Surah Al-Waqi'ah ni Arabic ati Yorùbá

Ka Surah Al-Waqi'ah pẹlu itumọ pipe ni Yorùbá ati iṣẹ́-ohun. Itumọ ẹsẹ kọọkan. (96 Ẹsẹ — مكية). Al-Waqi'ah Gbọ, Al-Waqi'ah Itumọ, Al-Waqi'ah mp3, Al-Waqi'ah pdf.

Ka ati Gbọ Surah Al-Waqi'ah

🎧 Ẹsẹ
M Mishary Rashid Alafasy
M Mahmoud Khalil Al-Husary
A Abdurrahman As-Sudais
M Mohamed Siddiq Al-Minshawi
A Abdul Basit Abdul Samad
A Ali Al-Hudhaify
A Ahmed ibn Ali al-Ajamy
A Abu Bakr Ash-Shaatree
M Muhammad Ayyoub
A Abdullah Basfar
A Abdullah Al-Juhani
M Maher Al Muaiqly
x1
إِذَا وَقَعَتِ الْوَاقِعَةُ ۝١
📖 Itumọ Ẹsẹ 1
Nigba ti Isele (Ajinde) ba sele
لَيْسَ لِوَقْعَتِهَا كَاذِبَةٌ ۝٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 2
ko si iro kan nipa isele re-E
خَافِضَةٌ رَّافِعَةٌ ۝٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 3
o maa mu (awon kan) wale (sinu Ina), o si maa gbe (awon kan) soke (ninu Ogba Idera)
إِذَا رُجَّتِ الْأَرْضُ رَجًّا ۝٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 4
Nigba ti won ba mi ile titi ni mimititi
وَبُسَّتِ الْجِبَالُ بَسًّا ۝٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 5
ati nigba ti Won ba fo awon apata ni fifo womuwomu
فَكَانَتْ هَبَاءً مُّنبَثًّا ۝٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 6
won si maa di eruku afedanu - E
وَكُنتُمْ أَزْوَاجًا ثَلَاثَةً ۝٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 7
eyin si maa je orisi meta
فَأَصْحَابُ الْمَيْمَنَةِ مَا أَصْحَابُ الْمَيْمَنَةِ ۝٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 8
ijo osi ati ijo asiwaju. Amo ninu surah al-Balad; 90:18-19 ati surah az-Zalzalah; 99:6-8 Allahu (subhanahu wa ta’ala) pin won si ijo meji. Ijo meji kuku ni gbogbo eda ni orun 8 Awon ero owo otun, ki ni (o maa ti dara to fun) awon ero owo otun
وَأَصْحَابُ الْمَشْأَمَةِ مَا أَصْحَابُ الْمَشْأَمَةِ ۝٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 9
Awon ero owo osi, ki ni (o maa ti buru to fun) awon ero owo osi
وَالسَّابِقُونَ السَّابِقُونَ ۝١٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 10
Awon asiwaju si ni awon asiwaju
أُولَٰئِكَ الْمُقَرَّبُونَ ۝١١
📖 Itumọ Ẹsẹ 11
Awon wonyen ni alasun-unmo (Allahu)
فِي جَنَّاتِ النَّعِيمِ ۝١٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 12
ninu Ogba Idera
ثُلَّةٌ مِّنَ الْأَوَّلِينَ ۝١٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 13
Won po ninu awon eni akoko
وَقَلِيلٌ مِّنَ الْآخِرِينَ ۝١٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 14
Won si kere ninu awon eni Ikeyin
عَلَىٰ سُرُرٍ مَّوْضُونَةٍ ۝١٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 15
(Won yoo wa) lori ite ti won fi goolu hun
مُّتَّكِئِينَ عَلَيْهَا مُتَقَابِلِينَ ۝١٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 16
Won yoo rogboku sori re, won si maa doju kora won
يَطُوفُ عَلَيْهِمْ وِلْدَانٌ مُّخَلَّدُونَ ۝١٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 17
Awon odokunrin ti ko nii darugbo yo si maa lo bo laaarin won
بِأَكْوَابٍ وَأَبَارِيقَ وَكَأْسٍ مِّن مَّعِينٍ ۝١٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 18
pelu awon ife omi, ohun iromi fenfe ati ife oti aladun
لَّا يُصَدَّعُونَ عَنْهَا وَلَا يُنزِفُونَ ۝١٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 19
Ko nii fo won lori; ko si nii mu won hunrira
وَفَاكِهَةٍ مِّمَّا يَتَخَيَّرُونَ ۝٢٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 20
Eso ti won yoo maa sesa ninu re (tun wa fun won)
وَلَحْمِ طَيْرٍ مِّمَّا يَشْتَهُونَ ۝٢١
📖 Itumọ Ẹsẹ 21
Ati eran eye, eyi ti won n fe (yo wa fun won)
وَحُورٌ عِينٌ ۝٢٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 22
Awon obinrin eleyinju ege (tun wa fun won)
كَأَمْثَالِ اللُّؤْلُؤِ الْمَكْنُونِ ۝٢٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 23
Won da bi okuta olowo-iyebiye ti won fi pamo
جَزَاءً بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ ۝٢٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 24
(Iwonyi ni) esan fun ohun ti won n se nise
لَا يَسْمَعُونَ فِيهَا لَغْوًا وَلَا تَأْثِيمًا ۝٢٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 25
Won ko nii gbo isokuso ati oro ese ninu Ogba Idera
إِلَّا قِيلًا سَلَامًا سَلَامًا ۝٢٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 26
Ayafi oro alaafia, alaafia
وَأَصْحَابُ الْيَمِينِ مَا أَصْحَابُ الْيَمِينِ ۝٢٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 27
Awon ero owo otun, ki ni (o maa ti dara to fun) awon ero owo otun
فِي سِدْرٍ مَّخْضُودٍ ۝٢٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 28
(Won yoo wa) ni idi igi ti ko ni egun
وَطَلْحٍ مَّنضُودٍ ۝٢٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 29
ati ogede t’o so jigbinni
وَظِلٍّ مَّمْدُودٍ ۝٣٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 30
ati iboji t’o gbooro
وَمَاءٍ مَّسْكُوبٍ ۝٣١
📖 Itumọ Ẹsẹ 31
ati omi t’o n san lai dawo duro
وَفَاكِهَةٍ كَثِيرَةٍ ۝٣٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 32
ati opolopo eso
لَّا مَقْطُوعَةٍ وَلَا مَمْنُوعَةٍ ۝٣٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 33
ti ko nii ja (ni odo won), ko si nii deewo (fun won)
وَفُرُشٍ مَّرْفُوعَةٍ ۝٣٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 34
(Won maa wa lori) ite ti won gbe soke
إِنَّا أَنشَأْنَاهُنَّ إِنشَاءً ۝٣٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 35
Dajudaju Awa tun (awon obinrin won) da ni eda otun
فَجَعَلْنَاهُنَّ أَبْكَارًا ۝٣٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 36
A si se won ni wundia
عُرُبًا أَتْرَابًا ۝٣٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 37
ololufe oko. Won si dogba ni ojo ori
لِّأَصْحَابِ الْيَمِينِ ۝٣٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 38
(Won wa) fun awon ero owo otun
ثُلَّةٌ مِّنَ الْأَوَّلِينَ ۝٣٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 39
Won po ninu awon eni akoko
وَثُلَّةٌ مِّنَ الْآخِرِينَ ۝٤٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 40
Won tun po ninu awon eni Ikeyin
وَأَصْحَابُ الشِّمَالِ مَا أَصْحَابُ الشِّمَالِ ۝٤١
📖 Itumọ Ẹsẹ 41
Awon ero owo osi, ki ni (o maa ti buru to fun) awon ero owo osi
فِي سَمُومٍ وَحَمِيمٍ ۝٤٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 42
(Won yoo wa) ninu ategun gbigbona ati omi gbigbona
وَظِلٍّ مِّن يَحْمُومٍ ۝٤٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 43
ati ni abe iboji eleeefin dudu
لَّا بَارِدٍ وَلَا كَرِيمٍ ۝٤٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 44
ko tutu, ko si dara
إِنَّهُمْ كَانُوا قَبْلَ ذَٰلِكَ مُتْرَفِينَ ۝٤٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 45
Dajudaju won ti je onigbedemuke siwaju iyen
وَكَانُوا يُصِرُّونَ عَلَى الْحِنثِ الْعَظِيمِ ۝٤٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 46
Won si maa n sorikunkun lori ese nla
وَكَانُوا يَقُولُونَ أَئِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَامًا أَإِنَّا لَمَبْعُوثُونَ ۝٤٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 47
Won si maa n wi pe: "Se nigba ti a ba di oku, ti a si di erupe ati egungun, nje Won yoo tun gbe wa dide ni
أَوَآبَاؤُنَا الْأَوَّلُونَ ۝٤٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 48
Se ati awon baba wa, awon eni akoko
قُلْ إِنَّ الْأَوَّلِينَ وَالْآخِرِينَ ۝٤٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 49
So pe: "Dajudaju awon eni akoko ati awon eni Ikeyin
لَمَجْمُوعُونَ إِلَىٰ مِيقَاتِ يَوْمٍ مَّعْلُومٍ ۝٥٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 50
dajudaju A oo ko won jo papo ni akoko ojo kan ti A ti mo
ثُمَّ إِنَّكُمْ أَيُّهَا الضَّالُّونَ الْمُكَذِّبُونَ ۝٥١
📖 Itumọ Ẹsẹ 51
Leyin naa, dajudaju eyin olusina, olupe-ododo-niro
لَآكِلُونَ مِن شَجَرٍ مِّن زَقُّومٍ ۝٥٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 52
dajudaju eyin maa je ninu igi zaƙƙum (igi iwo)
فَمَالِئُونَ مِنْهَا الْبُطُونَ ۝٥٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 53
Ikun yin si maa kun bamubamu fun (jije) igi naa
فَشَارِبُونَ عَلَيْهِ مِنَ الْحَمِيمِ ۝٥٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 54
Eyin yo si maa mu omi gbigbona le e lori
فَشَارِبُونَ شُرْبَ الْهِيمِ ۝٥٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 55
Eyin yoo maa mu un ni imumi rakunmi ti ongbe n gbe
هَٰذَا نُزُلُهُمْ يَوْمَ الدِّينِ ۝٥٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 56
Eyi ni nnkan alejo won ni Ojo esan
نَحْنُ خَلَقْنَاكُمْ فَلَوْلَا تُصَدِّقُونَ ۝٥٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 57
Awa l’A seda yin. Ki ni ko je ki e gbagbo lododo
أَفَرَأَيْتُم مَّا تُمْنُونَ ۝٥٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 58
E so fun Mi nipa ato ti e n da jade (sinu apoluke)
أَأَنتُمْ تَخْلُقُونَهُ أَمْ نَحْنُ الْخَالِقُونَ ۝٥٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 59
se eyin le seda re ni tabi Awa l’A seda re
نَحْنُ قَدَّرْنَا بَيْنَكُمُ الْمَوْتَ وَمَا نَحْنُ بِمَسْبُوقِينَ ۝٦٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 60
Awa l’A yan kadara (ojo) iku fun gbogbo yin. Awa ko si le kagara
عَلَىٰ أَن نُّبَدِّلَ أَمْثَالَكُمْ وَنُنشِئَكُمْ فِي مَا لَا تَعْلَمُونَ ۝٦١
📖 Itumọ Ẹsẹ 61
lati fi iru yin paaro yin, ki a si tun yin da sinu ohun ti e ko mo
وَلَقَدْ عَلِمْتُمُ النَّشْأَةَ الْأُولَىٰ فَلَوْلَا تَذَكَّرُونَ ۝٦٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 62
E kuku mo iseda akoko, e o se lo iranti
أَفَرَأَيْتُم مَّا تَحْرُثُونَ ۝٦٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 63
E so fun Mi nipa nnkan ti e n gbin sinu ile
أَأَنتُمْ تَزْرَعُونَهُ أَمْ نَحْنُ الزَّارِعُونَ ۝٦٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 64
se eyin l’e n je ki o hu jade ni tabi Awa l’A n je ki o hu jade
لَوْ نَشَاءُ لَجَعَلْنَاهُ حُطَامًا فَظَلْتُمْ تَفَكَّهُونَ ۝٦٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 65
Ti A ba fe ni, Awa iba so o di gbigbe, eyin yo si maa seemo (ti e oo maa ka abamo)
إِنَّا لَمُغْرَمُونَ ۝٦٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 66
(Eyin yo si wi pe:) "Dajudaju awa ti di onigbese
بَلْ نَحْنُ مَحْرُومُونَ ۝٦٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 67
(Awon miiran yo si wi pe:) "Rara o! Won se ikore oko ni eewo fun wa ni
أَفَرَأَيْتُمُ الْمَاءَ الَّذِي تَشْرَبُونَ ۝٦٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 68
E so fun mi nipa omi ti e n mu
أَأَنتُمْ أَنزَلْتُمُوهُ مِنَ الْمُزْنِ أَمْ نَحْنُ الْمُنزِلُونَ ۝٦٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 69
se eyin l’e n so o kale lati inu esujo ni tabi Awa l’A n so o kale
لَوْ نَشَاءُ جَعَلْنَاهُ أُجَاجًا فَلَوْلَا تَشْكُرُونَ ۝٧٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 70
Ti A ba fe ni, Awa iba se e ni omi t’o moro. E o se maa dupe
أَفَرَأَيْتُمُ النَّارَ الَّتِي تُورُونَ ۝٧١
📖 Itumọ Ẹsẹ 71
E so fun Mi nipa ina ti e n da
أَأَنتُمْ أَنشَأْتُمْ شَجَرَتَهَا أَمْ نَحْنُ الْمُنشِئُونَ ۝٧٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 72
se eyin l’e seda igi re ni tabi Awa ni Aseda
نَحْنُ جَعَلْنَاهَا تَذْكِرَةً وَمَتَاعًا لِّلْمُقْوِينَ ۝٧٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 73
Awa se ina aye ni iranti (fun Ina orun) ati nnkan elo fun awon onirin-ajo
فَسَبِّحْ بِاسْمِ رَبِّكَ الْعَظِيمِ ۝٧٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 74
Nitori naa, safomo fun oruko Oluwa re, Atobi
۞ فَلَا أُقْسِمُ بِمَوَاقِعِ النُّجُومِ ۝٧٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 75
Mo n bura pelu awon ibuso irawo
وَإِنَّهُ لَقَسَمٌ لَّوْ تَعْلَمُونَ عَظِيمٌ ۝٧٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 76
Dajudaju ibura nla ni, ti e ba mo
إِنَّهُ لَقُرْآنٌ كَرِيمٌ ۝٧٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 77
Dajudaju (al-Ƙur’an) ni nnkan kike alapon-onle
فِي كِتَابٍ مَّكْنُونٍ ۝٧٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 78
(t’o wa) ninu Tira aabo (ninu Laohul-Mahfuth)
لَّا يَمَسُّهُ إِلَّا الْمُطَهَّرُونَ ۝٧٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 79
Ko si eni to le fowo kan an (ni odo Allahu) afi awon eni mimo (iyen, awon molaika)
تَنزِيلٌ مِّن رَّبِّ الْعَالَمِينَ ۝٨٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 80
Won so al-Ƙur’an kale lati odo Oluwa gbogbo eda
أَفَبِهَٰذَا الْحَدِيثِ أَنتُم مُّدْهِنُونَ ۝٨١
📖 Itumọ Ẹsẹ 81
Nitori naa, se oro (al-Ƙur’an) yii l’e n pe niro
وَتَجْعَلُونَ رِزْقَكُمْ أَنَّكُمْ تُكَذِّبُونَ ۝٨٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 82
E si n so idupe arisiki yin di pe dajudaju e n pe ododo niro
فَلَوْلَا إِذَا بَلَغَتِ الْحُلْقُومَ ۝٨٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 83
Ki ni o maa ti ri (fun yin) nigba ti emi (yin) ba de ona ofun
وَأَنتُمْ حِينَئِذٍ تَنظُرُونَ ۝٨٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 84
ti eyin yo si maa woran nigba yen
وَنَحْنُ أَقْرَبُ إِلَيْهِ مِنكُمْ وَلَٰكِن لَّا تُبْصِرُونَ ۝٨٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 85
Awa si sunmo on ju eyin lo, sugbon eyin ko riran
فَلَوْلَا إِن كُنتُمْ غَيْرَ مَدِينِينَ ۝٨٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 86
Eyin ko se je eni ti A o nii gbesan lara re
تَرْجِعُونَهَا إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ ۝٨٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 87
ki e si da (emi ti o fe bo) pada, ti e ba je olododo
فَأَمَّا إِن كَانَ مِنَ الْمُقَرَّبِينَ ۝٨٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 88
Ni ti eni ti o ba wa ninu awon alasun-unmo (Wa)
فَرَوْحٌ وَرَيْحَانٌ وَجَنَّتُ نَعِيمٍ ۝٨٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 89
isinmi, ese t’o dara ati Ogba Idera (ni tire)
وَأَمَّا إِن كَانَ مِنْ أَصْحَابِ الْيَمِينِ ۝٩٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 90
Ni ti eni ti o ba wa ninu awon ero owo otun
فَسَلَامٌ لَّكَ مِنْ أَصْحَابِ الْيَمِينِ ۝٩١
📖 Itumọ Ẹsẹ 91
alaafia ni fun o laaarin awon ero owo otun
وَأَمَّا إِن كَانَ مِنَ الْمُكَذِّبِينَ الضَّالِّينَ ۝٩٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 92
Ni ti eni ti o ba wa ninu awon olupe-ododo-niro, awon olusina
فَنُزُلٌ مِّنْ حَمِيمٍ ۝٩٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 93
nnkan alejo (won) ni omi gbigbona
وَتَصْلِيَةُ جَحِيمٍ ۝٩٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 94
ati wiwo inu ina Jehim
إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ حَقُّ الْيَقِينِ ۝٩٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 95
Dajudaju eyi, ohun ni ododo t’o daju
فَسَبِّحْ بِاسْمِ رَبِّكَ الْعَظِيمِ ۝٩٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 96
Nitori naa, safomo fun oruko Oluwa re, Atobi
← 55 Al-Waqi'ah (56/114) 57 →
Kika Surah Al-Waqi'ah ni Yorùbá – Itumọ ati Ohun

56الواقعة Al-Waqi'ah 📚 96 Ẹsẹ مكية

Ẹsẹ kọọkan – Surah Al-Waqi'ah — 96 Ẹsẹ




Al-Kur'an


Tuesday, August 18, 2026

Don't forget us in your sincere prayers