Surah At-Taghabun ni Arabic ati Yorùbá

Ka Surah At-Taghabun pẹlu itumọ pipe ni Yorùbá ati iṣẹ́-ohun. Itumọ ẹsẹ kọọkan. (18 Ẹsẹ — مدنية). At-Taghabun Gbọ, At-Taghabun Itumọ, At-Taghabun mp3, At-Taghabun pdf.

Ka ati Gbọ Surah At-Taghabun

🎧 Ẹsẹ
M Mishary Rashid Alafasy
M Mahmoud Khalil Al-Husary
A Abdurrahman As-Sudais
M Mohamed Siddiq Al-Minshawi
A Abdul Basit Abdul Samad
A Ali Al-Hudhaify
A Ahmed ibn Ali al-Ajamy
A Abu Bakr Ash-Shaatree
M Muhammad Ayyoub
A Abdullah Basfar
A Abdullah Al-Juhani
M Maher Al Muaiqly
x1
يُسَبِّحُ لِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۖ لَهُ الْمُلْكُ وَلَهُ الْحَمْدُ ۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ ۝١
📖 Itumọ Ẹsẹ 1
Ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile n se afomo fun Allahu. TiRe ni ijoba. TiRe si ni ope. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan
هُوَ الَّذِي خَلَقَكُمْ فَمِنكُمْ كَافِرٌ وَمِنكُم مُّؤْمِنٌ ۚ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ ۝٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 2
Oun ni Eni ti O seda yin. Alaigbagbo wa ninu yin. Onigbagbo ododo si wa ninu yin. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se
خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بِالْحَقِّ وَصَوَّرَكُمْ فَأَحْسَنَ صُوَرَكُمْ ۖ وَإِلَيْهِ الْمَصِيرُ ۝٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 3
O seda awon sanmo ati ile pelu ododo. O ya aworan yin. O si se awon aworan yin daradara. Odo Re si ni abo eda
يَعْلَمُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَيَعْلَمُ مَا تُسِرُّونَ وَمَا تُعْلِنُونَ ۚ وَاللَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ ۝٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 4
O mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. O si mo ohun ti e n fi pamo ati ohun ti e n safi han re. Allahu si ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu igba-aya eda
أَلَمْ يَأْتِكُمْ نَبَأُ الَّذِينَ كَفَرُوا مِن قَبْلُ فَذَاقُوا وَبَالَ أَمْرِهِمْ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ ۝٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 5
Se iro awon t’o sai gbagbo ni isaaju ko ti i de ba yin ni? Nitori naa, won to iya oran won wo. Iya eleta-elero si wa fun won
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُ كَانَت تَّأْتِيهِمْ رُسُلُهُم بِالْبَيِّنَاتِ فَقَالُوا أَبَشَرٌ يَهْدُونَنَا فَكَفَرُوا وَتَوَلَّوا ۚ وَّاسْتَغْنَى اللَّهُ ۚ وَاللَّهُ غَنِيٌّ حَمِيدٌ ۝٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 6
Iyen nitori pe dajudaju awon Ojise won n wa ba won pelu awon eri t’o yanju. Won si wi pe: "Se abara l’o maa fi ona mo wa?" Nitori naa, won sai gbagbo. Won si peyin da (si ododo). Allahu si roro lai si awon. Ati pe Allahu ni Oloro, Olope
زَعَمَ الَّذِينَ كَفَرُوا أَن لَّن يُبْعَثُوا ۚ قُلْ بَلَىٰ وَرَبِّي لَتُبْعَثُنَّ ثُمَّ لَتُنَبَّؤُنَّ بِمَا عَمِلْتُمْ ۚ وَذَٰلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرٌ ۝٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 7
Awon t’o sai gbagbo lero pe A o nii gbe won dide. So pe: "Bee ko, mo fi Oluwa mi bura, dajudaju Won yoo gbe yin dide. Leyin naa, Won yoo fun yin ni iro ohun ti e se nise. Iyen si je irorun fun Allahu
فَآمِنُوا بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ وَالنُّورِ الَّذِي أَنزَلْنَا ۚ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ ۝٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 8
Nitori naa, e gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re ati imole ti A sokale. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se
يَوْمَ يَجْمَعُكُمْ لِيَوْمِ الْجَمْعِ ۖ ذَٰلِكَ يَوْمُ التَّغَابُنِ ۗ وَمَن يُؤْمِن بِاللَّهِ وَيَعْمَلْ صَالِحًا يُكَفِّرْ عَنْهُ سَيِّئَاتِهِ وَيُدْخِلْهُ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا ۚ ذَٰلِكَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ ۝٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 9
Ni ojo ti (Allahu) yoo ko yin jo fun ojo akojo. Iyen ni ojo ere ati adanu. Enikeni ti o ba gba Allahu gbo ni ododo, ti o si se ise rere, (Allahu) yoo pa awon asise re re fun un. O si maa mu un wo inu Ogba Idera, ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Iyen si ni erenje nla
وَالَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ خَالِدِينَ فِيهَا ۖ وَبِئْسَ الْمَصِيرُ ۝١٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 10
Awon t’o si sai gbagbo, ti won tun pe awon ayah Wa niro, awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re. Ikangun naa si buru
مَا أَصَابَ مِن مُّصِيبَةٍ إِلَّا بِإِذْنِ اللَّهِ ۗ وَمَن يُؤْمِن بِاللَّهِ يَهْدِ قَلْبَهُ ۚ وَاللَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ ۝١١
📖 Itumọ Ẹsẹ 11
Adanwo kan ko le sele ayafi pelu iyonda Allahu. Enikeni ti o ba gba Allahu gbo, Allahu maa fi okan re mona. Allahu si ni Onimo nipa gbogbo nnkan
وَأَطِيعُوا اللَّهَ وَأَطِيعُوا الرَّسُولَ ۚ فَإِن تَوَلَّيْتُمْ فَإِنَّمَا عَلَىٰ رَسُولِنَا الْبَلَاغُ الْمُبِينُ ۝١٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 12
Ki e tele ti Allahu. Ki e si tele ti Ojise. Ti e ba gbunri, ise-jije ponnbele lojuse Ojise Wa
اللَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۚ وَعَلَى اللَّهِ فَلْيَتَوَكَّلِ الْمُؤْمِنُونَ ۝١٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 13
Allahu, ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Allahu si ni ki awon onigbagbo ododo gbarale
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِنَّ مِنْ أَزْوَاجِكُمْ وَأَوْلَادِكُمْ عَدُوًّا لَّكُمْ فَاحْذَرُوهُمْ ۚ وَإِن تَعْفُوا وَتَصْفَحُوا وَتَغْفِرُوا فَإِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ ۝١٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 14
Eyin ti e gbagbo ni ododo, dajudaju ota wa fun yin ninu awon iyawo yin ati awon omo yin. Nitori naa, e sora fun won. Ti e ba samojukuro, ti e safojufo, ti e si saforijin (fun won), dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun
إِنَّمَا أَمْوَالُكُمْ وَأَوْلَادُكُمْ فِتْنَةٌ ۚ وَاللَّهُ عِندَهُ أَجْرٌ عَظِيمٌ ۝١٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 15
Ifooro ni awon dukia yin ati awon omo yin. Allahu si ni esan nla wa ni odo Re
فَاتَّقُوا اللَّهَ مَا اسْتَطَعْتُمْ وَاسْمَعُوا وَأَطِيعُوا وَأَنفِقُوا خَيْرًا لِّأَنفُسِكُمْ ۗ وَمَن يُوقَ شُحَّ نَفْسِهِ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ ۝١٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 16
Nitori naa, e beru Allahu bi e ba se lagbara mo. E gbo oro (Allahu), e tele e, ki e si nawo (fun esin Re) loore julo fun emi yin. Enikeni ti A ba so nibi ahun ati okanjua inu emi re, awon wonyen, awon ni olujere
إِن تُقْرِضُوا اللَّهَ قَرْضًا حَسَنًا يُضَاعِفْهُ لَكُمْ وَيَغْفِرْ لَكُمْ ۚ وَاللَّهُ شَكُورٌ حَلِيمٌ ۝١٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 17
Ti e ba ya Allahu ni dukia t’o dara, O maa sadipele re fun yin. O si maa forijin yin. Allahu si ni Olumoore, Alafarada
عَالِمُ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ ۝١٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 18
Onimo-ikoko ati gbangba, Alagbara, Ologbon
← 63 At-Taghabun (64/114) 65 →
Kika Surah At-Taghabun ni Yorùbá – Itumọ ati Ohun

64التغابن At-Taghabun 📚 18 Ẹsẹ مدنية

Ẹsẹ kọọkan – Surah At-Taghabun — 18 Ẹsẹ




Al-Kur'an


Tuesday, August 18, 2026

Don't forget us in your sincere prayers