Surah Al-Mulk ni Arabic ati Yorùbá

Ka Surah Al-Mulk pẹlu itumọ pipe ni Yorùbá ati iṣẹ́-ohun. Itumọ ẹsẹ kọọkan. (30 Ẹsẹ — مكية). Al-Mulk Gbọ, Al-Mulk Itumọ, Al-Mulk mp3, Al-Mulk pdf.

Ka ati Gbọ Surah Al-Mulk

🎧 Ẹsẹ
M Mishary Rashid Alafasy
M Mahmoud Khalil Al-Husary
A Abdurrahman As-Sudais
M Mohamed Siddiq Al-Minshawi
A Abdul Basit Abdul Samad
A Ali Al-Hudhaify
A Ahmed ibn Ali al-Ajamy
A Abu Bakr Ash-Shaatree
M Muhammad Ayyoub
A Abdullah Basfar
A Abdullah Al-Juhani
M Maher Al Muaiqly
x1
تَبَارَكَ الَّذِي بِيَدِهِ الْمُلْكُ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ ۝١
📖 Itumọ Ẹsẹ 1
Ibukun ni fun Eni ti ijoba wa ni Owo Re. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan
الَّذِي خَلَقَ الْمَوْتَ وَالْحَيَاةَ لِيَبْلُوَكُمْ أَيُّكُمْ أَحْسَنُ عَمَلًا ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْغَفُورُ ۝٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 2
Eni ti O da iku ati isemi nitori ki o le dan yin wo; ewo ninu yin l’o maa se ise rere julo. Oun si ni Alagbara, Alaforijin
الَّذِي خَلَقَ سَبْعَ سَمَاوَاتٍ طِبَاقًا ۖ مَّا تَرَىٰ فِي خَلْقِ الرَّحْمَٰنِ مِن تَفَاوُتٍ ۖ فَارْجِعِ الْبَصَرَ هَلْ تَرَىٰ مِن فُطُورٍ ۝٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 3
Eni ti O da awon sanmo meje ni ipele ipele. O o le ri aigunrege kan lara eda Ajoke-aye. Nitori naa, wo o pada, nje o ri oju sisan kan (lara sanmo)
ثُمَّ ارْجِعِ الْبَصَرَ كَرَّتَيْنِ يَنقَلِبْ إِلَيْكَ الْبَصَرُ خَاسِئًا وَهُوَ حَسِيرٌ ۝٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 4
Leyin naa, wo o pada ni ee meji, ki oju re pada si odo re pelu iyepere. O si maa kaaare
وَلَقَدْ زَيَّنَّا السَّمَاءَ الدُّنْيَا بِمَصَابِيحَ وَجَعَلْنَاهَا رُجُومًا لِّلشَّيَاطِينِ ۖ وَأَعْتَدْنَا لَهُمْ عَذَابَ السَّعِيرِ ۝٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 5
Dajudaju A ti fi (awon irawo t’o n tanmole bi) atupa se sanmo ile aye ni oso. A tun se won ni eta-irawo ti won n ju mo awon esu. A si pese iya Ina t’o n jo fofo sile de won
وَلِلَّذِينَ كَفَرُوا بِرَبِّهِمْ عَذَابُ جَهَنَّمَ ۖ وَبِئْسَ الْمَصِيرُ ۝٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 6
Iya ina Jahanamo si wa fun awon t’o sai gbagbo. Ikangun naa si buru
إِذَا أُلْقُوا فِيهَا سَمِعُوا لَهَا شَهِيقًا وَهِيَ تَفُورُ ۝٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 7
Nigba ti won ba ju won sinu re, won yoo maa gbo kikun re, ti o si maa ru soke
تَكَادُ تَمَيَّزُ مِنَ الْغَيْظِ ۖ كُلَّمَا أُلْقِيَ فِيهَا فَوْجٌ سَأَلَهُمْ خَزَنَتُهَا أَلَمْ يَأْتِكُمْ نَذِيرٌ ۝٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 8
Ina maa fee pinra re lati ara ibinu. Igbakigba ti won ba ju ijo kan sinu re, awon eso Ina yoo maa bi won leere pe: "Nje olukilo kan ko wa ba yin bi
قَالُوا بَلَىٰ قَدْ جَاءَنَا نَذِيرٌ فَكَذَّبْنَا وَقُلْنَا مَا نَزَّلَ اللَّهُ مِن شَيْءٍ إِنْ أَنتُمْ إِلَّا فِي ضَلَالٍ كَبِيرٍ ۝٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 9
Won yoo wi pe: "Rara, dajudaju olukilo kan ti wa ba wa, sugbon a pe e ni opuro. A si wi pe Allahu ko so nnkan kan kale. Ki ni eyin bi ko se pe e wa ninu isina t’o tobi
وَقَالُوا لَوْ كُنَّا نَسْمَعُ أَوْ نَعْقِلُ مَا كُنَّا فِي أَصْحَابِ السَّعِيرِ ۝١٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 10
Won tun wi pe: "Ti o ba je pe a gboran ni tabi pe a se laakaye ni, awa ko nii wa ninu ero inu Ina jijo
فَاعْتَرَفُوا بِذَنبِهِمْ فَسُحْقًا لِّأَصْحَابِ السَّعِيرِ ۝١١
📖 Itumọ Ẹsẹ 11
Won si jewo ese won. Nitori naa, ijinna si ike Allahu yo wa fun awon ero inu Ina t’o n jo fofo
إِنَّ الَّذِينَ يَخْشَوْنَ رَبَّهُم بِالْغَيْبِ لَهُم مَّغْفِرَةٌ وَأَجْرٌ كَبِيرٌ ۝١٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 12
Dajudaju awon t’o n paya Oluwa won ni ikoko, aforijin ati esan t’o tobi n be fun won
وَأَسِرُّوا قَوْلَكُمْ أَوِ اجْهَرُوا بِهِ ۖ إِنَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ ۝١٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 13
E wi oro yin ni jeeje tabi e wi i soke, dajudaju Oun ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu awon igba-aya eda
أَلَا يَعْلَمُ مَنْ خَلَقَ وَهُوَ اللَّطِيفُ الْخَبِيرُ ۝١٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 14
Se (Allahu) ko mo eni t’O da ni? Oun si ni Alaaanu, Alamotan
هُوَ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الْأَرْضَ ذَلُولًا فَامْشُوا فِي مَنَاكِبِهَا وَكُلُوا مِن رِّزْقِهِ ۖ وَإِلَيْهِ النُّشُورُ ۝١٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 15
Oun ni Eni ti O ro ile fun yin. Nitori naa, e rin ni awon agbegbe re kaakiri, ki e si je ninu arisiki Re. Odo Re si ni ajinde eda wa
أَأَمِنتُم مَّن فِي السَّمَاءِ أَن يَخْسِفَ بِكُمُ الْأَرْضَ فَإِذَا هِيَ تَمُورُ ۝١٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 16
Se e fokanbale si Eni ti O wa ni (oke) sanmo pe ko le je ki ile gbe yin mi? Nigba naa, ile yo si maa mi titi
أَمْ أَمِنتُم مَّن فِي السَّمَاءِ أَن يُرْسِلَ عَلَيْكُمْ حَاصِبًا ۖ فَسَتَعْلَمُونَ كَيْفَ نَذِيرِ ۝١٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 17
Tabi e fokanbale si Eni ti O wa ni (oke) sanmo pe ko le fi okuta ina ranse si yin ni? Nigba naa, e si maa mo bi ikilo Mi ti ri
وَلَقَدْ كَذَّبَ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ فَكَيْفَ كَانَ نَكِيرِ ۝١٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 18
Awon t’o siwaju won kuku pe ododo niro. Bawo si ni bi Mo se (fi iya) ko (aburu fun won) ti ri
أَوَلَمْ يَرَوْا إِلَى الطَّيْرِ فَوْقَهُمْ صَافَّاتٍ وَيَقْبِضْنَ ۚ مَا يُمْسِكُهُنَّ إِلَّا الرَّحْمَٰنُ ۚ إِنَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ بَصِيرٌ ۝١٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 19
Se won ko ri awon eye ti o wa ni oke won, ti (won) n na iye apa (won), ti won si n pa a mora? Kini kan ko mu won duro (sinu ofurufu) afi Ajoke-aye. Dajudaju Oun si ni Oluriran nipa gbogbo nnkan
أَمَّنْ هَٰذَا الَّذِي هُوَ جُندٌ لَّكُمْ يَنصُرُكُم مِّن دُونِ الرَّحْمَٰنِ ۚ إِنِ الْكَافِرُونَ إِلَّا فِي غُرُورٍ ۝٢٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 20
Ta ni eni ti o maa je omo ogun fun yin, ti o maa ran yin lowo leyin Ajoke-aye? (Ninu) ki ni awon alaigbagbo wa bi ko se ninu etan
أَمَّنْ هَٰذَا الَّذِي يَرْزُقُكُمْ إِنْ أَمْسَكَ رِزْقَهُ ۚ بَل لَّجُّوا فِي عُتُوٍّ وَنُفُورٍ ۝٢١
📖 Itumọ Ẹsẹ 21
Ta ni eni ti o maa pese fun yin ti O ba da arisiki Re duro? Nse ni won n sori kunkun si i ninu igberaga ati sisa fun ododo
أَفَمَن يَمْشِي مُكِبًّا عَلَىٰ وَجْهِهِ أَهْدَىٰ أَمَّن يَمْشِي سَوِيًّا عَلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ ۝٢٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 22
Nje eni t’o n rin ni idojubole l’o mona julo ni tabi eni t’o n rin san an loju ona taara
قُلْ هُوَ الَّذِي أَنشَأَكُمْ وَجَعَلَ لَكُمُ السَّمْعَ وَالْأَبْصَارَ وَالْأَفْئِدَةَ ۖ قَلِيلًا مَّا تَشْكُرُونَ ۝٢٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 23
So pe: "Oun ni Eni ti O seda yin. O si se igboro, iriran ati awon okan fun yin. Ope ti e n da si kere pupo
قُلْ هُوَ الَّذِي ذَرَأَكُمْ فِي الْأَرْضِ وَإِلَيْهِ تُحْشَرُونَ ۝٢٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 24
So pe: "Oun ni Eni ti O da yin si ori ile. Odo Re si ni won yoo ko yin jo si
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا الْوَعْدُ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ ۝٢٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 25
Won n wi pe: "Igba wo ni adehun yii yoo se ti e ba je olododo
قُلْ إِنَّمَا الْعِلْمُ عِندَ اللَّهِ وَإِنَّمَا أَنَا نَذِيرٌ مُّبِينٌ ۝٢٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 26
So pe: "Odo Allahu nikan ni imo (nipa) re wa. Emi kan je olukilo ponnbele ni
فَلَمَّا رَأَوْهُ زُلْفَةً سِيئَتْ وُجُوهُ الَّذِينَ كَفَرُوا وَقِيلَ هَٰذَا الَّذِي كُنتُم بِهِ تَدَّعُونَ ۝٢٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 27
Nigba ti won ba ri i t’o sunmo, oju awon t’o sai gbagbo yoo koro wa fun ibanuje. A o si so fun won pe: "Eyi ni ohun ti e n pe
قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِنْ أَهْلَكَنِيَ اللَّهُ وَمَن مَّعِيَ أَوْ رَحِمَنَا فَمَن يُجِيرُ الْكَافِرِينَ مِنْ عَذَابٍ أَلِيمٍ ۝٢٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 28
So pe: " E so fun mi, ti Allahu ba pa emi ati awon t’o wa pelu mi re, tabi ti O ba ke wa (se e le di I lowo ni?) Nitori naa, ta ni o maa gba awon alaigbagbo la ninu iya eleta-elero
قُلْ هُوَ الرَّحْمَٰنُ آمَنَّا بِهِ وَعَلَيْهِ تَوَكَّلْنَا ۖ فَسَتَعْلَمُونَ مَنْ هُوَ فِي ضَلَالٍ مُّبِينٍ ۝٢٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 29
So pe: "Oun ni Ajoke-aye. Awa gba A gbo. Oun si la gbarale. Laipe e maa mo ta ni o wa ninu isina ponnbele
قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِنْ أَصْبَحَ مَاؤُكُمْ غَوْرًا فَمَن يَأْتِيكُم بِمَاءٍ مَّعِينٍ ۝٣٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 30
So pe: " E so fun mi, ti omi yin ba gbe wa, ta ni eni ti o maa mu omi iseleru wa ba yin
← 66 Al-Mulk (67/114) 68 →
Kika Surah Al-Mulk ni Yorùbá – Itumọ ati Ohun

67الملك Al-Mulk 📚 30 Ẹsẹ مكية

Ẹsẹ kọọkan – Surah Al-Mulk — 30 Ẹsẹ




Al-Kur'an


Tuesday, August 18, 2026

Don't forget us in your sincere prayers