📖 0/604 oju-iwe ti a ka
📄 560
Surah At-Tahrim

Surah At-Tahrim

66:1
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ لِمَ تُحَرِّمُ مَآ أَحَلَّ ٱللَّهُ لَكَۖ تَبۡتَغِي مَرۡضَاتَ أَزۡوَٰجِكَۚ وَٱللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ ١
Iwo Anabi, nitori ki ni o se maa so nnkan ti Allahu se ni eto fun o di eewo? Iwo n wa iyonu awon iyawo re. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun
66:2
قَدۡ فَرَضَ ٱللَّهُ لَكُمۡ تَحِلَّةَ أَيۡمَٰنِكُمۡۚ وَٱللَّهُ مَوۡلَىٰكُمۡۖ وَهُوَ ٱلۡعَلِيمُ ٱلۡحَكِيمُ ٢
Dajudaju Allahu ti se alaye ofin itanran ibura yin fun yin. Allahu ni Oluranlowo yin. Oun si ni Onimo, Ologbon
66:3
وَإِذۡ أَسَرَّ ٱلنَّبِيُّ إِلَىٰ بَعۡضِ أَزۡوَٰجِهِۦ حَدِيثًا فَلَمَّا نَبَّأَتۡ بِهِۦ وَأَظۡهَرَهُ ٱللَّهُ عَلَيۡهِ عَرَّفَ بَعۡضَهُۥ وَأَعۡرَضَ عَنۢ بَعۡضٍۖ فَلَمَّا نَبَّأَهَا بِهِۦ قَالَتۡ مَنۡ أَنۢبَأَكَ هَٰذَاۖ قَالَ نَبَّأَنِيَ ٱلۡعَلِيمُ ٱلۡخَبِيرُ ٣
Ranti nigba ti Anabi ba okan ninu awon iyawo re s’oro asiri. Nigba ti (eni t’o ba soro, iyen Hafsoh) si soro naa fun (‘A’isah), Allahu si fi han Anabi (pe elomiiran ti gbo si i). Anabi si so apa kan re (fun Hafsoh pe: "O ti fi oro Moriyah to ‘A’isah leti."). O si fi apa kan sile (iyen, oro nipa ipo arole). Amo nigba ti (Anabi) fi iro naa to o leti, Hafsoh) so pe: "Ta ni o fun o ni iro eyi?" (Anabi) so pe: "Onimo, Alamotan l’O fun mi ni iro naa
66:4
إِن تَتُوبَآ إِلَى ٱللَّهِ فَقَدۡ صَغَتۡ قُلُوبُكُمَاۖ وَإِن تَظَٰهَرَا عَلَيۡهِ فَإِنَّ ٱللَّهَ هُوَ مَوۡلَىٰهُ وَجِبۡرِيلُ وَصَٰلِحُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۖ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ بَعۡدَ ذَٰلِكَ ظَهِيرٌ ٤
Ti eyin mejeeji ba ronu piwada si odo Allahu, (O maa gba ironupiwada yin). Sebi okan yin kuku ti te (sibi ki Anabi ma fee Moriyah). Ti e ba si ran ara yin lowo (lati ko ibanuje) ba a, dajudaju Allahu ni Oluranlowo re, ati (molaika) Jibril ati eni rere ninu awon onigbagbo ododo. Leyin iyen, awon molaika ti won je oluranlowo (tun wa fun un)
66:5
عَسَىٰ رَبُّهُۥٓ إِن طَلَّقَكُنَّ أَن يُبۡدِلَهُۥٓ أَزۡوَٰجًا خَيۡرًا مِّنكُنَّ مُسۡلِمَٰتٍ مُّؤۡمِنَٰتٍ قَٰنِتَٰتٍ تَٰٓئِبَٰتٍ عَٰبِدَٰتٍ سَٰٓئِحَٰتٍ ثَيِّبَٰتٍ وَأَبۡكَارًا ٥
O see se, ti o ba ko yin sile, ki Oluwa re fi awon obinrin kan, ti won loore ju yin lo ropo fun un, (ti won maa je) musulumi, onigbagbo ododo, awon olutele-ase, awon oluronupiwada, olujosin, olugbaawe ni adelebo ati wundia
66:6
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ قُوٓاْ أَنفُسَكُمۡ وَأَهۡلِيكُمۡ نَارًا وَقُودُهَا ٱلنَّاسُ وَٱلۡحِجَارَةُ عَلَيۡهَا مَلَٰٓئِكَةٌ غِلَاظٌ شِدَادٌ لَّا يَعۡصُونَ ٱللَّهَ مَآ أَمَرَهُمۡ وَيَفۡعَلُونَ مَا يُؤۡمَرُونَ ٦
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e so emi ara yin ati awon ara ile yin nibi Ina. Eniyan ati okuta ni nnkan ikona re. Awon molaika t’o roro, ti won le ni eso re. Won ko nii yapa ase Allahu nibi ohun ti O ba pa lase fun won. Won si n se ohun ti won ba pa lase fun won
66:7
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَا تَعۡتَذِرُواْ ٱلۡيَوۡمَۖ إِنَّمَا تُجۡزَوۡنَ مَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ ٧
Eyin ti e sai gbagbo, e ma se saroye ni ojo oni. Ohun ti e n se nise ni A oo fi san yin ni esan
العربيةEnglishBahasa IndonesiaTürkçeРусскийفارسیFrançaisاردوবাংলাDeutschEspañol中文हिन्दीPortuguêsItalianoภาษาไทยPolskiNederlandsShqipKiswahiliO'zbekதமிழ்MelayuBosanskiSoomaaliAzərbaycanکوردی한국어日本語SvenskaDanskNorskپښتوമലയാളംසිංහලTamazightHausaአማርኛБългарскиТоҷикӣҚазақшаFilipinoسنڌيYorùbáFulfuldeТатарчаئۇيغۇرچەКыргызчаਪੰਜਾਬੀJawaతెలుగుမြန်မာગુજરાતીOromoमराठीTiếng ViệtMalagasyНохчийнWolofދިވެހިಕನ್ನಡУкраїнськаΕλληνικάქართულიខ្មែរدریQafar afMaranaoनेपाली
Al-Kur'an
Monday, August 31, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







