La sourate Al-Fath en Yoruba
Dajudaju Awa fun o ni isegun ponnbele |
nitori ki Allahu le saforijin ohun ti o siwaju ninu asise re ati ohun ti o keyin (ninu re), ati nitori ki O le sasepe idera Re le o lori ati nitori ki O le fi ese re rinle soju ona taara (’Islam) |
ati nitori ki Allahu le saranse fun o ni aranse t’o lagbara |
Oun ni Eni ti O so ifayabale sinu okan awon onigbagbo ododo nitori ki won le lekun ni igbagbo si igbagbo won. Ti Allahu si ni awon omo ogun sanmo ati ile. Allahu si n je Onimo, Ologbon |
(O se bee fun won) nitori ki O le mu awon onigbagbo ododo lokunrin ati onigbagbo ododo lobinrin wo inu awon Ogba Idera, eyi ti awon odo n san ni isale re, olusegbere ni won ninu re, ati nitori ki O le pa awon asise won re. Iyen si je erenje nla ni odo Allahu |
Ati nitori ki O le fiya je awon sobe-selu musulumi lokunrin ati awon sobe-selu musulumi lobinrin, pelu awon osebo lokunrin ati awon osebo lobinrin, awon elerokero nipa Allahu ni ti ero aburu. Apadasi aburu n be fun won. Allahu ti binu si won. O ti sebi le won. O si ti pese ina Jahnamo sile de won. O si buru ni ikangun |
وَلِلَّهِ جُنُودُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ وَكَانَ اللَّهُ عَزِيزًا حَكِيمًا(7) Ti Allahu si ni awon omo ogun sanmo ati ile. Allahu si n je Alagbara, Ologbon |
Dajudaju Awa ran o nise (pe ki o je) olujerii, oniroo-idunnu ati olukilo |
لِّتُؤْمِنُوا بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ وَتُعَزِّرُوهُ وَتُوَقِّرُوهُ وَتُسَبِّحُوهُ بُكْرَةً وَأَصِيلًا(9) nitori ki e le ni igbagbo ododo ninu Allahu ati Ojise Re, ati (nitori ki) e le se iranlowo fun (Ojise naa) ati nitori ki e le pataki re, ati nitori ki e le safomo fun (Allahu) ni owuro ati ni asale |
Dajudaju awon t’o n sadehun fun o (pe awon ko nii fese fee loju ogun), dajudaju Allahu ni won n sadehun fun. Owo Allahu wa loke owo won. Enikeni ti o ba tu adehun re, o tu u fun emi ara re. Enikeni ti o ba si mu adehun t’o se fun Allahu se, (Allahu) yoo fun un ni esan nla |
Awon olusaseyin fun ogun esin ninu awon Larubawa oko yoo maa wi fun o pe: "Awon dukia wa ati awon ara ile wa l’o ko airoju ba wa. Nitori naa, toro aforijin fun wa." Won n fi ahon won wi ohun ti ko si ninu okan won. So pe: "Ta ni o ni ikapa kini kan fun yin lodo Allahu ti O ba gbero (lati fi) inira kan yin tabi ti O ba gbero anfaani kan fun yin? Rara (ko si). Allahu n je Alamotan nipa ohun ti e n se nise |
Rara (ki i se ise kan l’o di yin lowo lati lo jagun, amo) e ti lero pe Ojise ati awon onigbagbo ododo ko nii pada si odo ara ile won mo laelae. Won se iyen ni oso sinu okan yin. E si ro ero aburu. E si je ijo iparun |
وَمَن لَّمْ يُؤْمِن بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ فَإِنَّا أَعْتَدْنَا لِلْكَافِرِينَ سَعِيرًا(13) Enikeni ti ko ba gba Allahu ati Ojise Re gbo, dajudaju Awa pese Ina sile de awon alaigbagbo |
Ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile. O n saforijin fun eni ti O ba fe. O si n je eni ti O ba fe niya. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun |
Awon olusaseyin fun ogun (Hudaebiyyah) n wi pe: "Nigba ti e lo sibi oro-ogun (Kaebar) nitori ki e le ri nnkan ko, won ja wa ju sile ki a ma le tele yin lo." (Awon olusaseyin wonyi) si n gbero lati yi oro Allahu pada ni. (Iwo Anabi) so pe: "Eyin ko gbodo tele wa. Bayen ni Allahu se so teletele." Won yo si tun wi pe: "Rara (ko ri bee), e n se keeta wa ni." Rara (eyin ko se keeta won, amo), won ki i gbo agboye (oro) afi die |
So fun awon olusaseyin fun ogun ninu awon Larubawa oko pe: "Won maa pe yin si awon eniyan kan ti won ni agbara ogun jija. E maa ja won logun tabi ki won juwo juse sile (fun ’Islam). Ti eyin ba tele ase (yii), Allahu yoo fun yin ni esan t’o dara. Ti eyin ba si gbunri pada gege bi e se gbunri siwaju, (Allahu) yo si fi iya eleta-elero je yin |
Ko si ese fun afoju, ko si ese fun aro, ko si si ese fun alaisan (ti won ko ba lo soju ogun). Enikeni ti o ba tele ti Allahu ati Ojise Re, (Allahu) yoo mu un wo inu awon Ogba Idera, eyi ti awon odo n san ni isale re. Enikeni ti o ba si gbunri, O maa je e ni iya eleta-elero |
Dajudaju Allahu ti yonu si awon onigbagbo ododo nigba ti won n sadehun fun o labe igi (pe awon ko nii fese fee loju ogun). Nitori naa, (Allahu) mo ohun ti o wa ninu okan won. O si so ifokanbale kale fun won. O si san won ni esan isegun t’o sunmo |
وَمَغَانِمَ كَثِيرَةً يَأْخُذُونَهَا ۗ وَكَانَ اللَّهُ عَزِيزًا حَكِيمًا(19) ati awon oro ogun opolopo ti won yoo ri ko. Allahu n je Alagbara, Ologbon |
Ati pe Allahu sadehun awon oro ogun opolopo ti eyin yoo ri ko fun yin. O si tete mu eyi wa fun yin. O tun ko awon eniyan lowo ro fun yin nitori ki o le je ami kan fun awon onigbagbo ododo ati nitori ki O le fi ese yin rinle soju ona taara (’Islam) |
Ati omiran ti e o lagbara lori re, (amo ti) Allahu ti rokirika re. Allahu si n je Alagbara lori gbogbo nnkan |
Ti o ba je pe awon t’o sai gbagbo gbogun dide si yin ni, won iba peyin da (lati sagun fun yin). Leyin naa, won ko nii ri alaabo tabi alaranse kan |
سُنَّةَ اللَّهِ الَّتِي قَدْ خَلَتْ مِن قَبْلُ ۖ وَلَن تَجِدَ لِسُنَّةِ اللَّهِ تَبْدِيلًا(23) Ise Allahu, eyi t’o ti sele siwaju (ni eyi). O o si nii ri iyipada fun ise Allahu (lori awon ota Re) |
Oun si ni Eni ti O ko won lowo ro fun yin. O si ko eyin naa lowo ro fun won ninu ilu Mokkah leyin igba ti O ti fi yin bori won. Allahu si n je Oluriran nipa ohun ti e n se nise |
Awon (osebo) ni awon t’o sai gbagbo, ti won se yin lori kuro ni Mosalasi Haram, ti won tun de eran ore mole ki o ma le de aye re. Ti ki i ba se ti awon okunrin (ti won ti di) onigbagbo ododo ati awon obinrin (ti won ti di) onigbagbo ododo (ninu ilu Mokkah), ti eyin ko si mo won, ki eyin ma lo pa won, ki eyin ma lo fara ko ese lati ara won nipase aimo, (Allahu iba ti ko yin lowo ro fun won. Allahu ko yin lowo ro fun won se) nitori ki O le fi eni ti o ba fe sinu ike Re. Ti o ba je pe won wa ni otooto ni (onigbagbo ododo loto, alaigbagbo loto), Awa iba je awon t’o sai gbagbo ninu won ni iya eleta-elero |
(Ranti) nigba ti awon t’o sai gbagbo ko igbonara sinu okan won ni igbonara ti igba aimokan, Allahu si so ifokanbale kale fun Ojise Re ati awon onigbagbo ododo. O si je ki oro iberu (Re) wa pelu won; Won ni eto si i julo, awon ni won si ni in. Allahu si ni Onimo nipa gbogbo nnkan |
Dajudaju Allahu ti so ala Ojise Re di ododo pe - ti Allahu ba fe - dajudaju eyin yoo wo inu Mosalasi Haram ni eni ifayabale. E maa fa irun ori yin; e maa ge irun (ori yin mole), e o si nii paya. Nitori naa, (Allahu) mo ohun ti eyin ko mo. Yato si iyen, O tun se isegun t’o sunmo (fun yin) |
(Allahu) Oun ni Eni ti O fi imona ati esin ododo (’Islam) ran Ojise Re nitori ki O le fi bori esin (miiran), gbogbo re patapata. Allahu si to ni Elerii |
Muhammad ni Ojise Allahu. Awon t’o wa pelu re, won le mo awon alaigbagbo, alaaanu si ni won laaarin ara won. O maa ri won ni oludawote-orunkun ati oluforikanle (lori irun), ti won n wa oore ajulo ati iyonu lati odo Allahu. Ami won wa ni oju won nibi oripa iforikanle. Iyen ni apejuwe won ninu Taorah ati apejuwe won ninu ’Injil, gege bi koro eso igi t’o yo ogomo re jade. Leyin naa, o nipon (o lagbara), o si duro gbagidi lori igi re. O si n jo awon agbe loju. (Allahu fi aye gba Anabi ati awon Sohabah re) nitori ki O le fi won se ohun ibinu fun awon alaigbagbo. Allahu sadehun aforijin ati esan nla fun awon t’o gbagbo, ti won si se awon ise rere ninu won |
Plus de sourates en Yoruba :
Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :
Téléchargez le fichier mp3 de la sourate Al-Fath : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate Al-Fath complète en haute qualité.
Ahmed Al Ajmy Bandar Balila Khalid Al Jalil Saad Al Ghamdi Saud Al Shuraim Abdul Basit Abdul Rashid Sufi Abdullah Basfar Abdullah Al Juhani Fares Abbad Maher Al Muaiqly Al Minshawi Al Hosary Mishari Al-afasi Yasser Al Dosari
Donnez-nous une invitation valide