La sourate An-Nur en Yoruba
سُورَةٌ أَنزَلْنَاهَا وَفَرَضْنَاهَا وَأَنزَلْنَا فِيهَا آيَاتٍ بَيِّنَاتٍ لَّعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ(1) (Eyi ni) Surah kan ti A sokale. A se e ni ofin. A si so awon ayah t’o yanju kale sinu re nitori ki e le lo iranti |
Onisina lobinrin ati onisina lokunrin, e na enikookan ninu awon mejeeji ni ogorun-un koboko. E ma se je ki aanu won se yin nipa idajo Allahu ti e ba ni igbagbo ododo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Ki igun kan ninu awon onigbagbo ododo si jerii si iya awon mejeeji. ti o ba di oyun ti oko re ko si mo won ko nii fun won letoo si oorun ife miiran mo tori pe ko si itakoko yigi laaarin won. Bi o tile je pe a ri ninu awon onimo esin t’o ni won le se itakoko yigi obinrin naa fun arakunrin t’o se zina pelu re lori oyun zina naa nitori ki won le maa je igbadun ara won lo ni ona eto eyi ti o dara julo ni pe |
Onisina lokunrin ko nii se sina pelu eni kan bi ko se onisina lobinrin (egbe re) tabi osebo lobinrin. Onisina lobinrin, eni kan ko nii ba a se sina bi ko se onisina lokunrin (egbe re) tabi osebo lokunrin. A si se iyen ni eewo fun awon onigbagbo ododo |
Awon t’o n fi esun sina kan awon omoluabi lobinrin, leyin naa ti won ko mu awon elerii merin wa, e na won ni ogorin koboko. E ma se gba eri won mo laelae; awon wonyen si ni obileje |
إِلَّا الَّذِينَ تَابُوا مِن بَعْدِ ذَٰلِكَ وَأَصْلَحُوا فَإِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ(5) Ayafi awon t’o ronu piwada leyin iyen, ti won si se atunse. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun |
Awon t’o n fi esun sina kan awon iyawo won, ti ko si si elerii fun won afi awon funra won, eri eni kookan won ni ki o fi Allahu jerii ni ee merin pe dajudaju oun wa ninu awon olododo |
وَالْخَامِسَةُ أَنَّ لَعْنَتَ اللَّهِ عَلَيْهِ إِن كَانَ مِنَ الْكَاذِبِينَ(7) Ee karun-un si ni pe ki ibi dandan Allahu maa ba oun, ti oun ba wa ninu awon opuro |
Ohun ti o maa ye iya fun iyawo ni pe ki o fi Allahu jerii ni ee merin pe dajudaju oko oun wa ninu awon opuro |
وَالْخَامِسَةَ أَنَّ غَضَبَ اللَّهِ عَلَيْهَا إِن كَانَ مِنَ الصَّادِقِينَ(9) Ee karun-un si ni pe ki ibinu Allahu maa ba oun, ti oko oun ba wa ninu awon olododo |
وَلَوْلَا فَضْلُ اللَّهِ عَلَيْكُمْ وَرَحْمَتُهُ وَأَنَّ اللَّهَ تَوَّابٌ حَكِيمٌ(10) Ti ki i ba se oore ajulo Allahu ati ike Re lori yin ni (Allahu iba maa tu asiri yin ni). Dajudaju Allahu ni Olugba-ironupiwada, Ologbon |
Dajudaju awon t’o mu adapa iro wa je ijo kan ninu yin. E ma se lero pe aburu ni fun yin. Rara o, oore ni fun yin. Eni kookan ninu won ti ni ohun ti o da ni ese. Ati pe eni ti o da (ese) julo ninu won, iya nla ni tire |
Nigba ti e gbo o, ki ni ko je ki awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin ro daadaa rora won, ki won si so pe: “Eyi ni adapa iro ponnbele.” |
Ki ni ko je ki won mu elerii merin wa lori re? Nitori naa, nigba ti won ko ti mu awon elerii wa, awon wonyen, awon ni opuro lodo Allahu |
Ti ki i ba se ti oore ajulo Allahu ati ike Re lori yin ni ile aye ati ni orun ni, dajudaju iya nla iba fowo ba yin nipa ohun ti e n so kiri ni isokuso |
(E ranti) nigba ti e n gba a (laaarin ara yin) pelu ahon yin, ti e si n fi enu yin so ohun ti e o nimo nipa re; e lero pe nnkan t’o fuye ni, nnkan nla si ni lodo Allahu |
Nigba ti e gbo o, ki ni ko je ki e so pe: “Ki i se eto fun wa pe ki a so eyi. Mimo ni fun O (Allahu)! Eyi ni iparo-moni t’o tobi.” |
يَعِظُكُمُ اللَّهُ أَن تَعُودُوا لِمِثْلِهِ أَبَدًا إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ(17) Allahu n se waasi fun yin pe ki e ma se pada sibi iru re mo laelae ti e ba je onigbagbo ododo |
وَيُبَيِّنُ اللَّهُ لَكُمُ الْآيَاتِ ۚ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ(18) Allahu n salaye awon ayah naa. Allahu si ni Onimo, Ologbon |
Dajudaju awon t’o nifee si ki (oro) ibaje maa tan kale nipa awon t’o gbagbo ni ododo, iya eleta-elero n be fun won ni aye ati ni orun. Allahu nimo, eyin ko si nimo |
وَلَوْلَا فَضْلُ اللَّهِ عَلَيْكُمْ وَرَحْمَتُهُ وَأَنَّ اللَّهَ رَءُوفٌ رَّحِيمٌ(20) Ti ki i ba se oore ajulo Allahu ati ike Re lori yin ni (Allahu iba tete fiya je yin ni). Dajudaju Allahu ni Alaaanu, Asake-orun |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se tele awon oju-ese Esu. Enikeni ti o ba si tele awon oju-ese Esu, dajudaju (Esu) yoo pase iwa ibaje ati aburu (fun un). Ti ki i ba se oore ajulo Allahu ati ike Re lori yin ni, eni kan iba ti mo ninu yin laelae. Sugbon Allahu n safomo eni ti O ba fe. Allahu si ni Olugbo, Onimo |
Ki awon t’o ni ola ati igbalaaye ninu yin ma se bura pe awon ko nii se daadaa si awon ibatan, awon mekunnu ati awon t’o gbe ilu won ju sile nitori esin Allahu. Ki won saforijin, ki won si samojukuro. Se e o fe ki Allahu forijin yin ni? Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun |
Dajudaju awon t’o n paro sina mo awon omoluabi l’obinrin, awon ti sina ko si lori okan won, awon onigbagbo ododo lobinrin, A ti sebi le won ni aye ati ni orun. Iya nla si wa fun won |
يَوْمَ تَشْهَدُ عَلَيْهِمْ أَلْسِنَتُهُمْ وَأَيْدِيهِمْ وَأَرْجُلُهُم بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ(24) Ni ojo ti awon ahon won, owo won ati ese won yoo maa jerii tako won nipa ohun ti won n se nise |
ni ojo yen ni Allahu yoo san won ni esan won ti o to si won. Won yo si mo pe dajudaju Allahu, Oun ni Ododo ponnbele |
Awon obinrin buruku wa fun awon okunrin buruku. Awon okunrin buruku si wa fun awon obinrin buruku. Awon obinrin rere wa fun awon okunrin rere. Awon okunrin rere si wa fun awon obinrin rere. Awon (eni rere) wonyi mowo-mose ninu (aidaa) ti won n so si won. Aforijin ati ese alapon-onle n be fun won |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se wo awon ile kan yato si awon ile yin titi e maa fi toro iyonda ati (titi) e maa fi salamo si awon ara inu ile naa. Iyen loore julo fun yin nitori ki e le lo iranti |
Ti e o ba si ba eni kan kan ninu ile naa, e ma se wo inu re titi won yoo fi yonda fun yin. Ti won ba si so fun yin pe ki e pada, nitori naa e pada. Ohun l’o fo yin mo julo. Allahu si ni Onimo nipa ohun ti e n se nise |
Ko si ese fun yin lati wo inu awon ile kan ti ki i se ibugbe, ti anfaani wa ninu re fun yin . Allahu mo ohun ti e n safi han re ati ohun ti e n fi pamo |
So fun awon onigbagbo ododo lokunrin pe ki won re oju won nile, ki won si so abe won. Iyen fo won mo julo. Dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti won n se nise |
So fun awon onigbagbo ododo lobinrin pe ki won re oju won nile, ki won si so abe won. Ki won ma safi han oso won afi eyi ti o ba han ninu re.1 Ki won fi ibori won bo igba-aya won.2 Ati pe ki won ma safi han oso won afi fun awon oko won tabi awon baba won tabi awon baba oko won tabi awon omokunrin won tabi awon omokunrin oko won tabi awon arakunrin won tabi awon omokunrin arakunrin won tabi awon omokunrin arabinrin won tabi awon obinrin (egbe) won tabi awon erukunrin won tabi awon t’o n tele obinrin fun ise riran, ti won je okunrin akura tabi awon omode ti ko ti i da ihoho awon obinrin mo (si nnkan kan). Ki won ma se fi ese won rin irin-kokoka nitori ki awon (eniyan) le mo ohun ti won fi pamo (sara) ninu oso won. Ki gbogbo yin si ronu piwada sodo Allahu, eyin onigbagbo ododo nitori ki e le jere |
E fi iyawo fun awon apon ninu yin ati awon eni ire ninu awon erukunrin yin. (Ki e si wa oko rere fun) awon erubinrin yin. Ti won ba je alaini, Allahu yoo ro won loro ninu ola Re. Allahu si ni Olugbaaye, Onimo |
Ki awon ti ko ri (owo lati fe) iyawo mu oju won kuro nibi isekuse titi Allahu yoo fi ro won loro ninu ola Re.1 Awon t’o n wa iwe ominira ninu awon eru yin, e ko iwe ominira fun won ti e ba mo ohun rere nipa won. Ki e si fun won ninu dukia Allahu ti O fun yin. (Nitori dukia aye ti e n wa), e ma se je awon erubinrin yin nipa lati lo se sina, ti won ba fe so abe won nibi isekuse.2 Enikeni ti o ba je won nipa, dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun leyin ti e ti je won nipa |
Dajudaju A ti so awon ami t’o yanju, itan awon t’o ti lo siwaju yin ati waasi fun awon oluberu (Allahu) kale fun yin |
Allahu ni Olutan-imole sinu awon sanmo ati ile. Apejuwe imole Re da bi opo atupa kan ti atupa wa ninu re. Atupa naa si wa ninu dingi. Dingi naa da bi irawo kan t’o n tan yanranyanran. Won n tan (imole naa) lati ara igi ibukun kan, igi zaetun. Ki i gba imole nigba ti oorun ba n yo jade tabi nigba ti oorun ba n wo. Epo (imole) re fee da mu imole wa, ina ibaa ma de ibe. Imole lori imole ni. Allahu n to enikeni ti O ba fe si (ona) imole Re. Allahu n fi awon akawe lele fun awon eniyan. Allahu si ni Onimo nipa gbogbo nnkan |
(Awon atupa ibukun naa wa) ninu awon ile kan (iyen awon mosalasi) eyi ti Allahu yonda pe ki won gbega,1 ki won si maa daruko Re ninu re. (Awon eniyan) yo si maa safomo fun Un ninu re ni aaro ati asale |
Awon okunrin ti owo ati kara-kata ko di lowo nibi iranti Allahu, irun kiki ati Zakah yiyo, awon t’o n paya ojo kan ti awon okan ati oju yoo maa yi si otun yi si osi |
(Won se rere wonyi) nitori ki Allahu le fi eyi t’o dara ninu ohun ti won se nise san won ni esan rere ati nitori ki O le se alekun fun won ninu oore ajulo Re. Ati pe Allahu n pese arisiki fun eni ti O ba fe lai la isiro lo |
Awon t’o sai gbagbo, awon ise won da bi ahunpeena t’o wa ni papa, ti eni ti ongbe n gbe si lero pe omi ni titi di igba ti o de sibe, ko si ba kini kan nibe. O si ba Allahu nibi (ise) re (ni orun). (Allahu) si se asepe isiro-ise re fun un. Allahu ni Oluyara nibi isiro-ise |
Tabi (ise awon alaigbagbo) da bi awon okunkun kan ninu ibudo jijin, ti igbi omi n bo o mole, ti igbi omi miiran tun wa ni oke re, ti esujo si wa ni oke re; awon okunkun biribiri ti apa kan won wa lori apa kan (niyi). Nigba ti o ba nawo ara re jade, ko ni fee ri i. Enikeni ti Allahu ko ba fun ni imole, ko le si imole kan fun un |
Se o o ri i pe dajudaju Allahu ni gbogbo eni t’o n be ninu awon sanmo ati lori ile n se afomo fun? Awon eye naa (n se bee) nigba ti won ba n na iye apa won? Ikookan won kuku ti mo bi o se maa kirun re ati bi o se maa se afomo re (fun Un). Allahu si ni Onimo nipa ohun ti won n se nise |
وَلِلَّهِ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ وَإِلَى اللَّهِ الْمَصِيرُ(42) Ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile. Odo Allahu si ni abo eda |
Se o o ri i pe dajudaju Allahu n da esujo kaakiri ni? Leyin naa O n ko o jo mora won. Leyin naa, O n gbe won gun ara won, nigba naa ni o maa ri ojo ti o maa jade lati aarin re. Lati inu sanmo, O si n so awon yiyin kan (t’o da bi) awon apata kale si ori ile aye. O n mu un kolu eni ti O ba fe. O si n seri re kuro fun eni ti O ba fe. Kiko yanranyanran monamona inu esujo si fee le fo awon oju |
يُقَلِّبُ اللَّهُ اللَّيْلَ وَالنَّهَارَ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَعِبْرَةً لِّأُولِي الْأَبْصَارِ(44) Allahu n mu oru ati osan tele ara won ni telentele. Dajudaju ariwoye wa ninu iyen fun awon t’o ni oju iriran |
Allahu seda gbogbo abemi lati inu omi. O wa ninu won, eyi t’o n fi aya re wo. O wa ninu won, eyi t’o n fi ese meji rin. O si wa ninu won, eyi t’o n fi merin rin. Allahu n seda ohun ti O ba fe. Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
لَّقَدْ أَنزَلْنَا آيَاتٍ مُّبَيِّنَاتٍ ۚ وَاللَّهُ يَهْدِي مَن يَشَاءُ إِلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ(46) Dajudaju A ti so awon ayah t’o n yanju oro kale. Allahu si n to enikeni ti O ba fe si ona taara (’Islam) |
Won n wi pe: “A gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. A si tele (ase Won).” Leyin naa, igun kan ninu won n peyin da leyin iyen. Awon wonyen ki i se onigbagbo ododo |
وَإِذَا دُعُوا إِلَى اللَّهِ وَرَسُولِهِ لِيَحْكُمَ بَيْنَهُمْ إِذَا فَرِيقٌ مِّنْهُم مُّعْرِضُونَ(48) Ati pe nigba ti won ba pe won si ti Allahu ati ti Ojise Re nitori ki o le sedajo laaarin won, nigba naa ni igun kan ninu won yoo maa gbunri |
وَإِن يَكُن لَّهُمُ الْحَقُّ يَأْتُوا إِلَيْهِ مُذْعِنِينَ(49) Ti o ba si je pe awon ni won ni eto (are) ni, won yoo wa ba o ni tokan-tara |
Se arun wa ninu okan won ni tabi won seyemeji? Tabi won n paya pe Allahu ati Ojise Re yoo fi ejo won segbe ni? Rara o. Awon wonyen, awon ni alabosi |
Ohun ti o maa je oro awon onigbagbo ododo nigba ti won ba pe won si ti Allahu ati ti Ojise Re nitori ki o le sedajo laaarin won, ni pe won a so pe: “A gbo (ase), a si tele (ase).” Awon wonyen, awon ni olujere |
وَمَن يُطِعِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَيَخْشَ اللَّهَ وَيَتَّقْهِ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْفَائِزُونَ(52) Enikeni ti o ba tele ti Allahu ati ti Ojise Re, ti o n paya Allahu, ti o si n beru Re, awon wonyen, awon ni olujere |
Won si fi Allahu bura ti ibura won si ni agbara pe: "Dajudaju ti o ba pase fun awon, dajudaju awon yoo jade." So pe: “E ma se bura mo. Titele ase (pelu ibura iro enu yin) ti di ohun mimo (fun wa).” Dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise |
So pe: "E tele ti Allahu. Ki e si tele ti Ojise naa. Ti won ba peyin da, ohun ti A gbe ka a lorun l’o n be lorun re, ohun ti A si gbe ka yin lorun l’o n be lorun yin. Ti e ba si tele e, e maa mona taara. Ko si si ojuse kan fun Ojise bi ko se ise-jije ponnbele |
Allahu sadehun fun awon t’o gbagbo ni ododo ninu yin, ti won si se awon ise rere pe dajudaju O maa fi won se arole lori ile gege bi O se fi awon t’o siwaju won se arole. Dajudaju O maa fi aye gba esin won fun won, eyi ti O yonu si fun won. Leyin iberu won, dajudaju O maa fi ifayabale dipo re fun won. Won n josin fun Mi, won ko si fi nnkan kan sebo si Mi. Enikeni ti o ba si sai moore leyin iyen, awon wonyen, awon ni obileje |
وَأَقِيمُوا الصَّلَاةَ وَآتُوا الزَّكَاةَ وَأَطِيعُوا الرَّسُولَ لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ(56) E kirun. E yo Zakah. E tele Ojise naa nitori ki A le ke yin |
Ma se lero pe awon t’o sai gbagbo mori bo ninu iya lori ile. Ina ni ibugbe won. Ikangun naa si buru |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, ki awon eru yin ati awon ti ko ti i balaga ninu yin maa gba iyonda lodo yin nigba meta (wonyi): siwaju irun Subh, nigba ti e ba n bo aso yin sile fun oorun osan ati leyin irun ale. (Igba) meta fun iborasile yin (niyi). Ko si ese fun eyin ati awon leyin (asiko) naa pe ki won wole to yin; ki apa kan yin wole to apa kan. Bayen ni Allahu se n se alaye awon ayah naa fun yin. Allahu si ni Onimo, Ologbon |
Nigba ti awon omode yin ba si balaga, ki awon naa maa gba iyonda gege bi awon t’o siwaju won se gba iyonda. Bayen ni Allahu se n se alaye awon ayah Re fun yin. Allahu si ni Onimo, Ologbon |
Awon t’o ti dagba koja omo bibi ninu awon obinrin, awon ti ko reti ibalopo oorun ife mo, ko si ese fun won lati bo awon aso jilbab won sile, ti won ko si nii se afihan oso kan sita. Ki won si maa wo aso jilbab won lo bee loore julo fun won. Allahu si ni Olugbo, Onimo |
Ko si ese fun afoju, ko si ese fun aro, ko si ese fun alaisan, ko si si ese fun eyin naa lati jeun ninu ile yin, tabi ile awon baba yin, tabi ile awon iya yin, tabi ile awon arakunrin yin, tabi ile awon arabinrin yin, tabi ile awon arakunrin baba yin, tabi ile awon arabinrin baba yin, tabi ile awon arakunrin iya yin, tabi ile awon arabinrin iya yin, tabi (ile) ti e ni ikapa lori kokoro re, tabi (ile) ore yin. Ko si ese fun yin lati jeun papo tabi ni otooto. Nitori naa, ti e ba wo awon inu ile kan, e salamo sira yin. (Eyi je) ikini ibukun t’o dara lati odo Allahu. Bayen ni Allahu se n salaye awon ayah naa fun yin nitori ki e le se laakaye |
Awon onigbagbo ni awon t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Nigba ti won ba si wa pelu re lori oro kan ti o kan gbogbogbo, won ko nii lo titi won yoo fi gba iyonda lodo re. Dajudaju awon t’o n gba iyonda lodo re, awon wonyen ni awon t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Nitori naa, ti won ba gba iyonda lodo re fun apa kan oro ara won, fun eni ti o ba fe ni iyonda ninu won, ki o si ba won toro aforijin lodo Allahu. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun |
E ma se ladisokan pe ipe Ojise laaarin yin da bi ipe apa kan fun apa kan. Allahu kuku ti mo awon t’o n yo sa lo ninu yin. Nitori naa, ki awon t’o n yapa ase re sora nitori ki idaamu ma baa de ba won, tabi nitori ki iya eleta-elero ma baa je won |
Gbo! Dajudaju ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. O si ti mo ohun ti e wa lori re. (Ranti) ojo ti won yo da won pada si odo Re, O si maa fun won ni iro ohun ti won se nise. Allahu si ni Onimo nipa gbogbo nnkan |
Plus de sourates en Yoruba :
Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :
Téléchargez le fichier mp3 de la sourate An-Nur : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate An-Nur complète en haute qualité.
Ahmed Al Ajmy Bandar Balila Khalid Al Jalil Saad Al Ghamdi Saud Al Shuraim Abdul Basit Abdul Rashid Sufi Abdullah Basfar Abdullah Al Juhani Fares Abbad Maher Al Muaiqly Al Minshawi Al Hosary Mishari Al-afasi Yasser Al Dosari
Donnez-nous une invitation valide