Surah Muhammad with Yoruba
الَّذِينَ كَفَرُوا وَصَدُّوا عَن سَبِيلِ اللَّهِ أَضَلَّ أَعْمَالَهُمْ(1) Awon t’o sai gbagbo, ti won tun seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, (Allahu) maa so ise won dofo |
Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won se awon ise rere, ti won tun gbagbo ninu ohun ti Won sokale fun (Anabi) Muhammad, ohun si ni ododo lati odo Oluwa won, (Allahu) maa pa awon (ise) aburu won re, O si maa se atunse oro won si daadaa |
Iyen nitori pe dajudaju awon t’o sai gbagbo tele iro. Ati pe dajudaju awon t’o gbagbo tele ododo lati odo Oluwa won. Bayen ni Allahu se n fi apejuwe won lele fun awon eniyan |
Nitori naa, nigba ti e ba pade awon t’o sai gbagbo (loju ogun esin), e maa be won lorun nso titi di igba ti e maa fi bori won. (Ti e ba segun) ki e de won nigbekun. Leyin naa, e le tu won sile ni ofe tabi ki e tu won sile pelu owo itusile titi (okunfa) ogun esin yoo fi kase nile. Iyen (wa bee). Ti o ba je pe Allahu ba fe, iba gbesan funra Re (lai nii la ogun jija lo), sugbon nitori ki O le dan apa kan yin wo lara apa kan ni. Awon musulumi ti won si pa si oju ogun esin, Allahu ko nii so ise won dofo |
O maa to won sona. O si maa tun oro won se si daadaa |
O maa fi won wo inu Ogba Idera, eyi ti O ti fi mo won |
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِن تَنصُرُوا اللَّهَ يَنصُرْكُمْ وَيُثَبِّتْ أَقْدَامَكُمْ(7) Eyin ti e gbagbo ni ododo, ti e ba ran (esin) Allahu lowo, (Allahu) maa ran yin lowo. O si maa mu ese yin duro sinsin |
وَالَّذِينَ كَفَرُوا فَتَعْسًا لَّهُمْ وَأَضَلَّ أَعْمَالَهُمْ(8) Awon t’o sai gbagbo, egbe ni fun won. (Allahu) si maa ba ise won je |
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ كَرِهُوا مَا أَنزَلَ اللَّهُ فَأَحْبَطَ أَعْمَالَهُمْ(9) Iyen nitori pe dajudaju won korira ohun ti Allahu sokale. Nitori naa, (Allahu) si ba ise won je |
Se won ko rin kiri lori ile ki won wo bi ikangun awon t’o siwaju won se ri? Allahu pa won re. Iru re tun wa fun awon alaigbagbo |
ذَٰلِكَ بِأَنَّ اللَّهَ مَوْلَى الَّذِينَ آمَنُوا وَأَنَّ الْكَافِرِينَ لَا مَوْلَىٰ لَهُمْ(11) Iyen nitori pe dajudaju Allahu ni Oluranlowo awon t’o gbagbo ni ododo. Dajudaju awon alaigbagbo, ko si oluranlowo kan fun won |
Dajudaju Allahu yoo fi awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere wo inu awon Ogba Idera, eyi ti awon odo n san ni isale re. Awon t’o si sai gbagbo, awon n gbadun, won si n je (kiri) gege bi awon eran-osin se n je (kiri). Ina si ni ibugbe fun won |
Meloo meloo ninu awon (ara) ilu ti o lagbara ju (ara) ilu re, ti o le o jade, ti A si ti pa won re. Ko si si alaranse kan fun won |
Nje eni ti o wa lori eri t’o yanju lati odo Oluwa re, se o da bi eni ti won se ise aburu re ni oso fun, ti won si tele ife-inu won |
Apejuwe Ogba Idera eyi ti Won se ni adehun fun awon oluberu Allahu (niyi): awon omi odo wa ninu re ti ko nii yi pada ati awon odo wara ti adun re ko nii yi pada ati awon odo oti didun fun awon t’o maa mu un ati awon odo oyin mimo. Awon oniruuru eso wa fun won ninu re ati aforijin lati odo Oluwa won. (Se eni ti o wa ninu Ogba Idera yii) da bi olusegbere ninu Ina bi, ti won n fun won ni omi gbigbona mu, ti o si maa ja awon ifun won putuputu |
O wa ninu won, eni ti o teti si oro re titi di igba ti won ba jade kuro ni odo re tan, won yo si wi fun awon onimo-esin pe: "Ki l’o so leee kan na?" Awon wonyen ni awon ti Allahu ti di okan won pa. Won si tele ife-inu won |
وَالَّذِينَ اهْتَدَوْا زَادَهُمْ هُدًى وَآتَاهُمْ تَقْوَاهُمْ(17) Awon t’o si tele imona, (Allahu) salekun imona fun won. O si maa fun won ni iberu won (ninu Allahu) |
Se won n reti kini kan bi ko se Akoko naa, ti o maa de ba won ni ojiji? Awon ami re kuku ti de. Nitori naa, bawo ni iranti (yo se wulo fun) won nigba ti o ba de ba won |
Nitori naa, mo pe dajudaju ko si olohun ti ijosin to si afi Allahu. Ki o si toro aforijin fun ese re ati fun awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin. Allahu mo lilo-bibo yin ati ibusinmi yin |
Awon t’o gbagbo ni ododo n so pe: "Ki ni ko je ki Won so surah kan kale?" Nigba ti won ba so surah alainipon-na kale, ti won si so oro ija ogun esin ninu re, iwo yoo ri awon ti arun wa ninu okan won, ti won yoo maa wo o ni wiwo bi eni pe won ti daku lo ponrangandan. Ohun ti o si dara julo fun won |
ni itele ase (Allahu) ati (siso) oro rere. Nigba ti ogun esin si ti di dandan, won iba ni igbagbo ododo ninu Allahu, iba dara julo fun won |
فَهَلْ عَسَيْتُمْ إِن تَوَلَّيْتُمْ أَن تُفْسِدُوا فِي الْأَرْضِ وَتُقَطِّعُوا أَرْحَامَكُمْ(22) Nje ko sunmo ti eyin (alaisan okan wonyi) ba de’po ase, pe e o nii sebaje lori ile ati pe e o nii ja okun-ibi yin |
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ لَعَنَهُمُ اللَّهُ فَأَصَمَّهُمْ وَأَعْمَىٰ أَبْصَارَهُمْ(23) Awon wonyen ni awon ti Allahu ti sebi le. Nitori naa, O di won leti pa. O si fo iriran won |
أَفَلَا يَتَدَبَّرُونَ الْقُرْآنَ أَمْ عَلَىٰ قُلُوبٍ أَقْفَالُهَا(24) Se won ko nii ronu nipa al-Ƙur’an ni tabi awon agadagodo ti wa lori okan won ni |
Dajudaju awon t’o peyin da (si ’Islam) leyin ti imona ti foju han si won, Esu lo se isina ni oso fun won. O si fun won ni ireti asan nipa emi gigun |
Iyen nitori pe (awon alaisan okan) n so fun awon t’o korira ohun ti Allahu sokale pe: "Awa yoo tele yin ninu apa kan oro naa." Allahu si mo asiri won |
فَكَيْفَ إِذَا تَوَفَّتْهُمُ الْمَلَائِكَةُ يَضْرِبُونَ وُجُوهَهُمْ وَأَدْبَارَهُمْ(27) Bawo ni (o se maa ri) nigba ti awon molaika ba gba emi won, ti won yo si maa gba oju won ati eyin won |
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمُ اتَّبَعُوا مَا أَسْخَطَ اللَّهَ وَكَرِهُوا رِضْوَانَهُ فَأَحْبَطَ أَعْمَالَهُمْ(28) Iyen nitori pe dajudaju won tele ohun ti o bi Allahu ninu. Won si tun korira iyonu Re. Nitori naa, Allahu ti ba awon ise won je |
أَمْ حَسِبَ الَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٌ أَن لَّن يُخْرِجَ اللَّهُ أَضْغَانَهُمْ(29) Tabi awon ti arun wa ninu okan won n lero pe Allahu ko nii se afihan adisokan buruku won ni |
Ati pe ti A ba fe Awa iba fi won han o, iwo iba si mo won pelu ami won. Dajudaju iwo yoo mo won nipa ipekoro-soro (won). Allahu si mo awon ise (owo) yin |
Dajudaju A maa dan yin wo titi A fi maa safi han awon olujagun-esin ati awon onisuuru ninu yin. A si maa gbidanwo awon iro yin |
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, ti won tun ko inira ba Ojise Allahu leyin ti imona ti foju han si won, won ko le ko inira kini kan ba Allahu. (Allahu) yo si ba ise won je |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e tele (oro) Allahu, e tele (oro) Ojise naa, ki e si ma se ba awon ise yin je |
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, leyin naa ti won ku nigba ti won je alaigbagbo, Allahu ko nii forijin won |
E ma se kaaare, ki e si ma se pepe fun kosogunmo, nigba ti e ba n leke lowo. Allahu wa pelu yin; ko si nii ko adinku ba esan awon ise yin |
Ere ati iranu ni isemi aye. (Amo) ti e ba gbagbo (ninu Allahu), ti e si beru (Re), O maa fun yin ni awon esan yin. Ko si nii beere awon dukia yin (pe ki e fi gbogbo re yo Zakah) |
إِن يَسْأَلْكُمُوهَا فَيُحْفِكُمْ تَبْخَلُوا وَيُخْرِجْ أَضْغَانَكُمْ(37) Ti (Allahu) ba beere re ni owo yin (pe ki e fi gbogbo re yo Zakah), ti O si wonkoko mo yin, e maa sahun. O si maa mu arun okan yin jade (asiri yin yo si tu sita) |
Eyin naa ma niwonyi ti won n pe lati nawo fun esin Allahu. Sugbon eni t’o n sahun wa ninu yin. Enikeni ti o ba sahun, o se e fun emi ara re. Allahu ni Oloro. Eyin si ni alaini. Ti e ba gbunri, (Allahu) maa fi ijo miiran paaro yin. Leyin naa, won ko si nii da bi iru yin |
More surahs in Yoruba:
Download surah Muhammad with the voice of the most famous Quran reciters :
surah Muhammad mp3 : choose the reciter to listen and download the chapter Muhammad Complete with high quality
Ahmed Al Ajmy
Bandar Balila
Khalid Al Jalil
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdul Rashid Sufi
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Yasser Al Dosari
لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب