Surah Luqman with Yoruba
الم(1) ’Alif lam mim |
Iwonyi ni awon ayah Tira ogbon |
(O je) imona ati ike fun awon oluse-rere |
الَّذِينَ يُقِيمُونَ الصَّلَاةَ وَيُؤْتُونَ الزَّكَاةَ وَهُم بِالْآخِرَةِ هُمْ يُوقِنُونَ(4) awon t’o n kirun, ti won n yo zakah. Awon si ni won ni amodaju nipa Ojo Ikeyin |
أُولَٰئِكَ عَلَىٰ هُدًى مِّن رَّبِّهِمْ ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ(5) Awon wonyen wa lori imona lati odo Oluwa won. Awon wonyen si ni awon olujere |
O wa ninu awon eniyan, eni t’o n ra iranu-oro lati fi si awon eniyan lona kuro loju ona (esin) Allahu pelu ainimo ati nitori ki o le so esin di yeye. Awon wonyen si ni iya ti i yepere eda wa fun |
Ati pe nigba ti won ba n ke awon ayah Wa fun un, o maa peyinda ni ti igberaga, afi bi eni pe ko gbo o, afi bi eni pe edidi wa ninu eti re mejeeji. Nitori naa, fun un ni iro iya eleta-elero |
إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَهُمْ جَنَّاتُ النَّعِيمِ(8) Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, awon Ogba Idera n be fun won |
خَالِدِينَ فِيهَا ۖ وَعْدَ اللَّهِ حَقًّا ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ(9) Olusegbere ni won ninu re. (O je) adehun ti Allahu se ni ti ododo. Oun si ni Alagbara, Ologbon |
O da awon sanmo lai ni opo ti e le ri. O si ju awon apata t’o duro gbagidi sinu ile ki o ma fi le mi mo yin lese. O fon gbogbo nnkan abemi ka sori ile. A tun so omi kale lati sanmo, A si fi mu gbogbo orisirisi eso daadaa hu jade lati inu ile |
Eyi ni eda ti Allahu. Nitori naa, e fi ohun ti awon miiran leyin Re da han mi! Rara o! Awon alabosi wa ninu isina ponnbele ni |
Dajudaju A ti fun Luƙmon ni ogbon, pe: “Dupe fun Allahu.” Enikeni ti o ba dupe, o n dupe fun emi ara re ni. Enikeni ti o ba si sai moore, dajudaju Allahu ni Oloro, Olope (ti ope to si) |
(Ranti) nigba ti Luƙmon so fun omo re nigba ti o n se waasi fun un, pe: “Omo mi, ma se sebo si Allahu. Dajudaju ebo sise ni abosi nla |
Ati pe A pa a ni ase fun eniyan nipa awon obi re mejeeji - iya re gbe e ka (ninu oyun) pelu ailera lori ailera, o si gba omu lenu re laaarin odun meji – (A so) pe: “Dupe fun Emi ati awon obi re mejeeji.” Odo Mi si ni abo eda |
Ti awon mejeeji ba si ja o logun pe ki o fi ohun ti iwo ko ni imo nipa re sebo si Mi, ma se tele awon mejeeji.1 Fi daadaa ba awon mejeeji lo po ni ile aye.2 Ki o si tele oju ona eni ti o ba seri pada si odo Mi (ni ti ironupiwada). Leyin naa, odo Mi ni ibupadasi yin. Nitori naa, Mo maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise. nnkan daadaa ni. Iketa: ohunkohun ti asa ati ise eya eda kookan ba pe ni daadaa nnkan daadaa ni ni odiwon igba ti ayah kan tabi hadith kan ko ba ti lodi si irufe nnkan naa. Bi apeere |
Omo mi, dajudaju ti o ba je pe odiwon eso kardal kan lo wa ninu apata, tabi ninu awon sanmo, tabi ninu ile, Allahu yoo mu un wa. Dajudaju Allahu ni Alaaanu, Alamotan |
Omo mi, kirun, p’ase rere, ko aburu, ki o si se suuru lori ohun ti o ba sele si o. Dajudaju iyen wa ninu awon ipinnu oro t’o pon dandan |
Ma se ko parike re si eniyan. Ma si se rin lori ile pelu faari. Dajudaju Allahu ko feran gbogbo onigbeeraga, onifaari |
وَاقْصِدْ فِي مَشْيِكَ وَاغْضُضْ مِن صَوْتِكَ ۚ إِنَّ أَنكَرَ الْأَصْوَاتِ لَصَوْتُ الْحَمِيرِ(19) Je ki irin ese re wa ni iwontun-wonsi, ki o si re ohun re nile. Dajudaju ohun t’o buru julo ma ni ohun ketekete.” |
Se e o ri i pe dajudaju Allahu ro ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile fun yin, O si pe awon ike Re fun yin ni gbangba ati ni koro? O si wa ninu awon eniyan eni t’o n jiyan nipa Allahu lai ni imo (al-Ƙur’an) ati imona (ninu sunnah Anabi s.a.w.) ati tira (onimo-esin) t’o n tan imole (si oro esin) |
Nigba ti won ba si so fun won pe: “E tele ohun ti Allahu sokale.” Won a wi pe: “Rara! A maa tele ohun ti a ba lowo awon baba wa ni.” (Se won yoo tele awon baba won) t’ohun ti bi Esu se n pe won sibi iya Ina t’o n jo fofo |
Enikeni ti o ba jura re sile fun Allahu, ti o je oluse-rere, dajudaju onitoun ti diro mo okun t’o fokan bale julo. Ati pe odo Allahu ni ikangun awon oro (eda) |
Enikeni ti o ba si sai gbagbo, ma se je ki aigbagbo re ko ibanuje ba o. Odo Wa ni ibupadasi won. Nigba naa, A maa fun won ni iro ohun ti won se nise. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa ohun ti n be ninu igba-aya eda |
نُمَتِّعُهُمْ قَلِيلًا ثُمَّ نَضْطَرُّهُمْ إِلَىٰ عَذَابٍ غَلِيظٍ(24) A maa fun won ni igbadun die. Leyin naa, A maa taari won sinu iya t’o nipon |
Dajudaju ti o ba bi won leere pe: “Ta ni O da awon sanmo ati ile?”, dajudaju won a wi pe: “Allahu ni.” So pe: “Gbogbo ope n je ti Allahu, sugbon opolopo won ko mo |
لِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ إِنَّ اللَّهَ هُوَ الْغَنِيُّ الْحَمِيدُ(26) Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Dajudaju Allahu, Oun ni Oloro, Olope |
Ti o ba je pe kikida ohun t’o n be lori ile ni igi ni gege ikowe, ki agbami odo je tadaa re, agbami odo meje (tun wa) leyin re (t’o maa kun un), awon oro Allahu ko nii tan (leyin ti awon nnkan ikowe wonyi ba tan nile). Dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon |
مَّا خَلْقُكُمْ وَلَا بَعْثُكُمْ إِلَّا كَنَفْسٍ وَاحِدَةٍ ۗ إِنَّ اللَّهَ سَمِيعٌ بَصِيرٌ(28) Iseda yin ati ajinde yin ko tayo bi (iseda ati ajinde) emi eyo kan. Dajudaju Allahu ni Olugbo, Oluriran |
Se o o ri i pe dajudaju Allahu l’O n ti oru bo inu osan, O n ti osan bo inu oru, O si ro oorun ati osupa? Ikookan won si n rin titi di gbedeke akoko kan. Ati pe (se o o ri i pe) dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise |
Iyen nitori pe, dajudaju Allahu, Oun ni Ododo. Ati pe dajudaju ohun ti won n pe leyin Re ni iro. Dajudaju Allahu, O ga, O tobi |
Se o o ri i pe dajudaju oko oju-omi n rin ni oju omi pelu idera Re, (sebi) nitori ki (Allahu) le fi han yin ninu awon ami Re ni? Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun gbogbo onisuuru, oludupe |
Nigba ti igbi omi ba bo won mole daru bi awon apata ati esujo, won a pe Allahu (gege bi) olusafomo-adua fun Un. Nigba ti O ba si gba won la sori ile, onideede si maa wa ninu won. Ko si si eni t’o maa tako awon ayah Wa afi gbogbo odale, alaimoore |
Eyin eniyan, e beru Oluwa yin. Ki e si paya ojo kan ti obi kan ko nii sanfaani fun omo re; ati pe omo kan, oun naa ko nii sanfaani kini kan fun obi re. Dajudaju adehun Allahu ni ododo. Nitori naa, isemi aye yii ko gbodo tan yin je. (Esu) eletan ko si gbodo tan yin je nipa Allahu |
Dajudaju Allahu, odo Re ni imo Akoko naa wa. O n so ojo kale. O mo ohun t’o wa ninu apoluke. Emi kan ko si mo ohun ti o maa se nise ni ola. Emi kan ko si mo ile wo l’o maa ku si. Dajudaju Allahu ni Onimo, Alamotan |
More surahs in Yoruba:
Download surah Luqman with the voice of the most famous Quran reciters :
surah Luqman mp3 : choose the reciter to listen and download the chapter Luqman Complete with high quality
Ahmed Al Ajmy
Bandar Balila
Khalid Al Jalil
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdul Rashid Sufi
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Yasser Al Dosari
لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب