La sourate As-Sajdah en Yoruba
الم(1) ’Alif lam mim |
تَنزِيلُ الْكِتَابِ لَا رَيْبَ فِيهِ مِن رَّبِّ الْعَالَمِينَ(2) Isokale Tira naa, ko si iyemeji ninu re (pe o wa) lati odo Oluwa gbogbo eda |
Tabi won n wi pe: “O da adapa iro re ni.” Rara o! Ododo ni lati odo Oluwa re nitori ki o le fi sekilo fun awon eniyan kan, ti olukilo kan ko wa ba won ri siwaju re, nitori ki won le mona |
Allahu ni Eni ti O seda awon sanmo, ile ati nnkan t’o wa laaarin mejeeji laaarin ojo mefa. Leyin naa, O gunwa sori Ite-ola. Ko si alaabo ati olusipe kan fun yin leyin Re. Se e o nii lo iranti ni |
O n seto oro (eda) lati sanmo wa sori ile. Leyin naa, (abo oro eda) yoo gunke to O lo laaarin ojo kan ti odiwon re to egberun odun ninu onka ti e n ka |
ذَٰلِكَ عَالِمُ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ(6) Iyen ni Onimo-ikoko ati gbangba, Alagbara, Asake-orun |
الَّذِي أَحْسَنَ كُلَّ شَيْءٍ خَلَقَهُ ۖ وَبَدَأَ خَلْقَ الْإِنسَانِ مِن طِينٍ(7) Eni t’o se gbogbo nnkan ti O da ni daadaa. O si bere iseda eniyan lati inu erupe amo |
Leyin naa, O se awon aromodomo re lati ara ohun ti A mu jade lati ara omi lile yepere |
Leyin naa, O to (orikeerikee) re dogba. O si fe (emi) si i lara ninu emi Re (ti O da). O tun se igboro, iriran ati okan fun yin. Die ni ope ti e n da |
Won si wi pe: “Nje nigba ti a ba ti poora sinu ile, nje awa tun le wa ni eda titun mo? Ani se, awon ni alaigbagbo ninu ipade Oluwa won |
۞ قُلْ يَتَوَفَّاكُم مَّلَكُ الْمَوْتِ الَّذِي وُكِّلَ بِكُمْ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُمْ تُرْجَعُونَ(11) So pe: “Molaika iku eyi ti A fi ti yin maa gba emi yin. Leyin naa, odo Oluwa yin ni won maa da yin pada si.” gege bi O se je Eledaa ohun gbogbo. Ko si eda kan ti o maa to isemi wo afi pelu iyonda Allahu (subhanahu wa ta’ala). Ko si si eda kan ti o maa to iku wo afi pelu iyonda Allahu (subhanahu wa ta’ala). Nipa eyi Allahu l’O n fi ase Re gba emi kuro lara eda Re ni akoko ti O ti ko mo on ninu kadara. Iyen ni o jeyo ninu surah az-Zumor; 39:42. Bakan naa |
(Iwo iba ri eemo) ti o ba je pe o ri awon elese nigba ti won ba sori ko ni odo Oluwa won, (won si maa wi pe): “Oluwa wa, a ti riran, a si ti gboran (bayii), nitori naa, da wa pada (si ile aye) nitori ki a le lo se ise rere; dajudaju awa ni alamodaju.” |
Ti o ba je pe A ba fe ni, dajudaju A iba fun gbogbo emi kookan ni imona re, sugbon oro naa ti se lati odo Mi (bayii pe): “Dajudaju Mo maa mu ninu awon alujannu ati eniyan ni apapo kun inu ina Jahanamo.” |
Nitori naa, e to iya wo nitori pe e ti gbagbe ipade ojo yin (oni) yii. Dajudaju Awa naa yoo gbagbe yin sinu Ina. E to iya gbere wo nitori ohun ti e n se nise |
Awon t’o gbagbo ninu awon ayah Wa ni awon ti o je pe nigba ti won ba fi se isiti fun won, won yoo doju bole ni oluforikanle, won yo si se afomo pelu idupe fun Oluwa won. Won ko si nii segberaga |
Won n gbe egbe won kuro lori ibusun. Won si n pe Oluwa won ni ti ipaya ati ireti. Won si n na ninu ohun ti A pese fun won |
فَلَا تَعْلَمُ نَفْسٌ مَّا أُخْفِيَ لَهُم مِّن قُرَّةِ أَعْيُنٍ جَزَاءً بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ(17) Ko si emi kan ti o mo ohun ti A fi pamo fun won ninu awon nnkan itutu oju. (O je) esan ohun ti won n se nise (rere) |
أَفَمَن كَانَ مُؤْمِنًا كَمَن كَانَ فَاسِقًا ۚ لَّا يَسْتَوُونَ(18) Nje eni t’o je onigbagbo ododo da bi eni t’o je obileje bi? Won ko dogba |
Ni ti awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, awon ibugbe (ninu) Ogba Idera n be fun won. (O je) ohun ti A pese sile (de won) nitori ohun ti won n se nise (rere) |
Ni ti awon t’o baleje, Ina ni ibugbe won. Igbakigba ti won ba fe jade kuro ninu re, A o si maa da won pada sinu re. A si maa so fun won pe: “E to iya Ina ti e n pe niro wo.” |
وَلَنُذِيقَنَّهُم مِّنَ الْعَذَابِ الْأَدْنَىٰ دُونَ الْعَذَابِ الْأَكْبَرِ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ(21) Dajudaju A maa fun won to wo ninu iya t’o kere julo (nile aye) yato si iya t’o tobi julo (lorun) nitori ki won le seri pada (sibi ododo siwaju iku won) |
Ati pe ta l’o se abosi t’o tayo eni ti won fi awon ayah Wa se isiti fun, leyin naa, ti o gbunri kuro nibe? Dajudaju Awa maa gbesan lara awon elese |
Dajudaju A fun (Anabi) Musa ni Tira. Nitori naa, ma se wa ninu iyemeji nipa bi o se pade re (iyen, ninu irin-ajo oru ati gigun sanmo). A si se Tira naa ni imona fun awon omo ’Isro’il |
Ati pe A se awon asiwaju kan ninu won ni afinimona pelu ase Wa nigba ti won se suuru. Won si n ni amodaju nipa awon ayah Wa |
إِنَّ رَبَّكَ هُوَ يَفْصِلُ بَيْنَهُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ فِيمَا كَانُوا فِيهِ يَخْتَلِفُونَ(25) Dajudaju Oluwa re, O maa se idajo laaarin won ni Ojo Ajinde nipa ohun ti won n yapa enu si |
Se ko foju han si won pe, meloo meloo ninu awon iran ti A ti pare siwaju won. Awon naa si n rin koja ninu awon ibugbe won! Dajudaju awon ami wa ninu iyen. Nitori naa, se won ko nii teti gboro (ododo ni) |
Tabi won ko ri i pe dajudaju Awa l’A n wa omi ojo lo sori ile gbigbe, ti A si n fi mu irugbin jade? Awon eran-osin won ati awon naa si n je ninu re. Nitori naa, se won ko riran ni |
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا الْفَتْحُ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ(28) Won si n wi pe: “Igba wo ni Idajo yii ti e ba je olododo?” |
قُلْ يَوْمَ الْفَتْحِ لَا يَنفَعُ الَّذِينَ كَفَرُوا إِيمَانُهُمْ وَلَا هُمْ يُنظَرُونَ(29) So pe: “Ni Ojo Idajo, igbagbo won ko nii sanfaani fun awon t’o sai gbagbo (ninu Allahu). A o si nii fun won ni isinmi (ninu Ina).” |
Nitori naa, seri kuro lodo won, ki o si maa reti (Ojo Idajo). Dajudaju awon naa n reti (re) |
Plus de sourates en Yoruba :
Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :
Téléchargez le fichier mp3 de la sourate As-Sajdah : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate As-Sajdah complète en haute qualité.















Donnez-nous une invitation valide