Surah Al-Hadid with Yoruba
سَبَّحَ لِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ(1) Ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile n safomo fun Allahu. Oun si ni Alagbara, Ologbon |
لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ يُحْيِي وَيُمِيتُ ۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ(2) TiRe ni ijoba awon sanmo ati ile. O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Oun ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
هُوَ الْأَوَّلُ وَالْآخِرُ وَالظَّاهِرُ وَالْبَاطِنُ ۖ وَهُوَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ(3) Oun ni Akoko ati Ikeyin. O han (pelu ami bibe Re). O si pamo (fun gbogbo oju nile aye). Oun ni Onimo nipa gbogbo nnkan |
Oun ni Eni ti O seda awon sanmo ati ile fun ojo mefa. Leyin naa, O gunwa si ori Ite-ola. O mo nnkan t’o n wo inu ile ati nnkan t’o n jade lati inu re, ati nnkan t’o n sokale lati inu sanmo ati nnkan t’o n gunke sinu re. Ati pe O wa pelu yin ni ibikibi ti e ba wa (pelu imo Re). Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise |
لَّهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ وَإِلَى اللَّهِ تُرْجَعُ الْأُمُورُ(5) TiRe ni ijoba awon sanmo ati ile. Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si |
O n ti oru bo inu osan. O si n ti osan bo inu oru. Oun si ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu igba-aya eda |
E gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Ki e si na ninu ohun ti O fi yin se arole lori re. Nitori naa, awon t’o gbagbo ni ododo ninu yin, ti won si nawo (si oju ona esin), esan t’o tobi wa fun won |
Ki ni o mu yin ti eyin ko fi nii gba Allahu gbo ni ododo? Ojise si n pe yin nitori ki e le gba Oluwa yin gbo. Allahu si ti gba adehun lowo yin, ti eyin ba je onigbagbo ododo |
Oun ni Eni t’O n so awon ayah t’o yanju kale fun erusin Re nitori ki o le mu yin kuro ninu awon okunkun wa sinu imole. Dajudaju Allahu ni Alaaanu, Asake-orun fun yin |
Ki ni o mu yin ti eyin ko fi nii nawo fun esin Allahu? Ti Allahu si ni ogun awon sanmo ati ile. Eni ti o nawo siwaju sisi ilu Mokkah, ti o tun jagun esin, ko dogba laaarin yin (si awon miiran). Awon wonyen ni esan won tobi julo si ti awon t’o nawo leyin igba naa, ti won tun jagun esin. Eni kookan si ni Allahu s’adehun esan rere fun. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise |
مَّن ذَا الَّذِي يُقْرِضُ اللَّهَ قَرْضًا حَسَنًا فَيُضَاعِفَهُ لَهُ وَلَهُ أَجْرٌ كَرِيمٌ(11) Ta ni eni ti o maa ya Allahu ni dukia t’o dara, O si maa sadipele re fun un. Esan alapon-onle si tun wa fun un |
Ni ojo ti o maa ri awon onigbagbo ododo lokunrin ati onigbagbo ododo lobinrin, ti imole won yoo maa tan niwaju won ati ni owo otun won, (A oo so pe:) "Iro idunnu yin ni oni ni awon Ogba Idera kan ti awon odo n san ni isale re." Olusegbere ni yin ninu re. Iyen si ni erenje nla |
Ni ojo ti awon sobe-selu musulumi lokunrin ati awon sobe-selu musulumi lobinrin yoo wi fun awon t’o gbagbo pe: "E duro fun wa na, e je ki a mu ninu imole yin." A oo so fun won pe: "E pada s’eyin yin, ki e lo mu imole.” Won si maa fi ogiri kan, t’o ni ilekun saarin won. Ike wa ninu re, iya si wa ni ode re ni owo iwaju re |
(Awon sobe-selu musulumi) yoo pe (awon onigbagbo ododo) pe: "Se awa ko ti wa pelu yin ni?" Won so pe: "Rara, sugbon e ko iyonu ba emi ara yin (nipa isobe-selu), e reti iparun (wa), e si siyemeji (si ododo). Awon ife-okan ati iro oro si tan yin je titi ase Allahu fi de. Ati pe (Esu) eletan si tan yin je nipa Allahu |
Nitori naa, ni oni Awa ko nii gba itanran kan ni owo eyin ati awon t’o sai gbagbo. Ina ni ibugbe yin. Ohun l’o to si yin. Ikangun naa si buru |
Se akoko ko ti i to fun awon t’o gbagbo ni ododo pe ki okan won ro fun iranti Allahu ati ohun t’o sokale ninu ododo (iyen, al-Ƙur’an). Ki won si ma se da bi awon ti A fun ni Tira ni isaaju; igba pe lori won, okan won ba le. Opolopo ninu won si ni obileje |
