Surah Al-Insan ni Arabic ati Yorùbá
Ka Surah Al-Insan pẹlu itumọ pipe ni Yorùbá ati iṣẹ́-ohun. Itumọ ẹsẹ kọọkan. (31 Ẹsẹ — مدنية). Al-Insan Gbọ, Al-Insan Itumọ, Al-Insan mp3, Al-Insan pdf.Ka ati Gbọ Surah Al-Insan
🎧 Ẹsẹ
M
Mishary Rashid Alafasy
✓
Mishary Rashid Alafasy
✓
M
Mahmoud Khalil Al-Husary
✓
Mahmoud Khalil Al-Husary
✓
A
Abdurrahman As-Sudais
✓
Abdurrahman As-Sudais
✓
M
Mohamed Siddiq Al-Minshawi
✓
Mohamed Siddiq Al-Minshawi
✓
A
Abdul Basit Abdul Samad
✓
Abdul Basit Abdul Samad
✓
A
Ali Al-Hudhaify
✓
Ali Al-Hudhaify
✓
A
Ahmed ibn Ali al-Ajamy
✓
Ahmed ibn Ali al-Ajamy
✓
A
Abu Bakr Ash-Shaatree
✓
Abu Bakr Ash-Shaatree
✓
M
Muhammad Ayyoub
✓
Muhammad Ayyoub
✓
A
Abdullah Basfar
✓
Abdullah Basfar
✓
A
Abdullah Al-Juhani
✓
Abdullah Al-Juhani
✓
M
Maher Al Muaiqly
✓
Maher Al Muaiqly
✓
—
x1
هَلْ أَتَىٰ عَلَى الْإِنسَانِ حِينٌ مِّنَ الدَّهْرِ لَمْ يَكُن شَيْئًا مَّذْكُورًا ١
📖 Itumọ
Ẹsẹ 1
Sebi akoko kan ninu igba ti re koja lori eniyan ti (eniyan) ko je kini kan ti won n daruko
إِنَّا خَلَقْنَا الْإِنسَانَ مِن نُّطْفَةٍ أَمْشَاجٍ نَّبْتَلِيهِ فَجَعَلْنَاهُ سَمِيعًا بَصِيرًا ٢
📖 Itumọ
Ẹsẹ 2
Dajudaju Awa seda eniyan lati ara ato t’o ropo mora won (lati ara okunrin ati obinrin), ki A le dan an wo. A si se e ni olugbo, oluriran
إِنَّا هَدَيْنَاهُ السَّبِيلَ إِمَّا شَاكِرًا وَإِمَّا كَفُورًا ٣
📖 Itumọ
Ẹsẹ 3
Dajudaju A fi ona mo on; O le je oludupe, o si le je alaimoore
إِنَّا أَعْتَدْنَا لِلْكَافِرِينَ سَلَاسِلَ وَأَغْلَالًا وَسَعِيرًا ٤
📖 Itumọ
Ẹsẹ 4
Dajudaju Awa pese awon ewon, ajaga ati Ina sile de awon alaigbagbo
إِنَّ الْأَبْرَارَ يَشْرَبُونَ مِن كَأْسٍ كَانَ مِزَاجُهَا كَافُورًا ٥
📖 Itumọ
Ẹsẹ 5
Dajudaju awon eni rere, won yoo maa mu omi kan ninu ife. Ohun ti A popo mo (omi naa) ni kafura
عَيْنًا يَشْرَبُ بِهَا عِبَادُ اللَّهِ يُفَجِّرُونَهَا تَفْجِيرًا ٦
📖 Itumọ
Ẹsẹ 6
Omi iseleru kan ni, ti awon erusin Allahu yoo maa mu, ti won yo si maa mu un san jade daadaa (si ibi ti won ba fe)
يُوفُونَ بِالنَّذْرِ وَيَخَافُونَ يَوْمًا كَانَ شَرُّهُ مُسْتَطِيرًا ٧
📖 Itumọ
Ẹsẹ 7
Won n mu eje won se. Won si n paya ojo kan, ti aburu re je ohun ti o maa fonka gan-an
وَيُطْعِمُونَ الطَّعَامَ عَلَىٰ حُبِّهِ مِسْكِينًا وَيَتِيمًا وَأَسِيرًا ٨
📖 Itumọ
Ẹsẹ 8
Tohun ti bi won se ni ife si (oro to), won n fun mekunnu, omo orukan ati eru ni ounje je
إِنَّمَا نُطْعِمُكُمْ لِوَجْهِ اللَّهِ لَا نُرِيدُ مِنكُمْ جَزَاءً وَلَا شُكُورًا ٩
📖 Itumọ
Ẹsẹ 9
(Won si n so pe:) "Nitori Oju rere Allahu (nikan) l’a fi n fun yin ni ounje; awa ko si gbero esan tabi idupe kan lati odo yin
إِنَّا نَخَافُ مِن رَّبِّنَا يَوْمًا عَبُوسًا قَمْطَرِيرًا ١٠
📖 Itumọ
Ẹsẹ 10
Dajudaju awa n paya ni odo Oluwa wa ojo kan ti (eda yoo) faju ro koko
فَوَقَاهُمُ اللَّهُ شَرَّ ذَٰلِكَ الْيَوْمِ وَلَقَّاهُمْ نَضْرَةً وَسُرُورًا ١١
📖 Itumọ
Ẹsẹ 11
Nitori naa, Allahu yoo so won nibi aburu ojo yen. O si maa fun won ni itutu oju ati idunnu
وَجَزَاهُم بِمَا صَبَرُوا جَنَّةً وَحَرِيرًا ١٢
📖 Itumọ
Ẹsẹ 12
O si maa san won ni esan Ogba Idera ati aso alari nitori pe won se suuru
مُّتَّكِئِينَ فِيهَا عَلَى الْأَرَائِكِ ۖ لَا يَرَوْنَ فِيهَا شَمْسًا وَلَا زَمْهَرِيرًا ١٣
📖 Itumọ
Ẹsẹ 13
Won yoo maa rogbo ku sori awon ibusun won. Won ko si nii ri oorun tabi otutu
وَدَانِيَةً عَلَيْهِمْ ظِلَالُهَا وَذُلِّلَتْ قُطُوفُهَا تَذْلِيلًا ١٤
📖 Itumọ
Ẹsẹ 14
Awon ooji (inu Ogba Idera) yoo sunmo won. A si maa mu awon eso ibe sunmo arowoto won ni ti sisunmo
وَيُطَافُ عَلَيْهِم بِآنِيَةٍ مِّن فِضَّةٍ وَأَكْوَابٍ كَانَتْ قَوَارِيرَا ١٥
📖 Itumọ
Ẹsẹ 15
Ati pe won yoo maa gbe ife imumi nla ti won se lati ara fadaka ati awon ife imumi kekere ti o je alawo kaa kiri odo won
قَوَارِيرَ مِن فِضَّةٍ قَدَّرُوهَا تَقْدِيرًا ١٦
📖 Itumọ
Ẹsẹ 16
Ife alawo ti won se lati ara fadaka ni (won). A si se won niwon-niwon (ti o se weku ohun ti won fe mu)
وَيُسْقَوْنَ فِيهَا كَأْسًا كَانَ مِزَاجُهَا زَنجَبِيلًا ١٧
📖 Itumọ
Ẹsẹ 17
Ati pe won yoo maa fun won ni ife oti kan mu ninu (Ogba Idera). Ohun ti A popo mo (oti naa) ni atale
عَيْنًا فِيهَا تُسَمَّىٰ سَلْسَبِيلًا ١٨
📖 Itumọ
Ẹsẹ 18
Ninu Ogba Idera (won yoo tun maa mu) omi iseleru kan, ti A n pe ni omi salsabil
۞ وَيَطُوفُ عَلَيْهِمْ وِلْدَانٌ مُّخَلَّدُونَ إِذَا رَأَيْتَهُمْ حَسِبْتَهُمْ لُؤْلُؤًا مَّنثُورًا ١٩
📖 Itumọ
Ẹsẹ 19
Awon odokunrin ti ko nii gbo yo si maa lo bo laaarin won. Nigba ti iwo ba si ri won, iwo yoo ka won kun okuta olowo iyebiye ti won tan kale
وَإِذَا رَأَيْتَ ثَمَّ رَأَيْتَ نَعِيمًا وَمُلْكًا كَبِيرًا ٢٠
📖 Itumọ
Ẹsẹ 20
Nigba ti iwo ba si wo ibe yen (ninu Ogba Idera), iwo yoo ri idera ati ola t’o tobi
عَالِيَهُمْ ثِيَابُ سُندُسٍ خُضْرٌ وَإِسْتَبْرَقٌ ۖ وَحُلُّوا أَسَاوِرَ مِن فِضَّةٍ وَسَقَاهُمْ رَبُّهُمْ شَرَابًا طَهُورًا ٢١
📖 Itumọ
Ẹsẹ 21
Aso ara won ni aso aran felefele alawo eweko ati aso alagbaaa. A si maa fi egba-owo onifadaka se won ni oso. Oluwa won yo si fun won ni ohun mimu mimo mu
إِنَّ هَٰذَا كَانَ لَكُمْ جَزَاءً وَكَانَ سَعْيُكُم مَّشْكُورًا ٢٢
📖 Itumọ
Ẹsẹ 22
Dajudaju eyi je esan fun yin. Ise yin si ja si ope
إِنَّا نَحْنُ نَزَّلْنَا عَلَيْكَ الْقُرْآنَ تَنزِيلًا ٢٣
📖 Itumọ
Ẹsẹ 23
Dajudaju Awa l’A so al-Ƙur’an kale fun o diedie
فَاصْبِرْ لِحُكْمِ رَبِّكَ وَلَا تُطِعْ مِنْهُمْ آثِمًا أَوْ كَفُورًا ٢٤
📖 Itumọ
Ẹsẹ 24
Nitori naa, se suuru fun idajo Oluwa re. Ma se tele elese tabi alaimoore kan ninu won
وَاذْكُرِ اسْمَ رَبِّكَ بُكْرَةً وَأَصِيلًا ٢٥
📖 Itumọ
Ẹsẹ 25
Ranti oruko Oluwa re ni aaro ati ni asale
وَمِنَ اللَّيْلِ فَاسْجُدْ لَهُ وَسَبِّحْهُ لَيْلًا طَوِيلًا ٢٦
📖 Itumọ
Ẹsẹ 26
Ati ni oru, fori kanle fun Un. Ki o si safomo fun Un ni oru fun igba pipe
إِنَّ هَٰؤُلَاءِ يُحِبُّونَ الْعَاجِلَةَ وَيَذَرُونَ وَرَاءَهُمْ يَوْمًا ثَقِيلًا ٢٧
📖 Itumọ
Ẹsẹ 27
Dajudaju awon wonyi feran aye. Won si n pa ojo t’o wuwo ti seyin won
نَّحْنُ خَلَقْنَاهُمْ وَشَدَدْنَا أَسْرَهُمْ ۖ وَإِذَا شِئْنَا بَدَّلْنَا أَمْثَالَهُمْ تَبْدِيلًا ٢٨
📖 Itumọ
Ẹsẹ 28
Awa l’A seda won. A si se won ni alagbara. Nigba ti A ba si fe, A oo fi iru won (miiran) paaro won ni ti ipaaro
إِنَّ هَٰذِهِ تَذْكِرَةٌ ۖ فَمَن شَاءَ اتَّخَذَ إِلَىٰ رَبِّهِ سَبِيلًا ٢٩
📖 Itumọ
Ẹsẹ 29
Dajudaju eyi ni iranti. Nitori naa, eni ti o ba fe ki o mu oju ona to si odo Oluwa re
وَمَا تَشَاءُونَ إِلَّا أَن يَشَاءَ اللَّهُ ۚ إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمًا ٣٠
📖 Itumọ
Ẹsẹ 30
Eyin ko si nii fe (kini kan) afi ti Allahu ba fe. Dajudaju Allahu n je Onimo, Ologbon
يُدْخِلُ مَن يَشَاءُ فِي رَحْمَتِهِ ۚ وَالظَّالِمِينَ أَعَدَّ لَهُمْ عَذَابًا أَلِيمًا ٣١
📖 Itumọ
Ẹsẹ 31
O maa fi eni ti o ba fe sinu ike re. (Ni ti) awon alabosi, O si pese iya eleta-elero sile de won
Kika Surah Al-Insan ni Yorùbá – Itumọ ati Ohun
Al-Kur'an
Tuesday, August 18, 2026
Don't forget us in your sincere prayers

