La sourate Al-Ghashiyah en Yoruba
Nje oro nipa ohun t’o maa bo eda mole ti de odo re |
Awon oju kan yoo wale (ni ti iyepere) ni ojo yen |
Onise asekudorogbo (ni won nile aye) |
Won maa wo inu Ina t’o gbona janjan (ni orun) |
Won si maa fun (won) ni omi gbigbona mu |
Ko si ounje kan fun won ayafi igi elegun-un gbigbe |
Ko nii mu won sanra. Ko si nii ro won loro ninu ebi |
Awon oju kan yo si kun fun igbadun ni ojo yen |
nitori pe (o) yonu si (esan) ise re |
(O maa) wa ninu Ogba Idera giga |
Won ko nii gbo isokuso ninu re |
Omi iseleru t’o n san wa ninu re |
Awon ibusun ti won gbe soke wa ninu re |
ati awon ife imumi ti won gbe kale (si arowoto won) |
ati awon irori ti won to si egbe ara won |
ati awon ite ateeka |
Nitori naa, se won ko wo rakunmi, bi A ti seda re ni |
ati sanmo, bi A ti se gbe e soke |
ati apata, bi A ti se gbe e naro (sinu ile) |
ati ile, bi A ti se te e sile ni gbansasa |
Nitori naa, seranti. Iwo kuku ni oluseranti |
Iwo ki i se ajeni-nipa lori won |
afi eni ti o ba peyinda (si ododo), ti o si sai gbagbo |
Allahu si maa je e niya t’o tobi julo |
Dajudaju odo Wa ni abo won wa |
Leyin naa, dajudaju Awa l’A maa se isiro-ise won |
Plus de sourates en Yoruba :
Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :
Téléchargez le fichier mp3 de la sourate Al-Ghashiyah : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate Al-Ghashiyah complète en haute qualité.















Donnez-nous une invitation valide