E mo pe dajudaju Allahu l’O n so ile di aye leyin ti ile ti ku. A kuku ti salaye awon ayah naa nitori ki e le se laakaye |
Dajudaju awon olutore lokunrin ati awon olutore lobinrin, ti won tun ya Allahu ni dukia t’o dara, (Allahu) yoo sadipele re fun won. Esan alapon-onle si wa fun won |
Awon t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re, awon wonyen ni awon olododo ati elerii ni odo Oluwa won. Esan won ati imole won wa fun won. Awon t’o si sai gbagbo, ti won tun pe awon ayah Wa niro, awon wonyen ni ero inu ina Jehim |
E mo pe dajudaju isemi aye yii je ere, iranu, oso, sise iyanran laaarin ara yin ati wiwa opo dukia ati omo. (Iwonyi) da bi ojo (t’o mu irugbin jade). Irugbin re si n jo awon alaigbagbo loju. Leyin naa, o maa gbe. O si maa ri i ni pipon. Leyin naa, o maa di rirun (ti ategun maa fe danu). Iya lile ati aforijin pelu iyonu lati odo Allahu si wa ni orun. Ki si ni isemi aye yii bi ko se igbadun etan |
E yara lo sibi aforijin lati odo Oluwa yin ati Ogba Idera ti fife re da bi fife sanmo ati ile. Won pa a lese sile de awon t’o gbagbo ninu Allahu ati awon Ojise Re. Iyen ni oore ajulo Allahu ti O n fun eni ti O ba fe. Allahu si ni Oloore nla |
Adanwo kan ko nii sele ni ori ile tabi (ki o sele) si eyin ayafi ki o ti wa ninu Tira siwaju ki A t’o da eda. Dajudaju iyen rorun fun Allahu |
(Isele n to kadara leyin) nitori ki e ma se banuje lori ohun ti o ba bo fun yin ati nitori ki e ma se yo ayoju lori ohun ti O ba fun yin. Allahu ko si nifee si gbogbo onigbeeraga, onifaari |
Awon t’o n sahun, ti won si n pa awon eniyan lase ahun sise (ki won mo pe) enikeni ti o ba peyinda (ti ko nawo fun esin), dajudaju Allahu, Oun ni Oloro, Olope |
Dajudaju A fi awon eri t’o yanju ran awon Ojise Wa. A so Tira kale fun won ati osuwon nitori ki awon eniyan le ri deede se (laaarin ara won). A tun so irin kale. Ohun ijagun t’o lagbara ati awon anfaani wa ninu re fun awon eniyan nitori ki Allahu le safi han eni t’o n ran (esin) Re ati Ojise Re lowo ni ikoko. Dajudaju Allahu ni Alagbara, Olubori |
Dajudaju A fi ise ran (Anabi) Nuh ati (Anabi) ’Ibrohim. A fi ipo Anabi sinu awon aromodomo awon mejeeji pelu Tira (ti A fun won). Olumona wa ninu won. Opolopo ninu won si ni obileje |
Leyin naa, A fi awon Ojise Wa tele oripa won. A si mu ‘Isa omo Moryam tele won. A fun un ni al-’Injil. A fi aanu ati ike sinu okan awon t’o tele e. Asa adawa (lai loko tabi lai laya) won se adadaale re ni. A o se e ni oran-anyan le won lori. (Won ko si se adawa fun kini kan) bi ko se lati fi wa iyonu Allahu. Won ko si ri i so bi o se ye ki won so o. Nitori naa, A fun awon t’o gbagbo ni ododo ninu won ni esan won. Opolopo ninu won si ni obileje |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu, ki e si gba Ojise Re gbo ni ododo, nitori ki (Allahu) le fun yin ni ilopo meji ninu ike Re ati nitori ki O le fun yin ni imole ti e oo maa fi rin ati nitori ki O le fori jin yin. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun |
(Allahu se bee fun yin) nitori ki awon ahlu-l-kitab le mo pe awon ko ni agbara lori kini kan ninu oore ajulo Allahu. Ati pe dajudaju oore ajulo, owo Allahu l’o wa. O si n fun eni ti O ba fe. Allahu si ni Oloore nla |
More surahs in Yoruba:
Download surah Al-Hadid with the voice of the most famous Quran reciters :
surah Al-Hadid mp3 : choose the reciter to listen and download the chapter Al-Hadid Complete with high quality
Ahmed Al Ajmy
Bandar Balila
Khalid Al Jalil
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdul Rashid Sufi
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Yasser Al Dosari
لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب