Surah An-Naziat with Yoruba
Allahu bura pelu awon molaika t’o n fi ona ele gba emi awon alaigbagbo |
O tun bura pelu awon molaika t’o n fi ona ero gba emi awon onigbagbo ododo |
O tun bura pelu awon molaika t’o n yara gaga nibi ase Re |
O tun bura pelu awon molaika t’o maa siwaju emi awon onigbagbo ododo wonu Ogba Idera taara |
O tun bura pelu awon molaika t’o n seto ile aye |
Ni ojo ti ifon akoko fun opin aye maa mi gbogbo aye titi pelu ohun igbe |
Ifon keji fun Ajinde si maa tele e |
Awon okan yoo maa gbon pepe ni ojo yen |
Oju won yo si wale ni ti iyepere |
Won yoo wi pe: "Se Won tun maa da wa pada si ibere isemi (bii taye ni) |
Se nigba ti a ti di eegun t’o kefun tan |
Won wi pe: "Idapada ofo niyen nigba naa (fun eni t’o pe e niro) |
Nitori naa, igbe eyo kan si ni |
Nigba naa ni won yoo bara won lori ile gbansasa |
Nje oro (Anabi) Musa ti de odo re |
(Ranti) nigba ti Oluwa re pe e ni afonifoji mimo, Tuwa |
Lo ba Fir‘aon, dajudaju o ti tayo enu-ala |
Ki o si so pe: "Nje o maa safomo ara re (kuro ninu aigbagbo) bi |
Ki emi si fi ona mo o de odo Oluwa re. Nitori naa, ki o paya (Re) |
O si fi ami t’o tobi han an |
(Amo) o pe e lopuro. O si yapa re |
Leyin naa, o keyin si i. O si n sise (tako o) |
O ko (awon eniyan) jo, o si ke gbajari |
O si wi pe: "Emi ni oluwa yin, eni giga julo |
Nitori naa, Allahu gba a mu pelu iya ikeyin ati akoko (nipa oro enu re ikeyin yii ati akoko) |
Dajudaju ariwoye wa ninu iyen fun eni t’o n paya (Allahu) |
Se eyin le lagbara julo ni iseda ni tabi sanmo ti Allahu mo |
Allahu gbe aja re ga soke. O si se e ni pipe t’o gun rege |
O se oru re ni dudu. O si fa iyaleta re yo jade |
Ati ile, O te e perese leyin iyen |
O mu omi re ati irugbin re jade lati inu re |
Ati awon apata, O fi idi won mule sinsin |
Igbadun ni fun yin ati fun awon eran-osin yin |
Sugbon nigba ti iparun nla ba de |
ni ojo ti eniyan yoo ranti ohun t’o se nise |
Won si maa fi Ina han kedere fun (gbogbo) eni t’o riran |
Nitori naa, ni ti eni t’o ba tayo enu-ala |
ti o tun gbe ajulo fun isemi aye |
dajudaju ina Jehim, ohun ni ibugbe (re) |
وَأَمَّا مَنْ خَافَ مَقَامَ رَبِّهِ وَنَهَى النَّفْسَ عَنِ الْهَوَىٰ(40) Ni ti eni ti o ba paya iduro niwaju Oluwa re, ti o tun ko ife-inu fun emi (ara re) |
dajudaju Ogba Idera, ohun ni ibugbe (re) |
Won n bi o leere nipa Akoko naa pe: "Igba wo l’o maa sele |
Ona wo ni iwo le fi ni (imo) iranti re na |
Odo Oluwa re ni opin imo nipa re wa |
Iwo kuku ni olukilo fun eni t’o n paya re |
كَأَنَّهُمْ يَوْمَ يَرَوْنَهَا لَمْ يَلْبَثُوا إِلَّا عَشِيَّةً أَوْ ضُحَاهَا(46) Ni ojo ti won maa ri i, won maa da bi eni pe won ko lo tayo irole tabi iyaleta (ojo) kan lo (nile aye) |
More surahs in Yoruba:
Download surah An-Naziat with the voice of the most famous Quran reciters :
surah An-Naziat mp3 : choose the reciter to listen and download the chapter An-Naziat Complete with high quality
Ahmed Al Ajmy
Bandar Balila
Khalid Al Jalil
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdul Rashid Sufi
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Yasser Al Dosari
لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب