سورة عبس باليوربا
(Anabi s.a.w.) faju ro, o si peyin da |
nitori pe afoju wa ba a |
Ki si l’o maa fi mo o pe o see se ki o safomo (ara re kuro ninu aigbagbo) |
tabi ki o gbo iranti, ki iranti naa si se e ni anfaani |
Ni ti eni ti o ka ara re kun oloro |
oun ni iwo teti si |
Ko si si ese fun o bi ko ba se afomo (ara re kuro ninu aigbagbo) |
Ni ti eni ti o si wa ba o, t’o n yara gaga (si iranti, iyen afoju) |
ti o si n paya (Allahu) |
iwo ko si kobi ara si i |
Rara (ko to bee). Dajudaju al-Ƙur’an ni iranti |
Nitori naa, eni ti o ba fe ki o ranti re |
(Al-Ƙur’an) wa ninu awon takada alapon-onle |
A gbe e ga, A si se e ni mimo |
ni owo awon onkotia (iyen, awon molaika) |
كِرَامٍ بَرَرَةٍ(16) awon alapon-onle, awon eni rere |
Won ti fi eniyan gegun-un (nipa) bi o se je alaimoore julo |
Ki si ni Allahu fi seda re |
Ninu ato l’O ti seda re. O si pebubu (eya-ara) re |
Leyin naa, O se ona atiwaye ni irorun fun un |
Leyin naa, O maa pa a. O si maa fi sinu saree |
Leyin naa, nigba ti Allahu ba fe, O maa gbe e dide |
E gbo, eniyan ko ti i se nnkan ti Allahu pa lase fun un |
Nitori naa, ki eniyan woye si ounje re |
Dajudaju Awa n ro ojo ni pupo |
Leyin naa, A mu ile san kankan |
A si mu koro eso hu jade lati inu re |
ati eso ajara ati kannafuru |
ati igi ororo Zaetun ati dabinu |
ati awon ogba t’o kun fun igi |
ati awon eso (miiran) pelu ewe ti eranko n je, (A mu won hu jade) |
(Won je nnkan) igbadun fun eyin ati awon eran-osin yin |
Nigba ti fifon sinu iwo nigba keji ba sele |
ni ojo ti eniyan yoo sa fun arakunrin re |
ati iya re pelu baba re |
ati iyawo re pelu awon omo re |
Eni kookan won ni ojo yen l’o ti ni oran t’o maa to o o ran |
Awon oju kan lojo yen yoo mole |
Won yo maa rerin-in, won yo si maa dunnu |
Awon oju kan lojo yen ni eruku yo si bo mole |
Okunkun yo si bo won mole |
Awon wonyen, awon ni alaigbagbo, elese |
المزيد من السور باللغة اليوربا:
تحميل سورة عبس بصوت أشهر القراء :
قم باختيار القارئ للاستماع و تحميل سورة عبس كاملة بجودة عالية
أحمد العجمي
خالد الجليل
سعد الغامدي
سعود الشريم
عبد الباسط
عبد الله الجهني
علي الحذيفي
فارس عباد
ماهر المعيقلي
محمد جبريل
المنشاوي
الحصري
مشاري العفاسي
ناصر القطامي
ياسر الدوسري
Wednesday, January 22, 2025
لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب