La sourate Al-Mulk en Yoruba
تَبَارَكَ الَّذِي بِيَدِهِ الْمُلْكُ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ(1) Ibukun ni fun Eni ti ijoba wa ni Owo Re. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
Eni ti O da iku ati isemi nitori ki o le dan yin wo; ewo ninu yin l’o maa se ise rere julo. Oun si ni Alagbara, Alaforijin |
Eni ti O da awon sanmo meje ni ipele ipele. O o le ri aigunrege kan lara eda Ajoke-aye. Nitori naa, wo o pada, nje o ri oju sisan kan (lara sanmo) |
ثُمَّ ارْجِعِ الْبَصَرَ كَرَّتَيْنِ يَنقَلِبْ إِلَيْكَ الْبَصَرُ خَاسِئًا وَهُوَ حَسِيرٌ(4) Leyin naa, wo o pada ni ee meji, ki oju re pada si odo re pelu iyepere. O si maa kaaare |
Dajudaju A ti fi (awon irawo t’o n tanmole bi) atupa se sanmo ile aye ni oso. A tun se won ni eta-irawo ti won n ju mo awon esu. A si pese iya Ina t’o n jo fofo sile de won |
وَلِلَّذِينَ كَفَرُوا بِرَبِّهِمْ عَذَابُ جَهَنَّمَ ۖ وَبِئْسَ الْمَصِيرُ(6) Iya ina Jahanamo si wa fun awon t’o sai gbagbo. Ikangun naa si buru |
إِذَا أُلْقُوا فِيهَا سَمِعُوا لَهَا شَهِيقًا وَهِيَ تَفُورُ(7) Nigba ti won ba ju won sinu re, won yoo maa gbo kikun re, ti o si maa ru soke |
Ina maa fee pinra re lati ara ibinu. Igbakigba ti won ba ju ijo kan sinu re, awon eso Ina yoo maa bi won leere pe: "Nje olukilo kan ko wa ba yin bi |
Won yoo wi pe: "Rara, dajudaju olukilo kan ti wa ba wa, sugbon a pe e ni opuro. A si wi pe Allahu ko so nnkan kan kale. Ki ni eyin bi ko se pe e wa ninu isina t’o tobi |
وَقَالُوا لَوْ كُنَّا نَسْمَعُ أَوْ نَعْقِلُ مَا كُنَّا فِي أَصْحَابِ السَّعِيرِ(10) Won tun wi pe: "Ti o ba je pe a gboran ni tabi pe a se laakaye ni, awa ko nii wa ninu ero inu Ina jijo |
فَاعْتَرَفُوا بِذَنبِهِمْ فَسُحْقًا لِّأَصْحَابِ السَّعِيرِ(11) Won si jewo ese won. Nitori naa, ijinna si ike Allahu yo wa fun awon ero inu Ina t’o n jo fofo |
إِنَّ الَّذِينَ يَخْشَوْنَ رَبَّهُم بِالْغَيْبِ لَهُم مَّغْفِرَةٌ وَأَجْرٌ كَبِيرٌ(12) Dajudaju awon t’o n paya Oluwa won ni ikoko, aforijin ati esan t’o tobi n be fun won |
وَأَسِرُّوا قَوْلَكُمْ أَوِ اجْهَرُوا بِهِ ۖ إِنَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ(13) E wi oro yin ni jeeje tabi e wi i soke, dajudaju Oun ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu awon igba-aya eda |
Se (Allahu) ko mo eni t’O da ni? Oun si ni Alaaanu, Alamotan |
Oun ni Eni ti O ro ile fun yin. Nitori naa, e rin ni awon agbegbe re kaakiri, ki e si je ninu arisiki Re. Odo Re si ni ajinde eda wa |
أَأَمِنتُم مَّن فِي السَّمَاءِ أَن يَخْسِفَ بِكُمُ الْأَرْضَ فَإِذَا هِيَ تَمُورُ(16) Se e fokanbale si Eni ti O wa ni (oke) sanmo pe ko le je ki ile gbe yin mi? Nigba naa, ile yo si maa mi titi |
أَمْ أَمِنتُم مَّن فِي السَّمَاءِ أَن يُرْسِلَ عَلَيْكُمْ حَاصِبًا ۖ فَسَتَعْلَمُونَ كَيْفَ نَذِيرِ(17) Tabi e fokanbale si Eni ti O wa ni (oke) sanmo pe ko le fi okuta ina ranse si yin ni? Nigba naa, e si maa mo bi ikilo Mi ti ri |
وَلَقَدْ كَذَّبَ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ فَكَيْفَ كَانَ نَكِيرِ(18) Awon t’o siwaju won kuku pe ododo niro. Bawo si ni bi Mo se (fi iya) ko (aburu fun won) ti ri |
Se won ko ri awon eye ti o wa ni oke won, ti (won) n na iye apa (won), ti won si n pa a mora? Kini kan ko mu won duro (sinu ofurufu) afi Ajoke-aye. Dajudaju Oun si ni Oluriran nipa gbogbo nnkan |
Ta ni eni ti o maa je omo ogun fun yin, ti o maa ran yin lowo leyin Ajoke-aye? (Ninu) ki ni awon alaigbagbo wa bi ko se ninu etan |
أَمَّنْ هَٰذَا الَّذِي يَرْزُقُكُمْ إِنْ أَمْسَكَ رِزْقَهُ ۚ بَل لَّجُّوا فِي عُتُوٍّ وَنُفُورٍ(21) Ta ni eni ti o maa pese fun yin ti O ba da arisiki Re duro? Nse ni won n sori kunkun si i ninu igberaga ati sisa fun ododo |
Nje eni t’o n rin ni idojubole l’o mona julo ni tabi eni t’o n rin san an loju ona taara |
So pe: "Oun ni Eni ti O seda yin. O si se igboro, iriran ati awon okan fun yin. Ope ti e n da si kere pupo |
قُلْ هُوَ الَّذِي ذَرَأَكُمْ فِي الْأَرْضِ وَإِلَيْهِ تُحْشَرُونَ(24) So pe: "Oun ni Eni ti O da yin si ori ile. Odo Re si ni won yoo ko yin jo si |
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا الْوَعْدُ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ(25) Won n wi pe: "Igba wo ni adehun yii yoo se ti e ba je olododo |
قُلْ إِنَّمَا الْعِلْمُ عِندَ اللَّهِ وَإِنَّمَا أَنَا نَذِيرٌ مُّبِينٌ(26) So pe: "Odo Allahu nikan ni imo (nipa) re wa. Emi kan je olukilo ponnbele ni |
Nigba ti won ba ri i t’o sunmo, oju awon t’o sai gbagbo yoo koro wa fun ibanuje. A o si so fun won pe: "Eyi ni ohun ti e n pe |
So pe: " E so fun mi, ti Allahu ba pa emi ati awon t’o wa pelu mi re, tabi ti O ba ke wa (se e le di I lowo ni?) Nitori naa, ta ni o maa gba awon alaigbagbo la ninu iya eleta-elero |
So pe: "Oun ni Ajoke-aye. Awa gba A gbo. Oun si la gbarale. Laipe e maa mo ta ni o wa ninu isina ponnbele |
قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِنْ أَصْبَحَ مَاؤُكُمْ غَوْرًا فَمَن يَأْتِيكُم بِمَاءٍ مَّعِينٍ(30) So pe: " E so fun mi, ti omi yin ba gbe wa, ta ni eni ti o maa mu omi iseleru wa ba yin |
Plus de sourates en Yoruba :
Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :
Téléchargez le fichier mp3 de la sourate Al-Mulk : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate Al-Mulk complète en haute qualité.















Donnez-nous une invitation valide