La sourate Az-Zukhruf en Yoruba
حم(1) Ha mim |
(Allahu) fi Tira t’o yanju oro eda bura |
إِنَّا جَعَلْنَاهُ قُرْآنًا عَرَبِيًّا لَّعَلَّكُمْ تَعْقِلُونَ(3) Dajudaju Awa so o ni al-Ƙur’an. (A si so o kale ni) ede Larubawa nitori ki e le se laakaye |
وَإِنَّهُ فِي أُمِّ الْكِتَابِ لَدَيْنَا لَعَلِيٌّ حَكِيمٌ(4) Ati pe dajudaju ninu Tira Ipile t’o wa lodo Wa, al-Ƙur’an ga, o kun fun ogbon |
أَفَنَضْرِبُ عَنكُمُ الذِّكْرَ صَفْحًا أَن كُنتُمْ قَوْمًا مُّسْرِفِينَ(5) Se ki A ka Tira Iranti (al-Ƙur’an) kuro nile fun yin, ki A maa wo yin niran nitori pe e je ijo alakoyo |
Meloo meloo ninu awon Anabi ti A ti ran si awon eni akoko |
وَمَا يَأْتِيهِم مِّن نَّبِيٍّ إِلَّا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ(7) Ko si Anabi kan ti o wa ba won ayafi ki won maa fi se yeye |
فَأَهْلَكْنَا أَشَدَّ مِنْهُم بَطْشًا وَمَضَىٰ مَثَلُ الْأَوَّلِينَ(8) Nitori naa, A ti pa awon t’o ni agbara ju awon (wonyi) re. Apejuwe (iparun) awon eni akoko si ti siwaju |
Ti o ba bi won leere pe: "Ta ni O da awon sanmo ati ile?", dajudaju won a wi pe: "Eni t’o da won ni Alagbara, Onimo |
الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الْأَرْضَ مَهْدًا وَجَعَلَ لَكُمْ فِيهَا سُبُلًا لَّعَلَّكُمْ تَهْتَدُونَ(10) Eni ti O se ile ni ite fun yin. O si fi awon oju ona sinu re fun yin nitori ki e le mona |
Eni ti O n so omi kale lati sanmo niwon-niwon. O si n fi so oku ile di aye ile. Bayen naa ni won yoo se mu yin jade |
وَالَّذِي خَلَقَ الْأَزْوَاجَ كُلَّهَا وَجَعَلَ لَكُم مِّنَ الْفُلْكِ وَالْأَنْعَامِ مَا تَرْكَبُونَ(12) Eni ti O seda gbogbo nnkan ni orisirisi. O si se nnkan ti e n gun fun yin lati ara awon oko oju-omi ati awon eran-osin |
Nitori ki e le jokoo daadaa seyin re, leyin naa ki e le se iranti idera Oluwa yin nigba ti e ba jokoo daadaa tan sori re, ki e si so pe: "Mimo ni fun Eni ti O ro eyi fun wa, ki i se pe a je alagbara lori re |
Ati pe dajudaju odo Oluwa wa ni awa yoo pada si |
وَجَعَلُوا لَهُ مِنْ عِبَادِهِ جُزْءًا ۚ إِنَّ الْإِنسَانَ لَكَفُورٌ مُّبِينٌ(15) Won fi ipin kan ninu awon erusin (Allahu) ti si odo Re (ni ti omo bibi). Dajudaju eniyan ni alaimoore ponnbele |
أَمِ اتَّخَذَ مِمَّا يَخْلُقُ بَنَاتٍ وَأَصْفَاكُم بِالْبَنِينَ(16) Tabi (eyin n wi pe): "O mu ninu nnkan ti O da ni omobinrin (funra Re). O si fi awon omokunrin sa eyin lesa |
Nigba ti won ba fun eni kan ninu won ni iro idunnu ohun ti o fi se apeere fun Ajoke-aye (pe onitoun bi omobinrin), oju re maa sokunkun wa. O si maa kun fun ibanuje |
أَوَمَن يُنَشَّأُ فِي الْحِلْيَةِ وَهُوَ فِي الْخِصَامِ غَيْرُ مُبِينٍ(18) Se eni ti won n to ninu oso (ti o n to oso mora), ti ko si le bo si gbangba nibi ija (ni e n pe ni omo Ajoke-aye) |
Awon molaika, awon t’o je erusin Ajoke-aye, won tun so won di omobinrin! Se won foju ri iseda won ni? Won maa se akosile ohun ti won foju ri. Won si maa bi won leere (nipa re) |
Won tun wi pe: "Ti Ajoke-aye ba fe, awa iba ti josin fun won." Ko si imo kan fun won nipa iyen. Won ko si je kini kan bi ko se pe won n paro |
أَمْ آتَيْنَاهُمْ كِتَابًا مِّن قَبْلِهِ فَهُم بِهِ مُسْتَمْسِكُونَ(21) Tabi A ti fun won ni Tira kan siwaju al-Ƙur’an, ti won n lo ni eri |
بَلْ قَالُوا إِنَّا وَجَدْنَا آبَاءَنَا عَلَىٰ أُمَّةٍ وَإِنَّا عَلَىٰ آثَارِهِم مُّهْتَدُونَ(22) Rara. Won wi pe: "Dajudaju awa ba awon baba wa lori esin kan. Dajudaju awa si ni olumona lori oripa won |
Bakan naa, Awa ko ran olukilo kan si ilu kan siwaju re, ayafi ki awon onigbedemuke ilu naa wi pe: "Dajudaju awa ba awon baba wa lori esin kan. Dajudaju awa si ni olutele won lori oripa won |
(Olukilo) si so pe: "Nje emi ko ti mu wa fun yin ohun ti o je imona julo si ohun ti e ba awon baba yin lori re?" Won wi pe: "Dajudaju awa je alaigbagbo ninu ohun ti Won fi ran yin nise |
فَانتَقَمْنَا مِنْهُمْ ۖ فَانظُرْ كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُكَذِّبِينَ(25) Nitori naa, A gbesan lara won. Wo bi ikangun awon olupe-ododo-niro ti ri |
وَإِذْ قَالَ إِبْرَاهِيمُ لِأَبِيهِ وَقَوْمِهِ إِنَّنِي بَرَاءٌ مِّمَّا تَعْبُدُونَ(26) (Ranti) nigba ti (Anabi) ’Ibrohim so fun baba re ati awon eniyan re pe: "Dajudaju emi yowo yose kuro ninu ohun ti e n josin fun |
Afi Eni ti O seda mi. Dajudaju Oun l’O maa fi ona taara mo mi |
وَجَعَلَهَا كَلِمَةً بَاقِيَةً فِي عَقِبِهِ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ(28) Allahu si se e ni oro kan t’o maa wa titi laelae laaarin awon aromodomo re nitori ki won le seri pada (sibi ododo) |
بَلْ مَتَّعْتُ هَٰؤُلَاءِ وَآبَاءَهُمْ حَتَّىٰ جَاءَهُمُ الْحَقُّ وَرَسُولٌ مُّبِينٌ(29) Sugbon Mo fun awon wonyi ati awon baba won ni igbadun aye titi ododo ati Ojise ponnbele fi de ba won |
وَلَمَّا جَاءَهُمُ الْحَقُّ قَالُوا هَٰذَا سِحْرٌ وَإِنَّا بِهِ كَافِرُونَ(30) Nigba ti ododo de ba won, won wi pe: "Idan ni eyi; dajudaju awa ko si nii gba a gbo |
وَقَالُوا لَوْلَا نُزِّلَ هَٰذَا الْقُرْآنُ عَلَىٰ رَجُلٍ مِّنَ الْقَرْيَتَيْنِ عَظِيمٍ(31) Won tun wi pe: "Ki ni ko je ki Won so al-Ƙur’an yii kale fun okunrin pataki kan ninu awon ilu mejeeji |
Se awon ni won maa pin ike Oluwa re ni? Awa l’A pin nnkan isemi won fun won ninu igbesi aye. A si fi awon ipo giga gbe apa kan won ga ju apa kan lo nitori ki apa kan won le maa sise fun apa kan. Ike Oluwa re si loore julo si ohun ti won n ko jo |
Ati pe ti ki i ba se pe awon eniyan maa je ijo kan soso (lori aigbagbo ni), A iba se awon orule ati awon akaba ti won yoo fi maa gunke ninu ile ni fadaka fun eni t’o n sai gbagbo ninu Ajoke-aye |
وَلِبُيُوتِهِمْ أَبْوَابًا وَسُرُرًا عَلَيْهَا يَتَّكِئُونَ(34) (A iba tun se) awon enu ona ile won ati awon ibusun ti won yoo maa rogboku le lori (ni fadaka) |
ati goolu. Gbogbo nnkan wonyi ko je nnkan kan bi ko se igbadun isemi aye lasan. (Ogba Idera) Orun si wa ni odo Oluwa re fun awon oluberu (Allahu) |
وَمَن يَعْشُ عَن ذِكْرِ الرَّحْمَٰنِ نُقَيِّضْ لَهُ شَيْطَانًا فَهُوَ لَهُ قَرِينٌ(36) Enikeni ti o ba gbunri kuro nibi iranti Ajoke-aye, A maa yan esu kan fun un. Oun si ni alabaarin re |
وَإِنَّهُمْ لَيَصُدُّونَهُمْ عَنِ السَّبِيلِ وَيَحْسَبُونَ أَنَّهُم مُّهْتَدُونَ(37) Dajudaju awon esu naa yoo maa seri won kuro loju ona (esin Allahu). Won yo si maa lero pe dajudaju awon ni olumona |
Titi di igba ti o fi maa wa ba Wa, o si maa wi pe: "Haa! Ki o si je pe (itakete bi) itakete ibuyo-oorun ati ibuwo re si wa laaarin emi ati iwo (esu alabaarin yii, iba dara); alabaarin buruku si ni |
وَلَن يَنفَعَكُمُ الْيَوْمَ إِذ ظَّلَمْتُمْ أَنَّكُمْ فِي الْعَذَابِ مُشْتَرِكُونَ(39) (Abamo yin) ko nii se yin ni anfaani ni Oni nigba ti e ti sabosi. (Ati pe) dajudaju eyin (ati orisa yin) ni akegbe ninu iya |
أَفَأَنتَ تُسْمِعُ الصُّمَّ أَوْ تَهْدِي الْعُمْيَ وَمَن كَانَ فِي ضَلَالٍ مُّبِينٍ(40) Se iwo l’o maa fun awon aditi ni oro gbo tabi o maa fun awon afoju ni imona ati eni ti o wa ninu isina ponnbele |
فَإِمَّا نَذْهَبَنَّ بِكَ فَإِنَّا مِنْهُم مُّنتَقِمُونَ(41) Nitori naa, o see se ki A ti mu o kuro (lori ile aye siwaju asiko iya won), dajudaju Awa yoo gbesan (iya) lara won |
أَوْ نُرِيَنَّكَ الَّذِي وَعَدْنَاهُمْ فَإِنَّا عَلَيْهِم مُّقْتَدِرُونَ(42) Tabi ki A fi ohun ti A se ni ileri fun won han o, dajudaju Awa je Alagbara lori won |
فَاسْتَمْسِكْ بِالَّذِي أُوحِيَ إِلَيْكَ ۖ إِنَّكَ عَلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ(43) Nitori naa, di ohun ti A fi ranse si o mu sinsin. Dajudaju iwo wa loju ona taara (’Islam) |
وَإِنَّهُ لَذِكْرٌ لَّكَ وَلِقَوْمِكَ ۖ وَسَوْفَ تُسْأَلُونَ(44) Dajudaju al-Ƙur’an ni tira iranti fun iwo ati ijo re. Laipe Won maa bi yin leere (nipa re) |
Beere wo lowo awon ti A ran nise siwaju re ninu awon Ojise Wa (pe): "Nje A so awon kan di olohun ti won yoo maa josin fun leyin Ajoke-aye bi |
A kuku fi awon ami Wa ran (Anabi) Musa nise si Fir‘aon ati awon ijoye re. O si so pe: "Dajudaju emi ni Ojise Oluwa gbogbo eda |
فَلَمَّا جَاءَهُم بِآيَاتِنَا إِذَا هُم مِّنْهَا يَضْحَكُونَ(47) Sugbon nigba ti o mu awon ami Wa wa ba won, nse ni won n fi awon ami naa rerin-in nigba naa |
A o si nii fi ami kan han won ayafi ki o tobi ju iru re (t’o siwaju). A si fi iya je won nitori ki won le seri pada (sibi ododo) |
وَقَالُوا يَا أَيُّهَ السَّاحِرُ ادْعُ لَنَا رَبَّكَ بِمَا عَهِدَ عِندَكَ إِنَّنَا لَمُهْتَدُونَ(49) Won si wi pe: "Iwo opidan, pe Oluwa re fun wa nitori adehun ti O se pelu re. Dajudaju awa maa tele imona Re |
فَلَمَّا كَشَفْنَا عَنْهُمُ الْعَذَابَ إِذَا هُمْ يَنكُثُونَ(50) Sugbon nigba ti A mu iya kuro fun won, nigba naa ni won tun n ye adehun |
Fir‘aon si pepe laaarin awon eniyan re, o wi pe: "Eyin eniyan mi, se temi ko ni ijoba Misro ati awon odo wonyi t’o n san nisale (odo) mi? Se e o riran ni |
أَمْ أَنَا خَيْرٌ مِّنْ هَٰذَا الَّذِي هُوَ مَهِينٌ وَلَا يَكَادُ يُبِينُ(52) Tabi se emi ko loore julo si eyi ti o je ole yepere, ti o fee ma le da oro so yanju |
فَلَوْلَا أُلْقِيَ عَلَيْهِ أَسْوِرَةٌ مِّن ذَهَبٍ أَوْ جَاءَ مَعَهُ الْمَلَائِكَةُ مُقْتَرِنِينَ(53) Ki ni ko je ki Won fun un ni awon egba-owo goolu tabi (ki ni ko je ki) awon molaika wa pelu re, ki won je alabaarin (ti won yoo maa jerii re) |
فَاسْتَخَفَّ قَوْمَهُ فَأَطَاعُوهُ ۚ إِنَّهُمْ كَانُوا قَوْمًا فَاسِقِينَ(54) Nitori naa, o so awon eniyan re dope. Won si tele e. Dajudaju won je ijo obileje |
فَلَمَّا آسَفُونَا انتَقَمْنَا مِنْهُمْ فَأَغْرَقْنَاهُمْ أَجْمَعِينَ(55) Nigba ti won wa ibinu Wa, A gba esan (iya) lara won. Nitori naa, A te gbogbo won ri (sinu agbami odo) |
A si se won ni ijo asiwaju (ninu iparun) ati apeere (feyikogbon) fun awon eni ikeyin |
۞ وَلَمَّا ضُرِبَ ابْنُ مَرْيَمَ مَثَلًا إِذَا قَوْمُكَ مِنْهُ يَصِدُّونَ(57) Nigba ti awon osebo fi omo Moryam se apeere (fun orisa won), nigba naa ni awon eniyan re ba n fi (apeere naa) rerin-in |
Won si wi pe: "Se awon orisa wa l’o loore julo ni tabi oun? Won ko wule fi sapeere fun o bi ko se (fun) atako. Ani se, ijo oniyanjija ni won |
إِنْ هُوَ إِلَّا عَبْدٌ أَنْعَمْنَا عَلَيْهِ وَجَعَلْنَاهُ مَثَلًا لِّبَنِي إِسْرَائِيلَ(59) Ki ni oun bi ko se erusin kan ti A se idera fun. A si se e ni apeere rere fun awon omo ’Isro’il |
وَلَوْ نَشَاءُ لَجَعَلْنَا مِنكُم مَّلَائِكَةً فِي الْأَرْضِ يَخْلُفُونَ(60) Ti o ba je pe A ba fe, A iba maa fi awon molaika ropo yin lori ile |
وَإِنَّهُ لَعِلْمٌ لِّلسَّاعَةِ فَلَا تَمْتَرُنَّ بِهَا وَاتَّبِعُونِ ۚ هَٰذَا صِرَاطٌ مُّسْتَقِيمٌ(61) Dajudaju oun ni imo (tabi ami fun isunmo) Akoko naa. Nitori naa, e o gbodo seyemeji nipa re. Ki e si tele mi. Eyi ni ona taara |
وَلَا يَصُدَّنَّكُمُ الشَّيْطَانُ ۖ إِنَّهُ لَكُمْ عَدُوٌّ مُّبِينٌ(62) E ma se je ki Esu se yin lori; dajudaju oun ni ota ponnbele fun yin |
Nigba ti (Anabi) ‘Isa de pelu awon eri t’o yanju, o so pe: "Dajudaju mo de wa ba yin pelu ijinle ogbon. (Mo si de) nitori ki ng le se alaye apa kan eyi ti e n yapa enu nipa re fun yin. Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi |
إِنَّ اللَّهَ هُوَ رَبِّي وَرَبُّكُمْ فَاعْبُدُوهُ ۚ هَٰذَا صِرَاطٌ مُّسْتَقِيمٌ(64) Dajudaju Allahu ni Oluwa mi ati Oluwa yin. Nitori naa, e josin fun Un. Eyi ni ona taara |
فَاخْتَلَفَ الْأَحْزَابُ مِن بَيْنِهِمْ ۖ فَوَيْلٌ لِّلَّذِينَ ظَلَمُوا مِنْ عَذَابِ يَوْمٍ أَلِيمٍ(65) Awon ijo (re) si yapa (esin ’Islam) laaarin ara won. Nitori naa, egbe ni fun awon t’o sabosi ni ojo iya eleta-elero |
هَلْ يَنظُرُونَ إِلَّا السَّاعَةَ أَن تَأْتِيَهُم بَغْتَةً وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ(66) Se won n reti kini kan bi ko se Akoko naa; ti o maa de ba won ni ojiji; won ko si nii fura |
الْأَخِلَّاءُ يَوْمَئِذٍ بَعْضُهُمْ لِبَعْضٍ عَدُوٌّ إِلَّا الْمُتَّقِينَ(67) Awon ore ayo ni ojo yen, apa kan won yoo je ota fun apa kan ayafi awon oluberu (Allahu) |
يَا عِبَادِ لَا خَوْفٌ عَلَيْكُمُ الْيَوْمَ وَلَا أَنتُمْ تَحْزَنُونَ(68) Eyin erusin Mi, ko si iberu fun yin ni oni. Eyin ko si nii banuje |
(Awon ni) awon t’o gbagbo ninu awon ayah Wa, ti won si je musulumi (olujuwo-juse sile fun Allahu) |
ادْخُلُوا الْجَنَّةَ أَنتُمْ وَأَزْوَاجُكُمْ تُحْبَرُونَ(70) E wo inu Ogba Idera, eyin ati awon iyawo yin; ki e maa dunnu |
Won yoo maa gbe awon awo goolu ati awon ife imumi kaa kiri odo won. Ohun ti emi n fe ati (ohun ti) oju yoo maa dunnu si wa ninu re. Olusegbere si ni yin ninu re |
وَتِلْكَ الْجَنَّةُ الَّتِي أُورِثْتُمُوهَا بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ(72) Iyen ni Ogba Idera ti A jogun re fun yin nitori ohun ti e n se nise |
Eso pupo wa fun yin ninu re. Eyin yo si maa je ninu re |
Dajudaju awon elese ni olusegbere ninu iya ina Jahanamo |
A o nii gbe e fuye fun won. Won yo si soreti nu ninu Ina |
A o sabosi si won, sugbon awon ni won je alabosi |
وَنَادَوْا يَا مَالِكُ لِيَقْضِ عَلَيْنَا رَبُّكَ ۖ قَالَ إِنَّكُم مَّاكِثُونَ(77) Won yoo pe (molaika kan) pe: "Molik (eso Ina), je ki Oluwa re pa wa raurau." (Molik) yoo so pe: "Dajudaju eyin yoo maa gbe inu re ni |
