La sourate Al-Muddaththir en Yoruba
Iwo oludasobora |
Dide ki o sekilo |
Oluwa re si ni ki o gbe titobi fun |
Aso re ni ki o fo mo |
Orisa ni ki o jinna si |
Ma se tore nitori ki o le ri pupo gba |
Oluwa re ni ki o se suuru fun |
Nigba ti won ba fon fere oniwo fun ajinde |
iyen, ni ojo yen, ni ojo inira |
ti ko nii rorun fun awon alaigbagbo |
Fi Mi da eni ti Mo da ni oun nikan |
Mo si fun un ni opolopo dukia |
ati awon omokunrin t’o n be pelu re |
Mo si se aye nirorun fun un gan-an |
Leyin naa, o tun n jerankan pe ki Ng se alekun |
Rara o! Dajudaju o je alatako si awon ayah Wa |
Emi yoo la iya ponkeponke bo o lorun (ninu Ina) |
Dajudaju o ronu (lodi nipa al-Ƙur’an). O si pinnu (oro kan ninu emi re) |
Won si sebi le e nipa bi o se pinnu |
Leyin naa, Won tun sebi le e nipa bi o se pinnu |
ثُمَّ نَظَرَ(21) Leyin naa, o wo sun |
Leyin naa, o faju ro, o si diju magbari |
Leyin naa, o peyin da, o si segberaga |
O si wi pe: "Ki ni eyi bi ko se idan atowodowo |
Ki ni eyi bi ko se oro abara |
Emi yoo fi sinu ina Saƙor |
Ki l’o mu o mo ohun t’o n je ina Saƙor |
(Saƙor) ko nii se e ku, ko si nii pa a ti |
O maa jo awo ara di dudu |
(Awon molaika) mokandinlogun ni eso re |
Awa ko se eni kan ni eso Ina afi awon molaika. Awa ko si se onka won (bee) bi ko se (nitori ki o le je) adanwo fun awon t’o sai gbagbo, ati nitori ki awon ti A fun ni Tira le ni amodaju ati nitori ki awon ti won gbagbo ni ododo le lekun ni igbagbo ododo. (O ri bee) nitori ki awon ti A fun ni Tira ati awon onigbagbo ododo ma baa seyemeji ati nitori ki awon ti arun wa ninu okan won ati awon alaigbagbo le wi pe: "Ki ni Allahu gba lero pelu apejuwe yii?" Bayen ni Allahu se n si eni ti O ba fe lona, O si n to eni ti O ba fe sona. Ko si si eni ti o mo awon omo ogun Oluwa re afi Oun naa. (Ina Saƙor) ko si je kini kan bi ko se iranti fun abara |
E gbo! Allahu bura pelu osupa |
O tun bura pelu ale nigba ti o ba lo |
O tun bura pelu owuro nigba ti ojumo ba mo |
Dajudaju (ina Saƙor) ni okan ninu (awon adanwo) t’o tobi |
(O je) ikilo fun abara |
Fun eni ti o ba fe ninu yin lati te siwaju tabi lati fa seyin |
Emi kookan ni oniduuro fun ohun t’o se nise |
Ayafi awon ero owo otun |
Won yoo maa bira won leere oro ninu awon Ogba Idera |
nipa awon elese pe |
Ki ni o mu yin wo inu ina Saƙor |
Won yoo wi pe: "Awa ko si ninu awon olukirun ni |
Awa ko si si ninu awon t’o n bo awon mekunnu |
Awa si maa n so isokuso pelu awon onisokuso |
Ati pe awa maa n pe Ojo esan niro |
titi iku fi de ba wa |
Ipe awon olusipe ko si nii se won ni anfaani |
Ki lo mu won na ti won n gbunri kuro nibi iranti |
bi eni pe awon ni ketekete t’o n sa lo |
t’o sa fun kinihun |
بَلْ يُرِيدُ كُلُّ امْرِئٍ مِّنْهُمْ أَن يُؤْتَىٰ صُحُفًا مُّنَشَّرَةً(52) Rara, nse ni enikookan ninu won n fe ki A fun oun naa ni Tira ti o maa see te han awon eniyan (bii ti al-Ƙur’an) |
Rara. Won ko paya orun ni |
E gbo! Dajudaju al-Ƙur’an ni iranti |
Nitori naa, eni ti o ba fe ko ranti re |
وَمَا يَذْكُرُونَ إِلَّا أَن يَشَاءَ اللَّهُ ۚ هُوَ أَهْلُ التَّقْوَىٰ وَأَهْلُ الْمَغْفِرَةِ(56) Won ko si nii ranti (al-Ƙur’an) afi ti Allahu ba fe. (Allahu) Oun l’a gbodo beru. Oun l’o si laforijin |
Plus de sourates en Yoruba :
Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :
Téléchargez le fichier mp3 de la sourate Al-Muddaththir : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate Al-Muddaththir complète en haute qualité.















Donnez-nous une invitation valide