Nigba ti awon sekeseke ati ewon ba wa ni orun won, ti won yoo fi maa wo won |
sinu omi gbigbona. Leyin naa, won yoo fi won ko Ina |
Leyin naa, Won maa so fun won pe: "Ibo ni ohun ti e so di orisa wa |
(Ohun ti e josin fun) leyin Allahu (da)?" Won a wi pe: "Won ti di ofo mo wa lowo. Bee tie ko, awa ki i pe nnkan kan teletele." Bayen ni Allahu se n si awon alaigbagbo lona |
ذَٰلِكُم بِمَا كُنتُمْ تَفْرَحُونَ فِي الْأَرْضِ بِغَيْرِ الْحَقِّ وَبِمَا كُنتُمْ تَمْرَحُونَ(75) Iyen nitori pe e n yo lori ile lai letoo ati nitori pe e n se faari (lori aigbagbo) |
ادْخُلُوا أَبْوَابَ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا ۖ فَبِئْسَ مَثْوَى الْمُتَكَبِّرِينَ(76) E wo awon enu ona ina Jahanamo; olusegbere ni won ninu re. O si buru ni ibugbe fun awon onigbeeraga |
Nitori naa, se suuru. Dajudaju adehun Allahu ni ododo. O see se ki A fi apa kan eyi ti A se ni ileri fun won han o tabi ki A ti gba emi re (siwaju asiko naa). Odo Wa kuku ni won maa da won pada si |
Ati pe A kuku ti ran awon Ojise nise siwaju re. Awon ti A so itan won fun o wa ninu won. Awon ti A o si so itan won fun o wa ninu won. Ati pe ko to fun Ojise kan lati mu ami kan wa afi pelu iyonda Allahu. Nigba ti ase Allahu ba si de, A maa fi ododo dajo. Awon opuro si maa sofo danu nibe yen |
اللَّهُ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الْأَنْعَامَ لِتَرْكَبُوا مِنْهَا وَمِنْهَا تَأْكُلُونَ(79) Allahu ni Eni ti O da awon eran-osin fun yin nitori ki e le maa gun ninu won. E o si maa je ninu won |
Awon anfaani (miiran) wa fun yin lara eran-osin. Ati nitori ki e le de ona jijin t’o wa lokan yin lori (gigun) won (kiri). E o si maa fi awon (eran-osin) ati oko oju-omi gbe awon eru |
(Allahu) n fi awon ami Re han yin. Nitori naa, ewo ninu awon ami Allahu l’e maa tako |
Se won ko rin kiri lori ile ki won wo bi ikangun awon t’o siwaju won se ri? Won po (ni onka) ju won lo. Won ni agbara ju won lo. Won si lo ile (fun oko dida ju won lo). Sibesibe ohun ti won n se nise ko ro won loro (nibi iya) |
Nigba ti awon Ojise mu awon eri t’o yanju wa ba won, won yo ayoporo nitori ohun t’o wa lodo won ninu imo (aye). Ohun ti won si n fi se yeye si diya t’o yi won po |
Nigba ti won ri iya Wa, won wi pe: "A gbagbo ninu Allahu, Oun nikan soso. A si lodi si nnkan ti a so di akegbe fun Un |
Igbagbo won ko se won ni anfaani nigba ti won ri iya Wa. Ise Allahu, eyi ti o ti sele siwaju si awon eru Re (ni eyi). Awon alaigbagbo si sofo danu nibe yen |
More surahs in Yoruba:
Download surah Ghafir with the voice of the most famous Quran reciters :
surah Ghafir mp3 : choose the reciter to listen and download the chapter Ghafir Complete with high quality
Ahmed Al Ajmy
Bandar Balila
Khalid Al Jalil
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdul Rashid Sufi
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Yasser Al Dosari
لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب