Fatır suresi çevirisi Yoruba
Gbogbo ope n je ti Allahu, Olupileda awon sanmo ati ile, (Eni ti) O se awon molaika alapa meji ati meta ati merin ni Ojise. O n se alekun ohun ti O ba fe lara eda. Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
Ohunkohun ti Allahu ba si ona re sile ninu ike fun awon eniyan, ko si eni ti o le da a duro. Ohunkohun ti O ba si mu dani, ko si eni ti o le mu un wa leyin Re. Oun si ni Alagbara, Ologbon |
Eyin eniyan, e ranti idera Allahu lori yin. Nje eledaa kan yato si Allahu tun wa ti o n pese fun yin lati inu sanmo ati ile? Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, bawo ni won se n se yin lori kuro nibi ododo |
وَإِن يُكَذِّبُوكَ فَقَدْ كُذِّبَتْ رُسُلٌ مِّن قَبْلِكَ ۚ وَإِلَى اللَّهِ تُرْجَعُ الْأُمُورُ(4) Ti won ba pe o ni opuro, won kuku ti pe awon Ojise kan ni opuro siwaju re. Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si |
Eyin eniyan, dajudaju adehun Allahu ni ododo. E ma se je ki isemi aye tan yin je. Ki e si ma se je ki (Esu) eletan tan yin je |
Dajudaju Esu ni ota fun yin. Nitori naa, e mu un ni ota. O kan n pe awon ijo re nitori ki won le je ero inu Ina t’o n jo fofo |
Awon t’o sai gbagbo, iya lile n be fun won. Awon t’o si gbagbo ni ododo, ti won se ise rere, aforijin ati esan t’o tobi n be fun won |
Se eni ti won se ise aburu owo re ni oso fun, ti o si n ri i ni (ise) daadaa, (l’o fe banuje le lori?) Dajudaju Allahu n si eni ti O ba fe lona. O si n fi ona mo eni ti O ba fe. Nitori naa, ma se banuje nitori tiwon. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa ohun ti won n se |
Allahu ni Eni ti O fi awon ategun ranse. (Ategun naa) si maa tu esujo soke. A si fi fun ilu (ti ile re) ti ku lomi mu. A si fi ta ile naa ji leyin ti o ti ku. Bayen ni ajinde (eda yo se ri) |
Eni ti o ba n fe iyi dajudaju ti Allahu ni gbogbo iyi patapata. Odo Re ni oro daadaa n goke lo. O si n gbe ise rere goke (si odo Re). Awon ti won n pete awon aburu, iya lile n be fun won. Ete awon wonyen si maa parun |
Allahu da yin lati ara erupe. Leyin naa, (O tun da yin) lati ara ato. Leyin naa, O se yin ni ako-abo. Obinrin kan ko nii loyun, ko si nii bimo afi pelu imo Re. Ati pe A o nii fa emi elemii-gigun gun, A o si ni se adinku ninu ojo ori (elomiiran), afi ki o ti wa ninu tira kan. Dajudaju iyen rorun fun Allahu |
Awon odo meji naa ko dogba; eyi ni (omi) didun gan-an, ti mimu re n lo tinrin lofun. Eyi si ni (omi) iyo t’o moro. Ati pe ninu gbogbo (omi odo wonyi) l’e ti n je eran (eja) tutu. E si n wa kusa awon ohun oso ti e n wo (sara). O si n ri awon oko oju-omi t’o n la aarin omi koja nitori ki e le wa ninu oore Allahu ati nitori ki e le dupe (fun Un) |
(Allahu) n ti oru bo inu osan. O si n ti osan bo inu oru. O ro oorun ati osupa; ikookan won n rin fun gbedeke akoko kan. Iyen ni Allahu, Oluwa yin. TiRe ni ijoba. Awon ti e si n pe leyin Re, won ko ni ikapa kan lori epo koro inu dabinu |
Ti e ba pe won, won ko le gbo ipe yin. Ti o ba si je pe won gbo, won ko le da yin lohun. Ati pe ni Ojo Ajinde, won yoo tako bi e se fi won se akegbe fun Allahu. Ko si si eni ti o le fun o ni iro kan (nipa eda ju) iru (iro ti) Onimo-ikoko (fun o nipa won) |
۞ يَا أَيُّهَا النَّاسُ أَنتُمُ الْفُقَرَاءُ إِلَى اللَّهِ ۖ وَاللَّهُ هُوَ الْغَنِيُّ الْحَمِيدُ(15) Eyin eniyan, eyin ni alaini (ti e ni bukata) si Allahu. Allahu, Oun ni Oloro, Olope |
Ti O ba fe, O maa ko yin kuro nile. O si maa mu eda titun wa |
Iyen ko si kagara kan ba Allahu |
Eleru ese kan ko nii ru eru ese elomiiran. Koda ki eni kan ti eru ese wo lorun ke si (elomiiran) fun abaru eru ese re, won ko nii ba a ru kini kan ninu re, ibaa je ibatan. Awon ti o n sekilo fun ni awon t’o n paya Oluwa won ni ikoko, ti won si n kirun. Eni ti o ba safomo (ara re kuro ninu iwa ese), o safomo fun emi ara re ni. Odo Allahu si ni abo eda |
Afoju ati oluriran ko dogba |
Awon ookun ati imole (ko dogba) |
Awon iboji ati igbona oorun (ko dogba) |
Awon alaaye ati oku ko dogba. Dajudaju Allahu l’O n fun eni ti O ba fe ni oro gbo. Iwo ko si le fun eni ti o wa ninu saree ni oro gbo |
Iwo ko je kini kan bi ko se olukilo |
Dajudaju Awa fi ododo ran o nise. (O si je) oniroo-idunnu ati olukilo. Ko si ijo kan (siwaju re) afi ki olukilo ti re koja laaarin won |
Ti won ba si n pe o ni opuro, awon t’o siwaju won naa kuku pe (oro Allahu) niro (nigba ti) awon Ojise won wa ba won pelu awon eri t’o yanju, awon ipin-ipin Tira ati Tira t’o n tanmole si oro esin |
ثُمَّ أَخَذْتُ الَّذِينَ كَفَرُوا ۖ فَكَيْفَ كَانَ نَكِيرِ(26) Leyin naa, Mo gba awon t’o sai gbagbo mu. Bawo si ni bi Mo se (fi iya) ko (aburu fun won) ti ri |
Se o o ri i pe dajudaju Allahu l’O so omi kale lati sanmo? A si fi mu awon eso ti awo re yato sira won jade. Ati pe awon oju ona funfun ati pupa ti awo re yato sira won pelu alawo dudu kirikiri wa ninu awon apata |
Ati pe o wa ninu awon eniyan, awon nnkan elemii ati awon eran-osin ti awo won yato sira won, gege bi (awo eso ati apata) wonyen (se yato sira won). Awon t’o n paya Allahu ninu awon erusin Re ni awon onimo (ti won mo pe), dajudaju Allahu ni Alagbara, Alaforijin |
Dajudaju awon t’o n ke tira Allahu, ti won n kirun, ti won si n na ninu nnkan ti A se ni arisiki fun won ni ikoko ati ni gbangba, won n nireti si owo kan ti ko nii parun |
لِيُوَفِّيَهُمْ أُجُورَهُمْ وَيَزِيدَهُم مِّن فَضْلِهِ ۚ إِنَّهُ غَفُورٌ شَكُورٌ(30) (Won n se bee) nitori ki Allahu le san won ni esan rere won ati nitori ki O le se alekun fun won ninu oore ajulo Re. Dajudaju Oun ni Alaforijin, Olope |
Ohun ti A fi ranse si o ninu Tira, ohun ni ododo ti o n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o siwaju re. Dajudaju Allahu ni Onimo-ikoko, Oluriran nipa awon erusin Re |
Leyin naa, A jogun tira (al-Ƙur’an) fun awon ti A sa lesa ninu awon erusin Wa. Nitori naa, alabosi t’o n bo emi ara re si wa ninu won. Oluse-deede wa ninu won. Olugbawaju nibi awon ise rere tun wa ninu won pelu iyonda Allahu. Iyen si ni oore ajulo t’o tobi |
Awon Ogba Idera gbere ni won yoo wo inu re. Awon kerewu wura ati okuta olowo iyebiye ni A oo maa fi se oso fun won ninu re. Ati pe aso alaari ni aso won ninu re |
وَقَالُوا الْحَمْدُ لِلَّهِ الَّذِي أَذْهَبَ عَنَّا الْحَزَنَ ۖ إِنَّ رَبَّنَا لَغَفُورٌ شَكُورٌ(34) Won yoo so pe: “Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti O mu ibanuje kuro fun wa. Dajudaju Oluwa wa ni Alaforijin, Olope |
Eni ti O so wa kale sinu ibugbe gbere ninu oore ajulo Re. Wahala kan ko nii kan wa ninu re. Ikaaare kan ko si nii ba wa ninu re |
Ati pe awon t’o sai gbagbo, ina Jahnamo n be fun won. A o nii pa won (sinu re), ambosibosi pe won yoo ku. A o si nii gbe iya re fuye fun won. Bayen ni A se n san gbogbo awon alaigbagbo ni esan |
Won yoo maa logun iranlowo ninu re pe: “Oluwa wa, mu wa jade nitori ki a le lo se ise rere, yato si eyi ti a maa n se.” Se A o fun yin ni emi gigun lo to fun eni ti o ba fe lo isiti lati ri i lo ninu asiko naa ni? Olukilo si wa ba yin. Nitori naa, e to iya wo. Ko si nii si alaranse kan fun awon alabosi |
إِنَّ اللَّهَ عَالِمُ غَيْبِ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ إِنَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ(38) Dajudaju Allahu ni Onimo-ikoko awon sanmo ati ile. Dajudaju Oun ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu igba-aya eda |
Oun ni Eni t’O n fi yin se arole lori ile. Nitori naa, eni ti o ba sai gbagbo, (iya) aigbagbo re wa lori re. Aigbagbo awon alaigbagbo ko si nii fun won ni alekun kan lodo Oluwa won bi ko se ibinu. Aigbagbo awon alaigbagbo ko si nii fun won ni alekun kan bi ko se ofo |
So pe: “E so fun mi nipa awon orisa yin ti e n pe leyin Allahu, e fi ohun ti won da han mi lori ile? Tabi won ni ipin kan (pelu Allahu) nibi (iseda) awon sanmo? Tabi A fun won ni tira kan, ti won ni eri t’o yanju ninu re? Rara o! Ko si adehun kan ti awon alabosi, apa kan won n se fun apa kan bi ko se etan.” |
Dajudaju Allahu l’O n mu awon sanmo ati ile duro sinsin ti won ko fi ye lule. Dajudaju ti won ba si ye lule, ko si eni kan kan ti o maa mu un duro leyin Re. Dajudaju Allahu n je Alafarada, Alaforijin |
Won si fi Allahu bura ti ibura won si lagbara gan-an pe: "Dajudaju ti olukilo kan ba fi le wa ba awon, dajudaju awon yoo mona taara ju eyikeyii ninu ijo (t’o ti siwaju) lo." Nigba ti olukilo si wa ba won, (eyi) ko se alekun kan fun won bi ko se sisa (fun ododo) |
ni ti sise igberaga lori ile ati ni ti ipete aburu. Iya ipete aburu ko si nii ko le eni kan lori afi onise aburu. Se won n reti kini kan bi ko se ise (Allahu lori) awon eni akoko? Nitori naa, o o nii ri iyipada fun ise Allahu. Ani se, o o nii ri iyipada fun ise Allahu |
Se won ko rin kiri lori ile ki won wo bi ikangun awon t’o siwaju won se ri? Won si ni agbara ju awon (wonyi) lo! Ati pe ko si kini kan ninu awon sanmo ati ile ti o le mori bo lowo Allahu. Dajudaju Allahu n je Onimo, Alagbara |
Ti o ba je pe Allahu yo (tete) maa mu eniyan pelu ohun ti won se nise ni, iba ti se ku nnkan elemii kan kan mo lori ile. Sugbon O n lo won lara di gbedeke akoko kan. Nigba ti akoko naa ba de, dajudaju Allahu ni Oluriran nipa awon erusin Re |
Yoruba diğer sureler:
En ünlü okuyucuların sesiyle Fatır Suresi indirin:
Surah Fatir mp3: yüksek kalitede dinlemek ve indirmek için okuyucuyu seçerek
Ahmed El Agamy
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Ali Al Hudhaifi
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Muhammad Jibril
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Nasser Al Qatami
Yasser Al Dosari
Bizim için dua et, teşekkürler