سورة الزمر باليوربا
Isokale Tira naa (sele) lati odo Allahu, Alagbara, Ologbon |
إِنَّا أَنزَلْنَا إِلَيْكَ الْكِتَابَ بِالْحَقِّ فَاعْبُدِ اللَّهَ مُخْلِصًا لَّهُ الدِّينَ(2) Dajudaju Awa so Tira (al-Ƙur’an) kale fun o pelu ododo. Nitori naa, josin fun Allahu ni olusafomo-esin fun Un |
Gbo! Ti Allahu ni esin mimo. Awon ti won si mu awon alafeyinti kan yato si Allahu, (won wi pe): "A o josin fun won bi ko se pe nitori ki won le mu wa sunmo Allahu pekipeki ni." Dajudaju Allahu l’O maa dajo laaarin won nipa ohun ti won n yapa enu nipa re (iyen, esin ’Islam). Dajudaju Allahu ki i fi ona mo eni ti o je opuro, alaigbagbo |
Ti o ba je pe Allahu ba fe fi eni kan se omo ni, iba sesa ohun ti O ba fe (fi somo) ninu nnkan ti O da. Mimo ni fun Un (nibi eyi). Oun ni Allahu, Okan soso, Olubori |
O seda awon sanmo ati ile pelu ododo. O n ti oru bonu osan. O si n ti osan bonu oru. O si ro oorun ati osupa; ikookan won n rin fun gbedeke akoko kan. Gbo! Oun ni Alagbara, Alaforijin |
O seda yin lati ara emi eyo kan. Leyin naa, O da iyawo re lati ara re. O si so mejo kale fun yin ninu eran-osin ni tako-tabo. O n seda yin sinu iya yin, eda kan leyin eda kan ninu awon okunkun meta. Iyen ni Allahu, Oluwa yin. TiRe ni ijoba. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, bawo ni won se n se yin lori kuro nibi ododo |
Ti e ba sai moore, dajudaju Allahu roro lai si eyin (ko si ni bukata si yin). Ko si yonu si aimoore fun awon erusin Re. Ti e ba dupe, O maa yonu si i fun yin. Eleru-ese kan ko si nii ru eru ese elomiiran. Leyin naa, odo Oluwa yin ni ibupadasi yin. O si maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise. Dajudaju Oun ni Onimo nipa ohun ti n be ninu igba-aya eda |
Nigba ti inira kan ba fowo ba eniyan, o maa pe Oluwa re ni oluseri si odo Re. Leyin naa, nigba ti O ba se idera fun un lati odo Re, o maa gbagbe ohun t’o se ni adua si (Oluwa re) siwaju. O si maa so (awon eda kan) di akegbe fun Allahu nitori ki o le ko isina ba (elomiiran) ni oju ona esin Re (’Islam). So pe: "Fi aigbagbo re jegbadun aye fun igba die. Dajudaju iwo wa ninu awon ero inu Ina |
Nje eni ti o je olutele ti Allahu (t’o je) oluforikanle ati oludideduro (lori irun kiki) ni awon akoko ale, t’o n sora fun orun, t’o si n ni agbekele ninu aanu Oluwa re (da bi elese bi?) So pe: "Nje awon ti won nimo ati awon ti ko nimo dogba bi? Awon onilaakaye nikan l’o n lo iranti |
So pe: "Eyin erusin Mi ti e gbagbo ni ododo, e beru Oluwa yin. Esan rere wa fun awon t’o se rere ni ile aye yii. Ile Allahu si gbooro. Awon onisuuru ni Won si maa fun ni esan (rere ise) won lai la isiro lo |
قُلْ إِنِّي أُمِرْتُ أَنْ أَعْبُدَ اللَّهَ مُخْلِصًا لَّهُ الدِّينَ(11) So pe: "Dajudaju Won pa mi ni ase pe ki ng josin fun Allahu ni ti oluse-afomo-esin fun Un |
Won tun pa mi ni ase pe ki emi je eni akoko (ninu) awon musulumi (ni asiko temi) |
قُلْ إِنِّي أَخَافُ إِنْ عَصَيْتُ رَبِّي عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ(13) So pe: "Dajudaju emi n paya iya ojo nla, ti mo ba fi le yapa ase Oluwa mi |
So pe: "Allahu ni emi yoo maa josin fun (mo maa je) oluse-afomo-esin mi fun Un |
Nitori naa, ki e josin fun ohun ti e ba fe leyin Re." So pe: "Dajudaju awon eni ofo ni awon t’o se emi ara won ati ara ile won lofo ni Ojo Ajinde. Gbo! Iyen, ohun ni ofo ponnbele |
Awon aja Ina maa wa ni oke won. Awon aja yo si wa ni isale won. Iyen ni Allahu fi n deru ba awon erusin Re (bayii pe:) "Eyin erusin Mi, e beru Mi |
Awon ti won yago fun awon orisa lati josin fun un, won si seri pada si (jijosin fun) Allahu, iro idunnu n be fun won. Nitori naa, fun awon erusin Mi ni iro idunnu |
Awon t’o n teti gbo oro, ti won si n tele eyi t’o dara julo ninu re, awon wonyen ni awon ti Allahu fi mona. Awon wonyen, awon ni onilaakaye |
أَفَمَنْ حَقَّ عَلَيْهِ كَلِمَةُ الْعَذَابِ أَفَأَنتَ تُنقِذُ مَن فِي النَّارِ(19) Se eni ti oro iya Ina ti kole lori (nipa aigbagbo re, se ko nii wona ni?) Se iwo l’o maa la eni t’o wa ninu Ina (nipase aigbagbo re) ni |
Sugbon awon t’o beru Oluwa won, tiwon ni awon ile giga, ti awon ile giga tun wa loke re, awon odo yo si maa san ni isale re. Adehun Allahu ni (eyi). Allahu ko si nii ye adehun naa |
Se o o ri i pe dajudaju Allahu l’O so omi kale lati sanmo, O si mu omi naa bo sinu awon opopona odo ninu ile, leyin naa, O n fi mu irugbin ti awo won yato sira won jade, leyin naa, (irugbin naa) yoo gbe, o si maa ri i ni pipon, leyin naa, O maa so o di rirun? Dajudaju iranti wa ninu iyen fun awon onilaakaye |
Nje eni ti Allahu gba okan re laaye fun esin ’Islam, ti o si wa ninu imole lati odo Oluwa re (da bi alaigbagbo bi)? Egbe ni fun awon ti okan won le si iranti Allahu. Awon wonyen wa ninu isina ponnbele |
Allahu l’O so oro t’o dara julo kale, (o je) Tira, ti (awon oro inu re) jora won ni oro asotunso, ti awo ara awon t’o n paya Oluwa won yo si maa wariri nitori re. Leyin naa, awo ara won ati okan won yoo maa ro nibi iranti Allahu. Iyen ni imona Allahu. O si n fi se imona fun eni ti O ba fe. Eni ti Allahu ba si lona, ko si nii si afinimona kan fun un |
Nje eni ti o maa foju ara re ko aburu iya Ina ni Ojo Ajinde (da bi eni ti o maa wo inu Ogba Idera woorowo)? Won yo si so fun awon alabosi pe: "E to iya ohun ti e n se nise wo |
كَذَّبَ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ فَأَتَاهُمُ الْعَذَابُ مِنْ حَيْثُ لَا يَشْعُرُونَ(25) Awon t’o siwaju won pe ododo niro. Nitori naa, iya de ba won ni aye ti won ko ti fura |
Allahu fun won ni abuku iya to wo ninu isemi aye yii. Iya orun si tobi julo ti o ba je pe won mo |
وَلَقَدْ ضَرَبْنَا لِلنَّاسِ فِي هَٰذَا الْقُرْآنِ مِن كُلِّ مَثَلٍ لَّعَلَّهُمْ يَتَذَكَّرُونَ(27) A si ti se gbogbo akawe fun awon eniyan ninu al-Ƙur’an yii nitori ki won le lo iranti |
قُرْآنًا عَرَبِيًّا غَيْرَ ذِي عِوَجٍ لَّعَلَّهُمْ يَتَّقُونَ(28) Al-Ƙur’an ni ede Larubawa, eyi ti oro inu re ko doju ru (l’A sokale) nitori ki won le beru (Allahu) |
Allahu fi akawe kan lele; erukunrin kan t’o wa labe ase oga pupo ti won n fa a kiri (ko si mo ta ni o maa da lohun ninu awon oga re) ati (akawe) erukunrin kan t’o da wa gedegbe labe ogakunrin kan. Nje awon (eru) mejeeji dogba ni akawe bi? Gbogbo ope n je ti Allahu, sugbon opolopo won ni ko mo |
Dajudaju iwo maa ku. Dajudaju awon naa maa ku |
ثُمَّ إِنَّكُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ عِندَ رَبِّكُمْ تَخْتَصِمُونَ(31) Leyin naa, ni Ojo Ajinde dajudaju eyin yoo maa ba ara yin se ariyanjiyan ni odo Oluwa yin |
Nitori naa, ta l’o sabosi ju eni t’o paro mo Allahu, t’o tun pe ododo niro nigba ti o de ba a? Se ki i se Ina ni ibugbe fun awon alaigbagbo ni |
وَالَّذِي جَاءَ بِالصِّدْقِ وَصَدَّقَ بِهِ ۙ أُولَٰئِكَ هُمُ الْمُتَّقُونَ(33) Eni ti o si mu ododo wa (iyen, Anabi Muhammad s.a.w.) ati (awon) eni t’o gba a gbo ni ododo; awon wonyen, awon ni oluberu (Allahu) |
لَهُم مَّا يَشَاءُونَ عِندَ رَبِّهِمْ ۚ ذَٰلِكَ جَزَاءُ الْمُحْسِنِينَ(34) Ohunkohun ti won ba n fe wa fun won ni odo Oluwa won. Iyen si ni esan awon eni rere |
nitori ki Allahu le ba won pa aburu ti won se re ati (nitori) ki O le fi eyi t’o dara julo si ohun ti won n se nise san won ni esan won |
Se Allahu ko to fun erusin Re ni? Won si n fi awon elomiiran leyin Re deru ba o! Enikeni ti Allahu ba si lona, ko le si afinimona kan fun un |
وَمَن يَهْدِ اللَّهُ فَمَا لَهُ مِن مُّضِلٍّ ۗ أَلَيْسَ اللَّهُ بِعَزِيزٍ ذِي انتِقَامٍ(37) Enikeni ti Allahu ba fi mona (’Islam), ko le si asinilona fun un. Se Allahu ko ni Alagbara, Olugba-esan |
Dajudaju ti o ba bi won leere pe: "Ta ni O da awon sanmo ati ile?", dajudaju won a wi pe: "Allahu ni." So pe: "E so fun mi nipa awon nnkan ti e n pe leyin Allahu, ti Allahu ba gbero inira kan ro mi, nje won le mu inira Re kuro fun mi? Tabi ti O ba gbero ike kan si mi, nje won le da ike Re duro bi?" So pe: "Allahu to fun mi. Oun si ni awon olugbarale n gbarale |
قُلْ يَا قَوْمِ اعْمَلُوا عَلَىٰ مَكَانَتِكُمْ إِنِّي عَامِلٌ ۖ فَسَوْفَ تَعْلَمُونَ(39) So pe: "Eyin eniyan mi, e se tiyin ni aye yin. Emi naa n se temi. Nitori naa, laipe e maa mo |
مَن يَأْتِيهِ عَذَابٌ يُخْزِيهِ وَيَحِلُّ عَلَيْهِ عَذَابٌ مُّقِيمٌ(40) eni ti iya ti o maa yepere re maa de ba, ti iya gbere si maa ko le lori |
Dajudaju Awa so Tira kale fun o pelu ododo (ki o le fi se iranti) fun awon eniyan. Nitori naa, eni ti o ba mona, o mona fun emi ara re. Eni ti o ba si sina, o sina fun emi ara re. Iwo si ko ni oluso lori won |
Allahu l’O n gba awon emi ni akoko iku won ati (awon emi) ti ko ku soju oorun won. O n mu (awon emi) ti O ti pebubu iku le lori mole. O si n fi awon yooku sile titi di gbedeke akoko kan. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni arojinle |
Tabi won mu awon olusipe miiran leyin Allahu ni? So pe: "(Won mu won ni olusipe) t’o si je pe won ko ni agbara kan kan, won ko si nii laakaye |
So pe: "Ti Allahu ni gbogbo isipe patapata. TiRe ni ijoba awon sanmo ati ile. Leyin naa, odo Re ni won yoo da yin pada si |
Nigba ti won ba daruko Allahu nikan soso, okan awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo maa sa kuro (nibi mimu Allahu ni okan soso). Nigba ti won ba si daruko awon miiran (ti won n josin fun) leyin Re, nigba naa ni won yoo maa dunnu |
So pe: "Allahu, Olupileda awon sanmo ati ile, Onimo-ikoko ati gbangba, Iwo l’O maa dajo laaarin awon erusin Re nipa ohun ti won n yapa enu si |
Ti o ba je pe dajudaju gbogbo nnkan ti o wa lori ile je ti awon alabosi ati iru re miiran pelu re (tun je tiwon ni), won iba fi serapada (fun emi ara won) nibi aburu iya ni Ojo Ajinde. (Nigba yen) ohun ti won ko lero maa han si won ni odo Allahu |
وَبَدَا لَهُمْ سَيِّئَاتُ مَا كَسَبُوا وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ(48) Awon aburu ohun ti won se nise maa han si won. Ati pe ohun ti won n fi se yeye si maa diya t’o maa yi won po |
Nigba ti inira kan ba fowo ba eniyan, o maa pe Wa. Leyin naa, nigba ti A ba fun un ni idera kan lati odo Wa, o maa wi pe: "Won fun mi pelu imo ni." Ko si ri bee, adanwo ni, sugbon opolopo won ni ko mo |
قَدْ قَالَهَا الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ فَمَا أَغْنَىٰ عَنْهُم مَّا كَانُوا يَكْسِبُونَ(50) Awon t’o siwaju won kuku wi (iru) re, sugbon ohun ti won n se nise ko ro won loro |
Aburu ohun ti won se nise si ba won. Awon alabosi ninu awon wonyi naa, aburu ohun ti won se nise yoo ba won. Won ko si nii mori bo |
Se won ko mo pe dajudaju Allahu l’O n te arisiki sile fun eni ti O ba fe. O si n diwon re (fun elomiiran). Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo onigbagbo ododo |
So pe: "Eyin erusin Mi, ti e ti dese pupo si emi ara yin lorun, e ma se soreti nu nipa ike Allahu. Dajudaju Allahu l’O n saforijin gbogbo ese patapata. Dajudaju Allahu, Oun ni Alaforijin, Asake-orun |
E seri pada (ni ti ironupiwada) si odo Oluwa yin. Ki e si juwo-juse sile fun Un siwaju ki iya naa t’o wa ba yin. (Bi bee ko) leyin naa, A o nii ran yin lowo |
Ki e si tele ohun ti o dara julo ti won sokale fun yin lati odo Oluwa yin siwaju ki iya naa to wa ba yin ni ojiji, nigba ti eyin ko nii fura |
Nitori ki emi kan ma baa wi pe: "Mo ka abamo lori bi mo se jafara lori aitele ase Allahu. Ati pe emi wa ninu awon t’o n fi (oro Re) se yeye |
أَوْ تَقُولَ لَوْ أَنَّ اللَّهَ هَدَانِي لَكُنتُ مِنَ الْمُتَّقِينَ(57) Tabi ki o ma baa wi pe: "Ti o ba je pe Allahu fi ona mo mi ni, dajudaju emi iba wa ninu awon oluberu (Allahu) |
أَوْ تَقُولَ حِينَ تَرَى الْعَذَابَ لَوْ أَنَّ لِي كَرَّةً فَأَكُونَ مِنَ الْمُحْسِنِينَ(58) Tabi nigba ti o ba ri Ina ki o ma baa wi pe: "Ti o ba je pe ipadasaye wa fun mi ni, emi iba si wa ninu awon oluse-rere |
بَلَىٰ قَدْ جَاءَتْكَ آيَاتِي فَكَذَّبْتَ بِهَا وَاسْتَكْبَرْتَ وَكُنتَ مِنَ الْكَافِرِينَ(59) Rara o! Awon ayah Mi kuku ti de ba o. O pe e niro. O tun segberaga. O si wa ninu awon alaigbagbo |
Ati pe ni Ojo Ajinde, o maa ri awon t’o paro mo Allahu ti oju won maa dudu. Se inu ina Jahnamo ko ni ibugbe fun awon onigbeeraga ni |
Allahu yoo gba awon t’o beru (Re) la sinu ile igbala won (iyen, Ogba Idera). Aburu ko nii fowo ba won. Won ko si nii banuje |
اللَّهُ خَالِقُ كُلِّ شَيْءٍ ۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ وَكِيلٌ(62) Allahu ni Eledaa gbogbo nnkan. Oun si ni Oluso lori gbogbo nnkan |
TiRe ni awon kokoro apoti-oro awon sanmo ati ile. Awon t’o sai gbagbo ninu awon ayah Allahu, awon wonyen, awon ni eni ofo |
قُلْ أَفَغَيْرَ اللَّهِ تَأْمُرُونِّي أَعْبُدُ أَيُّهَا الْجَاهِلُونَ(64) So pe: "Se nnkan miiran yato si Allahu l’e n pa mi lase pe ki ng maa josin fun, eyin alaimokan |
Dajudaju A ti fi imisi ranse si iwo ati awon t’o siwaju re (pe) "Dajudaju ti o ba sebo, ise re maa baje. Dajudaju o si maa wa ninu awon eni ofo |
Rara (ma sebo). Allahu nikan ni ki o josin fun. Ki o si wa ninu awon oludupe (fun Un) |
Won ko bu iyi fun Allahu bi o se to lati bu iyi fun Un. Gbogbo ile patapata si ni (Allahu) maa fowo ara Re gbamu ni Ojo Ajinde. O si maa fi owo otun Re ka sanmo korobojo. Mimo ni fun Un. O si ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I |
Won a fon fere oniwo fun iku. Awon t’o wa ninu awon sanmo ati ile si maa ku afi eni ti Allahu ba fe. Leyin naa, won maa fon on ni ee keji, nigba naa won maa wa ni idide. Won yo si maa wo sun |
Ati pe ile naa yoo maa tan yanranyanran pelu imole Oluwa re. Won maa gbe iwe ise eda lele. Won si maa mu awon Anabi ati awon elerii wa. A o si sedajo laaarin won pelu ododo. A o si nii sabosi si won |
وَوُفِّيَتْ كُلُّ نَفْسٍ مَّا عَمِلَتْ وَهُوَ أَعْلَمُ بِمَا يَفْعَلُونَ(70) Ati pe Won maa san emi kookan ni esan ohun ti o se nise. Allahu si nimo julo nipa ohun ti won n se nise |
Won yo si da awon t’o sai gbagbo lo sinu ina Jahnamo nijonijo, titi di igba ti won ba de ibe, won maa si awon ilekun re sile (fun won). Awon eso re yo si so fun won pe: "Nje awon Ojise kan ko wa ba yin lati aarin ara yin, ti won n ke awon ayah Oluwa yin fun yin, ti won si n kilo ipade ojo yin oni yii fun yin?" Won wi pe: "Rara (won wa ba wa)." Sugbon oro iya ko le awon alaigbagbo lori ni |
قِيلَ ادْخُلُوا أَبْوَابَ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا ۖ فَبِئْسَ مَثْوَى الْمُتَكَبِّرِينَ(72) A oo so pe: "E wo enu ona ina Jahnamo. Olusegbere (ni yin) ninu re. Ibugbe awon olusegberaga si buru |
Ati pe A oo ko awon t’o beru Oluwa won lo sinu Ogba Idera nijonijo, titi di igba ti won ba de ibe, won maa si awon ilekun re sile (fun won). Awon eso re yo si so fun won pe: "Ki alaafia maa ba yin. Eyin se ise t’o dara. Nitori naa, e wo inu Ogba Idera, (ki e di) olusegbere (ninu re) |
Won a so pe: "Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti O mu adehun Re se fun wa. O tun jogun ile naa fun wa, ti a n gbe nibikibi ti a ba fe ninu Ogba Idera." Esan awon oluse-rere ma si dara |
O maa si ri awon Molaika ti won n rokirika ni egbe Ite-ola. Won n se afomo ati idupe fun Oluwa won. A maa fi ododo sedajo laaarin awon eda. Won si maa so pe: "Gbogbo ope n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda |
المزيد من السور باللغة اليوربا:
تحميل سورة الزمر بصوت أشهر القراء :
قم باختيار القارئ للاستماع و تحميل سورة الزمر كاملة بجودة عالية
أحمد العجمي
خالد الجليل
سعد الغامدي
سعود الشريم
عبد الباسط
عبد الله الجهني
علي الحذيفي
فارس عباد
ماهر المعيقلي
محمد جبريل
المنشاوي
الحصري
مشاري العفاسي
ناصر القطامي
ياسر الدوسري
Friday, January 3, 2025
لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب