📖 0/604 oju-iwe ti a ka
📄 332
Surah Al-Hajj

Surah Al-Hajj

22:1
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ٱتَّقُواْ رَبَّكُمۡۚ إِنَّ زَلۡزَلَةَ ٱلسَّاعَةِ شَيۡءٌ عَظِيمٌ ١
Eyin eniyan, e beru Oluwa yin. Dajudaju imi titi Akoko naa, nnkan nla ni
22:2
يَوۡمَ تَرَوۡنَهَا تَذۡهَلُ كُلُّ مُرۡضِعَةٍ عَمَّآ أَرۡضَعَتۡ وَتَضَعُ كُلُّ ذَاتِ حَمۡلٍ حَمۡلَهَا وَتَرَى ٱلنَّاسَ سُكَٰرَىٰ وَمَا هُم بِسُكَٰرَىٰ وَلَٰكِنَّ عَذَابَ ٱللَّهِ شَدِيدٌ ٢
(Akoko naa ni) ojo ti e maa ri i ti gbogbo obinrin t’o n fun omo lomu mu yoo gbagbe omo ti won n fun lomu ati pe gbogbo aboyun yo si maa bi oyun won. Iwo yo si ri awon eniyan ti oti yoo maa pa won. Oti ko si pa won, sugbon iya Allahu (t’o) le (l’o fa a)
22:3
وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يُجَٰدِلُ فِي ٱللَّهِ بِغَيۡرِ عِلۡمٍ وَيَتَّبِعُ كُلَّ شَيۡطَٰنٍ مَّرِيدٍ ٣
O si n be ninu awon eniyan eni t’o n jiyan nipa (esin) Allahu lai ni imo. O si n tele gbogbo esu olori kunkun
22:4
كُتِبَ عَلَيۡهِ أَنَّهُۥ مَن تَوَلَّاهُ فَأَنَّهُۥ يُضِلُّهُۥ وَيَهۡدِيهِ إِلَىٰ عَذَابِ ٱلسَّعِيرِ ٤
Won ko o le (Esu) lori pe dajudaju enikeni ti o ba tele e, o maa si i lona. O si maa to o si ona iya Ina t’o n jo fofo
22:5
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِن كُنتُمۡ فِي رَيۡبٍ مِّنَ ٱلۡبَعۡثِ فَإِنَّا خَلَقۡنَٰكُم مِّن تُرَابٍ ثُمَّ مِن نُّطۡفَةٍ ثُمَّ مِنۡ عَلَقَةٍ ثُمَّ مِن مُّضۡغَةٍ مُّخَلَّقَةٍ وَغَيۡرِ مُخَلَّقَةٍ لِّنُبَيِّنَ لَكُمۡۚ وَنُقِرُّ فِي ٱلۡأَرۡحَامِ مَا نَشَآءُ إِلَىٰٓ أَجَلٍ مُّسَمًّى ثُمَّ نُخۡرِجُكُمۡ طِفۡلًا ثُمَّ لِتَبۡلُغُوٓاْ أَشُدَّكُمۡۖ وَمِنكُم مَّن يُتَوَفَّىٰ وَمِنكُم مَّن يُرَدُّ إِلَىٰٓ أَرۡذَلِ ٱلۡعُمُرِ لِكَيۡلَا يَعۡلَمَ مِنۢ بَعۡدِ عِلۡمٍ شَيۡـًٔاۚ وَتَرَى ٱلۡأَرۡضَ هَامِدَةً فَإِذَآ أَنزَلۡنَا عَلَيۡهَا ٱلۡمَآءَ ٱهۡتَزَّتۡ وَرَبَتۡ وَأَنۢبَتَتۡ مِن كُلِّ زَوۡجِۭ بَهِيجٍ ٥
Eyin eniyan, ti e ba wa ninu iyemeji nipa ajinde, dajudaju Awa seda yin lati inu erupe, leyin naa lati inu ato, leyin naa lati inu eje didi, leyin naa lati inu baasi eran ti o pe ni eda ati eyi ti ko pe ni eda nitori ki A le salaye (agbara Wa) fun yin. A si n mu ohun ti A ba fe duro sinu apo ibimo titi di gbedeke akoko kan. Leyin naa, A oo mu yin jade ni oponlo. Leyin naa, (e oo maa semi lo) nitori ki e le sanngun dopin agbara yin. Eni ti o maa ku (ni kekere) wa ninu yin. O si wa ninu yin eni ti A oo da (isemi) re si di asiko ogbo kujokujo nitori ki o ma le mo nnkan kan mo leyin ti o ti mo on. Ati pe o maa ri ile ni gbigbe. Nigba ti A ba si so ojo kale le e lori, o maa yira pada. O maa gberu. O si maa mu gbogbo orisirisi irugbin t’o dara jade
العربيةEnglishBahasa IndonesiaTürkçeРусскийفارسیFrançaisاردوবাংলাDeutschEspañol中文हिन्दीPortuguêsItalianoภาษาไทยPolskiNederlandsShqipKiswahiliO'zbekதமிழ்MelayuBosanskiSoomaaliAzərbaycanکوردی한국어日本語SvenskaDanskNorskپښتوമലയാളംසිංහලTamazightHausaአማርኛБългарскиТоҷикӣҚазақшаFilipinoسنڌيYorùbáFulfuldeТатарчаئۇيغۇرچەКыргызчаਪੰਜਾਬੀJawaతెలుగుမြန်မာગુજરાતીOromoमराठीTiếng ViệtMalagasyНохчийнWolofދިވެހިಕನ್ನಡУкраїнськаΕλληνικάქართულიខ្មែរدریQafar afMaranaoनेपाली
Al-Kur'an
Tuesday, August 25, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







