Surah Ash_shuraa with Yoruba
حم(1) Ha mim |
عسق(2) ‘Aen sin ƙof |
كَذَٰلِكَ يُوحِي إِلَيْكَ وَإِلَى الَّذِينَ مِن قَبْلِكَ اللَّهُ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ(3) Bayen ni Allahu, Alagbara, Ologbon se n fi imisi ranse si iwo ati awon t’o siwaju re |
لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۖ وَهُوَ الْعَلِيُّ الْعَظِيمُ(4) TiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. O ga, O tobi |
Sanmo fee faya lati oke won (nipa titobi Allahu). Awon molaika si n se afomo pelu idupe fun Oluwa won. Won si n toro aforijin fun awon t’o wa lori ile. Gbo Mi, dajudaju Allahu, Oun ni Alaforijin, Asake-orun |
Awon t’o mu awon alatileyin kan leyin Re, Allahu si ni Alaabo lori won. Iwo si ko ni oluso lori won |
Bayen ni A se fi al-Ƙur’an ranse si o ni ede Larubawa nitori ki o le fi se ikilo fun ’Ummul-Ƙuro (iyen, ara ilu Mokkah) ati enikeni ti o ba wa ni ayika re (iyen, ara ilu yooku), ati nitori ki o le fi se ikilo nipa Ojo Akojo, ti ko si iyemeji ninu re. Ijo kan yoo wa ninu Ogba Idera. Ijo kan yo si wa ninu Ina t’o n jo |
Ti o ba je pe Allahu ba fe, iba se won ni ijo elesin eyo kan. Sugbon O n fi eni ti O ba fe sinu ike Re. Awon alabosi, ko si nii si alaabo ati alaranse kan fun won |
Se won mu awon alaabo kan leyin Re ni? Allahu, Oun si ni Alaabo. Oun l’O n so awon oku di alaaye. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
Ohunkohun ti e ba yapa enu nipa re, idajo re di odo Allahu. Iyen ni Allahu, Oluwa mi. Oun ni mo gbarale. Odo Re si ni mo maa seri pada si (ni ti ironupiwada). oro Allahu ati idajo Re. Pelu agboye yii ayah yii je okan ninu awon ayah t’o n pa wa lase lati fi al-Ƙur’an ati sunnah Anabi (sollalahu alayhi wa sallam) yanju awon oro iyapa-enu |
(Oun ni) Olupileda awon sanmo ati ile. O seda awon obinrin fun yin lati ara yin. O tun seda awon abo eran-osin lati ara awon ako eran-osin. O n mu yin po si i (nipa iseda yin ni ako-abo). Ko si kini kan bi iru Re. Oun si ni Olugbo, Oluriran |
TiRe ni awon kokoro apoti-oro awon sanmo ati ile. O n te arisiki sile fun eni ti O ba fe. O si n diwon re (fun elomiiran). Dajudaju Oun ni Onimo nipa gbogbo nnkan |
(Allahu) se ni ofin fun yin ninu esin (’Islam) ohun ti O pa ni ase fun (Anabi) Nuh ati eyi ti O fi ranse si o, ati ohun ti A pa lase fun (Anabi) ’Ibrohim, (Anabi) Musa ati (Anabi) ‘Isa pe ki e gbe esin naa duro. Ki e si ma se pin si ijo otooto ninu re. Wahala l’o je fun awon osebo nipa nnkan ti o n pe won si (nibi mimu Allahu ni okan soso). Allahu l’O n sesa eni ti O ba fe sinu esin Re (ti o n pe won si). O si n fi ona mo eni ti o ba n seri pada si odo Re (nipase ironupiwada) |
(Awon osebo) ko si pin si ijo otooto afi leyin ti imo (’Islam) de ba won. (Won se bee) nipase ote aarin won (si awon Anabi). Ti ko ba je pe oro kan ti siwaju lodo Oluwa re (pe Oun yoo lo won lara) titi di gbedeke akoko kan ni, Won iba ti dajo laaarin won. Dajudaju awon ti A jogun Tira fun leyin won si tun wa ninu iyemeji t’o gbopon nipa ’Islam |
Nitori iyen, pepe (sinu ’Islam), ki o si duro sinsin gege bi Won se pa o lase. Ma si se tele ife-inu won. Ki o si so pe: "Mo gbagbo ninu eyikeyii Tira ti Allahu sokale. Won si pa mi lase pe ki ng se deede laaarin yin. Allahu ni Oluwa wa ati Oluwa yin. Tiwa ni awon ise wa. Tiyin si ni awon ise yin. Ko si ija laaarin awa ati eyin. Allahu l’O si maa ko wa jo papo. Odo Re si ni abo eda.” |
Awon t’o n ba (Anabi s.a.w.) ja nipa (esin) Allahu leyin igba ti awon eniyan ti gba fun un, eri won maa wo lodo Oluwa won. Ibinu n be lori won. Iya lile si wa fun won |
Allahu ni Eni ti O so Tira (al-Ƙur’an) ati (ofin) osuwon (deede) kale pelu ododo. Ati pe ki l’o maa fi mo o pe o see se ki Akoko naa ti sunmo |
Awon ti ko gba a gbo n wa a pelu ikanju. Awon t’o si gbagbo ni ododo n paya re. Won si mo pe dajudaju ododo ni. Kiye si i, dajudaju awon t’o n jiyan nipa Akoko naa ti wa ninu isina t’o jinna |
اللَّهُ لَطِيفٌ بِعِبَادِهِ يَرْزُقُ مَن يَشَاءُ ۖ وَهُوَ الْقَوِيُّ الْعَزِيزُ(19) Allahu ni Alaaanu fun awon erusin Re. O n se arisiki fun eni ti O ba fe. Oun si ni Alagbara, Abiyi |
Enikeni ti o ba gbero lati gba eso (ise re ni) orun, A maa se alekun si eso re fun un. Enikeni ti o ba si gbero lati gba eso (ise re ni) aye, A maa fun un ninu re. Ko si nii si ipin kan kan fun un mo ni orun |
Tabi won ni awon orisa kan t’o sofin (iborisa) fun won ninu esin, eyi ti Allahu ko yonda re? Ti ko ba je ti oro asoyan (pe A o nii kanju je won niya), Awa iba ti mu idajo wa laaarin won. Dajudaju awon alabosi, iya eleta-elero si wa fun won |
O maa ri awon alabosi ti won yoo maa paya nitori ohun ti won se nise, ti o si maa ko le won lori. Awon t’o si gbagbo ni ododo, ti won se ise rere maa wa ni awon aye t’o rewa julo ninu Ogba Idera. Ohun ti won ba n fe maa wa fun won ni odo Oluwa won. Iyen, ohun ni oore ajulo t’o tobi |
Iyen ni eyi ti Allahu fi n se iro idunnu fun awon erusin Re, awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere. So pe: "Emi ko beere owo-oya lowo yin lori re bi ko se ife ebi.” Enikeni ti o ba se rere kan, A maa se alekun rere fun un. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Olope |
Tabi won n wi pe: "O da adapa iro mo Allahu ni?" Nitori naa, ti Allahu ba fe, O maa fi edidi di okan re pa. Ati pe Allahu yoo pa iro re. O si maa fi ododo rinle pelu oro Re. Dajudaju Oun ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu igba-aya eda |
Oun ni Eni t’O n gba ironupiwada awon erusin Re. O n se amojukuro nibi awon asise. O si mo ohun ti e n se nise |
O n gba adua awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere. O si n se alekun fun won ninu ola Re. Awon alaigbagbo, iya lile si wa fun won |
Ti o ba je pe Allahu te arisiki sile regede fun awon erusin Re ni, won iba tayo enu-ala lori ile. Sugbon O n so (arisiki) ti O ba fe kale niwon-niwon. Dajudaju Oun ni Alamotan, Oluriran nipa awon erusin Re |
Oun si ni Eni t’O n so omi ojo kale leyin igba ti won ti soreti nu. O si n fon ike Re ka. Oun si ni Alaabo, Eleyin |
Ati pe ninu ami Re ni iseda awon sanmo, ile ati nnkan ti O fonka saaarin mejeeji ninu awon nnkan abemi. Oun si ni Alagbara lori ikojo won nigba ti O ba fe |
وَمَا أَصَابَكُم مِّن مُّصِيبَةٍ فَبِمَا كَسَبَتْ أَيْدِيكُمْ وَيَعْفُو عَن كَثِيرٍ(30) Ohunkohun ti o ba kan yin ninu adanwo, ohun ti e fi owo ara yin fa ni. O si n samojukuro nibi opolopo |
وَمَا أَنتُم بِمُعْجِزِينَ فِي الْأَرْضِ ۖ وَمَا لَكُم مِّن دُونِ اللَّهِ مِن وَلِيٍّ وَلَا نَصِيرٍ(31) Eyin ko si nii mori bo (mo Allahu lowo) lori ile. Ko si alaabo ati alaranse kan fun yin leyin Allahu |
O tun wa ninu awon ami Re, awon oko oju-omi t’o n rin loju omi (t’o da) bi awon oke apata giga |
Ti Allahu ba fe, O maa mu ategun naa duro, (awon oko oju-omi naa) si maa di ohun ti ko nii lo mo lori omi. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun gbogbo onisuuru, oludupe |
Ti Allahu ba fe, O maa mu ategun naa duro, (awon oko oju-omi naa) si maa di ohun ti ko nii lo mo lori omi. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun gbogbo onisuuru, oludupe |
وَيَعْلَمَ الَّذِينَ يُجَادِلُونَ فِي آيَاتِنَا مَا لَهُم مِّن مَّحِيصٍ(35) Awon t’o n se atako si awon ayah Wa si maa mo pe ko si ibusasi kan fun won |
Nitori naa, ohunkohun ti A ba fun yin, igbadun aye nikan ni. Ohun ti o wa lodo Allahu loore julo, o si maa seku titi laelae fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si n gbarale Oluwa won |
وَالَّذِينَ يَجْتَنِبُونَ كَبَائِرَ الْإِثْمِ وَالْفَوَاحِشَ وَإِذَا مَا غَضِبُوا هُمْ يَغْفِرُونَ(37) (Ohun ti o wa lodo Allahu tun wa fun) awon t’o n jinna si awon ese nlanla ati awon iwa ibaje, ati (awon t’o je pe) nigba ti won ba binu, won yoo saforijin |
(Ohun ti o wa lodo Allahu tun wa fun) awon t’o jepe ti Oluwa won, ti won n kirun, oro ara won si je ijiroro laaarin ara won, won tun n na ninu arisiki ti A pese fun won |
وَالَّذِينَ إِذَا أَصَابَهُمُ الْبَغْيُ هُمْ يَنتَصِرُونَ(39) (Ohun ti o wa lodo Allahu tun wa fun) awon ti (o je pe) nigba ti won ba se abosi si won, won yoo gbesan won pada |
Esan aburu si ni aburu bi iru re. Enikeni ti o ba si samojukuro, ti o tun satunse, esan re wa lodo Allahu. Dajudaju (Allahu) ko nifee awon alabosi |
وَلَمَنِ انتَصَرَ بَعْدَ ظُلْمِهِ فَأُولَٰئِكَ مَا عَلَيْهِم مِّن سَبِيلٍ(41) Dajudaju eni ti o ba si gbesan leyin ti won se abosi si i, awon wonyen (ti won sabosi si), ko si ibawi kan kan fun won |
Awon ti ibawi wa fun ni awon t’o n sabosi si awon eniyan, ti won tun n tayo enu-ala lori ile lai letoo. Awon wonyen ni iya eleta-elero wa fun |
وَلَمَن صَبَرَ وَغَفَرَ إِنَّ ذَٰلِكَ لَمِنْ عَزْمِ الْأُمُورِ(43) Enikeni ti o ba se suuru, ti o tun saforijin, dajudaju iyen wa ninu awon ipinnu oro t’o pon dandan |
Enikeni ti Allahu ba si lona, ko tun si alaabo kan fun un mo leyin Re. O si maa ri awon alabosi nigba ti won ba ri Ina, won yoo wi pe: "Nje ona kan kan wa ti a le fi pada si ile aye |
O si maa ri won ti A maa ko won lo sinu Ina; won yoo palolo lati ara iyepere, won yo si maa wo fin-in-fin. Awon t’o gbagbo ni ododo si maa so pe: "Dajudaju awon eni ofo ni awon t’o se emi ara won ati ara ile won ni ofo ni Ojo Ajinde." Kiye si i, dajudaju awon alabosi yoo wa ninu iya gbere |
Ko si nii si alaabo kan fun won ti o maa ran won lowo leyin Allahu. Ati pe enikeni ti Allahu ba si lona, ko le si ona kan kan fun un |
E jepe Oluwa yin siwaju ki ojo kan to de, ti ko si idapada kan fun un ni odo Allahu. Ko si ibusasi kan fun yin ni ojo yen. Ko si nii si olukoya kan fun yin |
Nitori naa, ti won ba gbunri, A o ran o pe ki o je oluso fun won. Ko si kini kan t’o di dandan fun o bi ko se ise-jije. Ati pe dajudaju nigba ti A ba fun eniyan ni ike kan to wo lati odo Wa, o maa dunnu si i. Ti aburu kan ba si kan an nipase ohun ti owo won ti siwaju (ni ise aburu), dajudaju eniyan ni alaimoore |
Ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile. O n seda ohun ti O ba fe. O n ta eni ti O ba fe lore omobinrin. O si n ta eni ti O ba fe ni lore omokunrin |
أَوْ يُزَوِّجُهُمْ ذُكْرَانًا وَإِنَاثًا ۖ وَيَجْعَلُ مَن يَشَاءُ عَقِيمًا ۚ إِنَّهُ عَلِيمٌ قَدِيرٌ(50) Tabi ki O se won ni orisi meji; omokunrin ati omobinrin. O si n se eni ti O ba fe ni agan. Dajudaju Oun ni Onimo, Alagbara |
Ko letoo fun abara kan pe ki Allahu ba a soro afi ki (oro naa) je imisi (isipaya mimo), tabi ki o je leyin gaga, tabi ki O ran Ojise kan (ti) |
Bayen si ni A se fi imisi ranse si o ninu ase Wa. Iwo ko mo ki ni Tira ati igbagbo ododo tele (siwaju imisi naa),1 sugbon A se imisi naa ni imole kan ti A n fi se imona fun eni ti A ba fe ninu awon erusin Wa. Dajudaju iwo n pepe si ona taara (’Islam). 2 ise wiridi ni Anabi (sollalahu alayhi wa sallam) maa n se ninu ogbun Hira siwaju ki o to di Anabi Olohun iro l’o fi pa. Idi ni pe |
Ona Allahu, Eni ti ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile n je tiRe. Gbo! Odo Allahu ni awon oro eda yoo pada si |
More surahs in Yoruba:
Download surah Ash_shuraa with the voice of the most famous Quran reciters :
surah Ash_shuraa mp3 : choose the reciter to listen and download the chapter Ash_shuraa Complete with high quality
Ahmed Al Ajmy
Bandar Balila
Khalid Al Jalil
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdul Rashid Sufi
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Yasser Al Dosari
لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب