سورة القصص باليوربا
طسم(1) To sin mim |
Iwonyi ni awon ayah Tira t’o n yanju oro eda |
نَتْلُو عَلَيْكَ مِن نَّبَإِ مُوسَىٰ وَفِرْعَوْنَ بِالْحَقِّ لِقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ(3) A n ke ninu iro (Anabi) Musa ati Fir‘aon fun o pelu ododo nitori ijo t’o gbagbo lododo |
Dajudaju Fir‘aon segberaga lori ile. O se awon eniyan re ni ijo-ijo. O n da igun kan ninu won lagara; o n pa awon omokunrin won, o si n da awon obinrin won si. Dajudaju o wa ninu awon obileje |
A si fe sedera fun awon ti won foju tinrin lori ile, A (fe) se won ni asiwaju. A si (fe) ki won jogun (ile) |
A (fe) gba won laaye lori ile. Lati ara won, A si (fe) fi han Fir‘aon ati Hamon pelu awon omo ogun awon mejeeji ohun ti won n sora fun lara won |
A si ranse si iya (Anabi) Musa pe: “Fun un ni omu mu. Ti o ba si n paya lori re, ju u sinu agbami odo. Ma se beru. Ma si se banuje. Dajudaju Awa maa da a pada si odo re. A o si se e ni ara awon Ojise |
Nigba naa, awon eniyan Fir‘aon ri i he nitori ki o le je ota ati ibanuje fun won. Dajudaju Fir‘aon, Hamon ati awon omo ogun awon mejeeji, won je alasise |
Iyawo Fir‘aon wi pe: “Itutu-oju ni (omo yii) fun emi ati iwo. E ma se pa a. O le je pe o maa se wa ni anfaani tabi ki a fi se omo.” Won ko si fura |
Okan iya (Anabi) Musa pami (lori oro Musa, ko si ri nnkan miiran ro mo tayo re) o kuku fee safi han re (pe omo oun ni nigba ti won pe e de odo Fir‘aon) ti ko ba je pe A ki i lokan nitori ki o le wa ninu awon onigbagbo ododo |
وَقَالَتْ لِأُخْتِهِ قُصِّيهِ ۖ فَبَصُرَتْ بِهِ عَن جُنُبٍ وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ(11) O si so fun arabinrin re pe: “Topa re lo.” O si n wo o lati ibi t’o jinna. Won ko si fura (si i) |
A ko si je ki o mu oyan (miiran) siwaju (tiya re.) Arabinrin re si wi pe: “Se ki ng fi ara ile kan han yin, ti o maa gba a to fun yin? Won yo si je olutoju re.” |
A si da a pada si odo iya re nitori ki oju re le tutu (fun idunnu) ati nitori ki o ma baa banuje. Ati pe nitori ki o le mo pe dajudaju adehun Allahu, ododo ni, sugbon opolopo won ni ko mo |
Nigba t’o dagba, t’o di gende, A fun un ni ogbon ati imo. Bayen ni A se n san awon oluse-rere ni esan |
O wo inu ilu nigba ti awon ara ilu ti gbagbe (nipa oro re). O ri awon okunrin meji kan ti won n ja. Eyi wa lati inu iran re. Eyi si wa lati (inu iran) ota re. Eyi ti o wa lati inu iran re wa iranlowo re lori eyi ti o wa lati (inu iran) ota re. Musa kan an ni ese. O si pa a. O so pe: “Eyi wa ninu ise Esu. Dajudaju (esu) ni ota asini-lona ponnbele.” |
قَالَ رَبِّ إِنِّي ظَلَمْتُ نَفْسِي فَاغْفِرْ لِي فَغَفَرَ لَهُ ۚ إِنَّهُ هُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ(16) O so pe: “Oluwa mi, dajudaju emi ti sabosi si emi ara mi. Nitori naa, forijin mi.” O si forijin in. Dajudaju Allahu, Oun ni Alaforijin, Asake-orun |
قَالَ رَبِّ بِمَا أَنْعَمْتَ عَلَيَّ فَلَنْ أَكُونَ ظَهِيرًا لِّلْمُجْرِمِينَ(17) O so pe: “Oluwa mi, fun wi pe O ti se ike fun mi, emi ko nii je oluranlowo fun awon elese.” |
Nitori naa, o di eni t’o n beru ninu ilu, o si n reti (ehonu iran Fir‘aon). Nigba naa ni eni ti o wa iranlowo re ni ana tun n logun re fun iranlowo re. Musa so fun un pe: “Dajudaju iwo ni olusina ponnbele.” |
Amo nigba ti o fe gba eni ti o je ota fun awon mejeeji mu, eni naa wi pe: “Musa, se o fe pa mi bi o se pa eni kan ni ana? O o gbero kan tayo ki o je alailoju-aanu lori ile; o o si gbero lati wa ninu awon alatun-unse.” |
Okunrin kan sare de lati opin ilu naa, o wi pe: “Musa, dajudaju awon ijoye n da imoran lori re lati pa o. Nitori naa, jade (kuro ninu ilu), dajudaju emi wa ninu awon onimoran rere fun o.” |
فَخَرَجَ مِنْهَا خَائِفًا يَتَرَقَّبُ ۖ قَالَ رَبِّ نَجِّنِي مِنَ الْقَوْمِ الظَّالِمِينَ(21) O si jade kuro ninu (ilu) pelu ipaya, ti o n reti (ehonu won), o si so pe: “Oluwa mi, la mi lowo ijo alabosi.” |
وَلَمَّا تَوَجَّهَ تِلْقَاءَ مَدْيَنَ قَالَ عَسَىٰ رَبِّي أَن يَهْدِيَنِي سَوَاءَ السَّبِيلِ(22) Nigba ti o si doju ko okankan ilu Modyan, o so pe: “O sunmo ki Oluwa mi fona taara (si ilu Modyan) mo mi.” |
Nigba ti o de ibi (kannga) omi (ilu) Modyan, o ba ijo eniyan kan nibe ti won n fun awon eran-osin won ni omi mu. Leyin won, o tun ri awon obinrin meji kan ti won n fa seyin (pelu eran-osin won). O so pe: “Ki l’o se eyin mejeeji?” Won so pe: “A o le fun awon eran-osin wa ni omi mu titi awon adaran ba to ko awon eran-osin won lo. Agbalagba arugbo si ni baba wa.” |
O si ba won fun (eran-osin) won ni omi mu. Leyin naa, o pada sibi iboji, o si so pe: “Oluwa mi, dajudaju emi bukata si ohun ti O ba sokale fun mi ninu oore.” |
Okan ninu awon mejeeji wa ba a, o si n rin pelu itiju, o so pe: “Dajudaju baba mi n pe o nitori ki o le san o ni esan omi ti o fun (awon eran-osin) wa mu.” Nigba ti o de odo re, o so itan (ara re) fun un. (Baba naa) so pe: “Ma beru. O ti la lowo ijo alabosi.” |
Okan ninu (awon omobinrin) mejeeji so pe: “Baba mi o, gba a sise. Dajudaju eni t’o dara julo ti o le gba sise ni alagbara, olufokantan.” |
O so pe: “Dajudaju mo fe fi okan ninu awon omobinrin mi mejeeji wonyi fun o ni aya lori (adehun) pe o maa ba mi sise fun odun mejo. Sugbon ti o ba se e pe odun mewaa, lati odo re niyen. Emi ko si fe ko inira ba o. Ti Allahu ba fe, o maa ri i pe mo wa ninu awon eni rere.” |
(Musa) so pe: “(Adehun) yii wa laaarin emi ati iwo. Eyikeyii ti mo ba mu se ninu adehun mejeeji naa, iwo ko gbodo sabosi si mi. Allahu si ni Elerii lori ohun ti a n so (yii).” |
Nigba ti Musa pari akoko naa, o mu ara ile re rin (irin-ajo). O si ri ina kan ni eba apata. O so fun ara ile re pe: “E duro (sibi na). Emi ri ina kan. O se e se ki ng mu iro kan wa ba yin lati ibe tabi (ki ng mu) ogunna kan wa nitori ki e le ri ohun yena.” |
Nigba ti o de ibe, A pe e lati egbe afonifoji ni owo otun (re) ni aye ibukun lati ibi igi naa. (A so pe): “Musa, dajudaju Emi ni Allahu, Oluwa gbogbo eda |
Ju opa re sile.” (O si ju u sile). Nigba ti o ri i t’o n mira bi eni pe ejo ni, Musa peyin da, o n sa lo, ko si pada. (Allahu so pe): “Musa, maa bo pada, ma si se paya. Dajudaju iwo wa ninu awon olufayabale |
Ti owo re bo (abiya lati ibi) orun ewu re, o si maa jade ni funfun ti ki i se ti aburu. Pa owo re mora si (abiya re) nibi eru. Nitori naa, awon eri meji niwonyi lati odo Oluwa re si Fir‘aon ati awon ijoye re. Dajudaju won je ijo obileje.” |
قَالَ رَبِّ إِنِّي قَتَلْتُ مِنْهُمْ نَفْسًا فَأَخَافُ أَن يَقْتُلُونِ(33) (Anabi Musa) so pe: “Oluwa mi, dajudaju emi pa eni kan ninu won. Nitori naa, mo n beru pe won maa pa mi |
Ati pe arakunrin mi, Harun, o da lahon ju mi lo. Nitori naa, ran an nise pelu mi, ki o je oluranlowo ti yoo maa jerii si ododo oro mi. Dajudaju emi n beru pe won maa pe mi ni opuro.” |
(Allahu) so pe: “A maa fi arakunrin re kun o lowo. A o si fun eyin mejeeji ni agbara, won ko si nii le de odo eyin mejeeji. Pelu awon ami Wa, eyin mejeeji ati awon t’o ba tele eyin mejeeji l’o maa bori.” |
Nigba ti (Anabi) Musa de ba won pelu awon ami Wa, won wi pe: “Ki ni eyi bi ko se idan adahun. A ko si gbo eyi (ri) laaarin awon baba wa, awon eni akoko.” |
(Anabi) Musa si so pe: “Oluwa mi nimo julo nipa eni ti o mu imona wa lati odo Re ati eni ti atubotan ile (ike) maa je tire. Dajudaju awon alabosi ko nii jere.” |
Fir‘aon wi pe: “Eyin ijoye, emi ko mo pe olohun kan tun wa leyin mi! Nitori naa, Hamon, da ina fun mi, ki o fi mo amo, ki o si ko ile giga kan fun mi nitori ki emi le yoju wo Olohun Musa. (Nitori pe) dajudaju mo n ro o si ara awon opuro.” |
Oun ati awon omo ogun re si segberaga lori ile lai letoo. Won si ro pe dajudaju A o nii da won pada si odo Wa |
Nitori naa, A gba oun ati awon omo ogun re mu; A ju won sinu agbami odo. Wo bi atubotan awon alabosi ti ri |
وَجَعَلْنَاهُمْ أَئِمَّةً يَدْعُونَ إِلَى النَّارِ ۖ وَيَوْمَ الْقِيَامَةِ لَا يُنصَرُونَ(41) A se won ni asiwaju t’o n pepe sinu Ina. Ti o ba si di Ojo Ajinde, A o nii ran won lowo |
وَأَتْبَعْنَاهُمْ فِي هَٰذِهِ الدُّنْيَا لَعْنَةً ۖ وَيَوْمَ الْقِيَامَةِ هُم مِّنَ الْمَقْبُوحِينَ(42) Ati pe A fi egun topa won ni ile aye yii. Ni Ojo Ajinde, won yo si wa ninu awon eni iparun |
Dajudaju A ti fun (Anabi) Musa ni Tira leyin igba ti A ti pa awon ijo akoko re. (Tira naa je) ariwoye fun awon eniyan, imona ati ike nitori ki won le lo iranti |
Iwo ko si ni eba iwo-oorun nigba ti A fi oro naa ranse si (Anabi) Musa. Ati pe iwo ko si ninu awon t’o wa nibe |
Sugbon A seda awon iran kan ti emi won gun. O o kuku gbe laaarin ara ilu Modyan, ti o n ke awon ayah Wa fun won, sugbon Awa l’a n ran awon Ojise nise |
(Iwo ko si si ni eba apata, nigba ti A pepe, sugbon o je ike kan lati odo Oluwa re nitori ki o le sekilo fun awon eniyan ti olukilo kan ko wa ba ri siwaju re nitori ki won le lo iranti. 16:36 ati surah Fatir 35:24) bee naa l’a ri awon ayah miiran t’o n fi rinle pe Allahu ko ran Ojise tabi Anabi kan ri si awon Larubawa (gege bi o se rinle ninu surah al-Ƙosos ko si Ojise kan ti Allahu gbe dide laaarin won si gbogbo iran won ni apapo. Bi o tile je pe awon Larubawa ni anfaani lati gbo nipa Anabi ’Ibrohim ati omo re Anabi ’Ismo‘il pe Allahu ran won nise si awon eniyan kan amo ko si oye atinuwa fun imo nipa bi won maa se josin fun Allahu Eledaa won afi ki won ni Ojise kan t’o maa je asiwaju fun won gege bi olukoni rere. Idi niyi ti Allahu (subhanahu wa ta’ala) fi gbe Anabi Muhammad (sollalahu alayhi wa sallam) dide ni ara oto. Itumo “ni ara oto” ni pe |
Ti o ba je pe adanwo kan kan won nitori ohun ti won fi owo won ti siwaju, won iba wi pe: “Oluwa wa, ti O ba je pe O ran Ojise kan si wa ni, a a ba tele awon ayah Re, a a ba si wa ninu awon onigbagbo ododo.” |
Sugbon nigba ti ododo de ba won lati odo Wa, won wi pe: "Ki ni ko je ki Won fun un ni iru ohun ti Won fun (Anabi) Musa?" Se won ko si sai gbagbo ninu ohun ti A fun (Anabi) Musa siwaju bi? Won wi pe: “Opidan meji t’o n ranra won lowo (ni won).” Won si tun wi pe: “Dajudaju awa je alaigbagbo ninu ikookan (won).” |
So pe: “Nitori naa, e mu tira kan wa lati odo Allahu, t’o n to ni si ona ju ti awon mejeeji lo, mo si maa tele e, ti e ba je olododo.” |
Ti won ko ba jepe re, mo pe won kan n tele ife-inu won ni. Ta l’o si sina ju eni t’o tele ife-inu re, lai si imona (fun un) lati odo Allahu! Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi |
۞ وَلَقَدْ وَصَّلْنَا لَهُمُ الْقَوْلَ لَعَلَّهُمْ يَتَذَكَّرُونَ(51) Ati pe dajudaju A ti se alaye oro naa fun won nitori ki won le lo iranti |
الَّذِينَ آتَيْنَاهُمُ الْكِتَابَ مِن قَبْلِهِ هُم بِهِ يُؤْمِنُونَ(52) Awon ti A fun ni Tira siwaju re, won gba al-Ƙur’an gbo |
Ati pe nigba ti won ba n ke e fun won, won a so pe: “A gba a gbo. Dajudaju ododo ni lati odo Oluwa wa. Dajudaju awa ti je musulumi siwaju re.” |
Awon wonyen ni A maa fun won ni esan won ni ee meji nitori pe won se suuru, won si n fi daadaa ti aidaa danu. Ati pe won n na ninu ohun ti A pese fun won |
Ati pe nigba ti won ba gbo oro buruku, won a seri kuro nibe, won a si so pe: “Tiwa ni awon ise wa. Tiyin si ni awon ise yin. Ki alaafia maa ba yin. A ko wa awon alaimokan (ni alabaasepo).” |
Dajudaju iwo ko le fi ona mo eni ti o feran, sugbon Allahu l’O n fi ona mo eni ti O ba fe. Ati pe O nimo julo nipa awon olumona |
Won wi pe: “Ti a ba (fi le) tele imona pelu re, awon osebo yoo ko wa kuro lori ile wa.” Se A o fun won ni ibugbe (ti o je) aye owo ifokanbale, ti won si n ko awon eso gbogbo ilu wa sibe, ti o je ese lati odo Wa? Sugbon opolopo won ni ko mo |
Meloo meloo ninu ilu ti A pare, ti won yo ayoporo aye-jije ninu ilu. Iwonyen ni awon ibugbe won, ti A ko je ki eni kan kan gbe ibe leyin won bi ko se fun igba die. Awa si je Olujogun |
Oluwa re ko si nii pa awon ilu run (ni asiko tire yii) titi O fi maa gbe Ojise kan dide ninu Olu-ilu-aye (iyen, ilu Mokkah, eni ti) yoo maa ke awon ayah Wa fun won. (O si ti se bee.) A o si nii pa awon ilu (yii) run se afi ki awon ara ibe je alabosi |
Ko si ohun ti A fun yin bi ko se nitori igbadun aye ati oso re. Ohun t’o n be lodo Allahu loore julo, o si maa wa titi laelae. Nitori naa, se e o nii se laakaye ni |
Nje eni ti A ba sadehun ni adehun t’o dara, ti o si maa pade re, da bi eni ti A fun ni igbadun isemi aye bi, leyin naa ni Ojo Ajinde ti o maa wa ninu awon ti won yoo mu wa (fun iya Ina) |
وَيَوْمَ يُنَادِيهِمْ فَيَقُولُ أَيْنَ شُرَكَائِيَ الَّذِينَ كُنتُمْ تَزْعُمُونَ(62) (Ranti) ojo ti (Allahu) yoo pe won, O si maa so pe: “Nibo ni awon akegbe Mi ti e n so nipa won lai ni eri lowo wa?” |
Awon ti oro naa ko le lori wi pe: “Oluwa wa, awon wonyi ti a ko sina, a ko won sina gege bi awa naa se sina. A yowo yose (ninu oro won) niwaju Re (bayii); ki i se awa ni won n josin fun.” |
A so (fun won) pe: “E pe awon orisa yin.” Won si pe won, sugbon won ko da won lohun. Won ti ri Ina. Ti o ba je pe dajudaju won je olumona ni (iya iba ti je won) |
وَيَوْمَ يُنَادِيهِمْ فَيَقُولُ مَاذَا أَجَبْتُمُ الْمُرْسَلِينَ(65) (Ranti) ojo ti (Allahu) yoo pe won, O si maa so pe: “Ki ni e fo ni esi fun awon Ojise?” |
فَعَمِيَتْ عَلَيْهِمُ الْأَنبَاءُ يَوْمَئِذٍ فَهُمْ لَا يَتَسَاءَلُونَ(66) Esi oro yo si foju po mo won lowo ni ojo yen; won ko si nii bira won leere ibeere |
فَأَمَّا مَن تَابَ وَآمَنَ وَعَمِلَ صَالِحًا فَعَسَىٰ أَن يَكُونَ مِنَ الْمُفْلِحِينَ(67) Sugbon ni ti eni ti o ba ronu piwada, ti o gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere, o sunmo pe o maa wa ninu awon olujere |
Oluwa re l’O n seda ohun ti O ba fe. O si n sa (ohun ti O ba fe) ni esa. Sisa esa ko to si won. Mimo ni fun Allahu. O si ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I |
وَرَبُّكَ يَعْلَمُ مَا تُكِنُّ صُدُورُهُمْ وَمَا يُعْلِنُونَ(69) Oluwa re si mo ohun ti igba-aya won n fi pamo ati ohun ti won n se afihan re |
Oun si ni Allahu. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. TiRe ni ope ni ile aye yii ati ni orun. TiRe si ni idajo. Odo Re si ni won yoo da yin pada si |
So pe: " E so fun mi, ti Allahu ba so oru di ohun ti o maa wa titi laelae fun yin di Ojo Ajinde, olohun wo leyin Allahu l’o maa fun yin ni imole? Se e o gboro ni?” |
So pe: " E so fun mi, ti Allahu ba so osan di ohun ti o maa wa titi laelae fun yin di Ojo Ajinde, olohun wo leyin Allahu l’o maa fun yin ni ale ti e oo maa sinmi ninu re? Se e o riran ni?” |
Ninu ike Re (ni pe) O se oru ati osan fun yin; nitori ki e le sinmi ninu (oru) ati nitori ki e le wa ninu oore Re (ni osan) ati nitori ki e le dupe |
وَيَوْمَ يُنَادِيهِمْ فَيَقُولُ أَيْنَ شُرَكَائِيَ الَّذِينَ كُنتُمْ تَزْعُمُونَ(74) (Ranti) ojo ti (Allahu) yoo pe won, O si maa so pe: “Nibo ni awon akegbe Mi ti e n so nipa won lai ni eri lowo wa?” |
A si maa mu elerii kan jade ninu ijo kookan. A maa so pe: “E mu idi oro yin wa.” Nigba naa, won yoo mo pe dajudaju ododo n je ti Allahu. Ohun ti won si n da ni adapa iro yo si dofo mo won lowo |
Dajudaju Ƙorun wa ninu ijo (Anabi) Musa, sugbon o segberaga si won. A si fun un ni awon apoti-oro eyi ti awon kokoro re wuwo lati gbe fun opo eniyan, awon alagbara. (Ranti) nigba ti awon eniyan re so fun un pe: "Ma se yo ayo ayoju. Dajudaju Allahu ko feran awon alayoju |
Fi nnkan ti Allahu fun o wa ile Ikeyin. Ma se gbagbe ipin re ni ile aye. Se daadaa gege bi Allahu ti se daadaa fun o. Ma si se wa ibaje se lori ile. Dajudaju Allahu ko feran awon obileje |
O wi pe: "Dajudaju won fun mi pelu imo t’o n be lodo mi ni." Se ko mo pe dajudaju Allahu ti parun ninu awon iran t’o siwaju re, eni ti o lagbara ju u lo, ti o si ni akojo oro ju u lo? A o si nii bi awon arufin leere (ese won. O kuku ti wa ni akosile) |
O jade si awon eniyan re pelu oso re. Awon t’o n fe isemi aye yii si wi pe: “Haa! Ki a si ni iru ohun ti won fun Ƙorun. Dajudaju o ni ipin nla ninu oore.” |
Awon ti A fun ni imo so pe: “Egbe ni fun yin! Esan Allahu loore julo fun eni t’o ba gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere. Ko si si eni ti o maa ri (esan naa) gba afi awon onisuuru.” |
Nitori naa, A je ki ile gbe oun ati ile re mi. Ko ni ijo kan ti o le ran an lowo leyin Allahu. Ko si si ninu awon t’o le ran ara re lowo |
Awon t’o n rankan ipo re ni ana si bere si wi pe: “Se e ri i pe dajudaju Allahu l’O n te oro sile fun eni ti O ba fe ninu awon erusin Re. O si n diwon re (fun elomiiran). Ti ko ba je pe Allahu ke wa ni, iba je ki ile gbe awa naa mi ni. Se e ri i pe awon alaimoore ko nii jere.” |
Ile Ikeyin yen, A maa fi fun awon ti ko fe maa se igberaga ati ibaje lori ile. Igbeyin rere si wa fun awon oluberu (Allahu) |
Enikeni ti o ba mu ise rere wa, tire ni rere t’o loore julo si eyi t’o mu wa. Enikeni ti o ba si mu ise aburu wa, A o si nii san awon t’o se ise aburu ni esan kan afi ohun ti won n se nise |
Dajudaju Eni ti O se al-Ƙur’an ni oran-anyan fun o, O si maa da o pada si ebute kan. So pe: “Oluwa mi nimo julo nipa eni ti o mu imona wa ati ta ni o wa ninu isina ponnbele.” |
Iwo ko si reti pe A oo so tira al-Ƙur’an kale fun o (tele), amo o je ike kan lati odo Oluwa re. Nitori naa, o o gbodo je alatileyin fun awon alaigbagbo |
Ma se je ki won se o lori kuro nibi awon ayah Allahu leyin igba ti A ti so o kale fun o. Pepe si odo Oluwa re. Iwo ko si gbodo wa ninu awon osebo |
Ma se pe olohun miiran mo Allahu. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Gbogbo nnkan l’o maa parun afi Oju Re (afi Oun). TiRe ni idajo. Odo Re si ni won yoo da yin pada si |
المزيد من السور باللغة اليوربا:
تحميل سورة القصص بصوت أشهر القراء :
قم باختيار القارئ للاستماع و تحميل سورة القصص كاملة بجودة عالية
أحمد العجمي
خالد الجليل
سعد الغامدي
سعود الشريم
عبد الباسط
عبد الله الجهني
علي الحذيفي
فارس عباد
ماهر المعيقلي
محمد جبريل
المنشاوي
الحصري
مشاري العفاسي
ناصر القطامي
ياسر الدوسري
Thursday, November 21, 2024
لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب