Surah Al-Ghashiyah ni Arabic ati Yorùbá

Ka Surah Al-Ghashiyah pẹlu itumọ pipe ni Yorùbá ati iṣẹ́-ohun. Itumọ ẹsẹ kọọkan. (26 Ẹsẹ — مكية). Al-Ghashiyah Gbọ, Al-Ghashiyah Itumọ, Al-Ghashiyah mp3, Al-Ghashiyah pdf.

Ka ati Gbọ Surah Al-Ghashiyah

🎧 Ẹsẹ
M Mishary Rashid Alafasy
M Mahmoud Khalil Al-Husary
A Abdurrahman As-Sudais
M Mohamed Siddiq Al-Minshawi
A Abdul Basit Abdul Samad
A Ali Al-Hudhaify
A Ahmed ibn Ali al-Ajamy
A Abu Bakr Ash-Shaatree
M Muhammad Ayyoub
A Abdullah Basfar
A Abdullah Al-Juhani
M Maher Al Muaiqly
x1
هَلْ أَتَاكَ حَدِيثُ الْغَاشِيَةِ ۝١
📖 Itumọ Ẹsẹ 1
Nje oro nipa ohun t’o maa bo eda mole ti de odo re
وُجُوهٌ يَوْمَئِذٍ خَاشِعَةٌ ۝٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 2
Awon oju kan yoo wale (ni ti iyepere) ni ojo yen
عَامِلَةٌ نَّاصِبَةٌ ۝٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 3
Onise asekudorogbo (ni won nile aye)
تَصْلَىٰ نَارًا حَامِيَةً ۝٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 4
Won maa wo inu Ina t’o gbona janjan (ni orun)
تُسْقَىٰ مِنْ عَيْنٍ آنِيَةٍ ۝٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 5
Won si maa fun (won) ni omi gbigbona mu
لَّيْسَ لَهُمْ طَعَامٌ إِلَّا مِن ضَرِيعٍ ۝٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 6
Ko si ounje kan fun won ayafi igi elegun-un gbigbe
لَّا يُسْمِنُ وَلَا يُغْنِي مِن جُوعٍ ۝٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 7
Ko nii mu won sanra. Ko si nii ro won loro ninu ebi
وُجُوهٌ يَوْمَئِذٍ نَّاعِمَةٌ ۝٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 8
Awon oju kan yo si kun fun igbadun ni ojo yen
لِّسَعْيِهَا رَاضِيَةٌ ۝٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 9
nitori pe (o) yonu si (esan) ise re
فِي جَنَّةٍ عَالِيَةٍ ۝١٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 10
(O maa) wa ninu Ogba Idera giga
لَّا تَسْمَعُ فِيهَا لَاغِيَةً ۝١١
📖 Itumọ Ẹsẹ 11
Won ko nii gbo isokuso ninu re
فِيهَا عَيْنٌ جَارِيَةٌ ۝١٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 12
Omi iseleru t’o n san wa ninu re
فِيهَا سُرُرٌ مَّرْفُوعَةٌ ۝١٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 13
Awon ibusun ti won gbe soke wa ninu re
وَأَكْوَابٌ مَّوْضُوعَةٌ ۝١٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 14
ati awon ife imumi ti won gbe kale (si arowoto won)
وَنَمَارِقُ مَصْفُوفَةٌ ۝١٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 15
ati awon irori ti won to si egbe ara won
وَزَرَابِيُّ مَبْثُوثَةٌ ۝١٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 16
ati awon ite ateeka
أَفَلَا يَنظُرُونَ إِلَى الْإِبِلِ كَيْفَ خُلِقَتْ ۝١٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 17
Nitori naa, se won ko wo rakunmi, bi A ti seda re ni
وَإِلَى السَّمَاءِ كَيْفَ رُفِعَتْ ۝١٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 18
ati sanmo, bi A ti se gbe e soke
وَإِلَى الْجِبَالِ كَيْفَ نُصِبَتْ ۝١٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 19
ati apata, bi A ti se gbe e naro (sinu ile)
وَإِلَى الْأَرْضِ كَيْفَ سُطِحَتْ ۝٢٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 20
ati ile, bi A ti se te e sile ni gbansasa
فَذَكِّرْ إِنَّمَا أَنتَ مُذَكِّرٌ ۝٢١
📖 Itumọ Ẹsẹ 21
Nitori naa, seranti. Iwo kuku ni oluseranti
لَّسْتَ عَلَيْهِم بِمُصَيْطِرٍ ۝٢٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 22
Iwo ki i se ajeni-nipa lori won
إِلَّا مَن تَوَلَّىٰ وَكَفَرَ ۝٢٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 23
afi eni ti o ba peyinda (si ododo), ti o si sai gbagbo
فَيُعَذِّبُهُ اللَّهُ الْعَذَابَ الْأَكْبَرَ ۝٢٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 24
Allahu si maa je e niya t’o tobi julo
إِنَّ إِلَيْنَا إِيَابَهُمْ ۝٢٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 25
Dajudaju odo Wa ni abo won wa
ثُمَّ إِنَّ عَلَيْنَا حِسَابَهُم ۝٢٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 26
Leyin naa, dajudaju Awa l’A maa se isiro-ise won
← 87 Al-Ghashiyah (88/114) 89 →
Kika Surah Al-Ghashiyah ni Yorùbá – Itumọ ati Ohun

88الغاشية Al-Ghashiyah 📚 26 Ẹsẹ مكية

Ẹsẹ kọọkan – Surah Al-Ghashiyah — 26 Ẹsẹ




Al-Kur'an


Tuesday, August 18, 2026

Don't forget us in your sincere prayers