لَقَدْ جِئْنَاكُم بِالْحَقِّ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَكُمْ لِلْحَقِّ كَارِهُونَ(78) Dajudaju A ti mu ododo wa ba yin, sugbon opolopo yin korira ododo |
Tabi awon (alaigbagbo) ti pinnu oro kan ni? Dajudaju Awa naa n pinnu oro |
Tabi won n lero pe Awa ko gbo oro asiri won ati oro ikoko won? Rara (A n gbo); awon Ojise Wa wa ni odo won, ti won n se akosile (oro won) |
قُلْ إِن كَانَ لِلرَّحْمَٰنِ وَلَدٌ فَأَنَا أَوَّلُ الْعَابِدِينَ(81) So pe: "Ko si omo kan fun Ajoke aye. Nitori naa, emi ni eni akoko ninu awon olujosin (fun Allahu ni asiko temi) |
سُبْحَانَ رَبِّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ رَبِّ الْعَرْشِ عَمَّا يَصِفُونَ(82) Mimo ni fun Oluwa awon sanmo ati ile, Oluwa Ite-ola tayo iro ti won n pa (mo On) |
فَذَرْهُمْ يَخُوضُوا وَيَلْعَبُوا حَتَّىٰ يُلَاقُوا يَوْمَهُمُ الَّذِي يُوعَدُونَ(83) Nitori naa, fi won sile ki won maa so isokuso (won), ki won si maa sere won lo titi won yoo fi pade ojo won, ti A n se ni adehun fun won |
وَهُوَ الَّذِي فِي السَّمَاءِ إِلَٰهٌ وَفِي الْأَرْضِ إِلَٰهٌ ۚ وَهُوَ الْحَكِيمُ الْعَلِيمُ(84) (Allahu) Oun ni Olohun Eni ti ijosin to si ninu sanmo. Oun naa si ni Olohun Eni ti ijosin to si lori ile. Oun ni Ologbon, Onimo |
Ibukun ni fun Eni ti O ni ijoba awon sanmo ati ile ati ohunkohun t’o wa laaarin mejeeji. Odo Re si ni imo Akoko naa wa. Odo Re si ni won maa da yin pada si |
Awon ti won n pe leyin Re, won ko kapa isipe ayafi eni ti o ba jerii si ododo (kalmotus-sahaadah), ti won si nimo (re) |
وَلَئِن سَأَلْتَهُم مَّنْ خَلَقَهُمْ لَيَقُولُنَّ اللَّهُ ۖ فَأَنَّىٰ يُؤْفَكُونَ(87) Ati pe ti o ba bi won leere pe: "Ta ni O da won?", dajudaju won a wi pe: "Allahu ni." Nitori naa, bawo ni won se n seri won kuro nibi ododo |
وَقِيلِهِ يَا رَبِّ إِنَّ هَٰؤُلَاءِ قَوْمٌ لَّا يُؤْمِنُونَ(88) Oro (ti Anabi n so fun Allahu ni pe): "Oluwa Mi, dajudaju awon wonyi ni ijo ti ko gbagbo.” |
فَاصْفَحْ عَنْهُمْ وَقُلْ سَلَامٌ ۚ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ(89) Nitori naa, samoju kuro fun won, ki o si so pe: "Alaafia!" Laipe won maa mo |
Plus de sourates en Yoruba :
Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :
Téléchargez le fichier mp3 de la sourate Az-Zukhruf : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate Az-Zukhruf complète en haute qualité.
Ahmed Al Ajmy Bandar Balila Khalid Al Jalil Saad Al Ghamdi Saud Al Shuraim Abdul Basit Abdul Rashid Sufi Abdullah Basfar Abdullah Al Juhani Fares Abbad Maher Al Muaiqly Al Minshawi Al Hosary Mishari Al-afasi Yasser Al Dosari
Donnez-nous une invitation valide