سورة النجم باليوربا
(Allahu bura pelu) irawo nigba ti o ba jabo |
Eni yin ko sina, ko si sonu |
Ati pe ko nii soro ife-inu |
Ko nii so ohun kan tayo imisi ti A fi ranse si i |
Alagbara (iyen, molaika Jibril) l’o ko o ni imo (al-Ƙur’an) |
O ni alaafia t’o peye. Nitori naa, o duro wamuwamu |
nigba ti o wa ninu ofurufu loke patapata |
Leyin naa, o sun mo (Anabi). O si sokale (to o wa) |
(Alafo aarin awon mejeeji) si to iwon orun ofa meji, tabi ki o kere (si iyen) |
Allahu si fun erusin Re ni imisi t’O fun un |
Okan (Anabi) ko paro ohun t’o ri |
Se e oo ja a niyan nipa ohun t’o ri ni |
Ati pe dajudaju o ri i nigba keji Allahu (subhanahu wa ta’ala) ni o ri bi o tile je pe igun yii fi kun un pe okan l’o fi ri Allahu bii oro ti o todo Omo ‘Abbas (rodiyallahu anhu) wa pe “Anabi (sollalahu alayhi wa sallam) fi okan re ri Allahu ni.” Iyen ni pe |
nibi igi sidirah al-Muntaha |
nitosi re ni Ogba Ibugbe (gbere) wa |
(Ranti) nigba ti ohun t’o bo igi Sidirah bo o mole |
Oju (Anabi) ko ye, ko si tayo enu-ala |
Dajudaju o ri ninu awon ami Oluwa re, t’o tobi julo |
E so fun mi nipa orisa Lat ati orisa ‘Uzza |
ati Monah, orisa keta miiran |
Se omokunrin ni tiyin, omobinrin si ni tiRe |
Ipin abosi niyen nigba naa |
(Awon oruko orisa wonyen) ko si je kini kan bi ko se awon oruko kan ti eyin ati awon baba yin fi so (awon orisa yin funra yin). Allahu ko si so eri oro kan kale nipa re. Won ko si tele kini kan bi ko se aroso ati ohun ti emi (won) n fe. Imona kuku ti de ba won lati odo Oluwa won |
Tabi ti eniyan ni nnkan t’o ba n fe |
Ti Allahu si ni orun ati aye |
Ati pe meloo meloo ninu awon molaika t’o wa ninu awon sanmo, ti isipe won ko nii ro won loro kini kan ayafi leyin igba ti Allahu ba yonda fun eni ti O ba fe, ti O si yonu si |
إِنَّ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ لَيُسَمُّونَ الْمَلَائِكَةَ تَسْمِيَةَ الْأُنثَىٰ(27) Dajudaju awon ti ko ni igbagbo ododo ninu Ojo Ikeyin, awon ni won n fun awon molaika ni oruko obinrin |
Ko si imo kan fun won nipa re. Won ko si tele kini kan bi ko se aroso. Dajudaju aroso ko si nii roro kini kan lara ododo |
فَأَعْرِضْ عَن مَّن تَوَلَّىٰ عَن ذِكْرِنَا وَلَمْ يُرِدْ إِلَّا الْحَيَاةَ الدُّنْيَا(29) Nitori naa, seri kuro ni odo eni t’o keyin si iranti Wa, ti ko si gbero kini kan afi isemi aye |
Iyen ni odiwon (ati opin) imo won. Dajudaju Oluwa re, O nimo julo nipa eni t’o sina kuro loju ona Re. O si nimo julo nipa eni t’o mona |
Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile nitori ki O le san awon t’o se ise aburu ni esan ohun ti won se nise ati nitori ki O le san awon t’o se ise rere ni esan rere |
Awon t’o n jinna si ese nla nla ati iwa ibaje ayafi awon ese peepeepe, dajudaju Oluwa re gbooro ni aforijin. O nimo julo nipa yin nigba ti O seda yin lati inu ile ati nigba ti e wa ni ole ninu awon ikun iya yin. Nitori naa, e ma se fora yin mo. O nimo julo nipa eni t’o beru (Re) |
So fun mi nipa eni t’o gbunri (kuro nibi ododo) |
ti o fi die tore, ti o si di iyoku mowo |
Se imo ikoko wa ni odo re, ti o si n ri i (pe elomiiran l’o ma ba oun jiya lorun) |
Tabi won ko fun un ni iro ohun t’o wa ninu tira (Anabi) Musa ni |
ati (tira Anabi) ’Ibrohim, eni t’o mu (ofin Allahu) se |
pe dajudaju eleru-ese kan ko nii ru eru-ese elomiiran |
Ati pe ko si kini kan fun eniyan afi ohun t’o se nise |
Ati pe dajudaju ise re, laipe won maa fi han an |
Leyin naa, won maa san an ni esan re, ni esan t’o kun julo |
Ati pe dajudaju odo Oluwa re ni opin (irin-ajo eda) |
Dajudaju Oun l’O n pa (eda) ni erin. O si n pa (eda) ni ekun |
Dajudaju Oun l’O n so (eda) di oku. O si n so (eda) di alaaye |
Dajudaju Oun l’O da eda ni orisi meji, okunrin ati obinrin |
lati ara ato nigba ti won ba da a sinu apoluke |
Dajudaju Oun l’O maa se iseda ikeyin fun ajinde |
Dajudaju Oun l’O n se pupo, O si n se kekere (oore fun eda) |
Dajudaju Oun si ni Oluwa irawo Si‘ro (ti won so di orisa) |
Dajudaju Oun l’O pa iran ‘Ad re, awon eni akoko |
ati iran Thamud, ko si se won ku |
وَقَوْمَ نُوحٍ مِّن قَبْلُ ۖ إِنَّهُمْ كَانُوا هُمْ أَظْلَمَ وَأَطْغَىٰ(52) ati ijo Nuh t’o siwaju (won), dajudaju won je alabosi julo, won si tayo enu-ala julo |
ati ilu ti won dawo (ilu Anabi Lut) t’O ye lule (lati oke) |
Ohun t’o bo won mole bo won mole |
Nitori naa, ewo ninu idera Oluwa re ni iwo (eniyan) n ja niyan |
Eyi ni ikilo kan ninu awon ikilo akoko |
Ohun t’o sunmo sunmo |
Leyin Allahu, ko si eni t’o le safi han (Akoko naa) |
Se oro yii l’o n se yin ni kayefi |
E n rerin-in, e o si sunkun |
Afonu-fora ni yin |
Nitori naa, e fori kanle fun Allahu, ki e josin (fun Un) |
المزيد من السور باللغة اليوربا:
تحميل سورة النجم بصوت أشهر القراء :
قم باختيار القارئ للاستماع و تحميل سورة النجم كاملة بجودة عالية
أحمد العجمي
خالد الجليل
سعد الغامدي
سعود الشريم
عبد الباسط
عبد الله الجهني
علي الحذيفي
فارس عباد
ماهر المعيقلي
محمد جبريل
المنشاوي
الحصري
مشاري العفاسي
ناصر القطامي
ياسر الدوسري
Friday, January 3, 2025
لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب