La sourate An-Naba en Yoruba
Nipa ki ni won n bira won leere na |
Nipa iro ikoko nla ni |
eyi ti won n yapa enu si |
Rara! Won n bo wa mo |
Leyin naa, ni ti ododo won n bo wa mo |
Nje Awa ko se ile ni ite bi |
ati awon apata ni eekan (fun ile) |
A si seda yin ni orisirisi (ako ati abo) |
A se oorun yin ni isinmi |
A tun se ale ni ibora |
A tun se osan ni (asiko fun) wiwa ije-imu |
A tun mo sanmo meje t’o lagbara soke yin |
A tun se oorun ni imole t’o n tan gbola |
Ati pe A so omi t’o n bo telera won kale lati inu awon esujo |
nitori ki A le fi mu koro eso ati irugbin jade |
pelu awon ogba t’o kun digbi fun nnkan oko |
Dajudaju ojo ipinya, o ni gbedeke akoko kan |
(Iyen ni) ojo ti won a fon fere oniwo fun ajinde. Eyin yo si maa wa nijo-nijo |
Won si maa si sanmo sile. O si maa di awon ilekun |
Won maa mu awon apata rin (bo si aye miiran). O si maa di ahunpeena |
Dajudaju ina Jahanamo, o lugo sile loju ona |
(O je) ibugbe fun awon alakoyo |
Won yoo maa gbe inu re fun igba gbooro |
Won ko nii ri itura tabi ohun mimu kan towo ninu re |
ayafi omi gbigbona ati awoyunweje |
جَزَاءً وِفَاقًا(26) (O je) esan t’o se weku (ise won) |
Dajudaju won ki i reti isiro-ise |
Won si pe awon ayah Wa niro gan-an |
Gbogbo nnkan si ni A ti se akosile re sinu Tira kan |
Nitori naa, e to (iya) wo. A o si nii se alekun kan fun yin bi ko se iya |
Dajudaju igbala wa fun awon oluberu (Allahu) |
Awon ogba ati eso ajara |
ati awon olomoge, ti won ko jura won lo lojo-ori |
ati ife oti t’o kun denu (ni esan won) |
Won ko nii gbo isokuso ati oro iro ninu re |
(O je) esan lati odo Oluwa re, (o si je) ore ni ibamu si isiro-ise (won) |
رَّبِّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا الرَّحْمَٰنِ ۖ لَا يَمْلِكُونَ مِنْهُ خِطَابًا(37) (Esan naa wa lati odo) Oluwa awon sanmo, ile ati ohun t’o wa laaarin mejeeji, Ajoke-aye. Won ko si ni ikapa oro lodo Re |
Ojo ti molaika Jibril ati awon molaika (miiran) yoo duro ni owoowo. Won ko si nii soro afi eni ti Ajoke-aye ba yonda fun. Onitoun si maa soro t’o se weku |
ذَٰلِكَ الْيَوْمُ الْحَقُّ ۖ فَمَن شَاءَ اتَّخَذَ إِلَىٰ رَبِّهِ مَآبًا(39) Iyen ni ojo ododo. Nitori naa, eni ti o ba fe ki o mu ona to maa gba seri pada si odo Oluwa re pon (ni ti ironupiwada) |
Dajudaju A fi iya t’o sunmo se ikilo fun yin. Ojo ti eniyan yoo maa wo ohun ti o ti siwaju, alaigbagbo yo si wi pe: "Yee, emi iba si je erupe, (emi iba la ninu iya) |
Plus de sourates en Yoruba :
Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :
Téléchargez le fichier mp3 de la sourate An-Naba : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate An-Naba complète en haute qualité.















Donnez-nous une invitation valide