Surah Al-Hadid ni Arabic ati Yorùbá

Ka Surah Al-Hadid pẹlu itumọ pipe ni Yorùbá ati iṣẹ́-ohun. Itumọ ẹsẹ kọọkan. (29 Ẹsẹ — مدنية). Al-Hadid Gbọ, Al-Hadid Itumọ, Al-Hadid mp3, Al-Hadid pdf.

Ka ati Gbọ Surah Al-Hadid

🎧 Ẹsẹ
M Mishary Rashid Alafasy
M Mahmoud Khalil Al-Husary
A Abdurrahman As-Sudais
M Mohamed Siddiq Al-Minshawi
A Abdul Basit Abdul Samad
A Ali Al-Hudhaify
A Ahmed ibn Ali al-Ajamy
A Abu Bakr Ash-Shaatree
M Muhammad Ayyoub
A Abdullah Basfar
A Abdullah Al-Juhani
M Maher Al Muaiqly
x1
سَبَّحَ لِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ ۝١
📖 Itumọ Ẹsẹ 1
Ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile n safomo fun Allahu. Oun si ni Alagbara, Ologbon
لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ يُحْيِي وَيُمِيتُ ۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ ۝٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 2
TiRe ni ijoba awon sanmo ati ile. O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Oun ni Alagbara lori gbogbo nnkan
هُوَ الْأَوَّلُ وَالْآخِرُ وَالظَّاهِرُ وَالْبَاطِنُ ۖ وَهُوَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ ۝٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 3
Oun ni Akoko ati Ikeyin. O han (pelu ami bibe Re). O si pamo (fun gbogbo oju nile aye). Oun ni Onimo nipa gbogbo nnkan
هُوَ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ اسْتَوَىٰ عَلَى الْعَرْشِ ۚ يَعْلَمُ مَا يَلِجُ فِي الْأَرْضِ وَمَا يَخْرُجُ مِنْهَا وَمَا يَنزِلُ مِنَ السَّمَاءِ وَمَا يَعْرُجُ فِيهَا ۖ وَهُوَ مَعَكُمْ أَيْنَ مَا كُنتُمْ ۚ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ ۝٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 4
Oun ni Eni ti O seda awon sanmo ati ile fun ojo mefa. Leyin naa, O gunwa si ori Ite-ola. O mo nnkan t’o n wo inu ile ati nnkan t’o n jade lati inu re, ati nnkan t’o n sokale lati inu sanmo ati nnkan t’o n gunke sinu re. Ati pe O wa pelu yin ni ibikibi ti e ba wa (pelu imo Re). Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise
لَّهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ وَإِلَى اللَّهِ تُرْجَعُ الْأُمُورُ ۝٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 5
TiRe ni ijoba awon sanmo ati ile. Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si
يُولِجُ اللَّيْلَ فِي النَّهَارِ وَيُولِجُ النَّهَارَ فِي اللَّيْلِ ۚ وَهُوَ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ ۝٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 6
O n ti oru bo inu osan. O si n ti osan bo inu oru. Oun si ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu igba-aya eda
آمِنُوا بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ وَأَنفِقُوا مِمَّا جَعَلَكُم مُّسْتَخْلَفِينَ فِيهِ ۖ فَالَّذِينَ آمَنُوا مِنكُمْ وَأَنفَقُوا لَهُمْ أَجْرٌ كَبِيرٌ ۝٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 7
E gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Ki e si na ninu ohun ti O fi yin se arole lori re. Nitori naa, awon t’o gbagbo ni ododo ninu yin, ti won si nawo (si oju ona esin), esan t’o tobi wa fun won
وَمَا لَكُمْ لَا تُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ ۙ وَالرَّسُولُ يَدْعُوكُمْ لِتُؤْمِنُوا بِرَبِّكُمْ وَقَدْ أَخَذَ مِيثَاقَكُمْ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ ۝٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 8
Ki ni o mu yin ti eyin ko fi nii gba Allahu gbo ni ododo? Ojise si n pe yin nitori ki e le gba Oluwa yin gbo. Allahu si ti gba adehun lowo yin, ti eyin ba je onigbagbo ododo
هُوَ الَّذِي يُنَزِّلُ عَلَىٰ عَبْدِهِ آيَاتٍ بَيِّنَاتٍ لِّيُخْرِجَكُم مِّنَ الظُّلُمَاتِ إِلَى النُّورِ ۚ وَإِنَّ اللَّهَ بِكُمْ لَرَءُوفٌ رَّحِيمٌ ۝٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 9
Oun ni Eni t’O n so awon ayah t’o yanju kale fun erusin Re nitori ki o le mu yin kuro ninu awon okunkun wa sinu imole. Dajudaju Allahu ni Alaaanu, Asake-orun fun yin
وَمَا لَكُمْ أَلَّا تُنفِقُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَلِلَّهِ مِيرَاثُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ لَا يَسْتَوِي مِنكُم مَّنْ أَنفَقَ مِن قَبْلِ الْفَتْحِ وَقَاتَلَ ۚ أُولَٰئِكَ أَعْظَمُ دَرَجَةً مِّنَ الَّذِينَ أَنفَقُوا مِن بَعْدُ وَقَاتَلُوا ۚ وَكُلًّا وَعَدَ اللَّهُ الْحُسْنَىٰ ۚ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ ۝١٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 10
Ki ni o mu yin ti eyin ko fi nii nawo fun esin Allahu? Ti Allahu si ni ogun awon sanmo ati ile. Eni ti o nawo siwaju sisi ilu Mokkah, ti o tun jagun esin, ko dogba laaarin yin (si awon miiran). Awon wonyen ni esan won tobi julo si ti awon t’o nawo leyin igba naa, ti won tun jagun esin. Eni kookan si ni Allahu s’adehun esan rere fun. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise
مَّن ذَا الَّذِي يُقْرِضُ اللَّهَ قَرْضًا حَسَنًا فَيُضَاعِفَهُ لَهُ وَلَهُ أَجْرٌ كَرِيمٌ ۝١١
📖 Itumọ Ẹsẹ 11
Ta ni eni ti o maa ya Allahu ni dukia t’o dara, O si maa sadipele re fun un. Esan alapon-onle si tun wa fun un
يَوْمَ تَرَى الْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ يَسْعَىٰ نُورُهُم بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَبِأَيْمَانِهِم بُشْرَاكُمُ الْيَوْمَ جَنَّاتٌ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا ۚ ذَٰلِكَ هُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ ۝١٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 12
Ni ojo ti o maa ri awon onigbagbo ododo lokunrin ati onigbagbo ododo lobinrin, ti imole won yoo maa tan niwaju won ati ni owo otun won, (A oo so pe:) "Iro idunnu yin ni oni ni awon Ogba Idera kan ti awon odo n san ni isale re." Olusegbere ni yin ninu re. Iyen si ni erenje nla
يَوْمَ يَقُولُ الْمُنَافِقُونَ وَالْمُنَافِقَاتُ لِلَّذِينَ آمَنُوا انظُرُونَا نَقْتَبِسْ مِن نُّورِكُمْ قِيلَ ارْجِعُوا وَرَاءَكُمْ فَالْتَمِسُوا نُورًا فَضُرِبَ بَيْنَهُم بِسُورٍ لَّهُ بَابٌ بَاطِنُهُ فِيهِ الرَّحْمَةُ وَظَاهِرُهُ مِن قِبَلِهِ الْعَذَابُ ۝١٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 13
Ni ojo ti awon sobe-selu musulumi lokunrin ati awon sobe-selu musulumi lobinrin yoo wi fun awon t’o gbagbo pe: "E duro fun wa na, e je ki a mu ninu imole yin." A oo so fun won pe: "E pada s’eyin yin, ki e lo mu imole.” Won si maa fi ogiri kan, t’o ni ilekun saarin won. Ike wa ninu re, iya si wa ni ode re ni owo iwaju re
يُنَادُونَهُمْ أَلَمْ نَكُن مَّعَكُمْ ۖ قَالُوا بَلَىٰ وَلَٰكِنَّكُمْ فَتَنتُمْ أَنفُسَكُمْ وَتَرَبَّصْتُمْ وَارْتَبْتُمْ وَغَرَّتْكُمُ الْأَمَانِيُّ حَتَّىٰ جَاءَ أَمْرُ اللَّهِ وَغَرَّكُم بِاللَّهِ الْغَرُورُ ۝١٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 14
(Awon sobe-selu musulumi) yoo pe (awon onigbagbo ododo) pe: "Se awa ko ti wa pelu yin ni?" Won so pe: "Rara, sugbon e ko iyonu ba emi ara yin (nipa isobe-selu), e reti iparun (wa), e si siyemeji (si ododo). Awon ife-okan ati iro oro si tan yin je titi ase Allahu fi de. Ati pe (Esu) eletan si tan yin je nipa Allahu
فَالْيَوْمَ لَا يُؤْخَذُ مِنكُمْ فِدْيَةٌ وَلَا مِنَ الَّذِينَ كَفَرُوا ۚ مَأْوَاكُمُ النَّارُ ۖ هِيَ مَوْلَاكُمْ ۖ وَبِئْسَ الْمَصِيرُ ۝١٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 15
Nitori naa, ni oni Awa ko nii gba itanran kan ni owo eyin ati awon t’o sai gbagbo. Ina ni ibugbe yin. Ohun l’o to si yin. Ikangun naa si buru
۞ أَلَمْ يَأْنِ لِلَّذِينَ آمَنُوا أَن تَخْشَعَ قُلُوبُهُمْ لِذِكْرِ اللَّهِ وَمَا نَزَلَ مِنَ الْحَقِّ وَلَا يَكُونُوا كَالَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ مِن قَبْلُ فَطَالَ عَلَيْهِمُ الْأَمَدُ فَقَسَتْ قُلُوبُهُمْ ۖ وَكَثِيرٌ مِّنْهُمْ فَاسِقُونَ ۝١٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 16
Se akoko ko ti i to fun awon t’o gbagbo ni ododo pe ki okan won ro fun iranti Allahu ati ohun t’o sokale ninu ododo (iyen, al-Ƙur’an). Ki won si ma se da bi awon ti A fun ni Tira ni isaaju; igba pe lori won, okan won ba le. Opolopo ninu won si ni obileje
اعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ يُحْيِي الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا ۚ قَدْ بَيَّنَّا لَكُمُ الْآيَاتِ لَعَلَّكُمْ تَعْقِلُونَ ۝١٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 17
E mo pe dajudaju Allahu l’O n so ile di aye leyin ti ile ti ku. A kuku ti salaye awon ayah naa nitori ki e le se laakaye
إِنَّ الْمُصَّدِّقِينَ وَالْمُصَّدِّقَاتِ وَأَقْرَضُوا اللَّهَ قَرْضًا حَسَنًا يُضَاعَفُ لَهُمْ وَلَهُمْ أَجْرٌ كَرِيمٌ ۝١٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 18
Dajudaju awon olutore lokunrin ati awon olutore lobinrin, ti won tun ya Allahu ni dukia t’o dara, (Allahu) yoo sadipele re fun won. Esan alapon-onle si wa fun won
وَالَّذِينَ آمَنُوا بِاللَّهِ وَرُسُلِهِ أُولَٰئِكَ هُمُ الصِّدِّيقُونَ ۖ وَالشُّهَدَاءُ عِندَ رَبِّهِمْ لَهُمْ أَجْرُهُمْ وَنُورُهُمْ ۖ وَالَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَحِيمِ ۝١٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 19
Awon t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re, awon wonyen ni awon olododo ati elerii ni odo Oluwa won. Esan won ati imole won wa fun won. Awon t’o si sai gbagbo, ti won tun pe awon ayah Wa niro, awon wonyen ni ero inu ina Jehim
اعْلَمُوا أَنَّمَا الْحَيَاةُ الدُّنْيَا لَعِبٌ وَلَهْوٌ وَزِينَةٌ وَتَفَاخُرٌ بَيْنَكُمْ وَتَكَاثُرٌ فِي الْأَمْوَالِ وَالْأَوْلَادِ ۖ كَمَثَلِ غَيْثٍ أَعْجَبَ الْكُفَّارَ نَبَاتُهُ ثُمَّ يَهِيجُ فَتَرَاهُ مُصْفَرًّا ثُمَّ يَكُونُ حُطَامًا ۖ وَفِي الْآخِرَةِ عَذَابٌ شَدِيدٌ وَمَغْفِرَةٌ مِّنَ اللَّهِ وَرِضْوَانٌ ۚ وَمَا الْحَيَاةُ الدُّنْيَا إِلَّا مَتَاعُ الْغُرُورِ ۝٢٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 20
E mo pe dajudaju isemi aye yii je ere, iranu, oso, sise iyanran laaarin ara yin ati wiwa opo dukia ati omo. (Iwonyi) da bi ojo (t’o mu irugbin jade). Irugbin re si n jo awon alaigbagbo loju. Leyin naa, o maa gbe. O si maa ri i ni pipon. Leyin naa, o maa di rirun (ti ategun maa fe danu). Iya lile ati aforijin pelu iyonu lati odo Allahu si wa ni orun. Ki si ni isemi aye yii bi ko se igbadun etan
سَابِقُوا إِلَىٰ مَغْفِرَةٍ مِّن رَّبِّكُمْ وَجَنَّةٍ عَرْضُهَا كَعَرْضِ السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ أُعِدَّتْ لِلَّذِينَ آمَنُوا بِاللَّهِ وَرُسُلِهِ ۚ ذَٰلِكَ فَضْلُ اللَّهِ يُؤْتِيهِ مَن يَشَاءُ ۚ وَاللَّهُ ذُو الْفَضْلِ الْعَظِيمِ ۝٢١
📖 Itumọ Ẹsẹ 21
E yara lo sibi aforijin lati odo Oluwa yin ati Ogba Idera ti fife re da bi fife sanmo ati ile. Won pa a lese sile de awon t’o gbagbo ninu Allahu ati awon Ojise Re. Iyen ni oore ajulo Allahu ti O n fun eni ti O ba fe. Allahu si ni Oloore nla
مَا أَصَابَ مِن مُّصِيبَةٍ فِي الْأَرْضِ وَلَا فِي أَنفُسِكُمْ إِلَّا فِي كِتَابٍ مِّن قَبْلِ أَن نَّبْرَأَهَا ۚ إِنَّ ذَٰلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرٌ ۝٢٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 22
Adanwo kan ko nii sele ni ori ile tabi (ki o sele) si eyin ayafi ki o ti wa ninu Tira siwaju ki A t’o da eda. Dajudaju iyen rorun fun Allahu
لِّكَيْلَا تَأْسَوْا عَلَىٰ مَا فَاتَكُمْ وَلَا تَفْرَحُوا بِمَا آتَاكُمْ ۗ وَاللَّهُ لَا يُحِبُّ كُلَّ مُخْتَالٍ فَخُورٍ ۝٢٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 23
(Isele n to kadara leyin) nitori ki e ma se banuje lori ohun ti o ba bo fun yin ati nitori ki e ma se yo ayoju lori ohun ti O ba fun yin. Allahu ko si nifee si gbogbo onigbeeraga, onifaari
الَّذِينَ يَبْخَلُونَ وَيَأْمُرُونَ النَّاسَ بِالْبُخْلِ ۗ وَمَن يَتَوَلَّ فَإِنَّ اللَّهَ هُوَ الْغَنِيُّ الْحَمِيدُ ۝٢٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 24
Awon t’o n sahun, ti won si n pa awon eniyan lase ahun sise (ki won mo pe) enikeni ti o ba peyinda (ti ko nawo fun esin), dajudaju Allahu, Oun ni Oloro, Olope
لَقَدْ أَرْسَلْنَا رُسُلَنَا بِالْبَيِّنَاتِ وَأَنزَلْنَا مَعَهُمُ الْكِتَابَ وَالْمِيزَانَ لِيَقُومَ النَّاسُ بِالْقِسْطِ ۖ وَأَنزَلْنَا الْحَدِيدَ فِيهِ بَأْسٌ شَدِيدٌ وَمَنَافِعُ لِلنَّاسِ وَلِيَعْلَمَ اللَّهُ مَن يَنصُرُهُ وَرُسُلَهُ بِالْغَيْبِ ۚ إِنَّ اللَّهَ قَوِيٌّ عَزِيزٌ ۝٢٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 25
Dajudaju A fi awon eri t’o yanju ran awon Ojise Wa. A so Tira kale fun won ati osuwon nitori ki awon eniyan le ri deede se (laaarin ara won). A tun so irin kale. Ohun ijagun t’o lagbara ati awon anfaani wa ninu re fun awon eniyan nitori ki Allahu le safi han eni t’o n ran (esin) Re ati Ojise Re lowo ni ikoko. Dajudaju Allahu ni Alagbara, Olubori
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا نُوحًا وَإِبْرَاهِيمَ وَجَعَلْنَا فِي ذُرِّيَّتِهِمَا النُّبُوَّةَ وَالْكِتَابَ ۖ فَمِنْهُم مُّهْتَدٍ ۖ وَكَثِيرٌ مِّنْهُمْ فَاسِقُونَ ۝٢٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 26
Dajudaju A fi ise ran (Anabi) Nuh ati (Anabi) ’Ibrohim. A fi ipo Anabi sinu awon aromodomo awon mejeeji pelu Tira (ti A fun won). Olumona wa ninu won. Opolopo ninu won si ni obileje
ثُمَّ قَفَّيْنَا عَلَىٰ آثَارِهِم بِرُسُلِنَا وَقَفَّيْنَا بِعِيسَى ابْنِ مَرْيَمَ وَآتَيْنَاهُ الْإِنجِيلَ وَجَعَلْنَا فِي قُلُوبِ الَّذِينَ اتَّبَعُوهُ رَأْفَةً وَرَحْمَةً وَرَهْبَانِيَّةً ابْتَدَعُوهَا مَا كَتَبْنَاهَا عَلَيْهِمْ إِلَّا ابْتِغَاءَ رِضْوَانِ اللَّهِ فَمَا رَعَوْهَا حَقَّ رِعَايَتِهَا ۖ فَآتَيْنَا الَّذِينَ آمَنُوا مِنْهُمْ أَجْرَهُمْ ۖ وَكَثِيرٌ مِّنْهُمْ فَاسِقُونَ ۝٢٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 27
Leyin naa, A fi awon Ojise Wa tele oripa won. A si mu ‘Isa omo Moryam tele won. A fun un ni al-’Injil. A fi aanu ati ike sinu okan awon t’o tele e. Asa adawa (lai loko tabi lai laya) won se adadaale re ni. A o se e ni oran-anyan le won lori. (Won ko si se adawa fun kini kan) bi ko se lati fi wa iyonu Allahu. Won ko si ri i so bi o se ye ki won so o. Nitori naa, A fun awon t’o gbagbo ni ododo ninu won ni esan won. Opolopo ninu won si ni obileje
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اتَّقُوا اللَّهَ وَآمِنُوا بِرَسُولِهِ يُؤْتِكُمْ كِفْلَيْنِ مِن رَّحْمَتِهِ وَيَجْعَل لَّكُمْ نُورًا تَمْشُونَ بِهِ وَيَغْفِرْ لَكُمْ ۚ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ ۝٢٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 28
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu, ki e si gba Ojise Re gbo ni ododo, nitori ki (Allahu) le fun yin ni ilopo meji ninu ike Re ati nitori ki O le fun yin ni imole ti e oo maa fi rin ati nitori ki O le fori jin yin. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun
لِّئَلَّا يَعْلَمَ أَهْلُ الْكِتَابِ أَلَّا يَقْدِرُونَ عَلَىٰ شَيْءٍ مِّن فَضْلِ اللَّهِ ۙ وَأَنَّ الْفَضْلَ بِيَدِ اللَّهِ يُؤْتِيهِ مَن يَشَاءُ ۚ وَاللَّهُ ذُو الْفَضْلِ الْعَظِيمِ ۝٢٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 29
(Allahu se bee fun yin) nitori ki awon ahlu-l-kitab le mo pe awon ko ni agbara lori kini kan ninu oore ajulo Allahu. Ati pe dajudaju oore ajulo, owo Allahu l’o wa. O si n fun eni ti O ba fe. Allahu si ni Oloore nla
← 56 Al-Hadid (57/114) 58 →
Kika Surah Al-Hadid ni Yorùbá – Itumọ ati Ohun

57الحديد Al-Hadid 📚 29 Ẹsẹ مدنية

Ẹsẹ kọọkan – Surah Al-Hadid — 29 Ẹsẹ




Al-Kur'an


Tuesday, August 18, 2026

Don't forget us in your sincere prayers